Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí nìdí tí nọ́ńbà àwọn sáàmù àti ẹsẹ inú ìwé Sáàmù fi yàtọ̀ síra nínú onírúurú ìtumọ̀ Bíbélì?
Bíbélì kan ní ìtumọ̀ èdè Faransé tí Robert Estienne tẹ̀ jáde ní 1553 ni àkọ́kọ́ tá a pín sí orí àti ẹsẹ látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Àmọ́ ìwé Sáàmù ní tiẹ̀ ti wà ní pípín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tipẹ́ ṣáájú àkókò yẹn, nítorí pé àkópọ̀ àwọn sáàmù, tàbí orin ni, iye àwọn èèyàn tó sì kọ ọ́ pọ̀ díẹ̀.
Ó hàn gbangba pé, Jèhófà kọ́kọ́ darí Dáfídì láti kó àwọn sáàmù kan pa pọ̀ fún ìjọsìn ní gbangba. (1 Kíróníkà 15:16-24) A gbọ́ pé Ẹ́sírà, tó jẹ́ àlùfáà àti “ọ̀jáfáfá adàwékọ,” la wá lò níkẹyìn láti kó gbogbo ìwé Sáàmù jọ pọ̀ sí bó ṣe wà báyìí. (Ẹ́sírà 7:6) Ó wá túmọ̀ sí pé ọ̀kan-ò-jọ̀kan sáàmù ló kúnnú ìwé Sáàmù nígbà tí wọ́n ṣe àkópọ̀ rẹ̀ tán.
Nínú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú sínágọ́gù tó wà ní Áńtíókù (Písídíà) nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ àkọ́kọ́, ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé Sáàmù, ó ní: “Àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ nínú sáàmù kejì pé, ‘Ìwọ ni ọmọ mi, mo ti di Baba rẹ lónìí yìí.’” (Ìṣe 13:33) Ọ̀rọ̀ yẹn ṣì wà nínú sáàmù kejì, ẹsẹ keje nínú àwọn Bíbélì òde òní. Àmọ́ o, ìyàtọ̀ wà nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ nọ́ńbà sí ọ̀pọ̀ lára àwọn sáàmù inú onírúurú ìtumọ̀ Bíbélì. Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé orí ìwé àwọn Masorete lédè Hébérù ni wọ́n gbé àwọn ìtumọ̀ kan kà, nígbà tí wọ́n sì gbé àwọn ìtumọ̀ mìíràn karí ẹ̀dà ti Septuagint lédè Gíríìkì, tó jẹ́ ìtumọ̀ èdè Hébérù tí wọ́n parí ní ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa. Bí àpẹẹrẹ, Vulgate lédè Látìn, tó jẹ́ pé inú rẹ̀ ni wọ́n ti túmọ̀ ọ̀pọ̀ Bíbélì àwọn Kátólíìkì, lo nọ́ńbà àwọn sáàmù tó wà nínú ìtumọ̀ Septuagint, nígbà tí Ìtumọ̀ Ayé Tuntun àtàwọn mìíràn tẹ̀ lé ti èdè Hébérù.
Kí làwọn ìyàtọ̀ ibẹ̀ gan-an? Ìtumọ̀ èdè Hébérù ní àròpọ̀ àádọ́jọ sáàmù nínú. Àmọ́, ìtumọ̀ Septuagint pa Sáàmù 9 àti 10 pọ̀ di ẹyọ kan, ó tún pa Sáàmù 114 àti 115 pọ̀ di ẹyọ kan. Kò tán síbẹ̀ o, ó tún pín Sáàmù 116 àti Sáàmù 147 sí sáàmù méjì méjì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àròpọ̀ iye wọn bára mu, síbẹ̀ nọ́ńbà tí wọ́n kọ sí Sáàmù 10 títí dé Sáàmù 146 nínú ìtumọ̀ Septuagint fi ẹyọ kan dín sí ti èdè Hébérù. Abájọ tí Sáàmù 23 tí gbogbo èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó fi wà nínú Sáàmù 22 nínú Douay Version, tó tẹ̀ lé nọ́ńbà inú Vulgate lédè Látìn, nígbà tó sì jẹ́ pé nọ́ńbà inú ìtumọ̀ Septuagint nìyẹn tẹ̀ lé.
Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó ṣeé ṣe kí iye ẹsẹ tó wà nínú àwọn sáàmù kan yàtọ̀ síra nínú ìtumọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kí ló lè fa ìyẹn? Ìdí ni pé àwọn ìtumọ̀ kan tẹ̀ lé “àṣà àwọn Júù ti kíka ohun tó wà ní àkọlé sí ẹsẹ ìkíní,” gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ McClintock and Strong’s Cyclopedia ṣe sọ ọ́, àmọ́ àwọn mìíràn kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Àní sẹ́, tí ohun tó wà ní àkọlé náà bá gùn, wọ́n sábà máa ń kà á bí ẹsẹ méjì, èyí ló ń mú kí iye ẹsẹ tó wà nínú sáàmù náà tipa bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí i.