Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ẹ Jẹ́ Onígboyà Àti Alágbára!’

‘Ẹ Jẹ́ Onígboyà Àti Alágbára!’

‘Ẹ Jẹ́ Onígboyà Àti Alágbára!’

“Ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”—JÒHÁNÙ 16:33.

1. Nítorí àwọn ọ̀tá alágbára tó ń dúró de àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Kénáánì, ìṣírí wo ni wọ́n rí gbà?

 NÍGBÀ tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Odò Jọ́dánì kọjá sínú Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má fòyà tàbí kí o gbọ̀n rìrì níwájú wọn, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ẹni tí ń bá ọ lọ.” Mósè tún pe Jóṣúà, ẹni tá a ti yàn láti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Kénáánì, ó sì tún ìmọ̀ràn náà sọ fún un pé kí ó jẹ́ onígboyà. (Diutarónómì 31:6, 7) Nígbà tó yá, Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún Jóṣúà pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára . . . Kìkì pé kí o jẹ́ onígboyà àti alágbára gidigidi.” (Jóṣúà 1:6, 7, 9) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn bágbà mu gan-an ni. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á nílò ìgboyà láti kojú àwọn ọ̀tá alágbára tó ń gbé ní ìhà kejì odò Jọ́dánì.

2. Irú ipò wo la bá ara wa lónìí, kí la sì nílò?

2 Lónìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa tó kọjá sínú ayé tuntun tá a ṣèlérí, wọ́n sì gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà bíi ti Jóṣúà. (2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 7:14) Àmọ́ o, ipò tiwa wá yàtọ̀ sí ti Jóṣúà. Idà àti ọ̀kọ̀ ni Jóṣúà fi jagun tiẹ̀. Ogun tẹ̀mí làwa ń jà, a ò sì jẹ́ fọwọ́ kan ohun ìjà tara láé. (Aísáyà 2:2-4; Éfésù 6:11-17) Síwájú sí i, ọ̀pọ̀ ogun gbígbóná janjan ni Jóṣúà tún jà lẹ́yìn tó ti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Àmọ́ ìsinsìnyí làwa máa ja ogun tó gbóná jù lọ, ìyẹn ká tó wọnú ayé tuntun. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ipò bíi mélòó kan tó máa gba pé ká jẹ́ onígboyà yẹ̀ wò.

Kí Nìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Làkàkà?

3. Kí ni Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa olórí alátakò wa?

3 Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “A mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ ìdí pàtàkì táwọn Kristẹni fi ní láti làkàkà kí wọ́n bàa lè pa ìgbàgbọ́ wọn mọ́. Bí Kristẹni kan bá pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, ó ti borí Sátánì Èṣù dé àyè kan nìyẹn. Ìdí rèé tí Sátánì fi ń hùwà bíi “kìnnìún tí ń ké ramúramù,” tó ń wá ọ̀nà láti dẹ́rù ba àwọn Kristẹni olóòótọ́ kó sì pa wọ́n jẹ. (1 Pétérù 5:8) Ká sòótọ́, ogun gan-an ló ń bá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn jà o. (Ìṣípayá 12:17) Àwọn èèyàn tó dìídì ń ṣe ohun tó fẹ́ àtàwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìmọ̀ ló ń lò nínú ogun yìí. Ó gba ìgboyà láti kojú Sátánì àti gbogbo àwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀.

4. Ìkìlọ̀ wo ni Jésù ṣe, àmọ́ irú ànímọ́ wo làwọn Kristẹni tòótọ́ ti fi hàn?

4 Níwọ̀n bí Jésù ti mọ̀ pé torí tọrùn ni Sátánì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ á fi kẹ̀yìn sí ìhìn rere náà, Ó kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́, wọn yóò sì pa yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” (Mátíù 24:9) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nímùúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n sì tún ń nímùúṣẹ lónìí. Àní, inúnibíni tó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní ti jẹ́ èyí tí irú rẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rí. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń jẹ́ onígboyà láwọn àkókò líle koko bẹ́ẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé “wíwárìrì nítorí ènìyàn ni ohun tí ń dẹ ìdẹkùn,” wọn ò sì fẹ́ kó sínú ìdẹkùn.—Òwe 29:25.

5, 6. (a) Àwọn ipò wo ló lè béèrè pé ká jẹ́ onígboyà? (b) Kí làwọn Kristẹni olóòótọ́ máa ń ṣe nígbà tá a bá dán bí wọ́n ṣe nígboyà tó wò?

5 Àwọn ìpèníjà mìíràn wà tó tún yàtọ̀ sí inúnibíni tó sì ń béèrè pé ká nígboyà. Ìṣòro ńlá ló jẹ́ fáwọn kan láti sọ ìhìn rere náà fún ẹni tí wọn ò mọ̀ rí. A máa ń dán báwọn ọmọ ilé ìwé kan ṣe nígboyà tó wò nígbà tá a bá ní kí wọ́n wá ka ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè tàbí kí wọ́n kí àsíá. Nígbà tó sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ni irú ẹ̀jẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ Kristẹni ti fi tìgboyàtìgboyà pinnu pé ohun tínú Ọlọ́run dùn sí làwọn á ṣe, ìwà rere wọn yìí sì ń múnú ẹni dùn.

6 A tún nílò ìgboyà nígbà táwọn alátakò bá lọ kó sáwọn oníròyìn lórí táwọn yẹn wá ń sọ ìsọkúsọ nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, tàbí nígbà tí wọ́n bá gbìyànjú láti dá ìjọsìn tòótọ́ dúró nípa fífi “àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n.” (Sáàmù 94:20) Bí àpẹẹrẹ, báwo ló ṣe yẹ kó rí lára wa nígbà tí ìwé ìròyìn, rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n bá gbé ìròyìn tó lè ṣi àwọn èèyàn lọ́nà jáde nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí tí wọ́n parọ́ funfun mọ́ wa? Ṣé ó yẹ kíyẹn yà wá lẹ́nu? Rárá o. A mọ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ á ṣẹlẹ̀. (Sáàmù 109:2) Kò sì ní yà wá lẹ́nu nígbà táwọn kan tó gbọ́ irú ìròyìn èké yìí bá gbà wọ́n gbọ́, nítorí pé “ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀.” (Òwe 14:15) Síbẹ̀, àwọn Kristẹni adúróṣinṣin kì í kàn án gba gbogbo nǹkan táwọn èèyàn bá sọ nípa àwọn arákùnrin wọn gbọ́, wọn kì í sì í jẹ́ kí ìsọkúsọ táwọn èèyàn ń sọ kiri mú kí wọ́n máa pa ìpàdé jẹ, tàbí kí wọ́n má fi bẹ́ẹ̀ lọ sóde ẹ̀rí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, tàbí kí ìgbàgbọ́ wọn bẹ̀rẹ̀ sí yìnrìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n “ń dámọ̀ràn ara [wọn] gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run . . . nípasẹ̀ ògo àti àbùkù, nípasẹ̀ ìròyìn búburú àti ìròyìn rere; gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́tàn [lójú àwọn alátakò], síbẹ̀ [ní ti gidi] a jẹ́ olùsọ òtítọ́.”—2 Kọ́ríńtì 6:4, 8.

7. Àwọn ìbéèrè wíwọnilọ́kàn wo la lè bi ara wa?

7 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ lẹ́tà sí Tímótì, ó sọ pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára . . . Nítorí náà, má tijú ẹ̀rí nípa Olúwa wa.” (2 Tímótì 1:7, 8; Máàkù 8:38) Lẹ́yìn tá a ti ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, a lè bi ara wa léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ ohun ti mo gbà gbọ́ máa ń tì mí lójú, àbí mo nígboyà? Níbi iṣẹ́ mi (tàbí nílé ìwé), ǹjẹ́ mo jẹ́ káwọn ẹlẹgbẹ́ mi mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, àbí mi ò jẹ́ sọ fáwọn èèyàn bí mo ṣe jẹ́? Ṣé yíyàtọ̀ sáwọn yòókù máa ń tì mí lójú, àbí inú mi máa ń dùn pé mo yàtọ̀ nítorí àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà?’ Tí ẹ̀rù bá ń ba ẹnì kan láti wàásù ìhìn rere náà tàbí nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò fẹ́ràn ohun tó gbà gbọ́, kírú ẹni bẹ́ẹ̀ rántí ohun tí Jèhófà sọ fun Jóṣúà pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára.” Má ṣe gbà gbé pé kì í ṣe èrò àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí èrò àwọn ọmọ ilé ìwé ẹlẹgbẹ́ wa ló ṣe pàtàkì bí kò ṣe ti Jèhófà àti Jésù Kristi.—Gálátíà 1:10.

Bá A Ṣe Lè Di Onígboyà

8, 9. (a) Báwo la ṣe dán bí ìgboyà àwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe tó wò ní àkókò kan báyìí? (b) Kí ni Pétérù àti Jòhánù ṣe nígbà tí wọ́n halẹ̀ mọ́ wọn, kí sì ni àwọn ìrírí tí àwọn àtàwọn arákùnrin wọn ní?

8 Báwo la ṣe lè nírú ìgboyà tó máa mú ká jẹ́ olùṣòtítọ́ láwọn àkókò lílekoko yìí? Ó dára, báwo làwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe di onígboyà? Ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù sọ fún Pétérù àti Jòhánù pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù lórúkọ Jésù mọ́. Àwọn àpọ́sítélì náà ò yé wàásù o, àwọn èèyàn halẹ̀ mọ́ wọn títí àmọ́ wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ nígbà tó yá. Kíá ni wọ́n padà lọ bá àwọn ará wọn, gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà pà pọ̀ pé: “Jèhófà, fiyè sí àwọn ìhalẹ̀mọ́ni wọn, kí o sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹrú rẹ láti máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo rárá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.” (Ìṣe 4:13-29) Jèhófà dáhùn àdúrà wọn, ó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún wọn lókun, wọ́n sì fi ‘ẹ̀kọ́ wọn kún Jerúsálẹ́mù,’ gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣáájú Júù ṣe wá sọ nígbà tó yá.—Ìṣe 5:28.

9 Ẹ jẹ́ ká ṣàtúpalẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn. Nígbà táwọn aṣáájú Júù ń dáná ìjàngbọ̀n fáwọn ọmọ ẹ̀yìn, wọn ò tìtorí wàhálà yìí dáwọ́ wíwàásù dúró. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn gbàdúrà pé káwọn lè nígboyà láti máa wàásù nìṣó. Lẹ́yìn náà, wọ́n sapá láti ṣe ohun tí wọ́n gbàdúrà fún, Jèhófà sì fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún wọn lókun. Ìrírí wọn yìí fi hàn pé ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ nípa ọ̀ràn mìíràn láwọn ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn kan àwọn Kristẹni tó ń kojú inúnibíni. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:13.

10. Báwo ni ìrírí Jeremáyà ṣe lè ran àwọn tó jẹ́ onítìjú ẹ̀dá lọ́wọ́?

10 Àmọ́, bí ẹnì kan bá jẹ́ onítìjú ẹ̀dá ńkọ́? Ṣé ó ṣì lè sin Jèhófà tìgboyàtìgboyà lákòókò inúnibíni? Bẹ́ẹ̀ ni o! Rántí ohun tí Jeremáyà sọ nígbà tí Jèhófà yàn án gẹ́gẹ́ bíi wòlíì. Ọ̀dọ́kùnrin náà sọ pé: “Ọmọdé lásán ni mí.” Ohun tó sọ yìí fi hàn pé ó ronú pé òun ò tóótun. Síbẹ̀, Jèhófà fún un níṣìírí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Má ṣe wí pé, ‘ọmọdé lásán ni mí.’ Ṣùgbọ́n ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí èmi yóò rán ọ lọ ni kí o lọ; ohun gbogbo tí mo bá sì pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ. Má fòyà nítorí ojú wọn, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ láti dá ọ nídè.’” (Jeremáyà 1:6-10) Jeremáyà ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà, àbájáde rẹ̀ sì ni pé ní agbára Jèhófà ó borí lílọ́ tó ń lọ́ tìkọ̀ láti wàásù, ó sì wá di ẹlẹ́rìí tó nígboyà gan-an ní Ísírẹ́lì.

11. Kí ló ń ran àwọn Kristẹni òde òní lọ́wọ́ láti dà bí Jeremáyà?

11 Iṣẹ́ tá a gbé lé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lọ́wọ́ lónìí dà bíi ti Jeremáyà, pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti àwọn “àgùntàn mìíràn,” wọ́n ń bá a lọ láti polongo àwọn ète Jèhófà láìfi ìdágunlá, ìfiniṣẹlẹ́yà àti inúnibíni àwọn èèyàn pè. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Jeremáyà pé: “Má fòyà” ló ń fún wọn níṣìírí. Wọn ò jẹ́ gbàgbé pé Ọlọ́run ló fún àwọn níṣẹ́ náà àti pé ìhìn rẹ̀ làwọn ń wàásù.—2 Kọ́ríńtì 2:17.

Àpẹẹrẹ Ìgboyà Tó Yẹ Ká Fara Wé

12. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni Jésù fi lélẹ̀ lórí ọ̀ràn ìgboyà, báwo ló sì ṣe gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú?

12 Ṣíṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onígboyà bíi ti Jeremáyà lè ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe ń sapá láti jẹ́ onígboyà. (Sáàmù 77:12) Bí àpẹẹrẹ, bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ìgboyà rẹ̀ nígbà tí Sátánì dán an wò àti nígbà táwọn aṣáájú Júù gbé àtakò dìde, máa ń wú wa lórí. (Lúùkù 4:1-13; 20:19-47) Agbára tí Jèhófà fún Jésù ni ò jẹ́ kí mìmì kan lè mì ín, ó sì sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kété ṣáájú ikú rẹ̀ pé: “Nínú ayé, ẹ óò máa ní ìpọ́njú, ṣùgbọ́n ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòhánù 16:33; 17:16) Táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, àwọn náà á lè di ajagunṣẹ́gun. (1 Jòhánù 2:6; Ìṣípayá 2:7, 11, 17, 26) Àmọ́ wọn gbọ́dọ̀ “mọ́kànle.”

13. Ọ̀rọ̀ ìṣírí wo ni Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Fílípì?

13 Ní ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn ikú Jésù, wọ́n ju Pọ́ọ̀lù àti Sílà sẹ́wọ̀n ní Fílípì. Nígbà tó ṣe, Pọ́ọ̀lù gba ìjọ àwọn ará Fílípì níyànjú pé kí wọ́n “dúró gbọn-in gbọn-in nínú ẹ̀mí kan, pẹ̀lú ọkàn kan tí ẹ ń làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ fún ìgbàgbọ́ ìhìn rere, tí àwọn tí ó kọjú ìjà sí yín kò sì kó jìnnìjìnnì bá [wọn] lọ́nàkọnà.” Láti fún wọn lókun lórí èyí, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ohun yìí gan-an [àwọn Kristẹni tá a ṣe inúnibíni sí] ni ẹ̀rí ìparun fún wọn [àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wọn], ṣùgbọ́n ti ìgbàlà fún yín; ìtọ́ka yìí sì wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nítorí ẹ̀yin ni a fún ní àǹfààní náà nítorí Kristi, kì í ṣe láti ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú.”—Fílípì 1:27-29.

14. Kí ni ìgboyà tí Pọ́ọ̀lù ní ṣe fún àwọn ará ní Róòmù?

14 Ẹ̀wọ̀n ni Pọ́ọ̀lù tún wà nígbà tó kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Fílípì, àmọ́ Róòmù ló ti ń ṣẹ̀wọ̀n lọ́tẹ̀ yìí. Síbẹ̀, kò dẹ́kun fífi ìgboyà wàásù fáwọn èèyàn. Kí ló wá tìdí èyí jáde? Ó kọ̀wé pé: “Àwọn ìdè mi ti di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi láàárín gbogbo Ẹ̀ṣọ́ Ọba àti gbogbo àwọn yòókù; púpọ̀ jù lọ lára àwọn ará nínú Olúwa, tí wọ́n ní ìgbọ́kànlé nítorí àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi, sì túbọ̀ ń fi ìgboyà púpọ̀ sí i hàn láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù.”—Fílípì 1:13, 14.

15. Ibo la ti lè rí àpẹẹrẹ àtàtà nípa ìgbàgbọ́ èyí tó máa fún ìpinnu wa láti jẹ́ onígboyà lókun?

15 Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ń fún wa níṣìírí. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àpẹẹrẹ àtàtà àwọn Kristẹni òde òní tí wọ́n ti fara da inúnibíni láwọn orílẹ̀-èdè táwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ tàbí àwọn àlùfáà ti ń ṣàkóso. A ti kọ ìtàn ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí sínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! àtàwọn ìwé Yearbook of Jehovah’s Witnesses. Bó o ṣe ń ka àwọn ìrírí wọ̀nyí, máa fi sọ́kàn pé èèyàn ẹlẹ́ran ara bíi tiwa làwọn èèyàn wọ̀nyí; àmọ́ nígbà tí nǹkan le koko fún wọn, Jèhófà fún wọn ní agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá wọ́n sì forí tì í. A lè ní ìdánilójú pé ó máa fún àwa náà nírú agbára bẹ́ẹ̀ tá a bá wà nínú ipò tá a ti nílò rẹ̀.

Ìgboyà Wa Ń Mú Inú Jèhófà Dùn Ó sì Ń Fògo fún Un

16, 17. Báwo la ṣe lè jẹ́ onígboyà lónìí?

16 Tí Kristẹni kan bá dúró gbọn-in bí olóòótọ́ àti olódodo, onígboyà ni irú ẹni bẹ́ẹ̀. Tẹ́nì kan bá sì dúró lọ́nà yìí bí ẹ̀rù tiẹ̀ ń bà á nínú lọ́hùn-ún, a jẹ́ pé ìgboyà irú ẹni bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ tún légbá kan sí i. Ní ti gidi, Kristẹni èyíkéyìí ló lè nígboyà tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló fẹ́ ṣe ìfẹ́ Jèhófà, tó fẹ́ jẹ́ olóòótọ́, tó ń gbára lé Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà, tó sì ń rántí nígbà gbogbo pé àìmọye èèyàn bíi tòun ni Jèhófà ti fún lókun sẹ́yìn. Kò tán síbẹ̀ o, tá a bá fi sọ́kàn pé ìgboyà wa ń mú inú Jèhófà dùn tó sì ń fògo fún un, èyí á jẹ́ ká túbọ̀ pinnu láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀. Àá múra tán láti fara da ìfiniṣẹ̀sín tàbí ìwà àìdáa tó burú jùyẹn pàápàá nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an.—1 Jòhánù 2:5; 4:18.

17 Má ṣe gbàgbé láé pé nígbà tá a bá ń jìyà nítorí ìgbàgbọ́ wa, kò túmọ̀ sí pé a ti ṣe ohun kan tó burú. (1 Pétérù 3:17) Gbígbé tá à ń gbé ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lárugẹ, rere tá à ń ṣe àti bá ò ṣe jẹ́ apá kan ayé ló ń mú ká jìyà. Tìtorí èyí ni àpọ́sítélì Pétérù fi sọ pé: “Bí ẹ bá fara dà á nígbà tí ẹ bá ń ṣe rere, tí ẹ sì ń jìyà, èyí jẹ́ ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” Pétérù tún sọ pé: “Kí àwọn tí ń jìyà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run máa bá a nìṣó ní fífi ọkàn wọn lé Ẹlẹ́dàá olùṣòtítọ́ lọ́wọ́ bí wọ́n ti ń ṣe rere.” (1 Pétérù 2:20; 4:19) Dájúdájú, ìgbàgbọ́ wa ń múnú Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ dùn ó sì ń fògo fún un. Ẹ ò rí i pé ìdí pàtàkì rèé tó fi yẹ ká jẹ́ onígboyà!

Tá A Bá Ń Bá Àwọn Aláṣẹ Sọ̀rọ̀

18, 19. Tá a bá jẹ́ onígboyà níwájú adájọ́, ìhìn wo là ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ fún wọn?

18 Nígbà tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé àwọn èèyàn á ṣenúnibíni sí wọn, ó tún sọ fún wọn pé: “[Àwọn èèyàn] yóò fà yín lé àwọn kóòtù àdúgbò lọ́wọ́, wọn yóò sì nà yín lọ́rẹ́ nínú àwọn sínágọ́gù wọn. Họ́wù, wọn yóò fà yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn àti fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 10:17, 18) Ó gba ìgboyà láti lọ síwájú adájọ́ tàbí aláṣẹ nígbà táwọn èèyàn bá fẹ̀sùn èké kàn wá. Síbẹ̀, nígbà tá a bá fi ìgboyà lo àkókò yìí láti jẹ́rìí fáwọn èèyàn náà, à ń fi àǹfààní tó yọjú nínú àkókò líle koko ṣe ohun pàtàkì kan láṣeyanjú nìyẹn. Lẹ́nu kan, ńṣe là ń sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà nínú Sáàmù Kejì fún àwọn tó ń ṣèdájọ́ wa. Ó sọ pé: “Wàyí o, ẹ̀yin ọba, ẹ lo ìjìnlẹ̀ òye; ẹ gba ìtọ́sọ́nà, ẹ̀yin onídàájọ́ ilẹ̀ ayé. Ẹ fi ìbẹ̀rù sin Jèhófà.” (Sáàmù 2:10, 11) Ọ̀pọ̀ ìgbà táwọn kan ti fẹ̀sùn èké kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní kóòtù làwọn adájọ́ ti gbé ọ̀ràn náà karí òmìnira ìjọsìn, a sì dúpẹ́ fún èyí. Àmọ́ ṣá, àwọn adájọ́ kan ti jẹ́ káwọn alátakò lo orí wọn. Irú àwọn adájọ́ yìí ni Ìwé Mímọ́ sọ fún pé: “Ẹ gba ìtọ́sọ́nà.”

19 Àwọn adájọ́ gbọ́dọ̀ mọ̀ pé òfin Jèhófà Ọlọ́run ni òfin tó ga jù lọ. Wọ́n gbọ́dọ̀ rántí pé gbogbo ẹ̀dá èèyàn, tó fi dórí àwọn adájọ́, ló máa káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́ níwájú Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. (Róòmù 14:10) Ní tiwa, yálà àwọn adájọ́ dá ẹjọ́ wa bó ṣe yẹ tàbí ńṣe ni wọ́n gbé ẹ̀bi fún aláre, kò sóhun tó ní pé ká máà nígboyà nítorí pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn. Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tí ń sá di í.”—Sáàmù 2:12.

20. Kí nìdí tá a fi lè máa yọ̀ bí wọ́n ti ń ṣenúnibíni sí wa tí wọ́n sì ń bà wá lórúkọ jẹ́?

20 Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run; nítorí ní ọ̀nà yẹn ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ó wà ṣáájú yín.” (Mátíù 5:11, 12) Ká sòótọ́, inúnibíni kì í ṣohun tó rọrùn o, àmọ́ dídúró tá a bá dúró gbọn-in láìfi inúnibíni pè títí kan àwọn ìròyìn tó ń bani lórúkọ jẹ́ táwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń gbé kiri, ti tó fún wa láti máa yọ̀. Èyí túmọ̀ sí pé à ń múnú Jèhófà dùn, àá sì rí èrè níbẹ̀. Ìgboyà wa fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ tó dúró sán-ún ó sì ń jẹ́ kó dá wa lójú pé àá rí ojú rere Ọlọ́run. Àní sẹ́, ó ń fi hàn pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà. Irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ ṣe kókó fun Kristẹni, gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

Kí Lo Rí Kọ́?

• Àwọn ipò wo lónìí ló ń béèrè pé ká jẹ́ onígboyà?

• Báwo la ṣe lè ní ìgboyà?

• Àwọn wo ló fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa jíjẹ́ onígboyà?

• Kí nìdí tá a fi ń fẹ́ láti jẹ́ onígboyà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Simone Arnold (tó ti di Liebster báyìí) ní ilẹ̀ Jámánì, Widdas Madona ní Màláwì, Lydia Kurdas àti Oleksii Kurdas ní Ukraine ní ìgboyà wọn kò sì juwọ́ sílẹ̀ fún ẹni ibi náà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

A ò tijú ìhìn rere náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ìgboyà tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ṣe bẹbẹ láti mú kí ìhìn rere náà gbòòrò sí i

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Tá a bá fi tìgboyàtìgboyà ṣàlàyé fún adájọ́ nípa ipò tá a dì mú níbàámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́, iṣẹ́ pàtàkì kan là ń jẹ́ fún un yẹn