Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Wàá Béèrè Lọ́wọ́ Ọlọ́run?

Kí Ni Wàá Béèrè Lọ́wọ́ Ọlọ́run?

Kí Ni Wàá Béèrè Lọ́wọ́ Ọlọ́run?

JÁKÈJÁDÒ ayé làwọn èèyàn ti ń béèrè àwọn ìbéèrè tó ta kókó nípa ìgbésí ayé. Ṣé ìwọ náà ń ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn kan ti gbé ìbéèrè wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn àmọ́ wọn ò rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn gbà. Àwọn mìíràn ti fúnra wọn ronú lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí láyè ara wọn. Àwọn kan ti kúnlẹ̀ àdúrà fún ìtọ́sọ́nà. Ṣé lóòótọ́ ló ṣeé ṣe kó o rí ìdáhùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ọ̀ràn tó ń dà ọ́ láàmú? Lára àwọn ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé àwọn á fẹ́ béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run nìwọ̀nyí.

Ìwọ Ọlọ́run, ta tiẹ̀ ni ọ́?

Àṣà ìbílẹ̀, ẹ̀sìn táwọn òbí ń ṣe, ó sì tún ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun táwọn èèyàn fúnra wọn yàn ló máa ń pinnu irú ojú tí wọ́n fi ń wo Ọlọ́run. Àwọn kan ní orúkọ tí wọ́n fi ń pè é; àwọn mìíràn wulẹ̀ ń pè é ní Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ìyẹn já mọ́ ohunkóhun? Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run tòótọ́ kan wà, tó jẹ́ ká mọ òun tó sì sọ orúkọ tí òun ń jẹ́ fún wa?

Kí nìdí tí ìjìyà fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀?

Bí lílò tẹ́nì kan ń lo ìgbésí ayé rẹ̀ nílòkulò tàbí ìwà pálapàla tó ń hù bá sọ ọ́ di olókùnrùn tàbí sọ ọ́ di ẹdun arinlẹ̀, onítọ̀hún lè wá máa ṣàròyé. Àmọ́ ó lè mọ ohun tó fà á tóun fi ń jẹ irú ìyà bẹ́ẹ̀.

Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn mìíràn wà tí pásapàsa ìyà ń jẹ tí kì í sì í ṣe àfọwọ́fà wọn. Àwọn kan ní àrùn bárakú. Àwọn mìíràn ń sa gbogbo ipá wọn láti ṣẹ́pá àwọn ìṣòro tó dà bí èyí tí kò ṣeé borí kí wọ́n ṣáà lè rílé gbé kí wọ́n sì lè pèsè oúnjẹ tí ó tó fún ìdílé wọn. Ọ̀kẹ́ àìmọye ló ń fojú winá ìwà ọ̀daràn, ogun, ìwà ipá tí kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀, ìjábá, tàbí ìwà ìrẹ́nijẹ látọ̀dọ̀ àwọn tó wà nípò àṣẹ.

Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń béèrè pé: ‘Kí nìdí tí irú ipò bẹ́ẹ̀ fi gbòde kan? Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba gbogbo ìyà yìí?’

Kí nìdí tí mo fi wà láyé? Kí ni ìgbésí ayé túmọ̀ sí?

Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí sábà máa ń jẹ yọ nígbà ti gbogbo nǹkan bá tojú sú ẹnì kan tí ò rí ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn nínú ìgbòkègbodò rẹ̀ ojoojúmọ́—bí nǹkan sì ṣe rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn nìyẹn. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn mìíràn gbà pé Ọlọ́run ti yan ọ̀nà tẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa gbà gbé ìgbésí ayé ẹ̀ mọ́ ọn. Ṣé lóòótọ́ ni? Bí Ọlọ́run bá ní ète pàtàkì tó fi dá ọ, ó dájú pé wàá fẹ́ mọ ète yẹn.

Nínú gbogbo ìwé tó wà láyé, ọ̀kan wà tó sọ ọ́ ní kedere pé òun ní ìmísí Ọlọ́run. Ìwé yìí wà lárọ̀ọ́wọ́tó láwọn èdè tó pọ̀ gan-an ju ti ìwé èyíkéyìí mìíràn tá a tíì kọ lọ, bó sì ṣe yẹ kó o retí pé kí ìhìn tó dìídì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá fún gbogbo èèyàn rí nìyẹn. Bíbélì Mímọ́ ni ìwé ọ̀hún. Inú rẹ̀ ni Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé, ìyẹn Ọlọ́run fúnra rẹ̀, ti jẹ́ ká mọ ẹni tóun jẹ́ àti orúkọ òun. Ǹjẹ́ o mọ orúkọ yẹn? Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa irú Ẹni tí Ọlọ́run jẹ́? Ǹjẹ́ o mọ ohun tó sọ nípa ohun tí Ọlọ́run retí pé kó o ṣe?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Chad Ehlers/Index Stock Photography

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Òkè ńlá: Chad Ehlers/Index Stock Photography