Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lo Ipò Nǹkan Tó Ń Yí Padà Lọ́nà Tó Dáa

Lo Ipò Nǹkan Tó Ń Yí Padà Lọ́nà Tó Dáa

Lo Ipò Nǹkan Tó Ń Yí Padà Lọ́nà Tó Dáa

Àwọn mẹ́rin yìí, Pum, Jan, Dries àti Otto, tí wọ́n jẹ́ Kristẹni alàgbà ní Netherlands jọ ara wọn lọ́nà tó pọ̀. Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti láya àtọmọ sílé. Bákan náà, gbogbo wọn ló ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, wọ́n sì ń gbénú ilé tó dáa. Àmọ́ ṣá, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti fi iṣẹ́ sílẹ̀ wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí fi gbogbo àkókò wọn àti okun wọn ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba Ọlọ́run. Kí ló mú kí wọ́n ṣe ìyípadà yìí? Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lo ipò nǹkan tó ń yí padà lọ́nà tó dára.

BÓPẸ́BÓYÁ, èyí tó pọ̀ jù lára wa lá rí i pé ipò nǹkan ń yí padà lọ́nà kan tàbí òmíràn. Ipò tó ń yí padà yìí, bíi kéèyàn ṣègbéyàwó, kéèyàn bímọ tàbí kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú àwọn òbí tó ti dàgbà, máa ń mú ẹrù iṣẹ́ ńláǹlà dání. Àmọ́ ṣá, àwọn ìyípadà kan wà tó máa ń fúnni lómìnira láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa gbòòrò sí i. (Mátíù 9:37, 38) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ wa tó ti tójúúbọ́ lè lọ máa dá gbé, tàbí ká fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́.

Láfikún sí i, òótọ́ ni pé ipò wa lè yí padà yálà a fẹ́ bẹ́ẹ̀ tàbí a ò fẹ́ bẹ́ẹ̀, àmọ́ àwọn Kristẹni kan ti fúnra wọn ṣe àwọn ìyípadà kan tó sì ti fún wọn láǹfààní láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ohun tí Pum, Jan, Dries àti Otto ṣe gan-an nìyẹn. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é?

Nígbà Táwọn Ọmọ Bá Filé Sílẹ̀

Pum ló ń bójú tó àkọsílẹ̀ owó nílé iṣẹ́ kan tó ń ṣòwò egbòogi. Òun àti Anny ìyàwó rẹ̀, àtàwọn ọmọbìnrin wọn méjèèjì ló máa ń ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà lóòrèkóòrè. Pum àti Anny tún ṣètò fún eré ìnàjú pẹ̀lú àwọn mìíràn tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà bíi tiwọn. Wọ́n sọ pé: “Èyí dáàbò bò wá lọ́wọ́ ìṣòro tí bíbá oríṣi àwọn èèyàn mìíràn kẹ́gbẹ́ lè yọrí sí.” Àpẹẹrẹ àwọn òbí yìí wú àwọn ọmọ méjèèjì lórí gan-an débi pé gbàrà tí wọ́n jáde ilé ẹ̀kọ́ girama báyìí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà.

Nígbà táwọn ọmọ wọn filé sílẹ̀, Pum àti Anny wá kíyè sí i pé ipò nǹkan tó yí padà yìí á jẹ́ káwọn túbọ̀ lómìnira á sì jẹ́ kí wọ́n ni ṣéńjì díẹ̀ lọ́wọ́ ti wọ́n lè fi rin ìrìn àjò afẹ́ kiri kí wọ́n sì gbádùn ara wọn. Àmọ́, tọkọtaya yìí pinnu pé ńṣe làwọn á lo ipò tó yí padà yìí láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni gbòòrò sí i. Pum sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé kó máa yọ̀ǹda ọjọ́ kan fún òun láàárín ọ̀sẹ̀. Nígbà tó yá, Pum ṣe àwọn ètò tó máa mú kó lè máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láago méje àárọ̀ tá á sì ṣíwọ́ ní aago méjì ọ̀sán. Àmọ́ o, àkókò tó fi ń ṣiṣẹ́ tó dín kù yìí á túmọ̀ sí pé ìwọ̀nba owó lá á máa wọlé fún un. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ náà yọrí sí rere, ní ọdún 1991, Pum bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé bíi ti ìyàwó rẹ̀.

Nígbà tó yá, wọ́n ní kí Pum wá máa ran ẹni tó ń bojú tó Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́. Èyí túmọ̀ sí pé kí tọkọtaya náà ṣí kúrò ní ibi tí wọ́n ti ń gbé fún odidi ọgbọ̀n ọdún kí wọ́n sì lọ máa gbé inú iyàrá kan nínú ọgbà Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Wọ́n kúkú ṣí lọ síbẹ̀. Ǹjẹ́ ó rọrùn láti ṣe ohun tí wọ́n ṣe yìí? Anny dáhùn pé ìgbàkigbà tí àárò ilé bá ti ń sọ òun, ìbéèrè tóun máa ń bi ara òun ni pé, ‘Ṣé kì í ṣe pé mo ti fẹ́ di aya Lọ́ọ̀tì báyìí?’ Kò sì ‘bojú wẹ̀yìn’ rárá.—Jẹ́nẹ́sísì 19:26; Lúùkù 17:32.

Pum àti Anny rí i pé ìpinnu tí wọ́n ṣe ti mú ọ̀pọ̀ àǹfààní wá. Lára rẹ̀ ni gbígbádùn tí wọ́n ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn wọn ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ṣíṣètò sílẹ̀ de àpéjọ àgbègbè, àti pípàdé àwọn alábòójútó àyíká (òjíṣẹ́ arìnrìn àjò) tí wọ́n máa ń sọ àsọyé ní gbọ̀ngàn náà. Wọ́n tún máa ń bẹ àwọn ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nígbà tí Pum bá ń ṣe adelé alábòójútó àyíká.

Kí ló mú kí tọkọtaya yìí ṣàṣeyọrí nínú mímú kí iṣẹ́ ìsìn wọn gbòòrò sí i? Pum sọ pé: “Bí ìyípadà ńlá kan bá ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ, o gbọ́dọ̀ pinnu láti lo ipò tó yí padà náà lọ́nà tó dára jù lọ.”

Ṣètò Bó O Ṣe Máa Gbé Ìgbésí Ayé Ṣe-Bó-O-Ti-Mọ

Jan àti Woth ìyàwó rẹ̀, ní ọmọ mẹ́ta. Jan ṣe bíi ti Pum àti ìdílé rẹ̀, òun náà lo ipò nǹkan tó yí padà lọ́nà tó dáa. Ọ̀pọ̀ ọdún ni Jan fi ń ṣiṣẹ́ olówó ńlá ní báńkì, nǹkan sì ṣẹnuure fóun àti ìdílé rẹ̀. Àmọ́ ṣá, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe é bíi kó mú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ gbòòrò sí i. Ó ṣàlàyé pé: “Nínú ìgbésí ayé mi, mo túbọ̀ mọyì òtítọ́ náà, ìfẹ́ tí mo ní sí Jèhófà sì jinlẹ̀ sí i.” Nígbà tó di ọdún 1986, Jan ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ipò rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo lo àǹfààní yíyí tí wọ́n yí àwọn ètò kan padà níbi iṣẹ́ mi, iye ọjọ́ tí mo wá fi ń ṣiṣẹ́ kò tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tí ọ̀rọ̀ náà yà lẹ́nu bẹ̀rẹ̀ sí pè mí ní Diwodo (lẹ́tà tó bẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ mẹ́ta tí mo fi ń ṣiṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀), nítorí pé kìkì ọjọ́ Tuesday, Wednesday àti Thursday nìkan ni mò ń ṣiṣẹ́. Owó oṣù mi wá fi ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún dín kù sí ti tẹ́lẹ̀. Mo ta ilé wa mo sì ra ilé alágbèérìn lójú omi ká bàa lè lọ sìn lágbègbè táwọn akéde Ìjọba náà ò ti pọ̀. Nígbà tó yá, mo fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ láìtọ́jọ́; owó tó ń wọlé fún mi tún fi ìpín ogún nínú ìpín ọgọ́rùn-ún lọ sílẹ̀, àmọ́ mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé lọ́dún 1993.”

Lónìí, Jan wà lára Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn, gbogbo ìgbà ló sì ń ṣe alábòójútó àpéjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn ò fi Woth lọ́rùn sílẹ̀, síbẹ̀ ó máa ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóòrèkóòrè. Àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti ṣègbéyàwó báyìí, onítara òjíṣẹ́ Ìjọba náà sì ni gbogbo wọn àtọkọ àtaya.

Ọgbọ́n wo ni Jan àti Woth ń ta sí i pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé owó táṣẹ́rẹ́ ló ń wọlé fún wọn? Jan dáhùn pé: “Lọ́jọ́un àná, nígbà tówó wà lọ́wọ́ wa dáadáa, a ò jẹ́ káwọn nǹkan ti ara jẹ́ bàbàrà lójú wa. Èyí ni ò jẹ́ kó fi bẹ́ẹ̀ nira fún wa ní báyìí tó ti di pé a gbọ́dọ̀ ní sùúrù díẹ̀ ká tó lè ra àwọn ohun kan. Àmọ́ ìbùkún àtàwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ti ní kọjá gbogbo èyí láìmọye ọ̀nà.”

Dries àti Jenny ìyàwó rẹ̀ náà ṣe ohun tí Jan àti Woth ṣe, ìyẹn gbígbé ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ kí wọ́n lè túbọ̀ ráyè gbọ́ ti ọ̀rọ̀ Ìjọba náà. Aṣáájú ọ̀nà ni Dries àti Jenny títí dìgbà tí wọ́n bímọ. Kí Dries bàa lè bójú tó ìdílé rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe olùdarí ilé iṣẹ́ ńlá kan. Iṣẹ́ rẹ̀ wú àwọn ọ̀gá rẹ̀ lórí gan-an débí pé wọ́n láwọn á fún un ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́. Àmọ́ Dries kọ̀ pé òun ò fẹ́ ìgbéga yìí nítorí pé kò ní jẹ́ kí òun ráyè tó pọ̀ tó fún àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni.

Bíbójú tó ìdílé—àti bíbójú tó ìyá Jenny tó ń ṣàìsàn—ń gba àkókò àti okun tọkọtaya yìí gan-an. Síbẹ̀, wọ́n ṣì ní ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Jenny ṣàlàyé pé: “Àwọn aṣáájú ọ̀nà ń gbé lọ́dọ̀ wa, a máa ń pe àwọn aṣáájú ọ̀nà wá sílé wa láti wá bá wa jẹun, àwọn alábòójútó àyíká sì máa ń dé sílé wa.” Dries fi kún un pé: “Ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ là ń gbé, a kì í sì í kọrùn bọ gbèsè. A pinnu pé a ò ní ṣe òwò tó máa gba gbogbo àkókò wa tàbí kí á ra ilé, káwọn nǹkan yìí má bà a dí wa lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú.”

Ìpinnu tí Dries àti Jenny ṣe láti ṣe àwọn ètò tó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lákòókò fún àwọn ìgbòkègbodò Ìjọba náà méso rere jáde. Àwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì ló ti di alàgbà báyìí, ọ̀kan lára wọn àti ìyàwó rẹ̀ sì ń ṣe aṣáájú ọ̀nà. Dries àti Jenny wá ń ṣe aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, nígbà tó sì yá Jenny bẹ̀rẹ̀ sí bá Dries káàkiri nínú iṣẹ́ àyíká. Wọ́n ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì báyìí, Dries sì wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka.

Fífẹ̀yìntì Láìtọ́jọ́

Otto àti Judy ìyàwó rẹ̀ náà ṣe bíi ti Dries àti Jenny, wọ́n ṣe aṣáájú ọ̀nà kí wọ́n tó bí àwọn ọmọ wọn obìnrin méjèèjì. Nígbà tí Judy lóyún àkọ́bí wọn, Otto bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ olùkọ́.

Nígbà táwọn ọmọ náà ń dàgbà, Otto àti Juddy máa ń gba àwọn aṣáájú ọ̀nà lálejò nílé wọn káwọn ọmọ wọn lè rí báwọn Kristẹni òṣìṣẹ́ alákòókò kíkún ṣe ń láyọ̀. Nígbà tó ṣe, ọmọbìnrin wọn àkọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Nígbà tó yá, ó tẹ̀ lé ọkọ rẹ̀ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n sì ti di míṣọ́nnárì báyìí ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà. Ọmọbìnrin wọn kejì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ́dún 1987, Judy náà sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà.

Nígbà tí ipò nǹkan tó ń yí padà mú kí àkókò tí Otto fi ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìwé dín kù, ó lo àkókò náà láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Nígbà tó sì yá, ó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ pátápátá. Lónìí tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ arìnrìn àjò, Otto ń lo ìmọ̀ tó ní gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ láti gbé àwọn ìjọ ró nípa tẹ̀mí.

Ìmọ̀ràn wo ni Otto fún àwọn tó láǹfààní láti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ láìtọ́jọ́? Ó ní: “Tó o bá ti fẹ̀yìn tì, má ṣe sọ pé o fẹ́ fi odidi ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sinmi o. Ó rọrùn gan-an kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ‘jókòó tẹtẹrẹ.’ Kó o tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wàá ti gbàgbé ohun tó ń jẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Dípò ìyẹn, bẹ̀rẹ̀ sí fi kún ìgbòkègbodò rẹ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti nínú ìjọ ní kíá mọ́sá.”

Lílo Ìrírí Ìgbésí Ayé Lọ́nà Tó Dáa

Òótọ́ ni pé àwọn arákùnrin bíi Pum, Jan, Dries àti Otto kò lókun àti agbára mọ́ báyìí bíi tìgbà tí wọ́n wà léwe. Àmọ́ wọ́n dàgbà dénú gan-an, wọ́n ní ìrírí àti ọgbọ́n tó pọ̀. (Òwe 20:29) Wọ́n mọ iṣẹ́ tó wà nídìí jíjẹ́ baba, pẹ̀lú bí wọ́n sì ṣe bá àwọn aya wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, wọ́n tún mọ díẹ̀ lára iṣẹ́ àwọn abiyamọ. Àwọn àti ìyàwó wọn ti kojú ìṣòro ìdílé wọ́n sì ti gbé àwọn nǹkan tẹ̀mí ka iwájú àwọn ọmọ wọn láti máa lépa. Otto sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, tí mo bá fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìdílé, ìmọ̀ràn mi máa ń gbéṣẹ́ gan-an nítorí pé èmi náà ti tọ́mọ rí. Bákan náà, ìrírí tí Dries ti ní gẹ́gẹ́ bí baba jẹ́ kó wúlò gan-an fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ tó jẹ́ ọ̀dọ́ níbẹ̀.

Dájúdájú, ìrírí táwọn arákùnrin yìí ti ní ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bójú tó onírúurú ọ̀ràn tó bá ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ. Ìrírí wọn yìí ló dà bí èyí tó ń pọ́n irin iṣẹ́ tí wọ́n ń lò, èyí ń bù sí ìsapá wọn, ó sì ń mú àǹfààní ńláǹlà wá. (Oníwàásù 10:10) Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé láàárín àkókò kan pàtó, ohun tí wọ́n ń gbé ṣe ju èyí táwọn tí ara wọn le àmọ́ tí wọn ò nírìírí ń ṣe lọ fíìfíì.

Àpẹẹrẹ rere làwọn arákùnrin wọ̀nyí àtàwọn ìyàwó wọn jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ láàárín àwọn èèyàn Jèhófà. Àwọn ọ̀dọ́ mọ̀ pé irú àwọn tọkọtaya wọ̀nyí ti kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro wọ́n sì ti rí ọ̀pọ̀ ìbùkún irú àwọn tá à ń kọ sínú àwọn ìtẹ̀jáde àwa Kristẹni. Ìṣírí ńláǹlà ló jẹ́ láti rí tọkùnrin tobìnrin tí wọ́n ń fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ hàn bíi ti Kálébù tó béèrè pé kí Jèhófà fún òun ní iṣẹ́ tó le bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti darúgbó.—Jóṣúà 14:10-12.

Fara Wé Ìgbàgbọ́ Wọn

Ǹjẹ́ o lè fara wé ìgbàgbọ́ àti ìṣe àwọn tọkọtaya tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí? Rántí pé òtítọ́ náà lohun tó jà jù nínú ìgbésí ayé wọn. Wọ́n gbin ìfẹ́ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sọ́kàn àwọn ọmọ wọn. Gẹ́gẹ́ bí Jan ṣe sọ, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ “nípa fífi hàn wọ́n pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀, nípa ṣíṣètò fún ìbákẹ́gbẹ́ tó jíire, àti nípa kíkọ́ àwọn ọmọ náà ní bí wọ́n ṣe lè di ẹni tó tó ẹrù ara wọn gbé.” Wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ wọ́n sì máa ń ṣeré pa pọ̀ bí ìdílé. Pum rántí pé: “Lákòókò ọlidé, ńṣe la jọ máa ń lọ sóde ẹ̀rí láàárọ̀ tá ó sì jọ lọ gbafẹ́ tó bá di ọ̀sán.”

Kò tán síbẹ̀ o, àwọn Kristẹni wọ̀nyí máa ń ṣètò ṣáájú àkókò, tó fi jẹ́ pé tí ipò àwọn nǹkan bá yí padà wọ́n á lè lo àǹfààní náà lọ́nà tó dáa. Wọ́n máa ń gbé àwọn góńgó tí wọ́n fẹ́ lé bá kalẹ̀ wọ́n á sì ṣe àwọn ìpinnu táá jẹ́ kí ọwọ́ wọn lè tètè tẹ àwọn góńgó náà. Wọ́n máa ń wá ọ̀nà tí wọ́n á fi dín iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kù wọ́n sì máa ń múra tán láti máa gbé ìgbésí ayé wọn pẹ̀lú ìwọ̀nba owó táṣẹ́rẹ́ tó bá ń wọlé. (Fílípì 1:10) Àwọn ìyàwó wọn tún máa ń tì wọ́n lẹ́yìn gbágbáágbá. Wọ́n jùmọ̀ fẹ́ láti gba “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” wọlé, èyí á sì mú kí wọ́n rí ìbùkún rẹpẹtẹ látọ̀dọ̀ Jèhófà.—1 Kọ́ríńtì 16:9; Òwe 10:22.

Ṣé ìwọ náà fẹ́ mú ipa tó ò ń kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà gbòòrò sí i? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, lílo ipò àwọn nǹkan tó ń yí padà lọ́nà tó dáa lè fún ọ láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Pum àti Anny ń bójú tó Gbọ̀ngàn Àpéjọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Jan àti Woth wa lóde ẹ̀rí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Dries àti Jenny ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Otto àti Judy ń múra láti lọ bẹ ìjọ tó kàn wò