Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Gbogbo Ohun Tí Mo Nílò Ni Mo Rí”

“Gbogbo Ohun Tí Mo Nílò Ni Mo Rí”

“Gbogbo Ohun Tí Mo Nílò Ni Mo Rí”

ÌRÒYÌN kan látọ̀dọ̀ Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú bù ú pé kárí ayé, nǹkan bí ọgọ́fà mílíọ̀nù èèyàn ni ìdààmú ọkàn ń bá jà. Lọ́dọọdún, mílíọ̀nù kan èèyàn ló ń pa ara wọn, mílíọ̀nù mẹ́wàá sí ogún mílíọ̀nù ló sì ń gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn. Ìrànlọ́wọ́ wo làwọn tó ní ìdààmú ọkàn lè rí gbà? Ó ṣeé ṣe kí ìṣòro wọn dín kù tí wọ́n bá gba ìtọ́jú ìṣègùn, ó sì tún ṣe pàtàkì pé ká máa ṣaájò wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan lára àwọn tó ní ìdààmú ọkàn ti rí àfikún ìrànlọ́wọ́ gbà látinú àwọn ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a gbé karí Bíbélì, tó sì ní ìmọ̀ràn tó wúlò, gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà tó tẹ̀ lé e yìí láti ilẹ̀ Faransé ṣe fi hàn.

“Láìpẹ́ yìí, ilé ayé yìí sú mi. Mo wá gbàdúrà pé Ọlọ́run jọ̀ọ́ jẹ́ kí n kú. Ńṣe ló dà bíi pé mo ti kú sínú ara lọ́hùn-ún. Bí mo ṣe ń wá ìtọ́sọ́nà, mo gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà. Bákan náà, mo pinnu láti ka ìwé ọdọọdún náà 2002 Yearbook of Jehovah’s Witnesses mo sì kà á tán láàárín ọjọ́ mẹ́ta. Ká sòótọ́, ìwé yẹn gbà mí níyànjú gan-an ni, ó sì fún ìgbàgbọ́ mi lókun.

“Mo tún ṣe ìwádìí pẹ̀lú nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ohun tí mo sì ṣàwárí yà mí lẹ́nu gan-an! Ó ju ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ tí mo ti ń ka ìwé ìròyìn wọ̀nyí déédéé o, ṣùgbọ́n mi ò mọ̀ pé àwọn àpilẹ̀kọ inú wọn máa ń gbani níyànjú, pé ó sì ń gbéni ró bẹ́ẹ̀. Ìfẹ́ tó ṣọ̀wọ́n gidigidi lóde òní kún inú wọn bámúbámú. Gbogbo ohun tí mo nílò ni mo rí níbẹ̀.”

Bíbélì sọ pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Sáàmù 34:18) Láìsí àní-àní, gbogbo àwọn “oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà” tàbí àwọn “tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀” lè rí ọ̀rọ̀ ìyànjú àti ìrètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa gbà nínú Bíbélì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pín àwọn ìwé tá a gbé karí Bíbélì fún àwọn èèyàn kí ó lè mú káwọn tó níṣòro jàǹfààní látinú orísun ìtùnú tí Ọlọ́run mí sí yìí.