Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Jèhófà Ń Kíyè sí Ohun Tí Ò Ń Ṣe?

Ǹjẹ́ Jèhófà Ń Kíyè sí Ohun Tí Ò Ń Ṣe?

Ǹjẹ́ Jèhófà Ń Kíyè sí Ohun Tí Ò Ń Ṣe?

BÁWO lo ṣe máa dáhùn ìbéèrè yẹn? Ọ̀pọ̀ ló máa sọ pé: ‘Mo gbà pé Ọlọ́run kíyè sí ohun táwọn ọkùnrin bíi Mósè, Gídíónì, àti Dáfídì ṣe, àmọ́ kò dá mi lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ sí ohunkóhun tí mo lè ṣe. Mi ò tiẹ̀ lè fara mi wé Mósè, Gídíónì, tàbí Dáfídì rárá.’

Òótọ́ ni pé àwọn ọkùnrin olóòótọ́ kan tó wà láyé nígbà tá a kọ Bíbélì fi ìgbàgbọ́ ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà. Wọ́n ‘ṣẹ́gun àwọn ìjọba, wọ́n di ẹnu àwọn kìnnìún, wọ́n dá ipá iná dúró, wọ́n sì yè bọ́ lọ́wọ́ ojú idà.’ (Hébérù 11:33, 34) Àmọ́ àwọn mìíràn fi ìgbàgbọ́ wọn hàn láwọn ọ̀nà tí kò fi bẹ́ẹ̀ gba àfiyèsí, Bíbélì sì mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run kíyè sí ohun tí wọ́n fi ìgbàgbọ́ ṣe pẹ̀lú. Láti ṣàkàwé, gbé àpẹẹrẹ olùṣọ́ àgùntàn kan, ti wòlíì kan, àti ti opó kan tá a mẹ́nu kàn nínú Ìwé Mímọ́ yẹ̀ wò.

Olùṣọ́ Àgùntàn Kan Rú Ẹbọ

Kí lohun tó o rántí nípa Ébẹ́lì, ọmọkùnrin tí Ádámù àti Éfà bí ṣìkejì? O lè rántí pé ikú ajẹ́rìíkú ló kú, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irú ikú yẹn ni díẹ̀ lára wa máa kú. Àmọ́ ìdí mìíràn wà tí Ọlọ́run fi kíyè sí Ébẹ́lì ṣáájú àkókò yẹn.

Lọ́jọ́ kan, Ébẹ́lì mú èyí tó dára jù lọ nínú ẹran ọ̀sìn rẹ̀ ó sì fi rúbọ sí Ọlọ́run. Ẹ̀bùn rẹ̀ yẹn lè dà bí ohun tó kéré lọ́jọ́ òní, àmọ́ Jèhófà rí i, ó sì fi ojú rere wò ó. Àmọ́, kò tán síbẹ̀ o. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé nípa rẹ̀ nínú ìwé Hébérù. Ọlọ́run ò gbàgbé ẹbọ yẹn o, kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pàápàá!—Hébérù 6:10; 11:4.

Báwo ni Ébẹ́lì ṣe pinnu irú ẹbọ tó yẹ kóun rú? Bíbélì ò sọ ìyẹn fún wa, àmọ́ ó ti ní láti ronú lórí ọ̀ràn náà dáadáa. Olùṣọ́ àgùntàn ni, nítorí náà kò yani lẹ́nu pé ó fi díẹ̀ lára agbo ẹran rẹ̀ rúbọ. Tún ṣàkíyèsí pé èyí tó dára jù lọ níbẹ̀ ló lò—ìyẹn “àwọn apá tí ó lọ́ràá.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:4) Ó sì tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún ejò náà nínú ọgbà Édẹ́nì pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Ìṣípayá 12:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ébẹ́lì ò lóye irú ẹni tí “obìnrin náà” àti “irú-ọmọ” rẹ̀ jẹ́, síbẹ̀ ó ti lè mọ̀ pé ‘pípa’ irú ọmọ obìnrin náà ‘ní gìgísẹ̀’ yóò ní títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ nínú. Ó mọ̀ dájú pé kò sí ohunkóhun tó lè ṣeyebíye ju ohun abẹ̀mí lọ. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ níbẹ̀ ni pé ẹbọ tó rú yẹn dáa gan-an.

Bíi ti Ébẹ́lì, àwọn Kristẹni náà máa ń rú ẹbọ sí Ọlọ́run lóde òní. Kì í ṣe àkọ́bí nínú agbo ẹran ni wọ́n fi ń rúbọ bí kò ṣe “ẹbọ ìyìn . . . èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ [Ọlọ́run].” (Hébérù 13:15) Ètè wa ń ṣe ìpolongo ní gbangba nígbà tá a bá sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wa fáwọn ẹlòmíràn.

Ṣé o fẹ́ kí ẹbọ ìyìn tó ò ń rú túbọ̀ sunwọ̀n sí i? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ronú jinlẹ̀ dáadáa lórí ohun tó jẹ́ àìní àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ rẹ. Kí làwọn ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn? Kí ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí? Àwọn apá wo ló máa fà wọ́n mọ́ra nínú Bíbélì? Nígbà tó o bá wà lóde ẹ̀rí, ṣàyẹ̀wò ohun tó o ti bá àwọn èèyàn sọ kó o sì ronú lórí ọ̀nà tó o lè gbà já fáfá ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Nígbà tó o bá sì ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú, kó o sọ̀rọ̀ látọkànwá. Jẹ́ kí ẹbọ rẹ jẹ́ ojúlówó “ẹbọ ìyìn.”

Wòlíì Kan Wàásù Fáwọn Tí Ò Fẹ́ Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀

Wá gbé ọ̀rọ̀ wòlíì Énọ́kù yẹ̀ wò. Ó lè jẹ́ pé òun nìkan ṣoṣo gíro ni ẹlẹ́rìí fún Jèhófà Ọlọ́run lákòókò yẹn. Ṣé bíi ti Énọ́kù lọ̀rọ̀ tìẹ náà ṣe rí, tó jẹ́ pé ìwọ nìkan ṣoṣo lò ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà nínú ìdílé rẹ? Ṣé ìwọ nìkan ni akẹ́kọ̀ọ́ tó ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì ní kíláàsì rẹ tàbí ìwọ nìkan ni òṣìṣẹ́ tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ níbi iṣẹ́ rẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìṣòro lè dìde. Àwọn ọ̀rẹ́, àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn ọmọ kíláàsì ẹ, tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ pàápàá lè máa rọ̀ ẹ láti rú àwọn òfin Ọlọ́run. Wọ́n lè sọ pé: “Kò sẹ́ni tó máa mọ ohun tó o ṣe láéláé. A ò ní sọ fẹ́nì kankan.” Wọ́n lè sọ pé ìwà òmùgọ̀ ni kéèyàn máa da ara ẹ̀ láàmú nítorí àwọn ìlànà Bíbélì, nítorí pé kò sóhun tó kan Ọlọ́run nípa ohun tó o bá ṣe. Nítorí inú tó ń bí wọn pé o ò ronú bíi tiwọn o ò sì hùwà bíi tiwọn, wọ́n lè sa gbogbo ipá wọn láti mú ọ juwọ́ sílẹ̀.

Ká sọ tòótọ́, kò rọrùn láti borí irú pákáǹleke bẹ́ẹ̀, àmọ́ kì í ṣe ohun tí ò ṣeé borí. Ronú nípa Énọ́kù, ẹnì keje nínú ìlà láti ọ̀dọ̀ Ádámù. (Júúdà 14) Nígbà tó fi máa di àkókò tí wọ́n bí Énọ́kù, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni ò ka ìwà rere sí mọ́. Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ń dójú tini; ìwà wọn sì jẹ́ “amúnigbọ̀nrìrì.” (Júúdà 15) Wọ́n hùwà lọ́nà kan náà tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà ń hùwà lóde òní.

Báwo ni Énọ́kù ṣe kojú wọn? Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn jẹ́ ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí gan-an lóde òní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Énọ́kù ni ẹnì kan ṣoṣo tó ń jọ́sìn Jèhófà láyé nígbà yẹn, síbẹ̀ kò dá nìkan wà. Énọ́kù bá Ọlọ́run rìn.—Jẹ́nẹ́sísì 5:22.

Orí àtimú inú Ọlọ́run dùn ni Énọ́kù gbé gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ kà. Ó mọ̀ pé ohun tí bíbá Ọlọ́run rìn túmọ̀ sí kọjá kéèyàn kàn máa gbé ìgbésí ayé mímọ́ kó sì máa hùwà rere. Jèhófà retí pé kó wàásù. (Júúdà 14, 15) Ó yẹ kó kìlọ̀ fáwọn èèyàn náà pé ìwà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń hù ò fara sin rárá. Énọ́kù bá Ọlọ́run rìn fún ohun tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún—jàn-ànràn-jan-anran lèyí fi gùn ju iye ọdún tí èyíkéyìí lára wa ti lò. Títí tó fi kú, kò dẹ́kun rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 5:23, 24.

Bíi ti Énọ́kù, a ti pa á láṣẹ fún àwa náà láti wàásù. (Mátíù 24:14) Láfikún sí wíwàásù láti ilé de ilé, a tún ń gbìyànjú láti sọ ìhìn rere náà fáwọn mọ̀lẹ́bí wa, fún àwọn tá a jọ ń ṣòwò, àtàwọn ọmọ kíláàsì wa. Àmọ́ ṣá o, a lè máa lọ́ tìkọ̀ láti fìgboyà sọ̀rọ̀ nígbà mìíràn. Ṣé ìwọ náà ní irú ìṣòro yẹn? Má ṣe sọ̀rètí nù. Fara wé àwọn Kristẹni ìjímìjí, kó o sì gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún ọ nígboyà. (Ìṣe 4:29) Má ṣe gbàgbé pé níwọ̀n ìgbà tó o bá ti ń bá Ọlọ́run rìn, o ò lè dá nìkan wà láé.

Opó Kan Se Oúnjẹ

Fojú inú wò ó ná, àní opó kan tí a kò dárúkọ rẹ̀ gba ìbùkún méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nítorí pé ó se oúnjẹ kékeré kan! Kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì o, àjèjì kan tó gbé ìlú Sáréfátì ní ọ̀rúndún kẹwàá ṣááju Sànmánì Tiwa ni. Oúnjẹ opó náà ti fẹ́ tán lákòókò tí ọ̀dá àti ìyàn tó ti wà fún àkókò gígùn ṣì kù díẹ̀ kó dópin. Gbogbo ohun tó ní ò ju ìwọ̀nba ìyẹ̀fun àti òróró tó lè fi ṣe oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tí òun àti ọmọ rẹ̀ máa jẹ kẹ́yìn.

Àkókò yìí gan-an ni àlejò kan wọlé wẹ́rẹ́. Èlíjà, wòlíì Ọlọ́run ni. Ó sọ pé kí opó yìí jẹ́ kóun jẹ lára oúnjẹ kékeré tó ní. Ìwọ̀nba oúnjẹ tí òun àti ọmọ rẹ̀ máa jẹ ló kù, ó sì dájú pé kò sí oúnjẹ tó lè fún àlejò yìí. Àmọ́ Èlíjà mú kó dá obìnrin náà lójú, nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pé tó bá lè fún òun jẹ lára oúnjẹ náà, ebi ò ní pa òun àtọmọ rẹ̀. Ó gba ìgbàgbọ́ gan-an fún obìnrin yìí láti gbà pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì lè kíyè sí òun, tóun jẹ́ àjèjì. Síbẹ̀ ó gba ohun tí Èlíjà wí gbọ́, Jèhófà sì san èrè fún un. “Ìṣà títóbi ti ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, ìṣà kékeré ti òróró náà kò sì gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó sọ nípasẹ̀ Èlíjà.” Bí obìnrin náà àti ọmọ rẹ̀ ṣe rí oúnjẹ jẹ nìyẹn o, títí ìyàn náà fi kásẹ̀ nílẹ̀.—1 Àwọn Ọba 17:8-16.

Àmọ́, ìbùkún mìíràn tún ń bẹ fún opó náà. Nígbà tó ṣe díẹ̀ lẹ́yìn iṣẹ́ ìyanu yẹn, ọmọ obìnrin náà, tó fẹ́ràn gan-an ṣàìsàn, ó sì kú. Àánú rẹ̀ ṣe Èlíjà, ó sì bẹ Jèhófà pé kó jí ọmọdékùnrin náà dìde. (1 Àwọn Ọba 17:17-24) Ìyẹn yóò gba pé kó ṣe iṣẹ́ ìyanu tí irú rẹ̀ ò wáyé rí. Kò sí àkọsílẹ̀ pé ẹnì kan ti jíǹde rí! Ǹjẹ́ Jèhófà yóò tún fi àánú hàn sí àjèjì opó yìí? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ o. Jèhófà fún Èlíjà lágbára láti jí ọmọkùnrin náà dìde. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jésù wá sọ̀rọ̀ nípa obìnrin tó rìnnà kore yìí pé: ‘Ọ̀pọ̀ opó ní ń bẹ ní Ísírẹ́lì . . . Síbẹ a rán Èlíjà sí Sáréfátì ní ilẹ̀ Sídónì sí opó kan.’—Lúùkù 4:25, 26.

Ọ̀ràn ìṣúnná owó ò dúró sójú kan lóde òní, kódà láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà pàápàá. Àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ti gbaṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ wọn tó ti ń fi òótọ́ inú bá wọn ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. Nítorí ìbẹ̀rù kíṣẹ́ má bàa bọ́ lọ́wọ́ ẹni, Kristẹni kan lè fẹ́ lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́, kí ilé iṣẹ́ tó ti ń ṣiṣẹ́ má bàa gbaṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè máà jẹ́ kó ráyè lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, kò ní jẹ́ kó lè lọ sóde ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ náà ni ò sì ní ráyè bójú tó àìní ìdílé rẹ̀ ní ti ìmí ẹ̀dùn àti nípa tẹ̀mí. Síbẹ̀ ó múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe kíṣẹ́ yẹn má bàa bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Ó yẹ kí Kristẹni tó bá wà nírú ipò líle koko báyẹn ṣàníyàn ní tòótọ́. Kò rọrùn láti ríṣẹ́ mọ́ lóde òní. Kì í ṣe pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára wa fẹ́ di olówó rẹpẹtẹ o, àmọ́ bíi ti opó Sáréfátì yẹn, àwa náà fẹ́ ní àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé. Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé Ọlọ́run sọ pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” A lè fi ìdánilójú sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?” (Hébérù 13:5, 6) Pọ́ọ̀lù ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú ìlérí yẹn, Jèhófà ò sì yéé tọ́jú rẹ̀. Ọlọ́run yóò ṣe bákan náà fún wa tí a ò bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

A lè ronú pé kò sọ́gbọ́n tá a fi lè ṣe tó ohun tí irú àwọn ẹni tẹ̀mí bíi Mósè, Gídíónì, àti Dáfídì ṣe, síbẹ̀ a lè fara wé ìgbàgbọ́ wọn. A sì tún lè rántí àwọn ohun kéékèèké tí ìgbàgbọ́ sún Ébẹ́lì, Énọ́kù, àti opó Sáréfátì ṣe. Inú Jèhófà dùn sí gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ bá sún wa ṣe—kódà àwọn ohun kéékèèké pàápàá. Nígbà tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó bẹ̀rù Ọlọ́run bá kọ̀ láti gba oògùn olóró lọ́wọ́ àwọn ojúgbà rẹ̀, nígbà tí Kristẹni kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ bá kọ ìṣekúṣe táwọn èèyàn fi ń lọ̀ ọ́ níbi iṣẹ́, nígbà tí àgbàlagbà kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí bá ń wá sáwọn ìpàdé ìjọ déédéé láìfi àárẹ̀ àti àìlera pè, Jèhófà rí i. Ó sì ń múnú rẹ̀ dùn!—Òwe 27:11.

Ǹjẹ́ O Máa Ń Kíyè sí Ohun Táwọn Ẹlòmíràn Ń Ṣe?

Ó dájú pé Jèhófà ń kíyè sí ohun tá à ń ṣe. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí aláfarawé Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti kíyè sí ìsapá àwọn ẹlòmíràn. (Éfésù 5:1) O ò ṣe wo àwọn ìṣòro táwọn Kristẹni bíi tìrẹ ń dojú kọ kí wọ́n tó lè wá sáwọn ìpàdé ìjọ, kí wọ́n tó lè lọ sóde ẹ̀rí, kódà kí wọ́n tó lè máa bá ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́ lọ pàápàá?

Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ olùjọsìn Jèhófà mọ̀ pé o mọrírì ìsapá wọn. Inú wọn yóò dùn pé o kíyè sí i, àníyàn rẹ yẹn sì lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà ń kíyè sí i pẹ̀lú.