Ọjọ́ Tá Ò Gbọ́dọ̀ Gbàgbé
Ọjọ́ Tá Ò Gbọ́dọ̀ Gbàgbé
ỌJỌ́ NÁÀ ló yí ọjọ́ iwájú ẹ̀dá èèyàn padà tí wọ́n fi ní ìrètí ìbùkún tí ò lópin. Kò tíì tún sírú ọjọ́ tó dà bí ọjọ́ yìí tó nípa rere lórí ọjọ́ iwájú ẹ̀dá èèyàn. Ọjọ́ ọ̀hún lọjọ́ tí Jésù parí gbogbo nǹkan tó wáyé wá ṣe. Wọ́n kàn án mọ́ igi oró, ó mí èémí àmígbẹ̀yìn ó sì kígbe pé: “A ti ṣe é parí!” (Jòhánù 19:30) Kí nìdí tí Jésù fi wá sáyé?
Bíbélì sọ pé: “Ọmọ ènìyàn . . . wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ tàbí ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ ká lè gba ẹ̀dá èèyàn là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí wọ́n ti jogún. Dájúdájú, “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ẹ ò rí i pé ìpèsè tó ṣe pàtàkì gan-an ni ẹbọ Jésù jẹ́!
Ìdí mìíràn tún wà tá ò fi gbọ́dọ̀ gbàgbé ọjọ́ tí Jésù kú. Lọ́jọ́ náà tí Ọmọ Ọlọ́run kú, ó kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó máa mú kí wọ́n dúró gbọn-in bí olóòótọ́. Kò sí ni, àwọn ọ̀rọ̀ tó bá wọn sọ gbẹ̀yìn yìí á wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an! Àwọn ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wọn? Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ náà tí Jésù kọ́ wọn? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.