Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àkọsílẹ̀ Kan Tó Wúni Lórí Gan-an

Àkọsílẹ̀ Kan Tó Wúni Lórí Gan-an

Àkọsílẹ̀ Kan Tó Wúni Lórí Gan-an

RICHARD E. Byrd, tó jẹ́ olùṣèwádìí rin ìrìn àjò ẹ̀ẹ̀marùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láàárín ọdún 1928 sí 1956 láti ṣe àwọn ìwádìí kan. Àwọn àkọsílẹ̀ ara ẹni tó ṣe àtàwọn àkọsílẹ̀ pípé pérépéré tó kọ nípa ọkọ̀ òfuurufú tó lò, ló mú kóun àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò náà mọ ọ̀nà tí ẹ̀fúùfù gbà ń fẹ́, òun ló mú kí wọ́n lè ya àwòrán ilẹ̀, kí wọ́n sì tún mọ púpọ̀ sí i nípa ilẹ̀ Antarctic.

Àwọn ìrìn àjò tí Byrd rìn jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti máa pa àkọsílẹ̀ mọ́. Ohun tó máa ń wà nínú ìwé àkọsílẹ̀ yìí ni àwọn ìsọfúnni nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ ìrìn àjò lójú omi tàbí ti ojú òfuurufú. Èèyàn lè lo àwọn ìsọfúnni náà tó bá yá láti ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó wáyé nígbà ìrìn àjò tó rìn náà tàbí kó tibẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìsọfúnni tó máa wúlò fún un nígbà tó bá fẹ́ rìnrìn àjò mìíràn lọ́jọ́ iwájú.

Ìwé Mímọ́ ní àkọsílẹ̀ tó pé pérépéré nípa Ìkún Omi tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà. Ìkún Omi náà gba ohun tó lé ní odindi ọdún kan gbáko. Ní ìmúrasílẹ̀ fún Àkúnya Omi náà, nǹkan bí àádọ́ta tàbí ọgọ́ta ọdún ni Nóà, ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọ wọn ọkùnrin mẹ́ta àtàwọn aya wọn fi kan ọkọ Áàkì—ìyẹn ọkọ̀ ojú omi gìrìwò kan tí fífẹ̀ rẹ̀ tó ọ̀kẹ́ méjì [40,000] mítà níbùú àti lóòró. Kí ló mú wọn kan ọkọ̀ náà? Kí àwọn èèyàn díẹ̀ àtàwọn ẹranko bàa la Ìkún Omi náà já ni.—Jẹ́nẹ́sísì 7:1-3.

Lẹ́nu kan, ìwé Jẹ́nẹ́sísì inú Bíbélì ní àkọsílẹ̀ kan tá a lè pè ní àkọsílẹ̀ nípa ọjọ́ Nóà tó dá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ látìgbà tí Ìkún Omi náà ti bẹ̀rẹ̀ títí dìgbà tóun àti ìdílé rẹ̀ jáde nínú ọkọ̀ náà. Ǹjẹ́ ohun kan tiẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀ náà tó ṣe pàtàkì fún wa lónìí?