Ìwà Tútù—Ànímọ́ Kristẹni Tó Ṣe Pàtàkì
Ìwà Tútù—Ànímọ́ Kristẹni Tó Ṣe Pàtàkì
‘Ẹ fi ìwà tútù wọ ara yín láṣọ.’—KÓLÓSÈ 3:12.
1. Kí ló mú kí ìwà tútù jẹ́ ànímọ́ kan tó tayọ?
NÍGBÀ tí ojú ọjọ́ bá dára, ó máa ń tuni lára, ó sì máa ń gbádùn mọ́ni. Bí ẹnì kan bá sì jẹ́ oníwà tútù, ó máa ń gbádùn mọ́ni láti bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbé. Àmọ́ ṣá o, Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba tún sọ pé, ‘ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lè fọ́ egungun.’ (Òwe 25:15) Bẹ́ẹ̀ ni, ànímọ́ títayọ ni ìwà tútù, ó ń gbádùn mọ́ni, ó sì tún lágbára.
2, 3. Báwo ni ìwà tútù àti ẹ̀mí mímọ́ ṣe bára tán, kí ni a óò sì gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ́ yìí?
2 Ìwà tútù wà lára ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “èso ti ẹ̀mí” tó wà nínú Gálátíà 5:22, 23. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìwà tútù” ní ẹsẹ kẹtàlélógún nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ni a sábà máa ń lò fún “ọkàn tútù.” Ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn kan lédè Yorùbá tilẹ̀ pè é ní “ìwà pẹ̀lẹ́.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé nínú ọ̀pọ̀ jù lọ èdè, ó ṣòro láti rí ọ̀rọ̀ tó bá ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà mú rẹ́gí nítorí pé ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà kò ṣàpèjúwe ìwà pẹ̀lẹ́ tàbí ọkàn tútù tá a lè fi dá èèyàn mọ̀ lóde ara, bí kò ṣe ìwà tútù tàbí ìgbatẹnirò inú ọkàn lọ́hùn-ún; kì í ṣe ọ̀nà téèyàn ń gbà hùwà bí kò ṣe bó ṣe ń ronú àti ipò tí ọkàn rẹ̀ wà.
3 Kí a lè túbọ̀ lóye ìtumọ̀ ìwà tútù àti bó ṣe wúlò tó ní kíkún sí i, ẹ jẹ́ kí a gbé àpẹẹrẹ mẹ́rin yẹ̀ wò nínú Bíbélì. (Róòmù 15:4) Bí a ṣe ń gbé àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí yẹ̀ wò a óò lóye ohun tí ànímọ́ yìí jẹ́, a óò sì tún lóye bí a ṣe le ní in àti bí a ṣe lè máa fi í hàn nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe.
“Ó Níye Lórí Gidigidi Lójú Ọlọ́run”
4. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà mọrírì ìwà tútù gidigidi?
4 Níwọ̀n bí ìwà tútù ti jẹ́ apá kan èso ẹ̀mí Ọlọ́run, ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé ó wà lára àkópọ̀ ìwà títayọlọ́lá tí Ọlọ́run ní. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé ‘ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.’ (1 Pétérù 3:4) Ní tòótọ́, ànímọ́ Ọlọ́run ni ìwà tútù; Jèhófà sì mọrírì rẹ̀ gidigidi. Dájúdájú, èyí tó ohun tí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fi gbọ́dọ̀ mú ìwà tútù dàgbà. Báwo wá ni Ọlọ́run Olódùmarè, Aláṣẹ tó ga jù lọ láyé lọ́run ṣe fi ìwà tútù hàn?
5. Ìrètí ọjọ́ iwájú wo la ní, nítorí pé Jèhófà fi ìwà tútù hàn?
5 Nígbà tí ènìyàn méjì àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ṣàìgbọràn sí àṣẹ tó ṣe kedere tí Ọlọ́run pa pé kí wọ́n má ṣe jẹ nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú, wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn ni. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Mímọ̀ọ́mọ̀ tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn yẹn yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀, ikú àti sísọ ara wọn àtàwọn ọmọ tí wọ́n ń bọ̀ wá bí, dàjèjì sí Ọlọ́run. (Róòmù 5:12) Àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó bẹ́tọ̀ọ́ mu fún Jèhófà láti dá wọn lẹ́jọ́, kò fìbínú ro ìdílé ẹ̀dá ènìyàn pin bíi pé wọn ò lè wúlò mọ́ tí wọn ò sì lè ṣeé dá nídè. (Sáàmù 130:3) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni oore ọ̀fẹ́ àti ìmúratán Jèhófà láti má ṣe rin kinkin mọ́ nǹkan jù—èyí tí í ṣe ọ̀nà tó ń gbà fi ìwà tútù hàn—sún un láti pèsè ọ̀nà tí aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò gbà tọ òun wá kí wọ́n sì jèrè ojú rere òun. Dájúdájú, nípasẹ̀ ẹ̀bùn ẹbọ Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, Jèhófà mú kó ṣeé ṣe fún wa láti tọ òun wá lórí ìtẹ́ rẹ̀ gíga fíofío láìsí ìbẹ̀rù tàbí ìfòyà.—Róòmù 6:23; Hébérù 4:14-16; 1 Jòhánù 4:9, 10, 18.
6. Báwo ni ìwà tútù ṣe fara hàn nínú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá Kéènì lò?
6 Tipẹ́tipẹ́ kí Jésù tó wá sí ayé ni Jèhófà ti fi ìwà tútù rẹ̀ hàn nígbà tí Kéènì àti Ébẹ́lì, àwọn ọmọkùnrin Ádámù rú ẹbọ sí Ọlọ́run. Níwọ̀n bí Jèhófà ti mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, ó kọ ọrẹ ẹbọ Kéènì ṣùgbọ́n ó “fi ojú rere wo” Ébẹ́lì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀. Ojú rere tí Ọlọ́run fi wo Ébẹ́lì olóòótọ́ àti ẹbọ rẹ̀ gbé èrò òdì dìde nínú Kéènì. Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Ìbínú Kéènì sì gbóná gidigidi, ojú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí rẹ̀wẹ̀sì.” Kí ni Jèhófà wá ṣe? Ṣé ìwà burúkú Kéènì mú un bínú ni? Rárá o. Ó fẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ béèrè lọ́wọ́ Kéènì ohun tó ń bí i nínú. Jèhófà tiẹ̀ ṣàlàyé ohun tí Kéènì lè ṣe kí ara rẹ̀ lè “yá gágá.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-7) Lóòótọ́, Jèhófà máa ń fi ìwà tútù hàn lọ́nà pípé.—Ẹ́kísódù 34:6.
Ìwà Tútù Máa Ń Fani Mọ́ra Ó sì Ń Tuni Lára
7, 8. (a) Báwo la ṣe lè lóye ìwà tútù Jèhófà? (b) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Mátíù 11:27-29 fi hàn nípa Jèhófà àti Jésù?
7 Kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà lóye àwọn ànímọ́ aláìlẹ́gbẹ́ tí Jèhófà ní. (Jòhánù 1:18; 14:6-9) Nígbà tí Jésù wà ní Gálílì ní ọdún kejì iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì ní Kórásínì, Bẹtisáídà, Kápánáúmù àti àgbègbè tó yí wọn ká. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn náà gbéra ga, wọn ò bìkítà, wọ́n sì kọ̀ láti gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́. Kí ni Jésù ṣe? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rán wọn létí ohun tí àìnígbàgbọ́ wọn á yọrí sí, àánú ṣe é nígbà tó rí ipò òṣì nípa tẹ̀mí tí àwọn ʽam ha·ʼaʹrets, ìyẹn àwọn ẹni rírẹlẹ̀ láàárín wọn wà.—Mátíù 9:35, 36; 11:20-24.
8 Ohun tí Jésù ṣe tẹ̀ lé e fi hàn pé ó “mọ Baba ní kíkún” ó sì fara wé e. Jésù fi ọ̀yàyà ké sí àwọn gbáàtúù pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.” Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti mu ìtùnú àti ìtura bá àwọn tí a ti pọ́n lójú! Kódà, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń tu àwa pẹ̀lú nínú lóde òní. Tí a bá fi ìwà tútù wọ ara wa láṣọ lóòótọ́, nígbà náà a ó wà lára àwọn tí “Ọmọ fẹ́ láti ṣí” Bàbá rẹ̀ “payá fún.”—Mátíù 11:27-29.
9. Ànímọ́ wo ló bá ìwà tútù tan, báwo sì ni Jésù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú lílo àwọn ànímọ́ náà?
9 Ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ìyẹn jíjẹ́ “ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà” bá ìwà tútù tan dáadáa. Ìgbéraga ní tiẹ̀ máa ń mú kéèyàn máa ruga ó sì máa ń mú kéèyàn bá àwọn ẹlòmíràn lò lọ́nà líle koko, láìláàánú. (Òwe16:18, 19) Jésù fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ hàn látìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé títí tó fi parí rẹ̀. Àní nígbà tó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ mẹ́fà ṣáájú ikú rẹ̀ tí wọ́n sì yìn ín gẹ́gẹ́ bí Ọba àwọn Júù pàápàá, Jésù ò ṣe bíi tàwọn alákòóso ayé. Ó mú àsọtẹ́lẹ̀ tí Sekaráyà sọ nípa Mèsáyà ṣẹ pé: “Wò ó! Ọba rẹ ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ, onínú tútù, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, bẹ́ẹ̀ ni, lórí agódóńgbó, ọmọ ẹranko arẹrù.” (Mátíù 21:5; Sekaráyà 9:9) Dáníẹ́lì wòlíì olóòótọ́ nì rí ìran kan níbi tí Jèhófà ti gbé àṣẹ ìṣàkóso lé Ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Àní, nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tó wáyé tẹ́lẹ̀, ó ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí “ẹni rírẹlẹ̀ jù lọ nínú aráyé.” O ṣe kedere nígbà náà pé ìwà tútù àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀ jọ ń rìn ni.—Dáníẹ́lì 4:17; 7:13, 14.
10. Èé ṣe tí ìwà tútù Kristẹni kò fi túmọ̀ sí àìlera?
10 Ìwà tútù tó ń mára tuni tí Jèhófà àti Jésù fi hàn ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ wọn. (Jákọ́bù 4:8) Àmọ́ ṣá o, ìwà tútù kò túmọ̀ sí àìlera. Rárá o! Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè ní ọ̀pọ̀ yanturu agbára tó gadabú. Ó máa ń bínú gidigidi sí ìwà àìṣòdodo. (Aísáyà 30:27; 40:26) Jésù pẹ̀lú dúró gbọn-in lórí ìpinnu rẹ̀ láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ àní nígbà tí Sátánì Èṣù dojú ìjà kọ ọ́. Kò fàyè gba òwò bìrìbìrì táwọn aṣáájú ìsìn ọjọ́ rẹ̀ ń ṣe. (Mátíù 4:1-11; 21:12, 13; Jòhánù 2:13-17) Síbẹ̀síbẹ̀, ó lo inú tútù nígbà tó ń bójú tó ìkù-díẹ̀-káàtó àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì fi sùúrù fara dà àìlera wọn. (Mátíù 20:20-28) Ẹnì kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ṣàpèjúwe ìwà tútù lọ́nà tó ṣe wẹ́kú. Ó sọ pé: “Nínú ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni agbára bíi ti irin wà.” Ǹjẹ́ kí a máa fi ànímọ́ bíi ti Kristi yìí tí í ṣe ìwà tútù hàn.
Ọlọ́kàn Tútù Jù Lọ ní Ọjọ́ Rẹ̀
11, 12. Kí ló mú ìwà tútù Mósè ta yọ láìka ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ ọ dàgbà sí?
11 Àpẹẹrẹ kẹta tí a óò gbé yẹ̀ wò ni ti Mósè. Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó jẹ́ “ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Númérì 12:3) Lábẹ́ ìmísí Ọlọ́run ni a ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀. Ìwà tútù Mósè tó ta yọ mú kó máa tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà.
12 Ọ̀nà àrà ni wọ́n gbà tọ́ Mósè dàgbà. Jèhófà mú kí á pa ọmọ àwọn Hébérù olóòótọ́ yìí mọ́ láàyè lákòókò ọ̀tẹ̀ àti ìpànìyàn. Nígbà tí Mósè wà lọ́mọdé, ìyà rẹ̀ ló tọ́ ọ, ó sì fara balẹ̀ kọ́ ọ nípa Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà. Nígbà tó yá, wọ́n gbé Mósè láti ilé rẹ̀ lọ sí ibi tó yàtọ̀ pátápátá. Sítéfánù Kristẹni ajẹ́rìíkú ròyìn pé: “Mósè ni a fún ní ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì. Ní ti tòótọ́, ó jẹ́ alágbára nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀.” (Ìṣe 7:22) Ìgbàgbọ́ rẹ̀ wá sójútáyé nígbà tó ṣàkíyèsí ìwà ìkà tí àwọn tí Fáráò yàn láti máa kó àwọn ẹrú ṣiṣẹ́ ń hù sí àwọn arákùnrin rẹ̀. Mósè ní láti sá kúrò ní Íjíbítì lọ sí ilẹ̀ Mídíánì nítorí pé ó pa ọmọ Íjíbítì kan tó ń lu ẹni tó jẹ́ Hébérù.—Ẹ́kísódù 1:15, 16; 2:1-15; Hébérù 11:24, 25.
13. Ipa wo ni ogójì ọdún tí Mósè fi gbé ní Mídíánì ní lórí rẹ̀?
13 Ní ẹni ogójì ọdún, Mósè ní láti máa gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ nínú aginjù. Ní Mídíánì ó ṣalábàápàdé àwọn ọmọbìnrin Réúẹ́lì méje, ó sì ràn wọn lọ́wọ́ láti fa omi fún agbo ẹran ńlá ti bàbá wọn. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà darí délé, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi ṣàlàyé fún bàbá wọn pé “ará Íjíbítì kan” ló gba àwọn lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ń yọ àwọn lẹ́nu. Bí Réúẹ́lì ṣe ké sí Mósè nìyẹn tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pẹ̀lú ìdílé náà. Àwọn ìpọ́njú tó bá a kò mú kó di òǹrorò; bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò dí i lọ́wọ́ kó má lè mú ìgbé ayé rẹ̀ bá àyíká tuntun tó wà mú. Ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ kò yingin. Jálẹ̀ gbogbo ogójì ọdún tí Mósè fi bójú tó àgùntàn Réúẹ́lì, tó fi fẹ́ Sípórà, tó sì fi tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó mú ànímọ́ tí a wá mọ̀ mọ́ ọn dàgbà. Òótọ́ ọ̀rọ̀, Mósè kẹ́kọ̀ọ́ ìwà tútù nípa fífara da ipò líle koko.—Ẹ́kísódù 2:16-22; Ìṣe 7:29, 30.
14. Ṣàlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó fi ìwà tútù Mósè hàn nígbà tó ń ṣe olórí Ísírẹ́lì.
14 Lẹ́yìn tí Jèhófà yan Mósè ṣe olórí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ànímọ́ ìwà tútù tó ní ṣì fara hàn. Ọ̀dọ́kùnrin kan sọ fún Mósè pé Ẹ́lídádì àti Médádì ń ṣe bíi wòlíì nínú àgọ́—bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò sí níbẹ̀ nígbà tí Jèhófà tú ẹ̀mí rẹ̀ dà sórí àwọn àádọ́rin àgbà ọkùnrin tí wọ́n á máa ṣèránṣẹ́ fún Mósè. Jóṣúà sọ pé: “Olúwa mi Mósè, dá wọn lẹ́kun!” Mósè fẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ fèsì pé: “Ṣé o ń jowú fún mi ni? Rárá, ì bá wù mí kí gbogbo àwọn ènìyàn Jèhófà jẹ́ wòlíì, nítorí pé Jèhófà yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ sára wọn!” (Númérì 11:26-29) Ìwà tútù ṣèrànwọ́ láti paná awuyewuye yẹn.
15. Bí Mósè tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere rẹ̀?
15 Nígbà kan Mósè kùnà láti fi ìwà tútù hàn. Ní Mẹ́ríbà, lẹ́bàá Kádéṣì, ó kùnà láti fi ògo fún Jèhófà, Oníṣẹ́ Ìyanu. (Númérì 20:1, 9-13) Bí Mósè tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí kò mì ràn án lọ́wọ́ jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, ìwà tútù rẹ̀ títayọ sì ń fà wá mọ́ra títí dòní.—Hébérù 11:23-28.
Ìwà Òǹrorò àti Ìwà Tútù
16, 17. Ìkìlọ̀ wo ni a rí gbà látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Nábálì àti Ábígẹ́lì?
16 Àpẹẹrẹ kan tó ń fún wa ní ìkìlọ̀ wáyé nígbà ayé Dáfídì, kété lẹ́yìn ikú Sámúẹ́lì, wòlíì Ọlọ́run. Ọ̀ràn náà kan tọkọtaya kan, Nábálì àti Ábígẹ́lì. Àwọn méjèèjì yìí mà yàtọ̀ síra gan-an ni o! Ábígẹ́lì ní tirẹ̀ “ní ọgbọ́n inú dáadáa,” àmọ́ ọkọ rẹ̀ “le koko, ó sì burú ní àwọn ìṣe rẹ̀.” Nábálì fi ìwà òǹrorò kọ̀ jálẹ̀ láti pèsè oúnjẹ fún àwọn ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ Dáfídì, àwọn tí wọ́n ran Nábálì lọ́wọ́ láti ṣọ́ agbo ẹran rẹ̀ ńlá nítorí àwọn olè. Inú Dáfídì ru lọ́nà òdodo, ni òun àti àwùjọ àwọn ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ bá sán idà wọn, wọ́n sì lọ láti gbéjà ko Nábálì.—1 Sámúẹ́lì 25:2-13.
17 Nígbà tí ìròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí dé etígbọ̀ọ́ Ábígẹ́lì, ó tètè mú búrẹ́dì, wáìnì, ẹran, àti ìṣù èso àjàrà gbígbẹ àti ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́, ó sì jáde lọ pàdé Dáfídì. Ó sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé: “Ìwọ olúwa mi, kí ìṣìnà náà wà lórí èmi gan-an; jọ̀wọ́, sì jẹ́ kí ẹrúbìnrin rẹ sọ̀rọ̀ ní etí rẹ, sì fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ ẹrúbìnrin rẹ.” Ọkàn Dáfídì rọ̀ nígbà tí Ábígẹ́lì fi ohùn tútù bẹ̀ ẹ́. Lẹ́yìn tí Dáfídì ti gbọ́ àlàyé Ábígẹ́lì, ó sọ pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi! Ìbùkún sì ni fún ìlóyenínú rẹ, ìbùkún sì ni fún ìwọ tí o ti dá mi dúró lónìí yìí kí n má bàa wọnú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.” (1 Sámúẹ́lì 25:18, 24, 32, 33) Ìwà òǹrorò Nábálì ló pàpà ṣekú pa á. Ànímọ́ rere tí Ábígẹ́lì ní fún un láyọ̀ níkẹyìn nígbà tó di aya Dáfídì. Ìwà tútù rẹ̀ jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn tó ń sin Jèhófà lónìí.—1 Sámúẹ́lì 25:36-42.
Máa Lépa Ìwà Tútù
18, 19. (a) Àwọn ìyípadà wo ló máa ń fara hàn kedere bí a ṣé ń fi ìwà tútù wọ ara wa láṣọ? (b) Kí ló lè ràn wa lọ́wọ́ láti yẹ ara wa wò lọ́nà tó gbéṣẹ́?
18 Kòṣeémáàní ni ìwà tútù jẹ́. Ó ju ìwà pẹ̀lẹ́ lọ; ó jẹ́ ànímọ́ fífanimọ́ra kan tó ń tu ẹlòmíràn lára. Tẹ́lẹ̀ rí, a ti lè máa sọ̀rọ̀ lọ́nà líle koko ká sì máa hùwà àìláàánú. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí a ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì a ti yí padà, a sì ti di ẹni tó ṣeé sún mọ́, tí ìwà rẹ̀ kò sì léni sá. Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ìyípadà yìí nígbà tó rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.” (Kólósè 3:12) Bíbélì fi ìyípadà yìí wé bí àwọn ẹranko ẹhànnà bí ìkookò, àmọ̀tẹ́kùn, kìnnìún, béárì, àti ṣèbé, á ṣe wá dà bí àwọn ẹran agbéléjẹ̀ tí kì í ṣeni léṣe bí àgùntàn, agódóńgbó, ọmọ màlúù àti màlúù. (Aísáyà 11:6-9; 65:25) Ìyípadà àkópọ̀ ìwà bẹ́ẹ̀ á fara hàn kedere débi pé ẹnu á bẹ̀rẹ̀ sí ya àwọn tó ń kíyè sí i. Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń mú ìyípadà yìí wá, ìwà tútù sì jẹ́ ọ̀kan lára àkópọ̀ èso rẹ̀ títayọlọ́lá.
19 Èyí ha túmọ̀ sí pé gbàrà tí a bá ti ṣe àwọn ìyípadà tó pọn dandan tí a sì ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a lè ṣíwọ́ láti máa hùwà tútù? Rárá o. Bí àpẹẹrẹ, aṣọ tuntun ń fẹ́ àbójútó láti mú kí ó máa wà ní mímọ́ tóní kó sì bójú mu. Wíwo inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ inú rẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣàyẹ̀wò ara wa déédéé. Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí tó dà bíi dígí fi hàn nípa rẹ?—Jákọ́bù 1:23-25.
20. Báwo la ṣe lè ṣàṣeyọrí nínú fífi ìwà tútù hàn?
20 Ànímọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní. Ànímọ́ ìwà tútù yìí sì máa ń fara hàn lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan ju àwọn mìíràn lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, gbogbo Kristẹni ló yẹ kó mú èso ẹ̀mí Ọlọ́run dàgbà títí kan ìwà tútù. Pọ́ọ̀lù fìfẹ́ gba Tímótì níyànjú pé: “Máa lépa òdodo, fífọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, inú tútù.” (1 Tímótì 6:11) Ọ̀rọ̀ náà “lépa” fi hàn pé ó gba ìsapá. Ìtumọ̀ Bíbélì kan túmọ̀ ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí sí ‘fi ọkàn rẹ sí.’ (New Testament in Modern English, látọwọ́ J. B. Phillips) Bí o bá ń sapá láti ṣàṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ rere látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n lè di apá kan ara rẹ, bí ẹni pé a bí wọn mọ́ ọ. Wọ́n á máa darí ìrònú rẹ, wọ́n á sì máa ṣamọ̀nà rẹ.—Jákọ́bù 1:21.
21. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lépa ìwà tútù? (b) Kí ni a óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé e?
21 Ìwà tí à ń hù sí àwọn ẹlòmíràn ló ń fi hàn bá a ti ń ṣe dáadáa sí nínú fífi ìwà tútù hàn. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù béèrè pé: “Ta ni nínú yín tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye? Kí ó fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn láti inú ìwà rẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n.” (Jákọ́bù 3:13) Báwo ni a ṣe lè fi ànímọ́ Kristẹni yìí hàn nínú ilé, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, àti nínú ìjọ? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e pèsè ìtọ́sọ́nà tó ń ranni lọ́wọ́.
Àtúnyẹ̀wò
• Kí lo rí kọ́ nípa ìwà tútù látinú àpẹẹrẹ
• Jèhófà?
• Jésù?
• Mósè?
• Ábígẹ́lì?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lépa ìwà tútù?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Kí nìdí tí Jèhófà fi fojú rere wo ọrẹ ẹbọ Ébẹ́lì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Jésù fi hàn pé ńṣe ni ìwà tútù àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀ jọ ń rìn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Mósè fi àpẹẹrẹ rere ti ìwà tútù lélẹ̀