Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Ti Ṣe Pàtàkì Tó?

Báwo Ni Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Ti Ṣe Pàtàkì Tó?

Báwo Ni Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Ti Ṣe Pàtàkì Tó?

“BÍBÉLÌ sọ pé: “Ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra nínú ará ayé ni inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́.” (Òwe 19:22) Ká sòótọ́, àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ tí ìfẹ́ bá sún wa láti fi inú rere hàn. Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà ‘inú-rere-onífẹ̀ẹ́’ tọ́ka sí inú rere tá a gbé karí àjọṣe tó wà láàárín ẹnì kan àti ẹlòmíràn látilẹ̀wá, bí irú èyí tá a gbé karí inú rere tí ẹnì kan ti ṣe fún ọmọnìkejì rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ìgbà tí ẹnì kan ní ìfẹ́ dídúróṣinṣin ló rí.

Jèhóáṣì Ọba Júdà kùnà láti ní ànímọ́ tó fani mọ́ra yìí. Ó yẹ kí Jèhóáṣì dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ àbúrò bàbá rẹ̀ obìnrin àti Jèhóádà ọkọ obìnrin náà. Kò tí ì pé ọmọ ọdún kan nígbà tí ìyá ìyá rẹ̀ òṣónú sọ ara rẹ̀ di ayaba, tó sì pa gbogbo àwọn arákùnrin Jèhóáṣì tó lẹ́tọ̀ọ́ sípò ọba pátápátá. Kò rí Jèhóáṣì pa ní tiẹ̀ nítorí pé àbúrò bàbá rẹ̀ àti ọkọ obìnrin yìí lọ gbé e pa mọ́. Wọ́n tún kọ́ ọ ní Òfin Ọlọ́run. Nígbà tí Jèhóáṣì pé ọmọ ọdún méje, ọkọ àbúrò bàbá rẹ̀ lo ọlá àṣẹ tó ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà láti pa ayaba búburú yìí, ó sì gbé Jèhóáṣì gorí ìtẹ́.—2 Kíróníkà 22:10–23:15.

Jèhóáṣì ọ̀dọ́kùnrin yìí jọba lọ́nà rere títí di ìgbà ikú ọkọ àbúrò bàbá rẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn náà ó kó wọnú ìbọ̀rìṣà. Ọlọ́run wá rán Sekaráyà tó jẹ́ ọmọ Jèhóádà láti lọ kìlọ̀ fún Jèhóáṣì nítorí sísọ tó sọ ara rẹ̀ di apẹ̀yìndà. Jèhóáṣì sì pàṣẹ pé kí wọn sọ Sekaráyà ní òkúta pa. Ìwà àìní ìdúróṣinṣin sí ìdílé tó ṣe é lóore ńlá bàǹtà banta yìí mà kúkú burú o! —2 Kíróníkà 24:17-21.

Bíbélì sọ pé: “Jèhóáṣì Ọba kò sì rántí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí baba [Sekaráyà] ṣe sí i, tí ó fi pa ọmọkùnrin rẹ̀.” Bí Sekaráyà ti ń kú lọ, ó ní: “Kí Jèhófà rí sí i, kí ó sì béèrè rẹ̀ padà.” Bí Sekaráyà ṣe sọ gẹ́lẹ́ ló rí, Jèhóáṣì di olókùnrùn, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì pa á. —2 Kíróníkà 24:17-25.

Dípò kéèyàn kàgbákò bíi ti Jèhóáṣì Ọba, gbogbo àwọn tó bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí ni ọjọ́ ọ̀la wọn yóò dára. Bíbélì sọ pé: “Kí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ má fi ọ́ sílẹ̀. . . . Kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ojú rere . . . ní ojú Ọlọ́run àti ti ará ayé.”—Òwe 3:3, 4.