Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ǹjẹ́ Ẹ̀ Ń Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí?

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ǹjẹ́ Ẹ̀ Ń Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí?

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ǹjẹ́ Ẹ̀ Ń Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí?

NÍGBÀ tí Hideo ronú padà sẹ́yìn sígbà tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama, ó sọ pé: “Bí mo tiẹ̀ ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, ìfẹ́ tí mo ní láti sin Jèhófà ò jinlẹ̀ rárá. Mo máa ń fojú inú wo ara mi bíi pé mo gbajúmọ̀ láàárín àwọn ọmọ kíláàsì mi tí mo sì ń yan fanda fanda láàárín ìgboro pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin kan. Mi ò ní góńgó kan pàtó tí mò ń lépa, mi ò sì nífẹ̀ẹ́ sí àtiní ìlọsíwájú kankan nípa tẹ̀mí.” Bí Hideo ṣe rí yẹn lọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ míì rí, tí wọ́n kàn wà ṣáá láìnífẹ̀ẹ́ sí lílépa góńgó tó ní láárí kankan tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ní ìlọsíwájú pàápàá.

Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ́ ni ẹ́, ó ṣeé ṣe kínú ẹ máa dùn ṣìnkìn nígbà tó o bá ń ṣe eré ìdárayá tàbí tó o bá ń ṣe ohun kan tó máa ń wù ẹ́ láti fi pawọ́. Àmọ́ tó bá dórí nǹkan tẹ̀mí ó lè má ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí góńgó tẹ̀mí múni lọ́kàn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀? Ọ̀rọ̀ onísáàmù yìí ni kó o gbé yẹ̀ wò tó sọ pé: “Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n. . . . Àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.” (Sáàmù 19:7, 8) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè mú kí “aláìní ìrírí” hùwà ọgbọ́n, kó sì ‘mú kí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀.’ Dájúdájú nǹkan tẹ̀mí lè máyọ̀ kúnnú rẹ. Àmọ́ kí ló máa mú kó o nírú ìmọ̀lára yẹn? Ibo ló yẹ kó o ti bẹ̀rẹ̀?

Jẹ́ Kí Ọkàn Rẹ Sún Ọ Láti Sin Ọlọ́run

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, o gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọkàn rẹ sún ọ gbé ìgbésẹ̀. Gbé àpẹẹrẹ ti Jòsáyà ọ̀dọ́ Ọba Júdà yẹ̀ wò. Nígbà tí wọ́n ṣàwárí ìwé Òfin Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì, Jòsáyà ní kí wọ́n kà á sóun létí, ohun tí wọ́n kà sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan an ni. Àbájáde rẹ̀ ni pé, “Jòsáyà mú gbogbo àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí kúrò nínú gbogbo àwọn ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (2 Kíróníkà 34:14-21, 33) Kíkà tí Jòsáyà ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sún un láti ṣe bẹbẹ ní gbígbé ìjọsìn tòótọ́ ga.

Ìwọ náà lè mú ìfẹ́ fún sísin Jèhófà dàgbà nínú ọkàn ẹ bó o bá ń ka Bíbélì déédéé tó o sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tó ò ń kà. Ohun tó sún Hideo gan-an nìyẹn. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá aṣáájú ọ̀nà àgbàlagbà kan rìn, ìyẹn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Aṣáájú Ọ̀nà náà jẹ́ ẹni tó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ gidigidi láti inú Bíbélì tó sì ń gbìyànjú láti fi ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Àpẹẹrẹ aṣáájú ọ̀nà yìí wú Hideo lórí débi pé òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í fara wé bó ṣe ń ṣe, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, ó sì ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ìtẹ̀síwájú tó ní nípa tẹ̀mí yìí yọrí sí ìgbésí ayé tó nítumọ̀ fún un.

Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ lè sún àwọn ọ̀dọ́ ṣe ohun tó dára. Takahiro sọ pé: “Nígbàkigbà tí mo bá fẹ́ sùn àmọ́ tí mo wá rántí lórí bẹ́ẹ̀dì pé mi ò tíì ka Bíbélì tó yẹ kí n kà lọ́jọ́ yẹn, ńṣe ni màá fò dìde kíá láti lọ kà á. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, mo wá ń rí i pé Jèhófà ń tọ́ mí sọ́nà. Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ ti ràn mí lọ́wọ́ gan an láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Kété lẹ́yìn tí mo jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga ni mo wọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà torí pé mo ti pinnu láti ṣe púpọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Bí oyin ṣe rí lẹ́nu gẹ́lẹ́ niṣẹ́ náà rí lára mi.”

Láfikún sí Bíbélì kíkà, kí ni nǹkan míì tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tí wàá fi túbọ̀ ní ìfẹ́ àtọkànwá láti yin Jèhófà? Ìyá Tomohiro ló kọ́ ọ ní òtítọ́ Bíbélì. Ó wá sọ pé: “Ìgbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Life Does Have a Purpose parí lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún ni mo tó wá mọrírì ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa àti ẹbọ ìràpadà Jésù. Ìmọrírì tí mo ní fún ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa yẹn ló sún mi láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.” (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni a sì ń gbà níyànjú bíi ti Tomohiro, pé kí wọn ní ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí bí wọ́n ti ń lépa láti fi taratara dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Pẹ̀lú ẹ̀ náà, bí ìfẹ́ tó o ní láti sin Jèhófà bá ṣì jẹ́ tojú ayé ńkọ́? Ṣe o lẹ́ni tó o lè yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín, . . . kí ẹ lè fẹ́ láti ṣe, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀.” (Fílípì 2:13) Jèhófà yóò rọ̀jò ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí ẹ tó máa fún ẹ lágbára kó o lè“fẹ́ láti ṣe” kó o sì “gbé ìgbésẹ̀” ìyẹn bó o bá gbàdúrà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ohun tí èyí wá túmọ̀ sí ni pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run á mú kó o ṣe bó o ṣe fẹ́ fi gbogbo agbára rẹ ṣe tó nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dọkùnrin nípa tẹ̀mí. Rí i dájú pé agbára Jèhófà lo gbẹ́kẹ̀ lé, kó o sì máyà le!

Gbé Àwọn Góńgó Tó O Máa Lépa Kalẹ̀

Gbàrà tó o bá ti pinnu pé o fẹ́ túbọ̀ sin Jèhófà sí i ló yẹ kó o gbé àwọn góńgó kan kalẹ̀ fúnra rẹ kó o lè ní ìlọsíwájú nípa tẹ̀mí. Kristẹni ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Mana sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ ńlá ni góńgó tí mo gbé kalẹ̀ ṣe fún mi. Kàkà kí n máa jó àjórẹ̀yìn, ńṣe ni mò ń tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìgboyà. Nítorí pé nǹkan tí mò ń lépa ló wà lọ́kàn mi, mo wá gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà pé kó tọ́ mi sọ́nà, torí náà, ó mú kí n ní ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí láìsí ohun mìíràn tó gbà mí láfiyèsí.

Góńgó tó ṣe é lé bá ló yẹ kó o gbé ka iwájú ẹ. Kíka orí kan nínú Bíbélì lójúmọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ góńgó tó mọ́gbọ́n dání. O lè dáwọ́ lé ṣíṣe ìwádìí nínú Bíbélì pàápàá. O lè fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tá a tò sínú ìwé Watch Tower Publications Index lábẹ́ ìsọ̀rí tó sọ pé “Qualities by Name” [Orúkọ Ànímọ́ Kọ̀ọ̀kan] lábẹ́ kókó ọ̀rọ̀ tá a pè ní “Jehovah”, ìyẹn tá a bá ní ká fi ohun tá a ti tẹ̀ jáde lèdè Gẹ̀ẹ́sì nìkan ṣàpèjúwe. Àwọn kókó tó o tún lè gbé yẹ̀ wò tó nǹkan bí ogójì. Láìsí àní-àní, ìwádìí náà á mú ẹ sún mọ́ Jèhófà, á sì koná mọ́ ẹ nídìí láti ṣiṣẹ́ tó pọ̀ fún un. Lára àwọn góńgó míì tó o lè lé bá ni pé, kó o dáhùn ìbéèrè nípàdé Kristẹni kọ̀ọ̀kan ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan nígbà tá a bá darí ìbéèrè sáwùjọ, kó o túbọ̀ dojúlùmọ̀ ó kéré tán ọ̀kan lára àwọn ará ìjọ ẹ nígbà ìpàdé kọ̀ọ̀kan, kó o má sì pa ọjọ́ kan jẹ láìtọ Jèhófà lọ nínú àdúrà kó o sì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fáwọn ẹlòmíràn.

Á ti lọ dára jù tó o bá fi ṣe góńgó ẹ láti forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn tó ò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ o ti ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba? Bó ò bá tíì bẹ̀rẹ̀ sí í jáde òde ẹ̀rí, o lè sakun kó o di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Láì tiẹ̀ tún sọ fún ọ, ohun tó máa kàn ni pé kó o ronú dáadáa nípa àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà kó o sì ya ara rẹ sí mímọ́ fún un. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ kan kó wọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kí wọn lè gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wọn.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára kó o ní góńgó tó ò ń lépa nínú ìgbésí ayé rẹ, síbẹ̀ o gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó o má lọ ní ẹ̀mí ìbánidíje. Ohun tó ò ń ṣe á jẹ́ kí ayọ̀ rẹ túbọ̀ kún sí i tó ò bá fi ara rẹ wé àwọn ẹlòmíràn.—Gálátíà 5:26; 6:4.

Bóyá ò ń ronú pé o ò nírìírí, pé á ṣòro fún ẹ láti gbé góńgó tó níláárí kan kalẹ̀. Tó bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Dẹ etí rẹ sílẹ̀ kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.” (Òwe 22:17) Wá ìmọ̀ràn àwọn òbí ẹ tàbí Kristẹni mìíràn tó dàgbà dénú. Bó bá dórí ọ̀ràn yìí, ó yẹ káwọn òbí àtàwọn mìíràn lo òye kí wọn sì fúnni níṣìírí. Bí àwọn ọ̀dọ́ kan bá rí i pé tìpá tìkúùkù la fi ń mú kí wọn lé góńgó táa gbé ka iwájú wọn bá, èyí lè mú wọn banú jẹ́ kó tiẹ̀ ba ète tá a fi gbé góńgó náà kalẹ̀ jẹ́ pàápàá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọdébìnrin kan nìyẹn, tó sọ pé: “Ńṣe làwọn òbí mi kàn gbé góńgó kalẹ̀ fún mi ṣáá bó ṣe wù wọ́n, wọ́n ní kí n forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, kí n bẹ̀rẹ̀ sí í jáde òde ẹ̀rí, kí n ṣèrìbọmi, kí n sì tún di aṣáájú ọ̀nà. Mo sapá gidigidi kí n tó lè lé ọ̀kọ̀ọ̀kan góńgó wọ̀nyẹn bá. Kàkà kí àwọn òbí mi yìn mí nígbà tọ́wọ́ mi bá tẹ góńgó kan, ńṣe ni wọ́n tún máa gbé góńgó mìíràn ka iwájú mi. Bíi pé tìpá tìkúùkù ni wọ́n fi ń mú mi ṣe nǹkan ló wá rí lára mi. Gbogbo ẹ̀ wá tojú sú mi, ó wa dà bíi pé mi ò ṣàṣeyọrí kankan.” Kí làṣìṣe ibẹ̀? Gbogbo góńgó wọ̀nyẹn ló dáa pátá, àmọ́ òun kọ́ ló gbé wọn ka iwájú ara rẹ̀. O gbọ́dọ̀ ṣe tán láti fúnra rẹ gbé góńgó tó o máa lépa kalẹ̀, tó o bá fẹ́ ṣàṣeyọrí!

Gbé àpẹẹrẹ Jésù Kristi yẹ̀ wò. Ó mọ ohun tí Jèhófà, Bàbá rẹ̀, fẹ́ kó ṣe nígbà tó fi wá sáyé. Ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà kì í wulẹ̀ ṣe góńgó tí Jésù ń lépa, àmọ́ ó tún jẹ́ iṣẹ́ àyànfúnni kan tó gbọ́dọ̀ ṣe. Ojú wo ni Jésù fi wo iṣẹ́ tá a yàn fún un? Ó sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 4:34) Ńṣe ni ṣíṣe tí Jésù ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà ń mú inú rẹ̀ dùn ṣìnkìn, ó sì ṣe é bí Bàbá rẹ̀ ṣe fẹ́ kó ṣe é gan-an. Bí ìgbà tí Jésù ń jẹun ló rí lára ẹ̀—iṣẹ́ tí wọ́n gbé lé e lọ́wọ́ láti ṣe parí náà jẹ́ orísun ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn fún un. (Hébérù 10:5-10) Ìwọ náà lè rí ìdùnnú nígbà tó o bá fi ọkàn tó dáa ṣe ohun táwọn òbí ẹ gbà ẹ́ níyànjú láti ṣe.

Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ ní Ṣíṣe Ohun Tó Dáa

Gbàrà tó o ba ti gbé góńgó kan ka iwájú, sán ṣòkòtò ẹ dáadáa kó o lè lé e bá. Gálátíà 6:9 sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.” Má ṣe gbára lé agbára tàbí okun tìẹ nìkan o. Ó ṣeé ṣe kó o bá ìṣòro pàdé àti pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan o lè ní ìjákulẹ̀ pàápàá. Àmọ́ Bíbélì ki wá láyà nígbà tó sọ pé: “Ṣàkíyèsí [Ọlọ́run] ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:6) Jèhófà yóò mẹ́sẹ̀ ẹ dúró, bó o ti ń sakun kí ọwọ́ rẹ lè tẹ góńgó tẹ̀mí tó ò ń lépa.

Dájúdájú, bó o bá ń mú ìfẹ́ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà dàgbà, tó o sì ń sakun láti lé àwọn góńgó tẹ̀mí bá, á ṣeé ṣe fún ọ láti jẹ́ kí ‘ìlọsíwájú rẹ fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.’ (1 Tímótì 4:15) Wàá sì gbádùn ìgbésí ayé tó nítumọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Bíbélì kíkà àti ṣíṣàṣàrò lórí ohun tó o kà yóò sún ọ láti sìn Jèhófà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Jésù ṣe bí Bàbá rẹ̀ ṣe fẹ́ kó ṣe gan-an