Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

“Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò . . . gbẹ́kẹ̀ lé ọ.”—SÁÀMÙ 9:10.

1, 2. Àwọn nǹkan òfìfo wo làwọn èèyàn ń gbẹ́kẹ̀ lé fún ààbò?

 LÓDE òní tó jẹ́ pé ẹgbàágbèje nǹkan ló ń wu ẹ̀mí wa léwu, ohun tó bá ìwà ẹ̀dá mu ni pé kéèyàn wá ẹnì kan tàbí ohun kan tó lè dáàbò boni. Àwọn kan ronú pé mìmì kan ò lè mi àwọn lọ́jọ́ iwájú táwọn bá ti lówó rẹpẹtẹ, àmọ́ ká sòótọ́ ohun ààbò tí ò ṣe é gbẹ́kẹ̀ lé ni owó. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀—òun fúnra rẹ̀ yóò ṣubú.” (Òwe 11:28) Àwọn aṣáájú ẹ̀dá èèyàn làwọn mìíràn gbọ́kàn lé, àmọ́ ṣá àwọn tó ṣèèyàn jù lọ lára àwọn aṣáájú yìí ń ṣàṣìṣe. Tó bá sì yá, gbogbo wọn á kú. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 146:3) Àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí wọ̀nyẹn tún kì wá nílọ̀ pé ká má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé agbára tiwa nìkan. ‘Ọmọ ará ayé’ lásánlàsàn làwa náà jẹ́.

2 Wòlíì Aísáyà bá àwọn olórí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àkókò rẹ̀ wí nítorí pé “ibi ìsádi irọ́” ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé. (Aísáyà 28:15-17) Ibi tí wọ́n ti ń wá ààbò kiri ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn olóṣèlú orílẹ̀-èdè ìtòsí wọn. Irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ kò ṣe é gbọ́kàn lé rárá—irọ́ gbuu ló wà ńbẹ̀. Lọ́nà kan náà lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí dòwò pọ̀ pẹ̀lú àwọn olóṣèlú. “Irọ́” làwọn àjọṣe wọ̀nyẹn náà máa já sí. (Ìṣípayá 17:16, 17) Wọn ò lè pèsè ààbò tó máa wà pẹ́ títí.

Àpẹẹrẹ Rere Jóṣúà àti Kálébù

3, 4. Báwo ni ìròyìn Jóṣúà àti Kálébù ṣe yàtọ̀ sí tàwọn amí mẹ́wàá tó kù?

3 Ibo ló wá yẹ ká wá ààbò lọ? Ibi tí Jóṣúà àti Kálébù wá a lọ nígbà ayé Mósè ni. Ní kété tí a dá Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì, orílẹ̀-èdè náà ti múra tán láti wọ ilẹ̀ Kénáánì, ìyẹn Ilẹ̀ Ìlérí. A rán àwọn ọkùnrin méjìlá lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, lẹ́yìn ogójì ọjọ́ wọ́n padà dé láti ròyìn bọ́hùn-ún ṣe rí. Kìkì amí méjì péré, ìyẹn Jóṣúà àti Kálébù ló sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé Ísírẹ́lì á rọ́wọ́ mú ní ilẹ̀ Kénáánì. Àwọn tó kù jẹ́rìí sí i pé ilẹ̀ náà dára o, àmọ́ wọ́n sọ pé: “Òtítọ́ náà ni pé àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára, àwọn ìlú ńlá olódi náà sì tóbi gan-an . . . Àwa kò lè gòkè lọ láti gbéjà ko àwọn ènìyàn náà, nítorí pé wọ́n lágbára jù wá lọ.”—Númérì 13:27, 28, 31.

4 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ohun táwọn amí mẹ́wàá náà sọ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù, wọ́n tiẹ̀ bá a débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mósè. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Jóṣúà àti Kálébù wá fi tinútinú sọ pé: “Ilẹ̀ náà tí a là kọjá láti ṣe amí rẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára gidigidi. Bí Jèhófà bá ní inú dídùn sí wa, dájúdájú, nígbà náà òun yóò mú wa wá sínú ilẹ̀ yìí, yóò sì fi í fún wa, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin. Kìkì kí ẹ má ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà; àti ẹ̀yin, kí ẹ má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.” (Númérì 14:6-9) Pẹ̀lú gbogbo ìṣírí yìí náà, ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó agídí borí, èyí ló sì fà á tí wọn ò fi dé Ilẹ̀ Ìlérí lákòókò náà.

5. Kí nìdí tí Jóṣúà àti Kálébù fi mú ìròyìn tó dáa wá?

5 Kí nìdí tí Jóṣúà àti Kálébù fi mú ìròyìn rere bọ̀ tó sì jẹ́ pé ìròyìn búburú làwọn amí mẹ́wàá tó kù mú bọ̀? Gbogbo àwọn amí méjìlá náà ló kúkú rí àwọn ìlú ńláńlá tó jẹ́ alágbára àtàwọn orílẹ̀-èdè tí ò ṣeé bì ṣubú náà. Òótọ́ sì lohun táwọn amí mẹ́wàá náà sọ pé Ísírẹ́lì ò lágbára láti ṣẹ́gun ilẹ̀ náà. Jóṣúà àti Kálébù náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá, ojú ẹ̀dá èèyàn làwọn mẹ́wàá náà fi wo ọ̀ràn ọ̀hún. Ṣùgbọ́n Jóṣúà àti Kálébù ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà. Wọ́n ti rí àwọn nǹkan alágbára tó ṣe ní Íjíbítì, èyí tó ṣe ní Òkun Pupa àtèyí tó ṣe ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Òkè Sínáì. Kódà, ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún lẹ́yìn náà, ìròyìn àwọn iṣẹ́ ńláńlá rẹ̀ yìí lásán tí Ráhábù gbọ́ ní Jẹ́ríkò ló mú kó fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu nítorí àwọn èèyàn Jèhófà! (Jóṣúà 2:1-24; 6:22-25) Jóṣúà àti Kálébù tí wọ́n ti fojú ara wọn rí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe sẹ́yìn, ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Ọlọ́run pé kò ní yéé jà fáwọn èèyàn rẹ̀. Ogójì ọdún lẹ́yìn náà, ìgbọ́kànlé wọn yìí wá já sóòótọ́ nígbà tí ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tuntun, tí Jóṣúà jẹ́ aṣáájú wọn, wọ ilẹ̀ Kénáánì tí wọ́n sì ṣẹ́gun ilẹ̀ náà.

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Ní Kíkún

6. Èé ṣe táwọn Kristẹni fi ń kojú àdánwò lónìí, ta ló sì yẹ kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé?

6 Ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” tá a wà yìí, bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì làwa náà ṣe ní àwọn ọ̀tá tó lágbára jù wá lọ. (2 Tímótì 3:1) À ń dán ìwà rere wa wò, à ń dán wa wò nípa tẹ̀mí àti nígbà mìíràn nípa tara. Bí a bá dá a dá agbára tiwa nìkan, a ò lè borí àwọn àdánwò yìí nítorí pé àtọ̀dọ̀ ẹni tó lágbára ju ẹ̀dá èèyàn lọ ló ti ń wá, ìyẹn Sátánì Èṣù. (Éfésù 6:12; 1 Jòhánù 5:19) Ibo la ti lè rí ìrànlọ́wọ́? Nígbà tí ọkùnrin olóòótọ́ kan ń gbàdúrà sí Jèhófà láyé ọjọ́un, ó sọ pé: “Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ.” (Sáàmù 9:10) Tá a bá mọ Jèhófà lóòótọ́ tá a sì mọ ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀, àá gbẹ́kẹ̀ lé e láìmikàn bíi ti Jóṣúà àti Kálébù.—Jòhánù 17:3.

7, 8. Báwo ni ìṣẹ̀dá ṣe fi hàn pé ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (b) Àwọn ohun wo ni Bíbélì sọ tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

7 Kì nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Lára ohun tó mú kí Jóṣúà àti Kálébù ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ti rí ẹ̀rí agbára Jèhófà. Àwa náà si ti rí i. Bí àpẹẹrẹ, gbé iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Jèhófà yẹ̀ wò, títí kan ọ̀run òun ayé, pẹ̀lú àìmọye bílíọ̀nù àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀. Àwọn arabaríbí agbára tó ṣe é fojú rí tó wà níkàáwọ́ Jèhófà fi hàn pé lóòótọ́ ló jẹ́ Ọlọ́run Olódùmarè. Bá a ṣe ń ronú nípa àwọn ohun àgbàyanu ìṣẹ̀dá, àwa náà gbà pẹ̀lú ohun tí Jóòbù sọ nípa Jèhófà pé: “Ta ní lè dè é lọ́nà? Ta ni yóò sọ fún un pé, ‘Kí ni ìwọ ń ṣe?’” (Jóòbù 9:12) Òdodo ọ̀rọ̀, tí Jèhófà bá ń dáàbò bò wá, a ò ní bẹ̀rù ẹnikẹ́ni láyé òun ọ̀run.—Róòmù 8:31.

8 Bákan náà, tún gbé Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Jèhófà yẹ̀ wò. Orísun ọgbọ́n Ọlọ́run tí kì í gbẹ yìí lágbára gan-an láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn ìwà tí ò dáa ká sì mú ìgbésí ayé wa bá ohun tí Jèhófà fẹ́ mu. (Hébérù 4:12) Bíbélì ló jẹ́ ká mọ orúkọ Jèhófà àti ohun tí orúkọ náà túmọ̀ sí. (Ẹ́kísódù 3:14) A mọ̀ pé Jèhófà lè di ohunkóhun tó bá wù ú, ó lè di Baba onífẹ̀ẹ́, Onídàájọ́ òdodo, àti Ajagunṣẹ́gun kó bàa lè mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. A sì tún rí báwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe ń nímùúṣẹ. Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run làwa náà ń sọ ọ̀rọ̀ tí onísáàmù náà sọ pé: “Mo [ti] gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ”—Sáàmù 119:42; Aísáyà 40:8.

9. Báwo ni ìràpadà náà àti àjíǹde Jésù ṣe mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i?

9 Ètò tí Jèhófà ṣe fún ìràpadà tún jẹ́ ìdí mìíràn tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé e. (Mátíù 20:28) Ẹ ò rí i pé rírán tí Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ láti wá kú fún ìràpadà wa kì í ṣe nǹkan kékeré! Iṣẹ́ ńlá sì ni ìràpadà yìí ṣe. Òun ni ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ẹ̀dá èèyàn tó bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì fi ọkàn mímọ́ tọ Jèhófà lọ. (Jòhánù 3:16; Hébérù 6:10; 1 Jòhánù 4:16, 19) Apá kan lára ọ̀nà tá a gbà san ìràpadà náà ni jíjí tá a jí Jésù dìde. Iṣẹ́ ìyanu yẹn tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn rí, tún jẹ́ ẹ̀rí mìíràn tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ó jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú pé ìgbẹ́kẹ̀lé wa ò ní já sófo.—Ìṣe 17:31; Róòmù 5:5; 1 Kọ́ríńtì 15:3-8.

10. Àwọn nǹkan wo ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwa fúnra wa tó ń mú ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà?

10 Ìwọ̀nba díẹ̀ nìwọ̀nyí lára ìdí tá a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti ìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní, ọ̀pọ̀ lára wọn ló jẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwa fúnra wa. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo wa ni ìgbésí ayé máa ń le koko fún lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bá a sì ṣe ń wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà láti yanjú àwọn ìṣòro yìí là ń rí i pé ìtọ́sọ́nà náà gbéṣẹ́ gan-an. (Jákọ́bù 1:5-8) Bá a bá ṣe túbọ̀ ń gbára lé Jèhófà tó lójoojúmọ́ tá a sì ń rí i pé rere ló ń tibẹ̀ jáde, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú rẹ̀ á túbọ̀ máa lágbára sí i.

Dáfídì Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

11. Lójú àwọn ipò wo ni Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

11 Dáfídì ti Ísírẹ́lì ìgbàanì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ewu lọ́tùn-ún ewu lósì ló dojú kọ Dáfídì látọwọ́ Sọ́ọ̀lù Ọba tó fẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀ àti ọmọ ogun àwọn Filísínì tí wọ́n fẹ́ ṣẹ́gun Ísírẹ́lì. Síbẹ̀, ó yọ nínú gbogbo ewu náà, ó tiẹ̀ ṣẹ́gun pàápàá. Báwo ló ṣe ṣe é? Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi. Ta ni èmi yóò bẹ̀rù? Jèhófà ni odi agbára ìgbésí ayé mi. Ta ni èmi yóò ní ìbẹ̀rùbojo fún?” (Sáàmù 27:1) Àwa náà á borí tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

12, 13. Báwo ni Dáfídì ṣe fi hàn pé a gbọ́dọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà kódà nígbà táwọn alátakò bá ń fi ahọ́n wọn gbógun tì wá?

12 Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Dáfídì gbàdúrà pé: “Ọlọ́run, gbọ́ ohùn mi nínú ìdàníyàn mi. Kí o fi ìṣọ́ ṣọ́ ìwàláàyè mi lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo fún ọ̀tá. Kí o pa mí mọ́ lọ́wọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí àwọn aṣebi, lọ́wọ́ ìrúkèrúdò àwọn aṣenilọ́ṣẹ́, àwọn tí ó ti pọ́n ahọ́n wọn gẹ́gẹ́ bí idà, àwọn tí ó ti fi ọfà wọn, tí í ṣe ọ̀rọ̀ kíkorò, sun ibi ìfojúsùn, kí wọ́n lè ta aláìlẹ́bi lọ́fà láti àwọn ibi tí ó lùmọ́.” (Sáàmù 64:1-4) A ò mọ ohun tó fà á gan-an tí Dáfídì fi kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ a mọ̀ pé lọ́jọ́ tòní náà, àwọn alátakò ń “pọ́n ahọ́n wọn,” ọ̀rọ̀ ẹnu wọn sì ni wọ́n fi ń jagun. Wọ́n ń fi àwọn ọ̀rọ̀ èké tí wọ́n ń sọ tàbí èyí ti wọ́n ń kọ ṣe “ọfà” tí wọ́n ń “ta” sí àwọn Kristẹni aláìlẹ́bi. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà dáadáa, kí ló máa jẹ́ àbájáde rẹ̀?

13 Dáfídì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ọlọ́run yóò ta wọ́n lọ́fà lójijì. Wọ́n ti gbọgbẹ́, wọ́n sì mú kí ènìyàn kọsẹ̀. Ṣùgbọ́n ahọ́n wọn dojú ìjà kọ àwọn fúnra wọn. . . . Olódodo yóò sì máa yọ̀ nínú Jèhófà, yóò sì sá di í ní tòótọ́.” (Sáàmù 64:7-10) Lóòótọ́, àwọn ọ̀tá lè máa pọ́n ahọ́n wọn kó sì mú bérébéré, àmọ́ lásẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ‘ahọ́n wọn á dojú ìjà kọ àwọn fúnra wọn.’ Jèhófà á jẹ́ kí dáadáa gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà, káwọn tó ti gbẹ́kẹ̀ lé e báa lè máa fi ìdùnnú yọ̀ nínú rẹ̀.

Ìgbẹ́kẹ̀lé Hesekáyà Tọ̀nà

14. (a) Lójú ewu ńlá wo ni Hesekáyà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (b) Báwo ni Hesekáyà ṣe fi hàn pé òun ò gba irọ́ àwọn ará Ásíríà gbọ́?

14 Ẹlòmíràn tó tún ní ìgbẹ́kẹ̀lé tó tọ̀nà nínú Jèhófà ni Hesekáyà Ọba. Nígbà tí Hesekáyà wà lórí àlééfà, àwọn ọmọ ogun Ásíríà bẹ̀rẹ̀ sí dún kookò mọ́ Jerúsálẹ́mù. Àwọn ọmọ ogun yẹn ti ṣẹ́gun ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Kódà gbogbo ìlú tó wà ní Júdà ló ti ṣẹ́gun àyàfi Jerúsálẹ́mù, Senakéríbù sì ti bẹ̀rẹ̀ sí fọ́nnu pé òun á ṣẹ́gun ìlú ńlá yẹn náà. Nípasẹ̀ Rábúṣákè, ó sọ ọ́ pé òtúbáńtẹ́ ni gbígbẹ́kẹ̀lé Íjíbítì máa já sí, òótọ́ ló sì sọ. Ó tún wá sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run rẹ tí o gbẹ́kẹ̀ lé tàn ọ́ jẹ, wí pé: ‘A kì yóò fi Jerúsálẹ́mù lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.’” (Aísáyà 37:10) Àmọ́ Hesekáyà ní tiẹ̀ mọ̀ pé Jèhófà ò lè tan òun jẹ. Èyí ló fi gbàdúrà pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, gbà wá là lọ́wọ́ [àwọn ará Ásíríà], kí gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé lè mọ̀ pé ìwọ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.” (Aísáyà 37:20) Jèhófà gbọ́ àdúrà Hesekáyà. Lóru ọjọ́ kan ṣoṣo, áńgẹ́lì kan pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] àwọn ọmọ ogun Ásíríà. Bá a ṣe gba Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ nìyẹn o, Senakéríbù wá fi Júdà sílẹ̀ kò sì padà wá mọ́ láé. Gbogbo àwọn tó gbọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ló rí i pé Jèhófà tóbi lọ́ba.

15. Kí lohun kan ṣoṣo tó lè mú wa gbára dì fún ipò èyíkéyìí tá a lè bá ara wa nínú ayé tí nǹkan kò fara rọ yìí?

15 Àwa náà ń jagun lónìí bíi ti Hesekáyà. Àmọ́ ogun tẹ̀mí ni tiwa. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi jagunjagun tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn ohun tó máa gbà wá là nípa tẹ̀mí. A gbọ́dọ̀ mọ̀gbà tí ọ̀tá bá ń kógun bọ̀ ká sì gbára dì láti kojú rẹ̀. (Éfésù 6:11, 12, 17) Nínú ayé tí nǹkan kò fara rọ yìí, ipò nǹkan lè yí padà lójijì. Ìlú lè dà rú lójijì. Àwọn orílẹ̀-èdè tó ti fàyè gba onírúurú ẹ̀sìn tẹ́lẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí fúngun mọ́ àwọn ẹ̀sìn kan. Àyàfi tá a bá ṣe bí Hesekáyà, tá a gbára dì nípa níní ìgbẹ́kẹ̀lé tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú Jèhófà la tó lè sọ pé kò sóhun tó ń bọ̀ lókè tí ilẹ̀ ò gbà.

Kí Ni Gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà Túmọ̀ Sí?

16, 17. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà?

16 Gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà kì í ṣe ohun téèyàn kàn ń fẹnu sọ lásán o. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ọkàn wa, ìwà wa ni yóò sì fi èyí hàn. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àá gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójú méjèèjì. Àá máa kà á lójoojúmọ́, àá máa ṣàṣàrò lórí rẹ̀, àá sì jẹ́ kó máa ṣamọ̀nà ìgbésí ayé wa. (Sáàmù 119:105) Gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà tún kan gbígbẹ́kẹ̀lé agbára ẹ̀mí mímọ́. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, àá lè ní àwọn ànímọ́ tí Jèhófà fẹ́ràn, àá sì lè fi àwọn ìwàkiwà tó ti mọ́ wa lára sílẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 6:11; Gálátíà 5:22-24) Àní, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ẹ̀mí mímọ́ ti ràn lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú sìgá mímú àti lílo oògùn olóró. Àwọn mìíràn ti jáwọ́ nínú ìṣekúṣe. Dájúdájú, tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, agbára rẹ̀ làá máa fi hùwà kì í ṣe tiwa.—Éfésù 3:14-18.

17 Kò tán síbẹ̀ o, gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà tún túmọ̀ sí pé àá gbẹ́kẹ̀ lé àwọn tó fọkàn tán. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ti ṣètò pé kí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” máa bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ ti Ìjọba náà lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 24:45-47) A ò ní máa ṣe ohun tó bá sáà ti wù wá, a sì gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló yan ẹrú náà sípò, nítorí pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìṣètò Jèhófà. Bákan náà, àwọn alàgbà ń sìn nínú ìjọ Kristẹni, ẹ̀mí mímọ́ ló sì yàn wọ́n sípò gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ. (Ìṣe 20:28) A tún ń fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nípa títi ètò táwọn alàgbà bá ṣe nínú ìjọ lẹ́yìn.—Hébérù 13:17.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù

18. Báwo làwọn Kristẹni òde òní ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, kí sì ni wọn kò gbẹ́kẹ̀ lé?

18 Ojú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí màbo nídìí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi tiwa náà. Lákòókò tirẹ̀, àwọn èèyàn lọ máa ń sọ ìsọkúsọ fáwọn aláṣẹ nípa ẹ̀sìn Kristẹni, àmọ́ ó máa ń gbìyànjú nígbà míì láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé irọ́ funfun báláú làwọn ọ̀rọ̀ náà tàbí kó fìdí iṣẹ́ ìwàásù múlẹ̀ lábẹ́ òfin. (Ìṣe 28:19-22; Fílípì 1:7) Àpẹẹrẹ rẹ̀ làwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé lónìí. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, à ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ bí iṣẹ́ wa ṣe jẹ́, ọ̀nà èyíkéyìí tó bá sì ṣí sílẹ̀ la fi ń ṣe èyí. A tún ń sapá láti gbèjà ìhìn rere náà ká sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin. Àmọ́ ṣá, kì í ṣe irú ìsapá bẹ́ẹ̀ la gbẹ́kẹ̀ lé, nítorí a ò gbà pé jíjàre bọ̀ láti ilé ẹjọ́ tàbí pé káwọn èèyàn máa sọ̀rọ̀ tó dáa nípa iṣẹ́ wa ló máa pinnu bóyá a ṣiṣẹ́ wa yọrí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé. À ń rántí ìṣírí tó fún Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Agbára ńlá yín yóò sì wà nínú àìní ìyọlẹ́nu rárá àti nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé.”—Aísáyà 30:15.

19. Báwo ni adùn ṣe ń gbẹ̀yìn ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn ará wa nínú Jèhófà nígbà tí wọn bá dojú kọ inúnibíni?

19 Lóde òní, àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa tàbí ká wa lọ́wọ́ kò ní apá Ìlà Oòrùn àti apá Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù, láwọn apá ibì kan ní Éṣíà àti Áfíríkà, àti láwọn orílẹ̀-èdè kan ní apá Gúúsù àti apá Àríwá Amẹ́ríkà. Ǹjẹ́ èyí wá túmọ̀ sí pé ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà ti já sófo? Rárá o. Lóòótọ́ ni Jèhófà ti fàyè gba inúnibíni rírorò fún àwọn ìdí kan tó mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì, àmọ́ ó ti fi tìfẹ́tìfẹ́ fún àwọn tó ti fara da irú inúnibíni bẹ́ẹ̀ lókun. Inúnibíni ti mú kí ọ̀pọ̀ Kristẹni ní ìgbọ́kànlé àti ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run.

20. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè máa jàǹfààní òmìnira lábẹ́ òfin, láwọn ọ̀nà wo la ò ti ní sọra wa di kò ṣeku kò ṣẹyẹ?

20 Tá a bá tún gba ọ̀nà mìíràn wò ó, ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ni wọ́n ti gbà wá láyè lábẹ́ òfin, tí àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde sì ń sọ̀rọ̀ tó dára nípa wa. Inú wa dùn sí èyí a sì mọ̀ pé èyí náà tún ń mú ète Jèhófà ṣẹ. Pẹ̀lú ìbùkún rẹ̀, à ń fi òmìnira tá a ní sin Jèhófà ní gbangba àti lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, a ò lò ó fún àǹfààní tara wa. Àmọ́ o, a ò jẹ́ torí pé káwọn aláṣẹ lè máa buyì fún wa ká wá di kò ṣeku kò ṣẹyẹ, ká bẹ̀rẹ̀ sí dẹwọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa, tàbí kí iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí lọọlẹ̀ láwọn ọ̀nà mìíràn. Ọmọ abẹ́ Ìjọba Mèsáyà ni wá, ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ la sì tì lẹ́yìn. Ìrètí wa kì í ṣe nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí o, inú ayé tuntun ló wà, níbi tí Ìjọba Mèsáyà lókè ọ̀run á ti jẹ́ ìjọba kan ṣoṣo táá máa ṣàkóso lé ayé yìí lórí. Kò sí àdó olóró, ohun ìjà èyíkéyìí, títí kan èyí tó ń pa àwọn èèyàn lọ bẹẹrẹbẹ, tó máa lè mi ìjọba yẹn tàbí tí yóò bì í ṣubú látọ̀run. Ìjọba tí kò ṣe é ṣẹ́gun ni, á sì mú ète Jèhófà ṣẹ.—Dáníẹ́lì 2:44; Hébérù 12:28; Ìṣípayá 6:2.

21. Kí lohun náà tá a pinnu láti máa ṣe?

21 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun, ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.” (Hébérù 10:39) Nítorí náà, ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà títí dópin. Kò sóhun tó ní ká máà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nísinsìnyí àti títí láé.—Sáàmù 37:3; 125:1.

Kí Lo Rí Kọ́?

• Kí nìdí tí Jóṣúà àti Kálébù fi mú ìròyìn rere bọ̀?

• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láìmikàn?

• Kí ló túmọ̀ sí láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà?

• Kí lohun tá a pinnu láti ṣe bá a ti ń ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Kí nìdí tí Jóṣúà àti Kálébù fi mú ìròyìn rere bọ̀?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ìṣẹ̀dá túbọ̀ ń mú ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà

[Credit Line]

Àwòrán mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Anglo-Australian Observatory, fọ́tò látọwọ́ David Malin

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà túmọ̀ sí pé àá gbẹ́kẹ̀ lé àwọn tó fọkàn tán