Ẹ “Máa Fi Gbogbo Ìwà Tútù Hàn Sí Ènìyàn Gbogbo”
Ẹ “Máa Fi Gbogbo Ìwà Tútù Hàn Sí Ènìyàn Gbogbo”
“Máa bá a lọ ní rírán wọn létí . . . láti jẹ́ afòyebánilò, kí wọ́n máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.”—TÍTÙ 3:1, 2.
1. Èé ṣe tí kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti fi ìwà tútù hàn?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 11:1) Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ń sapá gidigidi láti tẹ̀ lé ìṣílétí yìí. Òótọ́ ni pé kò rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé a ti jogún àwọn ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan àti àwọn ànímọ́ tí kò bá àpẹẹrẹ Kristi mu látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́. (Róòmù 3:23; 7:21-25) Síbẹ̀síbẹ̀, tó bá di pé ká fi ìwà tútù hàn, gbogbo wa la lè ṣe é bí a bá sapá gidigidi. Ṣùgbọ́n wíwulẹ̀ pinnu pé a fẹ́ láti fi ànímọ́ yìí hàn kò tó. Kí lohun tó tún kù?
2. Báwo la ṣe lè fi “gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo”?
2 Ìwà tútù bíi ti Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èso ẹ̀mí mímọ́. Bí a bá ṣe túbọ̀ ń yọ̀ọ̀da ara wa fún ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run láti darí wa tó, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe máa fara hàn kedere tó pé à ń so èso rẹ̀. Kìkì ìgbà náà ní yóò ṣeé ṣe fún wa láti máa fi “gbogbo ìwà tútù” hàn sí ènìyàn gbogbo. (Títù 3:2) Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà tá a lè gbà ṣàfarawé àpẹẹrẹ Jésù kí a sì jẹ́ kí àwọn tí ń dara pọ̀ mọ́ wa “rí ìtura.”—Mátíù 11:29; Gálátíà 5:22, 23.
Nínú Ìdílé
3. Àwọn nǹkan tó ń fi ẹ̀mí ayé hàn wo ló ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé?
3 Ìwà tútù jẹ́ kòṣeémánìí nínú ìdílé. Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ìwà ipá nínú ìdílé ń fi ìlera àwọn obìnrin wewu lọ́nà kan tó ga fíìfíì ju ti jàǹbá mọ́tò àti àrùn ibà lọ. Bí àpẹẹrẹ, nílùú London, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìdá mẹ́rin gbogbo ìwà ọ̀daràn bíburú jáì tí wọ́n fi tó àwọn agbófinró létí, ló ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀ọ̀dẹ̀. Lemọ́lemọ́ làwọn ọlọ́pàá máa ń ṣalábàápàdé àwọn èèyàn tí ń fi ìhónú hàn nípa ‘lílọgun àti sísọ̀rọ̀ èébú.’ Èyí tó tún wá burú jù ni tàwọn tọkọtaya kan tí wọ́n ti jẹ́ kí “ìwà kíkorò onínú burúkú” ba àjọṣepọ̀ àwọn jẹ́. Gbogbo ìwà wọ̀nyí jẹ́ àbájáde bíbaninínújẹ́ ti “ẹ̀mí ayé.” Irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ò sì ṣètẹ́wọ́gbà nínú ìdílé Kristẹni.—Éfésù 4:31; 1 Kọ́ríńtì 2:12.
4. Ipa wo ni ìwà tútù lè ní lórí ìdílé?
4 Ká tó lè borí àwọn èrò ti ayé, a nílò ẹ̀mí Ọlọ́run. “Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.” (2 Kọ́ríńtì 3:17) Ìfẹ́, inú rere, ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìpamọ́ra ń fún ìṣọ̀kan àwọn ọkọ àti aya tí wọ́n jẹ́ aláìpé lókun. (Éfésù 5:33) Inú tútù a máa mú kínú dún kí ara sì yá gágá, ó sì yàtọ̀ pátápátá gbáà sí ariwo ìjà àti asọ̀ tí ń sọ ọ̀pọ̀ ìdílé dìdàkudà. Ohun tí ẹnì kan sọ ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n ọ̀nà tó gbà sọ ọ́ ló ń fi irú ẹ̀mí tó wà lẹ́yìn ohun tó sọ hàn. Fífi ìwà tútù ṣàlàyé àníyàn àti ìdààmú tí ń bẹ lọ́kàn ẹni máa ń dín pákáǹleke kù. Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba kọ̀wé pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.”—Òwe 15:1.
5. Báwo ni ìwà tútù ṣe lè ṣèrànwọ́ nínú ìdílé tí ẹ̀sìn ò ti pa pọ̀?
5 Ìwà tútù ṣe pàtàkì gan-an nínú ìdílé tí ẹ̀sìn ò ti pa pọ̀. Bí a bá fi ṣíṣe àwọn nǹkan lọ́nà pẹ̀lẹ́tù kún un, ó lè ṣèrànwọ́ láti fa àwọn tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere wá sọ́dọ̀ Jèhófà. Pétérù gba àwọn Kristẹni aya nímọ̀ràn pé: “Ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀. Kí ọ̀ṣọ́ yín má sì jẹ́ ti irun dídì lóde ara àti ti fífi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára tàbí ti wíwọ àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù, èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.”—1 Pétérù 3:1-4.
6. Báwo ni fífi ìwà tútù hàn ṣe lè mú kí ìdè àárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ túbọ̀ lókun sí i?
6 Àjọṣe àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn lè máà gún régé, pàápàá jù lọ níbi tí kò bá ti sí ìfẹ́ fún Jèhófà. Àmọ́ nínú gbogbo agbo ìdílé Kristẹni pátá, ó pọ́n dandan kí a fi ìwà tútù hàn. Pọ́ọ̀lù gba àwọn bàbá nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Bí ìwà tútù bá gbilẹ̀ nínú ìdílé kan, ìdè tímọ́tímọ́ tó wà láàárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ ni a óò fún lókun. Dean, ọ̀kan lára àwọn ọmọ márùn-ún tó tinú ìdílé kan wá, sọ ohun tó rántí nípa bàbá rẹ̀. Ó ní: “Onínú tútù ni Dádì. A ò jara wa níyàn rí—kódà nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́langba. Ní gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, àní bí inú bá tiẹ̀ ń bí i pàápàá. Nígbà míì, á tì mí mọ́nú yàrá tàbí kó fi àwọn àǹfààní kan dù mí, ṣùgbọ́n kì í bá mi ṣawuyewuye. Kì í ṣe Bàbá wa nìkan. Àmọ́ ó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ wa àtàtà, a kì í sì í fẹ́ láti já a kulẹ̀.” Láìsí àní-àní, ìwà tútù ń mú kí ìdè àárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ túbọ̀ lágbára sí i.
Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
7, 8. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fi ìwà tútù hàn nígbà tí a bá ń wàásù fún àwọn ẹlòmíràn?
7 Ibòmíràn tí ìwà tútù tún ti ṣe pàtàkì ni òde ẹ̀rí. Bí a ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run náà fáwọn ẹlòmíràn, onírúurú àwọn èèyàn tí ànímọ́ wọn yàtọ̀ síra là ń bá pàdé. Àwọn kan ń tẹ́tí sí ìhìn iṣẹ́ ìrètí tí à ń mú tọ̀ wọ́n lọ tayọ̀tayọ̀. Nígbà tó sì jẹ́ pé, nítorí àwọn ìdí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn míì lè máà fìfẹ́ gbà á. Ibi ti ànímọ́ ìwà tútù ti lè ṣèrànwọ́ fún wa gan-an nìyí láti mú iṣẹ́ wa ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.—Ìṣe 1:8; 2 Tímótì 4:5.
8 Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ṣùgbọ́n ẹ sọ Kristi di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Olúwa nínú ọkàn-àyà yín, kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:15) Nítorí pé a ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Kristi gẹ́gẹ́ bí Àwòkọ́ṣe wa, à ń rí sí i pé à ń fi ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ hàn nígbà tí a bá ń wàásù fún àwọn tí ń fi ìkanra sọ̀rọ̀. Híhùwà lọ́nà yìí máa ń sábàá mú àbájáde tó ta yọ lọ́lá wá.
9, 10. Sọ ìrírí kan tó fi bí ìwà tútù ti ṣeyebíye tó hàn nígbà tí a bá wà lóde ẹ̀rí.
9 Nígbà tí ìyàwó Keith lọ dá ẹnì kan tó ń kanlẹ̀kùn ilé wọn lóhùn, ńṣe ni Keith dákẹ́ sínú yàrá tó sì ṣe bí ẹni pé òun ò sí nílé. Nígbà tí ìyàwó Keith wá rí i pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń kanlẹ̀kùn, ńṣe ló fàbínú yọ tó sì fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí pé wọ́n máa ń fìyà jẹ àwọn ọmọdé. Arákùnrin náà ò bá a bínú. Ńṣe ló fẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ fèsì pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ má bínú o. Ṣùgbọ́n bí ẹ bá yọ̀ǹda fún mi, ǹjẹ́ mo lè fi ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ hàn yín?” Keith tó ń fetí kọ́ ìjíròrò náà níbi tó dákẹ́ sí nínú ilé wá bá wọn lẹ́nu ilẹ̀kùn láti fòpin sí ìjíròrò náà.
10 Lẹ́yìn ìgbà yẹn ni tọkọtaya náà bẹ̀rẹ̀ sí í kábàámọ̀ pé àwọn kanra mọ́ arákùnrin náà. Ìwà tútù tí arákùnrin náà hù mà kúkú wú wọn lórí o! Èyí tó wá jọ wọ́n lójú ni pé ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà arákùnrin yẹn tún padà bẹ̀ wọ́n wò. Keith àti ìyàwó rẹ̀ sì yọ̀ǹda fún un láti fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fún wọn. Wọ́n wá sọ lẹ́yìn náà pé: “Jálẹ̀ odindi ọdún méjì tó tẹ̀ lé e, á máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn bá bá wa sọ.” Àwọn méjèèjì tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ṣèrìbọmi lẹ́yìn náà gẹ́gẹ́ bí àmì pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Èrè ńlá gbáà lèyí jẹ́ fún Ẹlẹ́rìí náà tó kọ́kọ́ lọ wàásù fún Keith àti ìyàwó rẹ̀! Ẹlẹ́rìí náà bá Keith àti ìyàwó rẹ̀ pàdé ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ó sì wá rí i pé wọ́n ti di arákùnrin àti arábìnrin òun nípa tẹ̀mí. Bí ìwà tútù ṣe kógo já nìyẹn o.
11. Lọ́nà wo ni ìwà tútù lè gbà mú kó rọrùn fún ẹnì kan láti tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Kristẹni?
11 Àwọn ìrírí tí Harold ní nígbà tó ń ṣiṣẹ́ sójà sọ ọ́ dí ẹni tó kún fún ìkórìíra tó sì ń ṣiyè méjì pé bóyá lóòótọ́ ni Ọlọ́run wà. Èyí tó tún wá mú kí ìṣòro Harold túbọ̀ lọ́jú pọ̀ ni jàǹbá ọkọ tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tí ọ̀mùtí awakọ̀ kan kọ lù ú, tó sì sọ ọ́ di aláàbọ̀ ara. Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù dé ilé Harold, ó sọ fún wọn pé òun ò tún gbọ́dọ̀ rẹ́sẹ̀ wọn nílé òun mọ́. Ṣùgbọ́n lọ́jọ́ kan, Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Bill lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ olùfìfẹ́hàn kan tó ń gbé ní yàrá kẹta sí ti Harold. Ló bá ṣèèṣì kan ilẹ̀kùn Harold. Nígbà tí Harold ṣe tàgétàgé dé ìdí ilẹ̀kùn pẹ̀lú ọ̀pá tó fi ń tilẹ̀, kíá ni Bill tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀, tó sì ṣàlàyé fún un pé yàrá kan tó wà nítòsí rẹ̀ ni òun ti fẹ́ rí ẹnì kan. Kí ni Harold ṣe? Bill ò mọ̀ pé Harold ti gbọ́ ìròyìn kan lórí tẹlifíṣọ̀n nípa bí àwọn Ẹlẹ́rìí ti jùmọ̀ fi àkókò kúkúrú kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kan. Rírí tó rí àwọn èèyàn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan wú u lórí, ìyẹn sì ti yí ìṣesí rẹ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí pa dà. Níwọ̀n bí àforíjì tí Bíll tọrọ lọ́wọ́ rẹ̀ àti fífi tó fi pẹ̀lẹ́ hùwà ti dùn mọ́ Harold nínú, ó gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí máa wá sọ́dọ̀ òun. Ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó tẹ̀ síwájú, ó sì di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ṣèrìbọmi.
Nínú Ìjọ
12. Irú àwọn ìwà táwọn èèyàn ayé ń hù wo ni àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni gbọ́dọ̀ yẹra fún?
12 Inú ìjọ Kristẹni ni ibì kẹta tí ìwà tútù ti ṣeyebíye. Ìjà àjàkú akátá ló kúnnú ayé lóde òní. Iyàn jíjà, èdèkòyédè, awuyewuye, lohun tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn tó ń ronú lọ́nà tayé. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, irú ìwà táwọn èèyàn ayé ń hù yìí lè yọ́ kẹ́lẹ́ wọnú ìjọ Kristẹni, kó sì wá yọrí sí asọ̀ àti èébú. Ó máa ń ba àwọn tó ń bójú tó ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ nínú jẹ́ bí irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ bá ń béèrè àbójútó wọn. Síbẹ̀, ìfẹ́ fún Jèhófà àti ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin wọn máa ń sún wọn láti gbìyànjú láti mú àwọn tó bá ṣi ẹsẹ̀ gbé padà bọ̀ sípò.—Gálátíà 5:25, 26.
13, 14. Kí ló lè jẹ́ àbájáde ‘fífún àwọn tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere ní ìtọ́ni pẹ̀lú ìwà tútù’?
13 Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn kan nínú ìjọ dá ìṣòro sílẹ̀ fún Pọ́ọ̀lù àti Tímótì alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún Tímótì pé kó ṣọ́ra fún àwọn arákùnrin tí wọ́n fara jọ ohun èlò tó wà fún “ète tí kò ní ọlá.” Pọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé pé: “Ṣùgbọ́n kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni, tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi, kí ó máa fún àwọn tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere ní ìtọ́ni pẹ̀lú ìwà tútù.” Bí a bá fi inú tútù hàn, àní nígbà tí a bá mú wa bínú pàápàá, ó sábà máa ń mú kí àwọn alátakò dà á rò bóyá kí wọ́n ṣàríwísí tàbí kí wọ́n kọwọ́ ọmọ wọn bọ aṣọ. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ síwájú sí i nínú lẹ́tà rẹ̀, Jèhófà lè wá “fún wọn ní ìrònúpìwàdà tí ń ṣamọ̀nà sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (2 Tímótì 2:20, 21, 24, 25) Kíyè sí i pé Pọ́ọ̀lù so jíjẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ àti ìkóra-ẹni-níjàánu pọ̀ mọ́ ìwà tútù.
14 Pọ́ọ̀lù fi ohun tó wàásù rẹ̀ ṣèwà hù. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ‘àpọ́sítélì adárarégèé’ tó wà nínú ìjọ Kọ́ríńtì, ó rọ àwọn ará pé: “Wàyí o, èmi fúnra mi, Pọ́ọ̀lù, fi ìwà tútù àti inú rere Kristi pàrọwà fún yín, bí mo tilẹ̀ jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ ní ìrísí láàárín yín, ṣùgbọ́n mo láyà sí yín nígbà tí èmi kò bá sí lọ́dọ̀ yín.” (2 Kọ́ríńtì 10:1; 11:5) Pọ́ọ̀lù fara wé Kristi ní tòótọ́. Kíyè sí i pé “ìwà tútù” Kristi ni Pọ́ọ̀lù fi pàrọwà fún àwọn ará wọ̀nyí. Ó tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún ìṣarasíhùwà ìjẹgàbalénilórí tàbí ti ìpàṣẹwàá. Kò sí iyèméjì pé ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ̀ fa àwọn tó ní ọkàn àyà rere nínú ìjọ náà mọ́ra. Ó yanjú aáwọ̀ tó wà nílẹ̀ ó sì fìdí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan múlẹ̀ nínú ìjọ. Ǹjẹ́ kì í ṣe irú ìgbésẹ̀ yìí náà ló yẹ kí gbogbo wa máa làkàkà láti gbé? Ó yẹ kí àwọn alàgbà ní pàtàkì máa mú àpẹẹrẹ ti Kristi àti Pọ́ọ̀lù lò nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà hùwà.
15. Èé ṣe tí ìwà tútù fi ṣe pàtàkì nígbà tí a bá ń gbani nímọ̀ràn?
15 Ó dájú pé ẹrù iṣẹ́ náà láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kò mọ sí kìkì ìgbà tí àlááfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ bá fẹ́ bà jẹ́. Kó tiẹ̀ tó di pé aáwọ̀ ṣẹlẹ̀ rárá ló ti yẹ kí àwọn ará rí ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́ gbà. Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Ẹ̀yin ará, bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nípa rẹ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ tóótun nípa tẹ̀mí gbìyànjú láti tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà.” Ṣùgbọ́n báwo la ó ṣe tọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà? “Nínú ẹ̀mí ìwà tútù, bí olúkúlùkù yín ti ń ṣọ́ ara rẹ̀ lójú méjèèjì, kí a má bàa dẹ ìwọ náà wò.” (Gálátíà 6:1) Pípa “ẹ̀mí ìwà tútù” mọ́ kì í fi gbogbo ìgbà rọrùn o. Olórí ohun tó fà á tó sì fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé gbogbo Kristẹni, títí kan àwọn ọkùnrin tí a yàn sípò, ni wọ́n ní ìtẹ̀sí láti dẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀, ìwà tútù ló lè mú kó rọrùn láti mú kí ẹni tó ṣi ẹsẹ̀ gbé padà bọ̀ sípò.
16, 17. Kí ló lè fòpin sí ìlọ́tìkọ̀ èyíkéyìí láti fi ìmọ̀ràn sílò?
16 Nínú ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ tí a túmọ̀ sí ‘tọ́ sọ́nà padà’ tún lè tọ́ka sí títo egungun tí ó ti ṣẹ́. Ìtọ́jú tó máa ń mú ìroragógó dání gbáà lèyí jẹ́. Bí dókítà tó mọ bá a ti ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fini lọ́kàn balẹ̀ bá ń tún egungun tó ṣẹ́ tò, a máa sọ̀rọ̀ rere nípa àǹfààní tó wà nínú ìtọ́jú tó ń fún ẹni tí egungun rẹ̀ sẹ́ náà. Ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ á sì mára tu agbàtọ́jú náà. Ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ díẹ̀ tó bá sọ ṣáájú á ṣèrànwọ́ láti pẹ̀rọ̀ sí ìnira tó lè jẹ yọ. Bákan náà, ìtọ́sọ́nàpadà nípa tẹ̀mí lè roni lára. Ṣùgbọ́n ìwà tútù á mú kó túbọ̀ rọrùn láti gbà, tí á sì wá tipa bẹ́ẹ̀ fòpin sí aáwọ̀ náà, tí á sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tó ṣi ẹsẹ̀ gbé láti yí ọ̀nà rẹ̀ padà. Kódà bó bá dà bí ẹni pé ẹni tó ṣi ẹsẹ̀ gbé ò kọ́kọ́ fẹ́ gba ìmọ̀ràn, ìwà tútù agbaninímọ̀ràn lè fòpin sí lílọ́ tó ń lọ́ tìkọ̀ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yíyè kooro látinú Ìwé Mímọ́.—Òwe 25:15.
17 Nígbà tí a bá ń tọ́ àwọn ẹlòmíràn sọ́nà, ó máa ń sábàá ṣẹlẹ̀ pé kí ẹni tí à ń tọ́ sọ́nà ka ìmọ̀ràn tí à ń fún un sí àríwísí. Òǹkọ̀wé kan ṣàlàyé pé: “Bí a ò bá kíyè sára gidigidi nígbà tí a bá ń bá àwọn ẹlòmíràn wí, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ bí ẹni tó dá ara rẹ̀ lójú jù, nítorí náà a nílò ọkàn tútù gan-an ni.” Mímú ìwà tútù tó tinú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wá dàgbà yóò ran Kristẹni agbaninímọ̀ràn lọ́wọ́ láti yẹra fún ewu yìí.
“Sí Ènìyàn Gbogbo”
18, 19. (a) Èé ṣe tó fi lè ṣòro fún àwọn Kristẹni láti fi ìwà tútù hàn nínú ìbálò wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ? (b) Kí ni yóò ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti fi ìwà tútù hàn sí àwọn aláṣẹ, kí ló sì lè jẹ́ àbájáde ṣíṣe bẹ́ẹ̀?
18 Ibi kan tó ti máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti fi ìwà tútù hàn jẹ́ nínú ìbálò wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ. Òótọ́ ni pé ìwà táwọn aláṣẹ kan ń hù ti le koko jù ó sì fi hàn pé wọn ò gba tàwọn ẹlòmíràn rò. (Oníwàásù 4:1; 8:9) Àmọ́ ṣá o, ìfẹ́ tí a ní fún Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọyì ọlá àṣẹ rẹ̀ gíga jù lọ kí a sì fi ìtẹríba aláàlà tó tọ́ sí àwọn aláṣẹ ìjọba fún wọn. (Róòmù 13:1, 4; 1 Tímótì 2:1, 2) Kódà bí àwọn tó wà ní ipò gíga bá fẹ́ dín òmìnira tí a ní láti wàásù fún gbogbo èèyàn gẹ́gẹ́ bí apá kan ìjọsìn wa sí Jèhófà kù, tayọ̀tayọ̀ la ó fi wá àwọn ọ̀nà mìíràn tí a lè gbé e gbà láti máa rú ẹbọ ìyìn wa.—Hébérù 13:15.
19 A ò ní fi igbá tí àwọn aláṣẹ bá fi wín ọkà fún wa san án pa dà fún wọn láé. A ó sapá láti hùwà lọ́nà tó fi ìfòyebánilò hàn láìfi àwọn ìlànà òdodo báni dọ́rẹ̀ẹ́. Ọ̀nà yìí ni àwọn ará wa ń gbé e gbà tí wọ́n fi ń kẹ́sẹ járí láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn nìṣó ní òjìlérúgba ó dín mẹ́fà [234] ilẹ̀ yíká ayé. À ń ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé kí a “wà ní ìtẹríba àti láti jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso, láti gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo, láti má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan lọ́nà ìbàjẹ́, láti má ṣe jẹ́ aríjàgbá, láti jẹ́ afòyebánilò, kí [a] máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.”—Títù 3:1, 2.
20. Kí ni yóò jẹ́ èrè àwọn tó bá fi ìwà tútù hàn?
20 Ìbùkún yàbùgà-yabuga wà nípamọ́ fún gbogbo ẹni tó bá fi ìwà tútù hàn. Jésù kéde pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Ní ti àwọn ẹni àmì-òróró arákùnrin Kristi, pípa ìwà tútù mọ́ ń mú kí ayọ̀ wọn àti àǹfààní jíjọba lé ayé lórí nínú Ìjọba ti ọ̀run dájú sí i. Ní ti àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àgùntàn mìíràn,” wọ́n ń bá a nìṣó láti máa fi ìwà tútù hàn, wọ́n sì ń fojú sọ́nà fún ìwàláàyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé níbí. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16; Sáàmù 37:11) Ìrètí àgbàyanu gbáà lèyí jẹ́! Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣàì kọbi ara sí ìránnilétí tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni ní Éfésù pé: “Nítorí náà, èmi, ẹlẹ́wọ̀n nínú Olúwa, pàrọwà fún yín láti máa rìn lọ́nà tí ó yẹ ìpè tí a fi pè yín, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú àti ìwà tútù.”—Éfésù 4:1, 2.
Àtúnyẹ̀wò
• Ìbùkún wo ló ń wá látinú fífi ìwà tútù hàn
• nínú ìdílé?
• lóde ẹ̀rí?
• nínú ìjọ?
• Èrè wo la ṣèlérí fáwọn tó bá jẹ́ oníwà tútù?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ìwà tútù ṣe pàtàkì gan-an nínú ìdílé tí ẹ̀sìn ò ti pa pọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ìwà tútù ń fún ìdè ìdílé lókun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Fi ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ ṣe ìgbèjà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìwà tútù agbaninímọ̀ràn lè ran ẹni tó ṣi ẹsẹ̀ gbé lọ́wọ́