Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ló fà á tí Ilé Ìṣọ́ April 1, 2002, fi sọ ní ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 7, pé ṣíṣe táwọn Júù tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ ṣe ìrìbọmi ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa, jẹ́ àmì tó fi hàn pé “àwọn tí ya ara àwọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi,” nígbà tó sì jẹ́ pé òye tá a ti ní tẹ́lẹ̀ ni pé ìrìbọmi táwọn Júù ṣe láti ọdún 33 Sànmánì Tiwa títí di ọdún 36 Sànmánì Tiwa kò nílò irú ìyàsímímọ́ bẹ́ẹ̀?

Lọ́dún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní láti di orílẹ̀-èdè mímọ́ fún òun kìkì bí wọ́n ‘bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn rẹ̀, tí wọ́n sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.’ Wọ́n dáhùn pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.”—Ẹ́kísódù 19:3-8; 24:1-8.

Gbígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà láti pa májẹ̀mú Òfin Mósè mọ́ yìí túmọ̀ sí pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Inú orílẹ̀-èdè tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ yìí la sì bí àwọn ìrandíran àwọn Júù sí. Àmọ́ ṣá o, ohun tó wé mọ́ ìrìbọmi táwọn Júù tí wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe láti Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa lọ kọjá wíwulẹ̀ sọ fún Ọlọ́run pé àwọn jẹ́ ara orílẹ̀-èdè tá a ti yà sí mímọ́. Ó jẹ́ àmì pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run nínú àjọṣe tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ní pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

Lẹ́yìn tá a tú ẹ̀mí mímọ́ sórí nǹkan bí ọgọ́fà ọmọ ẹ̀yìn ní yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pétérù dìde dúró ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fún ogunlọ́gọ̀ àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n ti pé jọ láti rí ohun tó ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn tó ti wàásù dáadáa, ó wá sọ fáwọn Júù tí ẹ̀rí ọkàn ti ń dà láàmú pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.” Inú wọn dùn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pétérù tún sọ fún wọn débi pé, “àwọn tí wọ́n fi tọkàntọkàn gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a batisí, ní ọjọ́ yẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkàn ni a sì fi kún wọn.”—Ìṣe 2:1-41.

Ṣé ara orílẹ̀-èdè tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ làwọn Júù tó ṣèrìbọmi lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pétérù sọ fún wọn? Ṣé a ti yà wọ́n sọ́tọ̀ pátápátá fún Ọlọ́run ni? Rárá o. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ‘Ọlọ́run ti mú Òfin náà kúrò lójú ọ̀nà nípa kíkàn án níṣòó mọ́ òpó igi oró.’ (Kólósè 2:14) Nípasẹ̀ ikú Kristi lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa, Jèhófà Ọlọ́run mú májẹ̀mú Òfin náà kúrò—èyí tó jẹ́ olórí ìdí tó fi mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọnú àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. Orílẹ̀-èdè tó kọ Ọmọ Ọlọ́run sílẹ̀ wá di èyí tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀. ‘Èyí tó jẹ́ Ísírẹ́lì nípa ti ara’ kò wá lè sọ pé òun ni orílẹ̀-èdè tá a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run mọ́.—1 Kọ́ríńtì 10:18; Mátíù 21:43.

Ọdún 33 Sànmánì Tiwa la fòpin sí májẹ̀mú Òfin náà, àmọ́ àkókò tí Ọlọ́run là kalẹ̀ láti ṣàánú àwọn Júù lọ́nà àkànṣe àti láti gbọ́ tiwọn kò dópin lákòókò náà. a Àkókò náà sì ní láti máa báa lọ títí di ọdún 36 Sànmánì Tiwa, nígbà tí Pétérù wàásù fún Kọ̀nílíù ará Ítálì nì tó bẹ̀rù Ọlọ́run, àti gbogbo ìdílé rẹ̀ àtàwọn Kèfèrí mìíràn. (Ìṣe 10:1-48) Kí ló fà á tí àkókò fún ojú rere náà fi gùn tó bẹ́ẹ̀?

Dáníẹ́lì 9:27, sọ pé: “[Mèsáyà náà] yóò sì mú májẹ̀mú máa ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan.” Májẹ̀mú Ábúráhámù ni májẹ̀mú tó wà lẹ́nu iṣẹ́ fún odindi ọdún méje, tàbí “ọ̀sẹ̀ kan,” ìyẹn látìgbà tí Jésù ti ṣèrìbọmi àti nígbà tí Mèsáyà náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ fún gbogbo èèyàn lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa. Kéèyàn tó lè wọnú májẹ̀mú náà, ó ní láti wà lára àwọn Hébérù tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. Àmọ́ májẹ̀mú àdáṣe yìí kò mú kéèyàn di ẹni tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà. Ìdí rèé táwọn Júù onígbàgbọ́ tí wọ́n ṣèrìbọmi lẹ́yìn ìwàásù Pétérù lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa, kò fi lè sọ pé a ti ya àwọn sọ́tọ̀ pátápátá fún Ọlọ́run nígbà tá a ti mú májẹ̀mú Òfin náà kúrò bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run bójú tó wọn lọ́nà àkànṣe gẹ́gẹ́ bíi Júù àbínibí. Wọ́n gbọ́dọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run.

Ìdí mìíràn tún wà táwọn Júù àtàwọn Aláwọ̀ṣe tí wọ́n ṣèrìbọmi ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, fi gbọ́dọ̀ ṣe ìyàsímímọ́. Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n ronú pìwà dà kí wọ́n sì ṣèrìbọmi lórúkọ Jésù. Ṣíṣe èyí béèrè pé kí wọ́n kọ ọ̀nà ti ayé sílẹ̀ kí wọ́n sì gbà pé Jésù ni Olúwa àti Mèsáyà, kí wọ́n gbà á gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà, pé òun lẹni náà tó jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run lókè ọ̀run. Wọ́n gbọ́dọ̀ pe orúkọ Jèhófà Ọlọ́run láti rí ìgbàlà nípasẹ̀ Jésù Kristi, èyí tó wé mọ́ lílo ìgbàgbọ́ nínú Kristi kí wọ́n sì gbà pé òun ni Aṣáájú wọn. Ohun tó jẹ́ olórí ìdí tí wọ́n fi ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà ti wá yí padà báyìí. Àwọn Júù yìí tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ fara mọ́ ìṣètò tuntun yìí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Lọ́nà wo? Nípa yíya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run kí wọ́n sì fi hàn ní gbangba pé àwọn ti ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣe ìrìbọmi lórúkọ Jésù Kristi. Ìrìbọmi jẹ́ àmì ìyàsímímọ́ wọn fún Ọlọ́run, èyí tó mú wọn wọnú àjọṣe tuntun pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi.—Ìṣe 2:21, 33-36; 3:19-23.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìgbà tí Jésù Kristi lọ sọ́run tó gbé ìtóye ẹbọ tó fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn ṣe fún Jèhófà Ọlọ́run la fagi lé Òfin Mósè, èyí sì wá mú kí “májẹ̀mú tuntun” tá a sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fìdí múlẹ̀.—Jeremáyà 31:31-34.