Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ilé Ẹjọ́ Gíga Ti Ìsìn Tòótọ́ Lẹ́yìn ní “Ilẹ̀ Árárátì”

Ilé Ẹjọ́ Gíga Ti Ìsìn Tòótọ́ Lẹ́yìn ní “Ilẹ̀ Árárátì”

Ilé Ẹjọ́ Gíga Ti Ìsìn Tòótọ́ Lẹ́yìn ní “Ilẹ̀ Árárátì”

Bàbá ọlọ́mọ mẹ́ta kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Armenia dúró, tòun ti ewú orí síwájú ilé ẹjọ́ gíga jù lọ lórílẹ̀ èdè rẹ̀. Òmìnira rẹ̀ àti tàwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ti dójú ọ̀gbagadè. Ilé Ẹjọ́ tẹ́tí sílẹ̀ bó ṣe ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Bíbélì láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ̀. Kó lè yé ọ bí ìgbẹ́jọ́ yìí ṣe yọrí sí ìṣẹ́gun ńláǹlà fún ìsìn tòótọ́ lórílẹ̀-èdè náà, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tó dé ipò yẹn.

ILẸ̀ Armenia wà lápá ìlà oòrùn ilẹ̀ Turkey àti gúúsù ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti Caucasus. Ó ju mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn tó ń gbé níbẹ̀. Téèyàn bá wà ní Yerevan, olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, kedere báyìí ni yóò máa wo téńté orí méjèèjì tí Òkè Árárátì nì, ìyẹn orí òkè tí ìtàn sọ pé ọkọ áàkì Nóà gúnlẹ̀ sí lẹ́yìn Ìkún Omi àgbáyé yẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 8:4. a

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń bá ìgbòkègbodò wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni bọ̀ láti ọdún 1975 ní Armenia. Lẹ́yìn tí Armenia gba òmìnira kúrò lábẹ́ ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́ lọ́dún 1991, wọ́n dá Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ẹ̀sìn fún Ìjọba sílẹ̀ kí àwọn ètò ẹ̀sìn lè lọ máa forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. Àmọ́ àjọ yìí fàáké kọ́rí, wọn ò gba orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọlé, ní pàtàkì nítorí ọ̀ràn àìdásí-tọ̀túntòsì wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Nítorí náà, láti ọdún 1991 ó ti ju ọgọ́rùn-ún ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ní Armenia tí wọ́n ti dá lẹ́jọ́, tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn sí dèrò ẹ̀wọ̀n, nítorí ìdúró wọn tó bá Bíbélì mu lórí ọ̀ràn wíwọṣẹ́ ológun.

Àjọ yìí tún sọ pé kí ilé iṣẹ́ ìpẹ̀jọ́ ti ìjọba ṣèwádìí nípa ìgbòkègbodò ìsìn ti ọ̀gbẹ́ni Lyova Margaryan, Kristẹni alàgbà àti ògbóǹkangí amòfin tí ilé iṣẹ́ iná mànàmáná ìlú tó ń lo agbára átọ́míìkì gbà síṣẹ́. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n fẹ̀sùn kan Arákùnrin Lyova Margaryan lábẹ́ Òfin kẹrìn-lé-ní-òjìlérúgba [244]. Òfin yìí jẹ́ ara àṣẹ́kù àwọn òfin tí ìjọba Soviet ṣe nígbà ìṣàkóso Khrushchev láti fi ṣèdíwọ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ètò ẹ̀sìn yòókù, kí gbogbo wọn lè pa rẹ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀.

Òfin yẹn sọ pé ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ láti dá ẹ̀sìn sílẹ̀ tàbí láti ṣe aṣáájú ẹ̀sìn tó jẹ́ pé, wọ́n ń sọ pé àwọn ń wàásù ìgbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ ńṣe ni ‘wọ́n ń tan àwọn ọ̀dọ́ lọ ṣe ìpàdé ẹ̀sìn tí kò lórúkọ lábẹ́ òfin’ tí wọ́n sì ‘darí àwọn ọmọ ìjọ wọn láti kọ ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ orílẹ̀-èdè sílẹ̀.’ Ohun tí olùpẹ̀jọ́ fún ìjọba fi ṣe ẹ̀rí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni wíwá táwọn ọmọdé ń wá sí àwọn ìpàdé tí Arákùnrin Lyova Margaryan ń darí ní ìlú Metsamor. Olùpẹ̀jọ́ yìí tún sọ pé Arákùnrin Margaryan ń fipá mú kí àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ ọmọ ìjọ kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.

Ìgbẹ́jọ́ Bẹ̀rẹ̀

Ọjọ́ Friday, July 20, 2001 ni ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ilé ẹjọ́ ẹkùn Armavir, iwájú Adájọ́ Manvel Simonyan sì ni wọ́n ti rojọ́. Ìgbẹ́jọ́ ń bá a lọ títí wọ oṣù August. Nígbà tí àwọn ẹlẹ́rìí olùpẹ̀jọ́ ń jẹ́rìí, wọ́n padà jẹ́wọ́ pé àwọn aṣojú ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá inú ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà náà National Security Ministry (tó ń jẹ́ KGB tẹ́lẹ̀) ló sọ apá kan ẹ̀sùn táwọn kọ sílẹ̀ pé Arákùnrin Margaryan jẹ̀bi rẹ̀ fáwọn, tí wọ́n sì tún fipá mú àwọn buwọ́ lu àkọsílẹ̀ yẹn. Kódà nígbà kan, obìnrin kan jẹ́wọ́ pé òṣìṣẹ́ kan ní Ilé Iṣẹ́ Ààbò ló ní kóun sọ pé “àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòdì sí ìjọba wa àti ẹ̀sìn wa.” Obìnrin náà jẹ́wọ́ pé òun ò tiẹ̀ fúnra òun mọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan pàápàá, pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n lòun kàn gbọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n ìjọba.

Nígbà tó kan Arákùnrin Margaryan láti sọ̀rọ̀, ó jẹ́rìí pé àwọn ọmọ kéékèèké tó ń wá sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba àṣẹ lọ́wọ́ òbí wọn kí wọ́n tó máa wá. Ó ṣàlàyé pé ìpinnu ara ẹni lọ̀ràn wíwọṣẹ́ ológun jẹ́. Ọjọ́ púpọ̀ ni olùpẹ̀jọ́ fi bi í ní àwọn ìbéèrè. Arákùnrin Margaryan sì ń rọra fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀, tí olùpẹ̀jọ́ sì ń ṣí Bíbélì tirẹ̀ láti wo Ìwé Mímọ́ tó ń tọ́ka sí.

Ní September 18, 2001, adájọ́ kéde pé Margaryan “kò jẹ̀bi,” pé “kò sí ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìrúfin” nínú ohun tó ń ṣe. Ìròyìn tó sọ òkodoro ọ̀rọ̀ nípa ẹjọ́ yìí jáde nínú ìwé ìròyìn Associated Press. Ó kà pé: “Wọ́n dá aṣáájú ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ní Armenia láre lónìí pé kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìyínilọ́kànpadà àti fífipá mú àwọn ọ̀dọ́ láti yẹ iṣẹ́ ológun sílẹ̀. Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ oṣù méjì, Ilé Ẹjọ́ sọ pé kò sí ẹ̀rí tó pọ̀ tó láti fi fẹ̀sùn kan aṣáájú ẹ̀sìn náà, Levon Markarian [Lyova Margaryan]. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún ni ì bá fi gbára. . . . Lóòótọ́ Òfin Orílẹ̀-Èdè Armenia sọ pé olúkúlùkù lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wù ú, ó ṣòro fún àwọn ètò ẹ̀sìn tuntun láti lè forúkọ sílẹ̀, ìlànà ìforúkọsílẹ̀ ọ̀hún sì rèé, Ìjọ Àpọ́sítélì Ilẹ̀ Armenia tó pọ̀ ju àwọn ìjọ yòókù lọ ló gbè.” Nínú àtẹ̀jáde tí Àjọ Ààbò àti Àjọṣe Ilẹ̀ Yúróòpù (OSCE) gbé jáde nípa rẹ̀ nínú ìwé ìròyìn ti September 18, 2001, wọ́n sọ pé: “Lóòótọ́ ìdájọ́ yìí dùn mọ́ wa o, síbẹ̀, pípè tí wọ́n tiẹ̀ pẹjọ́ yẹn pàápàá ṣì ń dun Iléeṣẹ́ OSCE.”

Ìpẹ̀jọ́ Ń Bá A Lọ

Síbẹ̀, àwọn olùpẹ̀jọ́ ṣì pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, oṣù mẹ́rin mìíràn ni wọ́n sì fi gbọ́ ẹjọ́ yìí. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ yìí, bó ṣe kan Arákùnrin Margaryan láti rojọ́, ọ̀kan nínú àwọn adájọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà ló kọ́kọ́ gbé ìbéèrè kò ó lójú. Bí Arákùnrin Margaryan ṣe bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn rẹ̀ ni obìnrin tó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ náà já lu ọ̀rọ̀ rẹ̀, tó sì da ìbéèrè bò ó. Lẹ́yìn náà, obìnrin yìí ò tiẹ̀ jẹ́ kí Arákùnrin Margaryan dáhùn ìbéèrè kan ṣoṣo yẹn délẹ̀. Àní ó tún yọ èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìbéèrè tí agbẹjọ́rò Margaryan bi Margaryan kúrò nínú àkọsílẹ̀ ẹjọ́ náà láìsọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà ìgbẹ́jọ́ náà, ńṣe ni àwọn agbawèrèmẹ́sìn, tó lòdì sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n kún yàrá ìgbẹ́jọ́ náà bámú, ń rọ̀jò èébú sórí Arákùnrin Margaryan. Bí àkókò ìgbẹ́jọ́ yẹn ṣe parí, onírúurú ìròyìn èké ni wọ́n ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n nípa ìgbẹ́jọ́ náà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ pé, Arákùnrin Margaryan kàn tiẹ̀ ti gbà pé òun alára jẹ̀bi.

Nígbà tí ìgbẹ́jọ́ dé ìdajì, alága ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà ṣe ohun kan tó ṣe àwọn òǹwòran ní kàyéfì. Ńṣe ló fa lẹ́tà kan tí Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ẹ̀sìn fún Ìjọba kọ sí wọn yọ, tó sọ pé kí ilé iṣẹ́ tó ń pẹjọ́ fún ìjọba má ṣàìwá nǹkan ṣe sí Arákùnrin Margaryan. Ìgbésẹ̀ yìí ṣe àwọn òǹwòran tó wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn ní kàyéfì gan-an ni, torí pé, níwọ̀n bí orílẹ̀-èdè Armenia ti kọ̀wé béèrè pé kí wọ́n gba òun sínú àjọ Ìparapọ̀ Yúróòpù, Armenia ti gbà pé ojúṣe òun ni “láti rí i dájú pé gbogbo Ṣọ́ọ̀ṣì tàbí ètò ẹ̀sìn yòókù, pàápàá àwọn èyí tí wọ́n ń pè ní ‘ẹ̀sìn àtòkèèrèwá,’ làwọn èèyàn lè máa ṣe láìsí ẹ̀tanú kankan.”

Bí wọ́n ṣe ń gbọ́ ẹjọ́ náà lọ láwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ńṣe ni ilé ẹjọ́ kan gógó. Àwọn alátakò ń kanra mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí nínú ilé ẹjọ́ àti níta, wọ́n tilẹ̀ ń wá wọn níjà. Wọ́n á gbá àwọn obìnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí lójúgun. Wọ́n tọ́ Ẹlẹ́rìí kan níjà, ṣùgbọ́n onítọ̀hún ò gbin, kò fọhùn, ni wọ́n bá jan nǹkan mọ́ ọn lógòóró ẹ̀yìn látẹ̀yìn, ọpẹ́lọpẹ́ ọsibítù lára ẹ̀.

Láàárín ìgbà yìí, wọ́n yan adájọ́ mìíràn ṣe alága ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ náà. Lóòótọ́ àwọn mélòó kan láàárín àwùjọ ṣì fẹ́ máa da àwọn agbẹjọ́rò Margaryan láàmú, àmọ́ alága tuntun yìí káwọ́ wọn. Kódà ó tiẹ̀ ní kí ọlọ́pàá mú obìnrin kan jáde nílé ẹjọ́ nígbà tó ń halẹ̀ mọ́ àwọn agbẹjọ́rò yìí.

Ẹjọ́ Dé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Armenia

Níkẹyìn, ní March 7, 2002, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fara mọ́ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́. Ó sì yani lẹ́nu pé, ó ku ọ̀la kí wọ́n kéde àbájáde yìí ni ìjọba kàn tú Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ẹ̀sìn fún Ìjọba ká. Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn olùpẹ̀jọ́ tún pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ yẹn, wọ́n sì pẹjọ́ náà sí Ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ní Armenia, ìyẹn Court of Cassation. Àwọn olùpẹ̀jọ́ ní kí Ilé Ẹjọ́ yìí tún ẹjọ́ yìí gbọ́ látìbẹ̀rẹ̀ láti lè “kéde ẹ̀bi òun àre tiwọn lọ́tọ̀.”

Àwọn adájọ́ mẹ́fà, tí Adájọ́ Mher Khachatryan jẹ́ alága wọn, jókòó ní agogo mọ́kànlá àárọ̀ April 19, 2002 láti gbọ́ ẹjọ́ yìí. Nígbà tí ẹni àkọ́kọ́ nínú olùpẹ̀jọ́ méjèèjì máa bẹ̀rẹ̀ sí í rojọ́, ńṣe ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ ìbínú lọ rẹpẹtẹ pé àwọn ilé ẹjọ́ méjì ìṣáájú kọ̀ láti dá Arákùnrin Margaryan lẹ́bi. Lọ́tẹ̀ yìí ṣá o, olùpẹ̀jọ́ làwọn adájọ́ dá ọ̀rọ̀ mọ́ lẹ́nu, tí adájọ́ mẹ́rin sì bi í láwọn ìbéèrè tó ṣe ṣàkó. Adájọ́ kan bá olùpẹ̀jọ́ wí pé ó fẹ́ kó Ilé Ẹjọ́ ṣìnà nígbà tó fi ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù àti àìsí orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ìwé ìjọba kún ẹ̀sùn tó kà sí Arákùnrin Margaryan lọ́rùn, bẹ́ẹ̀, nǹkan méjèèjì yìí kò sí lára ohun tí Òfin kẹrìn-lé-ní-òjìlérúgba [244] sọ pé ó lòdì. Adájọ́ yìí wá sọ pé ìgbésẹ̀ olùpẹ̀jọ́ jẹ́ “ṣíṣe inúnibíni síni nípa fífi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kanni.” Adájọ́ mìíràn mẹ́nu kan ọ̀kan-kò-jọ̀kan ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Yúróòpù ti dá sẹ́yìn tí wọ́n sì gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ara “ẹ̀sìn tí a mọ̀ dunjú” tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ààbò lábẹ́ Àdéhùn Àjọṣe Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Ọ̀rọ̀ yìí ń lọ lọ́wọ́ ni àlùfáà kan dédé kígbe láàárín àwùjọ ilé ẹjọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ fọ́ orílẹ̀-èdè Armenia o. Ilé Ẹjọ́ ní kó gbẹ́nu ẹ̀ dákẹ́.

Àwọn adájọ́ wá pe Lyova Margaryan jáde síwájú láti àárín èrò, tó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ irú rẹ̀ nílé ẹjọ́ gíga yìí. Arákùnrin Margaryan jẹ́rìí tó múná dóko nípa ojú táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo onírúurú ọ̀ràn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. (Máàkù 13:9) Àwọn adájọ́ wọ̀ ìyẹ̀wù lọ jíròrò fúngbà kúkúrú, wọ́n padà wá, wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan pé ìdájọ́ “kò jẹ̀bi” ti àtẹ̀yìnwá náà làwọn fara mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn Arákùnrin Margaryan balẹ̀, ará tù ú wàyí, kódà ó hàn lójú rẹ̀. Nínú àkọsílẹ̀ ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ yìí, wọ́n sọ pé: “Ohun tí [Lyova Margaryan] ń ṣe, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ lábẹ́ òfin ilẹ̀ wa tó wà lọ́wọ́, àti pé fífi irú ẹ̀sùn yìí kanni lòdì sí Òfin kẹtàlélógún nínú Òfin orílẹ̀-èdè Armenia àti Òfin kẹsàn-án nínú Àdéhùn Àjọṣe Ilẹ̀ Yúróòpù.”

Ipa Tí Ìdájọ́ Yìí Ní

Ká ní àwọn olùpẹ̀jọ́ borí ni, ì bá dohun táwọn èèyàn á fi máa pe gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí yòókù tó jẹ́ alàgbà ìjọ jákèjádò ilẹ̀ Armenia lẹ́jọ́. Àmọ́ báyìí, a retí pé ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ yìí kò ní jẹ́ kí irú ìyọlẹ́nu bẹ́ẹ̀ lè wáyé. Ká ní wọ́n dá wa lẹ́bi sẹ́, ìyẹn ni ìjọba ì bá fi bojú, tí wọ́n á wá máa kọ̀ láti forúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Àmọ́ a dúpẹ́, Ilé Ẹjọ́ ti bi ohun àfiṣe-bojúbojú wọn wó.

A ṣì ń wò ó pé bóyá lọ́jọ́ kan ṣáá, wọ́n á gbà láti forúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ju ẹgbẹ̀rún méje [7,000] lórílẹ̀-èdè yẹn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Kó tó dìgbà náà ṣá o, ẹ̀sìn tòótọ́ ṣì ń bẹ ó sì ń gbèrú “ní ilẹ̀ Árárátì” o.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìdí kan nìyí táwọn ará Armenia fi máa ń pe orílẹ̀-èdè wọn ní ilẹ̀ Òkè Árárátì. Láyé àtijọ́, Armenia jẹ́ ìjọba tó gbòòrò gan-an, kódà inú ilẹ̀ rẹ̀ ni gbogbo òkè tá à ń wí yìí wà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì Greek Septuagint fi túmọ̀ gbólóhùn náà “ilẹ̀ Árárátì” tó wà nínú Aísáyà 37:38 sí “Armenia.” Àmọ́ ní báyìí, Òkè Árárátì ti di ara orílẹ̀-èdè Turkey, ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà rẹ̀ apá ìlà oòrùn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Lyova Margaryan nígbà ìgbẹ́jọ́ rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Arákùnrin Margaryan àti ìdílé rẹ̀