Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Ké Sí Ọ Tọ̀yàyàtọ̀yàyà

A Ké Sí Ọ Tọ̀yàyàtọ̀yàyà

A Ké Sí Ọ Tọ̀yàyàtọ̀yàyà

OÚNJẸ Alẹ́ Olúwa tí Jésù Kristi Olúwa dá sílẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìtàn lásán. Láti ìgbà tá a ti dá a sílẹ̀ ló ti ń ní ipa tó lágbára lórí àwọn èèyàn. Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn kan sì rí kà nínú àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere nípa ìṣẹ̀lẹ̀ alẹ́ ọjọ́ yẹn ti sún wọn láti máa ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní onírúurú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe é.

Ohun tí wọ́n ṣe yẹn ò burú nítorí pé Jésù Kristi fúnra rẹ̀ ló pa á láṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kí wọ́n sì máa se é déédéé. Ó sọ fún wọn ní pàtó pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” —Lúùkù 22:19; 1 Kọ́ríńtì 11:23-25.

Àmọ́ ṣá o, ká tó lè gbádùn ayẹyẹ yìí dáadáa, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ìtumọ̀ pípéye tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ayẹyẹ náà. Láfikún sí i, ó tún ṣe pàtàkì ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àkókò tó yẹ ká ṣe é, àti ọ̀nà tá a óò máa gbà ṣe é.

Ní ìgbọràn sí ohun tí Jésù pa láṣẹ, káàkiri àgbáyé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò ti péjọ ní alẹ́ Wednesday, April 16, 2003 láti ṣayẹyẹ ìṣe ìrántí ikú Jésù. Wọ́n á lo àkókò náà láti ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ àti láti sọ ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí wọ́n ní dọ̀tun nínú Jésù Kristi Olúwa, ẹni tó sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) A ké sí ọ tọ̀yàyàtọ̀yàyà síbi ayẹyẹ yìí kí ìwọ náà lè fún ìgbàgbọ́ tó o ní nínú Jésù Kristi àti Jèhófà, Bàbá wa ọ̀run lókun kí ìfẹ́ tó o ní fún wọn sì lè pọ̀ sí i.