Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwá Ìjọba náà Lákọ̀ọ́kọ́ Ló Jẹ́ Kí Ìgbésí Ayé Wa Kún fún Ìfọ̀kànbalẹ̀ àti Ayọ̀

Wíwá Ìjọba náà Lákọ̀ọ́kọ́ Ló Jẹ́ Kí Ìgbésí Ayé Wa Kún fún Ìfọ̀kànbalẹ̀ àti Ayọ̀

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Wíwá Ìjọba náà Lákọ̀ọ́kọ́ Ló Jẹ́ Kí Ìgbésí Ayé Wa Kún fún Ìfọ̀kànbalẹ̀ àti Ayọ̀

GẸ́GẸ́ BÍ JETHA SUNAL ṢE SỌ Ọ́

Lẹ́yìn tá a jẹ oúnjẹ àárọ̀ tán la gbọ́ ìkéde náà lórí rédíò pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòdì sófin, a sì ti fòfin de iṣẹ́ wọn.”

ỌDÚN 1950 ni, àwa obìnrin mẹ́rin tá a ti lé lẹ́ni ogún ọdún ń sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Dominican Republic lákòókò náà. Ó ti tó ọdún kan táa ti dé síbẹ̀.

Iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì kọ́ ni mo ní lọ́kàn láti fi ìgbésí ayé mi ṣe. Òótọ́ ni pé mo máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì nígbà tí mo wà lọ́mọdé. Ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ń lọ lọ́wọ́ ni bàbá mi ò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Lọ́jọ́ tí mò ń ṣe ayẹyẹ ìgbọ́wọ́léni nínú Ìjọ Oníbíṣọ́ọ̀bù lọ́dún 1933, ẹsẹ kan ṣoṣo péré ni bíṣọ́ọ̀bù kà látinú Bíbélì, tó wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa ìṣèlú. Ọ̀rọ̀ náà bí màmá mi nínú gan-an débi pé kò tún padà dé ṣọ́ọ̀ṣì náà mọ́.

Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Wa Yí Padà

Ọmọ márùn-ún làwọn òbí mi tórúkọ wọn ń jẹ́ William Karl àti Mary Adams bí. Orúkọ àwọn ọmọ wọn ọkùnrin ń jẹ́ Don, Joel, àti Karl. Joy àbúrò mi obìnrin ni wọ́n bí gbẹ̀yìn, èmi sì ni àgbà gbogbo wọn. Màá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọmọ ọdún mẹ́tàlá nígbà tí mo ti ilé ìwé dé lọ́jọ́ kan tí mo bá Mọ́mì níbi tó ti ń ka ìwé kékeré kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. Àkòrí ìwé náà ni Ijọba Na, Ireti Aiye. Ó wá sọ fún mi pé: “Òtítọ́ lèyí.”

Gbogbo wa pátá ni Mọ́mì sọ nípa ohun tó ń kọ́ látinú Bíbélì fún. Nípa ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀, ó tẹ ìjẹ́pàtàkì ìmọ̀ràn Jésù yẹn mọ́ wa lọ́kàn pé: ‘Ẹ máa wá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.’—Mátíù 6:33.

N kì í fẹ́ gbọ́ ohun tí Mọ́mì ń sọ rárá. Ìgbà kan wà tí mo sọ pé: “Mọ́mì, ẹ yé wàásù fún mi o, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ mi ò ní bá yín nu àwo mọ́.” Síbẹ̀ ó máa ń fọgbọọgbọ́n bá wa sọ̀rọ̀. Ó máa ń kó gbogbo wa lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe nílé Clara Ryan, tí ilé rẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sílé wa ní Elmhurst, Illinois, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.

Clara tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní dùùrù títẹ̀. Nígbà táwọn tó ń kọ́ lórin bá lọ síbi tí gbogbo gbòò ti máa ń forin dánra wò lọ́dọọdún, ó máa ń lo àǹfààní yẹn láti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ìrètí àjíǹde. Èmi náà nífẹ̀ẹ́ sórin kíkọ nítorí pé mo ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń ta gòjé látìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún méje, ìyẹn ló wá jẹ́ ki n bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sí ọ̀rọ̀ tí Clara ń sọ.

Láìpẹ́, a bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé Mọ́mì lọ sáwọn ìpàdé ìjọ ní apá ìwọ̀ oòrùn Chicago. Ọ̀nà jíjìn tùnnù-tunnu tá a máa ń wọ bọ́ọ̀sì àti tasí ìgboro ká tó débẹ̀ ni, àmọ́ ó jẹ́ ara ẹ̀kọ́ tá a ti kọ́ látìbẹ̀rẹ̀ nípa ohun tó túmọ̀ sí láti wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́. Mo tẹ̀ lé Mọ́mì lọ sí àpéjọ kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní Chicago lọ́dún 1938, ìyẹn ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí Mọ́mì ṣèrìbọmi. Ibí yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àádọ́ta ìlú ńlá tí wọ́n ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àpéjọ yìí látinú tẹlifóònù orí rédíò. Ohun tí mo gbọ́ níbẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin.

Síbẹ̀, ìfẹ́ tí mo ní sórin ò kúrò lọ́kàn mi. Mo gboyè jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga lọ́dún 1938, Bàbá sì ṣètò pé kí n lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa orin ní American Conservatory of Music ní Chicago. Fún ìdí yìí, ọdún méjì tó tẹ̀ lé e ni mo fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa orin, mo bá ẹgbẹ́ olórin méjì kọrin, mo sì ronú pé iṣẹ́ yẹn ni mo máa ṣe jálẹ̀ ìgbésí ayé mi.

Yúróòpù ni tíṣà mi, ìyẹn Herbert Butler, tó ń kọ́ mi ni gòjé títa, ti kúrò tó wá ń gbé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Mo fún un ní ìwé kékeré náà, Refugees, a lérò pe ó ṣeé ṣe kó kà á. Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, ìgbà tá a parí kíláàsì lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e ló sọ fún mi pé: “Jetha, o mọ gòjé ta dáadáa, tó o bá sì fojú sí ẹ̀kọ́ rẹ, o lè ríṣẹ́ sílé iṣẹ́ rédíò olórin tàbí kó o máa kọ́ àwọn èèyàn lórin.” Ó wá tọ́ka sí ìwé tí mo fún un yẹn, ó ní: “Àmọ́, mo lérò pé inú ohun tó wà nínú ìwé yìí lọ́kàn rẹ wà. O ò ṣe kúkú fi èyí ṣe iṣẹ́ tó o máa ṣe nígbèésí ayé rẹ?”

Mo ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó sọ yẹn. Dípò kí n máa bá ẹ̀kọ́ mi lọ nílé ẹ̀kọ́ náà, mo gbà láti tẹ̀ lé Mọ́mì lọ sí àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣe ní Detroit, Michigan, ní July 1940. Inú ahéré kan la gbé ní ìlú tí wọ́n kó ọkọ̀ àfiṣelé sí. Àmọ́ mo gbé gòjé mi dání o, mo sì ta á níbi orin àpéjọ náà. Ṣùgbọ́n mo pàdé ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà (ìyẹn àwọn oníwàásù alákòókò kíkún) ní ìlú ọlọ́kọ̀ àfiṣelé náà. Inú gbogbo wọn dùn kọjá ààlà. Mo pinnu láti ṣe batisí kí n sì fọwọ́ síwèé láti di aṣáájú ọ̀nà. Mo gbàdúrà sí Jèhófà kó lè jẹ́ kí n máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún náà lọ jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé mi.

Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní ìlú mi. Ẹ̀yìn ìyẹn ni mo lọ sìn ní Chicago. Mo kó lọ sí Kentucky ní 1943. Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn, ṣáájú àpéjọ àgbègbè ni mo rí ìwé gbà pé kí n wá sí kíláàsì kejì ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, níbi tí mo ti máa gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì. September 1943 ni kíláàsì náà máa bẹ̀rẹ̀.

Lákòókò àpéjọ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn, mo dé sọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí kan tó fún mi ni gbogbo ohun tó wù mí nínú àpótí tí ọmọ rẹ̀ kó aṣọ sí. Ọmọ rẹ̀ obìnrin ti lọ wọṣẹ́ ológun, ó sì sọ pé kí ìyá òun fi gbogbo ẹrù òun tọrẹ. Lójú tèmi, ohun tó fún mì wọ̀nyí dà bí ìmúṣẹ ìlérí Jésù tó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:33) Kò pẹ́ rárá tí oṣù márùn-ún tá a lò ní Gílíádì fi pé, bá a ṣe ń parí ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ní January 31, 1944 ni mo ti ń hára gàgà láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì.

Àwọn Náà Yan Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún

Mọ́mì ti wọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní 1942. Àwọn àbúrò mi ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àtàbúrò mi obìnrin ṣì wà nílé ìwé lákòókò yẹn. Mọ́mì sábà máa ń kó wọn lọ sóde ẹ̀rí nígbà tí wọ́n bá ti ilé ìwé dé. Ó tún kọ́ wọn bá a ṣe ń ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé. Òun alára kì í tètè sùn, á máa lọṣọ á sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tó yẹ ní ṣíṣe kó lè lọ sóde ẹ̀rí lójú mọmọ.

Ní January 1943, nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní Kentucky, Don àbúrò mi ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Èyí dun Dádì gan-an, nítorí ó fẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ òun lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga bíi ti òun àti Mọ́mì. Lẹ́yìn tí Don ti ṣe aṣáájú ọ̀nà fún nǹkan bí ọdún méjì, wọ́n pè é láti wá máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún rẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn, New York.

Joel bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní June 1943 nígbà tó ṣì wà nílé. Lákòókò yẹn ló gbìyànjú láti rọ Dádì pé kó wá sí àpéjọ kan, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá rẹ̀ já sí. Àmọ́, nígbà tí Joel sa gbogbo ipá rẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lágbègbè yẹn tí ò sì ṣeé ṣe fún un ni Dádì wá gbà pé kó wá máa bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé “Otitọ Yio Sọ Nyin Di Ominira.” Ó máa ń dáhùn àwọn ìbéèrè ibẹ̀ dáadáa, àmọ́ á wá ní kí Joel fi ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ ti ohun tí ìwé náà sọ lẹ́yìn. Ìyẹn ló wá ran Joel lọ́wọ́ tó fi fọwọ́ dan-indan-in mú òtítọ́ Bíbélì gan-an.

Joel rò pé Ìgbìmọ̀ Tó Ń Yanni fún Iṣẹ́, èyí tó fún Don ní ìwé àṣẹ pé kó má wọṣẹ́ ológun nítorí pé ó jẹ́ òjíṣẹ́ ìsìn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ fún òun náà pẹ̀lú. Àmọ́ nígbà tí ìgbìmọ̀ náà rí bí Joel ṣe kéré tó, wọ́n kọ̀ láti yàn án gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìsìn, wọ́n wá fi ìwé ṣọwọ́ sí i pé kó wá wọṣẹ́ ológun. Nígbà tó kọ̀ láti lọ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́, wọ́n ní kí wọ́n lọ mú un. Nígbà tí Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ (FBI) rí i mú, ó lo ọjọ́ mẹ́ta ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Cook County.

Dádì fi ilé wa dógò kí wọ́n lè dá a sílẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún ṣe ohun kan náà fún àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tó bára wọn ní ipò kan náà. Bí wọn ò ṣe dá ẹjọ́ náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ bí bàbá mi nínú gan-an, ó sì tẹ̀ lé Joel lọ sí Washington, D.C., láti lọ mọ̀ bóyá ó ṣeé ṣe láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Níkẹyìn, wọ́n fún Joel ní ìwé àṣẹ tó fi hàn pe ó ti di òjíṣẹ́ ìsìn, wọ́n sì tú ẹjọ́ náà ká. Bàbá mi kọ̀wé sí mi níbi tí mo ti ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ó ní: “Jèhófà ló yẹ ká yìn lógo fún ìṣẹ́gun yìí!” Nígbà tó fi máa di August 1946, wọ́n ti pe Joel pé kí òun náà wá sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ orílé iṣẹ́ ní Brooklyn.

Karl ṣe aṣáájú ọ̀nà láwọn àkókò tó wà lọ́lidé, ó ṣe èyí lọ́pọ̀ ìgbà kó tó jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1947 tó sì wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ara Dádì ti ń dara àgbà lákòókò yẹn, Karl wá ń bá Dádì bójú tó iṣẹ́ okòwò rẹ̀ fúngbà díẹ̀ kó tó di pé ó lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà níbòmíràn. Ní òpin ọdún 1947, Karl náà bẹ̀rẹ̀ sí sìn pẹ̀lú Don àti Joel gẹ́gẹ́ bí ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní orílé iṣẹ́ wa ní Brooklyn.

Nígbà tí Joy ṣe tán nílé ẹ̀kọ́ gíga, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà. Nígbà tó sì di 1951, ó lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì. Ó ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìtọ́jú ilé àti Ẹ̀ka Ìforúkọsílẹ̀ fún Ìwé. Ní 1955, ó fẹ́ Roger Morgan, tí òun náà jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Ní nǹkan bí ọdún méje lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n yàn láti ní ìdílé tiwọn, wọ́n sì fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, wọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn méjèèjì dàgbà, àwọn yẹn náà sì ń sin Jèhófà.

Nígbà tí gbogbo àwa ọmọ ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, Mọ́mì gba Dádì níyànjú gan-an débi pé Dádì náà ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ṣe batisí ní 1952. Fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún gbáko, títí dọjọ́ ikú rẹ̀, ló fi jẹ́ ògbóṣáṣá nínú wíwá ọ̀nà láti sọ òtítọ́ Ìjọba náà fáwọn ẹlòmíràn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn ò jẹ́ kó ṣe tó bó ṣe fẹ́.

Lẹ́yìn tí Mọ́mì dáwọ́ dúró fúngbà díẹ̀ nítorí àìsàn Dádì, ó tún ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà rẹ̀ lọ títí tó fi kú. Kò ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò gun kẹ̀kẹ́ rí. Èèyàn kúkúrú ni, kò síbi tí ò fẹsẹ̀ rìn dé, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń rìn lọ sáwọn àgbègbè àrọko, láti lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì Yá

Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, àwa bíi mélòó kan ṣe aṣáájú ọ̀nà ní apá àríwá New York City fún ọdún kan ká tó rí ìwé àṣẹ ìrìn-àjò gbà. Níkẹyìn, ní 1945, a forí lé ibi tí wọ́n yàn wá sí, ìyẹn Cuba, níbi tí ọ̀nà ìgbésí ayé tuntun ti wá mọ́ wa lára ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Àwọn èèyàn ibẹ̀ tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ìwàásù wa, kò sì pẹ́ tí gbogbo wa fi bẹ̀rẹ̀ sí darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọdún bíi mélòó kan la fi sìn níbẹ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n tún yàn wá sí Dominican Republic. Lọ́jọ́ kan, mo pàdé obìnrin kan tó bẹ̀ mí pé kí n rí oníbàárà òun kan, ìyẹn obìnrin ará Faransé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Suzanne Enfroy, tó ń wá ẹni tó máa ran òun lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì.

Júù ni Suzanne, ìgbà tí Hitler fogun ká ilẹ̀ Faransé mọ́ ni ọkọ rẹ̀ yára kó òun àtàwọn ọmọ wọn méjèèjì lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn. Kíá ni Suzanne bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn ẹlòmíràn. Ó kọ́kọ́ sọ ọ́ fún obìnrin tó sọ pé kí n lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ yẹn, ẹ̀yìn ìyẹn ló wá sọ ọ́ fún Blanche, ìyẹn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó wá láti ilẹ̀ Faransé. Àwọn méjèèjì ló sì tẹ̀ síwájú títí tí wọ́n fi ṣèrìbọmi.

Suzanne wá bi mí pé: “Kí ni mo lè ṣe láti ran àwọn ọmọ mi lọ́wọ́?” Ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ń kọ́ nípa ìṣègùn, ọmọ rẹ̀ obìnrin sì ń kọ́ ijó alálọ̀ọ́yípo, pẹ̀lú ìrètí àtilọ máa jó ní Gbọ̀ngàn Orin Ilé Iṣẹ́ Rédíò ní New York. Suzanne wá ṣètò àsansílẹ̀ Ilé Ìṣọ́ àti Jí! fún wọn. Nípa kíka àwọn ìwé wọ̀nyí, ọmọ Suzanne ni o, ìyàwó ọmọ rẹ̀ ni o, àti obìnrin tí òun àti aya ọmọ rẹ̀ jọ jẹ́ ìbejì pàápàá, gbogbo wọn ló di Ẹlẹ́rìí. Ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ba Louis, nítorí ìfẹ́ tí ìyàwó rẹ̀ Suzanne, ní sí ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí pé ìjọba Dominican Republic ti gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ wa lákòókò yẹn. Àmọ́ nígbà tí gbogbo ìdílé wọn wá kó lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, òun náà di Ẹlẹ́rìí ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀.

A Wà Lábẹ́ Ìfòfindè àmọ́ A Ṣì Ń Sìn

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pẹ́ tá a dé Dominican Republic nígbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀ lọ́dún 1949, ìpinnu wa ni pé Ọlọ́run la ó ṣègbọràn sí gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn. (Ìṣe 5:29) À ń bá a lọ láti máa wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́ nípa sísọ ìhìn rere nípa rẹ̀ di mímọ̀, bí Jésù ṣe pa á láṣẹ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe. (Mátíù 24:14) Àmọ́, a wá kọ́ láti jẹ́ ‘oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ a tún jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà’ bá a ṣe ń bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ. (Mátíù 10:16) Bí àpẹẹrẹ, gòjé mi ṣèrànwọ́ gan-an ni. Gbogbo ibi tí mo bá ti lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni mo máa ń gbé e dání lọ. Àwọn tí mò ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ò di atagòjé o, àmọ́ àwọn ìdílé bíi mélòó kan lára wọn di ìránṣẹ́ Jèhófà!

Nígbà tí ìfòfindè náà bẹ̀rẹ̀, àwa obìnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin—ìyẹn èmi, Mary Aniol, Sophia Soviak, àti Edith Morgan—ni wọ́n kó kúrò ní ilé míṣọ́nnárì tó wà ní San Francisco de Macorís tí wọ́n sì kó wa lọ sí ilé míṣọ́nnárì tó wà ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ní Santo Domingo, tó jẹ́ olú ìlú. Àmọ́ oṣooṣù ni mo máa ń rìnrìn àjò lọ síbi tó jẹ́ ìpínlẹ̀ tiwa gan-an láti lọ kọ́ àwọn èèyàn lórin níbẹ̀. Ìyẹn ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti máa kó oúnjẹ tẹ̀mí sínú àpò gòjé mi lọ fáwọn Kristẹni arákùnrin wa tó wà níbẹ̀, tí mo sì ń bá wọn kó ìròyìn iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn wá sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́.

Nígbà tí wọ́n fi àwọn arákùnrin wa láti San Francisco de Macorís sẹ́wọ̀n ní Santiago nítorí àìdásí-tọ̀túntòsì wọn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, èmi ni wọ́n ní kó lọ fún wọn lówó, tó bá sì ṣeé ṣe kí n tún fún wọn ní Bíbélì, kí n sì wá sọ bí wọ́n ṣe ń ṣe sí fáwọn ìdílé wọn. Nígbà táwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Santiago rí àpò gòjé tí mo gbé kọ́ apá, wọ́n bi mí pé, “Kí lo fẹ́ fìyẹn ṣe?” Mo dáhùn pé, “Mo fẹ́ fi dá wọn lára yá.”

Ọ̀kan lára àwọn orin tí mo fi gòjé kọ ni èyí tí Ẹlẹ́rìí kan kọ sínú ìwé nígbà tó wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Násì. Orin yẹn ni orin 29 nínú ìwé orin àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí. Mo fi gòjé kọ orin yẹn gan-an káwọn arákùnrin wa tó wà lẹ́wọ̀n lè mọ̀ ọ́n kọ.

Wọ́n sọ fún mi pé púpọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà ni wọ́n ti kó lọ sí oko kan tó jẹ́ ti Trujillo, olórí ìjọba. Wọ́n ní ibẹ̀ ò jìnnà síbi tí bọ́ọ̀sì máa ń dé dúró. Bó ṣe ń di ọwọ́ ọ̀sán ni mo bọ́ sílẹ̀ láti inú bọ́ọ̀sì mò wá béèrè ọ̀nà tó lọ sí oko náà. Ẹni tó ni ṣọ́ọ̀bù ìtajà kékeré kan tọ́ka síbi tó wà ní ìsọdá àwọn òkè bíi mélòó kan ó sì sọ pé òun á fún mi ní ẹṣin òun àti ọmọkùnrin kan tó máa fọ̀nà hàn mí, bí mo bá ti lè fi gòjé mi dógò.

Bá a ṣe ré kọjá àwọn òkè wọ̀nyẹn la rí odò kan tá a máa sọdá, àwa méjèèjì sì wà lórí ẹṣin náà bó ṣe ń lúwẹ̀ẹ́ lọ. Ibẹ̀ la ti rí agbo àwọn ayékòótọ́, tí wọ́n ní àwọ̀ ewéko àti àwọ̀ búlúù àti oríṣiríṣi àwọ̀ mìíràn tí ìyẹ́ wọn ń tàn yinrin nínú oòrùn. Àrímáleèlọ ni wọn! Mo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ pé: “Jèhófà, o ṣeun bó o ṣe fẹwà jíǹkí wọn.” Níkẹyìn, a dé oko náà láago mẹ́rin ọ̀sán. Àwọn sójà tó ń bójú tó ọgbà náà fún mi láyè láti bá àwọn arákùnrin náà sọ̀rọ̀, wọ́n sì jẹ́ kí n kó gbogbo ohun tí mo kó wá fún wọn, títí kan Bíbélì kékeré kan.

Nígbà tá à ń padà bọ̀, ńṣe ni mo ṣáà ń gbàdúrà ṣáá, nítorí pé ilẹ̀ ti ṣú lákòókò yẹn. Òjò ti rẹ wá gbingbin nígbà tá a fi máa padà dé ṣọ́ọ̀bù náà. Nítorí pé bọ́ọ̀sì tó máa lọ kẹ́yìn lọ́jọ́ yẹn ti lọ, mo bẹ oníṣọ́ọ̀bù náà pé kó bá mi dá ọkọ akẹ́rù kan tó ń kọjá dúró. Ǹjẹ́ ẹ̀mí mi dè báyìí bí mo ṣe wà nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin méjì yìí? Ọ̀kan lára wọn bi mi pé: “Ǹjẹ́ o mọ Sophie? Òun ló ń bá àbúrò mi obìnrin ṣèkẹ́kọ̀ọ́.” Mo wá rí i pé ọ̀nà tí Jèhófà gbà gbọ́ àdúrà mi nìyí! Wọ́n gbé mi dé Santo Domingo láìséwu.

Ní 1953, mo wà lára àwọn tó ti Dominican Republic wá sí àpéjọ àgbáyé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní Pápá Ìṣeré Yankee nílùú New York. Gbogbo ìdílé mi, títí kan bàbá mi ló wà níbẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ka ìròyìn nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń tẹ̀ síwájú ní Dominican Republic, èmi àti Mary Aniol tó jẹ́ ẹnì kejì mi nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì, kópa kékeré kan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà tá a ti ṣàṣefihàn bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa lábẹ́ ìfòfindè.

Ayọ̀ Àrà Ọ̀tọ̀ Tó Wà Nínú Iṣẹ́ Arìnrìn-Àjò

Ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn ni mo pàdé Rudolph Sunal, tó wá di ọkọ mi ní ọdún tó tẹ̀ lé e. Ìdílé rẹ̀ ti di Ẹlẹ́rìí ní Allegheny, Pennsylvania, ní kété tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí. Lẹ́yìn tó parí àkókò tó fi ṣẹ̀wọ̀n gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tí kò dá sí tọ̀túntòsì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ló wá bẹ̀rẹ̀ sí í sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn, New York. Kété lẹ́yìn tá a ṣe ìgbéyàwó ni wọ́n sọ pé kó lọ máa bẹ àwọn ìjọ wó gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Ọdún méjìdínlógún tó tẹ̀ lé e ni mo fi ń bá a lọ káàkiri nínú iṣẹ́ àyíká.

Lára ibi tí iṣẹ́ àyíká wa gbé wa dé ni Pennsylvania, West Virginia, New Hampshire, àti Massachusetts. Ilé àwọn Kristẹni arákùnrin wa la sábà máa ń dé sí. Ayọ̀ àrà ọ̀tọ̀ ló jẹ́ láti mọ̀ wọ́n dáadáa àti láti sin Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú wọn. Ìfẹ́ àti aájò àlejò tí wọ́n máa ń fi hàn sí wa kì í ṣe ti ojú ayé rárá. Lẹ́yìn tí Joel fẹ́ Mary Aniol, tó jẹ́ ẹnì kejì mi nínú iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀, wọ́n lo ọdún mẹ́ta lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò, wọ́n bẹ àwọn ìjọ wò ní Pennsylvania àti Michigan. Lẹ́yìn náà, ní 1958, wọ́n tún pe Joel pé kó wá di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì lẹ́ẹ̀kan sí i, àmọ́ òun àti Mary ni lọ́tẹ̀ yìí.

Karl ti wà ní Bẹ́tẹ́lì fún nǹkan bí ọdún méje nígbà tí wọ́n ní kó lọ ṣe iṣẹ́ àyíká fún oṣù díẹ̀ kó lè túbọ̀ nírìírí sí i. Nígbà tó yá ó di olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ní 1963, ó fẹ́ Bobbie, tó fi ìṣòtítọ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì títí tó fi kú ní October 2002.

Láàárín ọ̀pọ̀ ọdún tí Don lò ní Bẹ́tẹ́lì, ó máa ń rìnrìn àjò lọ sáwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti lọ bẹ àwọn tó wà ní àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ àtàwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì wò. Iṣẹ́ rẹ̀ ti gbé e dé Ìlà Oòrùn Ayé, Áfíríkà, Yúróòpù, àti onírúurú ibi nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Dolores, ìyàwó àtàtà tí Don fẹ́ sábà máa ń tẹ̀ lé e lọ.

Ipò Nǹkan Yí Padà

Bàbá mi kú lẹ́yìn àìsàn tó ti ń ṣe é tipẹ́, àmọ́ kó tó kú, ó sọ̀ fún mi pé inú òun dùn gan-an pé a yàn láti sin Jèhófà Ọlọ́run. Ó ní a ti rí ọ̀pọ̀ jaburata ìbùkún gbà ju èyí tí à bá rí ká ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́lẹ́ẹ̀jì tóun ní lọ́kàn fún wa là ń lé kiri. Lẹ́yìn tí mo ran Mọ́mì lọ́wọ́ láti kó lọ sí ibì kan tó wà nítòsí ilé Joy, àbúrò mi, èmi àti ọkọ mi gbà láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà láwọn ìpínlẹ̀ bíi mélòó kan ní New England ká lè wa nítòsí ìyá rẹ̀, tó nílò ìrànlọ́wọ́ wa lákòókò yẹn. Lẹ́yìn tí ìyá rẹ̀ kú, ọdún mẹ́tàlá gbáko ni màmá mi fi gbé lọ́dọ̀ wa. Lẹ́yìn náà, ní January 18, 1987, ó parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún.

Gbogbo ìgbà táwọn ọ̀rẹ́ bá ti ń yin Mọ́mì fún bó ṣe tọ́ gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń sìn ín, ohun tó rọra fi ń dá wọn lóhùn ni pé: “Kì í ṣe mímọ̀ ọ́n ṣe mi pé mo rí ‘ilẹ̀’ rere gbin nǹkan sí.” (Mátíù 13:23) Ìbùkún ńlá ló mà jẹ́ o, láti ní àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí wọ́n fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún wa láti ní ìtara àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀!

Ìjọba Náà La Ṣì Fi Sípò Àkọ́kọ́

A ti ń bá a lọ láti fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa, a sì ti gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn Jésù sílò nípa wíwàásù rẹ̀ fáwọn ẹlòmíràn. (Lúùkù 6:38; 14:12-14) Jèhófà sì ti pèsè àwọn ohun tí a ṣaláìní lọ́pọ̀ yanturu. Ìgbésí ayé wa ti jẹ́ ìgbésí ayé aláyọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀.

Èmi àti Rudy ṣì nífẹ̀ẹ́ sí orin kíkọ gan-an. Inú wa sì máa ń dùn púpọ̀ nígbà táwọn mìíràn tó nífẹ̀ẹ́ sórin bá wá sílé wa nírọ̀lẹ́ ọjọ́ tá a bá fẹ́ dá àwọn èèyàn lára yá, tá a sì jùmọ̀ fi àwọn ohun èlò orin wa ṣeré. Àmọ́ orin kíkọ kọ́ ni iṣẹ́ mi. Ó kàn ń fi kún adùn ìgbésí ayé ni. Nísinsìnyí, béèyàn bá gẹṣin nínú èmi àti ọkọ mi, kò lè kọsẹ̀ nítorí bá a ṣe ń rí èso iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà wa, ìyẹn àwọn èèyàn tá a ti ràn lọ́wọ́ ní gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí.

Láìfi àwọn àìlera tá a wá ń ní báyìí pè, mo lè sọ pé ìgbésí ayé wa ti kún fún ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ láti ohun tó lé ní ọgọ́ta ọdún tá a ti wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Àràárọ̀ tí mo bá ti jí ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí pé ó dáhùn àdúrà tí mo gbà nígbà tí mo fẹ́ wọṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, mo sì máa ń rò ó pé, ‘Wàyí o, ọ̀nà wo ni ǹ bá tún gbà wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ lóde òní?’

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ̀ ẹ́ àmọ́ a ò ṣe é jáde mọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ìdílé wa lọ́dún 1948 (láti apá òsì sí apá ọ̀tún): Joy, Don, Mọ́mì, Joel, Karl, èmi, àti Dádì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Mọ́mì fi àpẹẹrẹ jíjẹ́ onítara nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lélẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Karl, Don, Joel, Joy àtèmi lónìí, ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Láti apá òsì sí àpá ọ̀tún: Èmi, Mary Aniol, Sophia Soviak, and Edith Morgan lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Dominican Republic

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Èmi àti Mary (lápá òsì) ní Pápá Ìṣeré Yankee

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi àti ọkọ mi nígbà tó wà nínú iṣẹ́ àyíká