Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Inúnibíni Nítorí Ẹ̀sìn—Kí Ló Fà Á?

Inúnibíni Nítorí Ẹ̀sìn—Kí Ló Fà Á?

Inúnibíni Nítorí Ẹ̀sìn—Kí Ló Fà Á?

ǸJẸ́ o gbà pé ó yẹ kí wọ́n máa ṣenúnibíni sáwọn èèyàn nítorí ẹ̀sìn wọn? Ó ṣeé ṣe kó o má gbà bẹ́ẹ̀, àgàgà tí ìgbòkègbodò wọn ò bá ti pa àwọn ẹlòmíràn lára. Bẹ́ẹ̀, kì í ṣòní kì í ṣàná tí wọ́n ti máa ń ṣenúnibíni sáwọn èèyàn nítorí ẹ̀sìn, inúnibíni ọ̀hún ò sì tíì dáwọ́ dúró. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló jẹ́ pé léraléra ni wọ́n fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n nílẹ̀ Yúróòpù àti láwọn apá ibòmíràn láyé, tí wọ́n sì ṣe wọ́n bí ọṣẹ́ ṣe ń ṣojú látìbẹ̀rẹ̀ dópin ọ̀rúndún ogún.

Láàárín àkókò yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fojú winá inúnibíni líle koko, táwọn èèyàn ń ṣe sí wọn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, tó sì ń bá a lọ fún àkókò gígùn lábẹ́ àwọn ìjọba aláṣẹ oníkùmọ̀ méjèèjì tó lókìkí jù nílẹ̀ Yúróòpù. Kí ni ìrírí wọn kọ́ wa nípa inúnibíni táwọn èèyàn máa ń ṣe nítorí ìsìn? Ẹ̀kọ́ wo la sì lè kọ́ látinú ọwọ́ tí wọ́n fi mú ìjìyà náà?

“Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá láti jẹ́ ẹni tí ń pa òfin mọ́, ẹni àlàáfíà, àti ẹni tó níwà rere. Wọn kì í lòdì síjọba tàbí kí wọ́n máa wá bí wọ́n ṣe máa figẹ̀ wọngẹ̀ pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kì í ṣe ohun tó lè fa inúnibíni nítorí àtidi ajẹ́rìíkú. Àwọn Kristẹni wọ̀nyí kì í dá sí tọ̀túntòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú. Èyí wà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “[Àwọn ọmọlẹ́yìn mi] kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn alákòóso ló mọyì jíjẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí jẹ́ aláìdásí-tọ̀tún-tòsì. Àmọ́ àwọn alákòóso ìjọba aláṣẹ oníkùmọ̀ ò fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ yẹn pé àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan ayé.

Wọ́n ṣàlàyé ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ níbi ìpàdé àpérò kan tó wáyé ní Yunifásítì Heidelberg, ní Jámánì, ní November ọdún 2000. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àpérò náà ni “Ìnilára àti Ìtẹnilóríba: Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lábẹ́ Ìjọba Ẹgbẹ́ Àjùmọ̀ní àti Kọ́múníìsì Aláṣẹ Bóofẹ́bóokọ̀.” Ọ̀mọ̀wé Clemens Vollnhals tó wà ní Ibùdó Ìṣèwádìí Ọ̀ràn Ìjọba Oníkùmọ̀ ti Hannah-Arendt sọ pé: “Àwọn ìjọba oníkùmọ̀ ò fagbára wọn mọ sórí ọ̀ràn ìṣèlú nìkan. Wọ́n tún fẹ́ kéèyàn fi gbogbo ara rẹ̀ sábẹ́ wọn pẹ̀lú.”

Àwọn Kristẹni tòótọ́ kò lè fi “gbogbo ara” wọn sábẹ́ ìjọba ènìyàn, nítorí pé wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé lágbègbè tí Ìjọba aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ ti ń ṣàkóso ti rí i pé ohun tí Ìjọba fẹ́ àti ohun tí ìgbàgbọ́ wọn fàyè gbà máa ń forí gbárí láwọn ìgbà mìíràn. Kí ni wọ́n ti ṣe láti kojú irú ìforígbárí bẹ́ẹ̀? Ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ni pé ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi sọ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ lé, ìyẹn ni pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ni kò yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́ wọn tí wọn ò sì lọ́wọ́ sí ọ̀ràn ìṣèlú, kódà lójú inúnibíni gbígbóná janjan pàápàá. Báwo ni wọ́n ṣe lè fara dà á? Ibo ni wọ́n ti rí okun tí wọ́n fi ṣe é? Ẹ jẹ́ káwọn fúnra wọn dáhùn. Ẹ sì jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa, àti Ẹlẹ́rìí àti ẹni ti kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, lè kọ́ látinú àwọn ìrírí wọn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Jámánì fojú winá inúnibíni líle koko táwọn èèyàn ṣe sí wọn fún àkókò gígùn lábẹ́ àwọn ìjọba oníkùmọ̀ méjèèjì tó lókìkí jù ní ọ̀rúndún ogún

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Àwọn ìjọba oníkùmọ̀ ò fi agbára wọn mọ sórí ọ̀ràn ìṣèlú nìkan. Wọ́n tún fẹ́ kéèyàn fi gbogbo ara rẹ̀ sábẹ́ wọn pẹ̀lú.”—Ọ̀mọ̀wé Clemens Vollnhals

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Wọ́n fi òmìnira tó yẹ ki ìdílé Kusserow ní dù wọ́n nítorí pé wọn ò juwọ́ sílẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Wọ́n pa Johannes Harms nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba Násì nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀