Ẹ Dúró Ṣinṣin Kẹ́ Ẹ sì Gba Ẹ̀bùn Eré Ìje Ìyè
Ẹ Dúró Ṣinṣin Kẹ́ Ẹ sì Gba Ẹ̀bùn Eré Ìje Ìyè
KÁ LÓ o fẹ́ rin ìrìn àjò kọjá lójú òkun tí ìjì ti ń jà burúkú burúkú, irú ọkọ̀ òkun wo lo máa fẹ́ fi rin ìrìn àjò náà? Ṣé ọkọ̀ òbèlè kékeré kan ni wà á fẹ́ àbí ọkọ̀ òkun ńlá tó lágbára? Ó dájú pé ọkọ̀ òkun ńlá tó lágbára lo máa fẹ́ lò nítorí pé á lè la ìgbì òkun lílágbára náà kọjá.
Bá a ṣe ń kọjá láàárín ìjì líle ti ètò búburú yìí, à ń kojú àwọn ìṣòro tó ń mú ká máa ronú pé a ò láàbò. Àpẹẹrẹ kan ni tàwọn èwe, gbogbo nǹkan lè tojú sú wọn nígbà míì kó sì máa ṣe wọ́n bí ẹni pé wọn ò láàbò nínú ayé táwọn èrò àtàwọn àṣà inú rẹ̀ ń dani lọ́kàn rú yìí. Ọkàn àwọn mìíràn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kámi-kàmì-kámi. Kódà àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin tí wọ́n ti ń fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún lè máà rí àwọn ohun tí wọ́n rò pé ó ti yẹ kó ṣẹlẹ̀, èyí sì lè di àdánwò fún wọn.
Àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í ṣe nǹkan tuntun. Àwọn ìgbà míì wà tí ọkàn àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà bíi Mósè, Jóòbù àti Dáfídì pòrúurùu. (Númérì 11:14, 15; Jóòbù 3:1-4; Sáàmù 55:4) Síbẹ̀, wọ́n gbé ìgbésí ayé wọn pẹ̀lú ìdúróṣinṣin sí Jèhófà. Àpẹẹrẹ rere wọn ń fún àwa náà níṣìírí láti dúró ṣinṣin bíi tiwọn, àmọ́ Sátánì Èṣù fẹ́ mú wa yẹsẹ̀ nínú eré ìje ìyè àìnípẹ̀kun. (Lúùkù 22:31) Nígbà náà, báwo la ṣe lè dúró ṣinṣin, ká “dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́”? (1 Pétérù 5:9) Báwo la sì ṣe lè fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lókun?
Jèhófà Fẹ́ Ká Dúró Ṣinṣin
Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, gbogbo ìgbà láá máa ràn wá lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin. Dáfídì onísáàmù náà dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro, àmọ́ ó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run èyí ló sì mú kó kọrin pé: “[Jèhófà] sì tẹ̀ síwájú láti mú mi gòkè pẹ̀lú láti inú kòtò tí ń ké ramúramù, láti inú ẹrẹ̀ pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀. Nígbà náà ni ó gbé ẹsẹ̀ mi sókè sórí àpáta gàǹgà; ó fi àwọn ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”—Sáàmù 40:2.
Jèhófà ń fún wa lókun láti ja “ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́” ká bàa lè “di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí.” (1 Tímótì 6:12) Ó tún ń pèsè ọ̀nà tá a máa gbà dúró gbọn-in fún wa ká bàa lè borí nínú ogun tẹ̀mí táà ń jà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ pé kí wọ́n “máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀” kí wọ́n sì ‘gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí wọ́n bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.’ (Éfésù 6:10-17) Àmọ́ kí làwọn ohun náà tó lè jin ìdúróṣinṣin wa lẹ́sẹ̀? Báwo la sì ṣe lè dènà àwọn ohun búburú bẹ́ẹ̀?
Ṣọ́ra Fáwọn Ohun Tó Lè Jin Ìdúróṣinṣin Rẹ Lẹ́sẹ̀
Ó yẹ ká máa rántí kókó pàtàkì náà pé: Bópẹ́bóyá, àwọn ìpinnu tá a bá ṣe á nípa lórí bá a ṣe
dúró dáadáa sí gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni yálà sí rere tàbí ìdàkejì rẹ̀. Ó di dandan káwọn èwe ṣe ìpinnu lórí àwọn ọ̀ràn bí iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe, àfikún ẹ̀kọ́ àti ìgbéyàwó. Àwọn àgbààgbà náà á pinnu bóyá káwọn ṣí lọ síbòmíràn tàbí kí wọ́n fi kún iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Ojoojúmọ́ là ń ṣèpinnu tó kan bá a ṣe ń lo àkókò wa àtàwọn ọ̀ràn mìíràn. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ tó máa mú ká túbọ̀ dúró déédéé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run? Ẹnì kan tó ti jẹ́ Kristẹni látọjọ́ pípẹ́ sọ pé: “Mo máa ń sọ fún Jèhófà kó ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo bá ń ṣèpinnu. Mo gbà pé ó ṣe kókó láti gba àwọn ìmọ̀ràn téèyàn ń rí nínú Bíbélì, láwọn ìpàdé Kristẹni, látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì, kéèyàn sì máa fi wọ́n sílò.”Tá a bá ń ṣe ìpinnu, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé inú mi á ṣì máa dùn sáwọn ìpinnu tí mò ń ṣe lónìí yìí ni ọdún márùn-ún tàbí mẹ́wàá sákòókò yìí, àbí ńṣe ni màá máa ki ìka àbámọ̀ bọnu? Ǹjẹ́ mò ń sapá láti rí i dájú pé àwọn ìpinnu tí mo ṣe ò ní kó mi sí yọ́ọ́yọ́ọ́ nípa tẹ̀mí àmọ́ pé ńṣe ló máa mú kí n túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí?’—Fílípì 3:16.
Ìgbésí ayé àwọn kan tí wọ́n ti ṣèrìbọmi kò dúró déédéé mọ́ nítorí pé wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn fún ìdẹwò tó fi ráyè borí wọn tàbí kẹ̀ kí wọ́n sún mọ́ bèbè ríré òfin Ọlọ́run kọjá. Àwọn díẹ̀ kan tá a yọ lẹ́gbẹ́ nítorí pé wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ láìronúpìwàdà ti sapá gan-an débi tá a fi gbà wọ́n padà. Àmọ́ kò pẹ́ tá a fi tún yọ wọ́n lẹ́gbẹ́ nítorí irú àṣemáṣe kan náà tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé àwọn èèyàn wọ̀nyí ò gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran àwọn lọ́wọ́ láti ‘kórìíra ohun burúkú tẹ̀gàntẹ̀gàn kí wọ́n sì rọ̀ mọ́ ohun rere’? (Róòmù 12:9; Sáàmù 97:10) Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ “máa bá a lọ ní ṣíṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ [wa].” (Hébérù 12:13) Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò àwọn kókó bíi mélòó kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin nípa tẹ̀mí.
Ẹ Dúró Ṣinṣin Nípasẹ̀ Ìgbòkègbodò Kristẹni
Ọ̀nà kan láti dúró ṣinṣin nínú eré ìje ìyè náà ni pé ká máa ní púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. Dájúdájú, iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni tá à ń ṣe jẹ́ ohun èèlò tó wúlò láti mú kí ọkàn àti èrò inú wa dá lórí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kó sì máa wọ̀nà fún ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. Èyí ló mú kí Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 15:58) ‘Fífẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin’ túmọ̀ sí pé kéèyàn ‘dúró digbí síbì kan.’ Kéèyàn di “aláìṣeéṣínípò” lè túmọ̀ sí pé ‘kéèyàn máà jẹ́ kí ohunkóhun yẹ òun lẹ́sẹ̀.’ Nítorí náà, jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lè mú ká dúró digbí sí ipa ọ̀nà Kristẹni tá à ń tọ̀. Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀ ó sì ń fún wa láyọ̀.—Ìṣe 20:35.
Kristẹni kan tó ń jẹ́ Pauline, tó ti ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì àti onírúurú iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún mìíràn fún ohun tó lé ní ọgbọ̀n ọdún, sọ pé: “Ààbò ni iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ fún mi nítorí pé bí mo ṣe ń wàásù fáwọn ẹlòmíràn ń jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé inú òtítọ́ náà ni mo wà.” Kíkópa déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni mìíràn tún ń jẹ́ kéèyàn ní irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀, bíi lílọ sípàdé àti dídákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Kárí Ayé Ń Mú Ká Dúró Ṣinṣin
Jíjẹ́ ara ètò àjọ àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ kárí ayé lè mú ká dúró ṣinṣin. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ló jẹ́ láti wà lára ẹgbẹ́ àwọn ará onífẹ̀ẹ́ kárí ayé! (1 Pétérù 2:17) A sì tún lè mú káwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa náà fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.
Ronú nípa àwọn ìgbésẹ̀ tó lè ranni lọ́wọ́ tí Jóòbù, ọkùnrin adúróṣinṣin náà gbé. Kódà Élífásì gan-an tó jẹ́ olùtùnú èké sọ pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ ń gbé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọsẹ̀ dìde; àwọn eékún tí ń yẹ̀ lọ ni ìwọ sì ń mú le gírígírí.” (Jóòbù 4:4) Ǹjẹ́ àwa náà ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ lọ́nà yìí? Ẹrù iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nípa tẹ̀mí lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bá a lọ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Nígbà tá a bá wà láàárín wọn, a lè hùwà níbàámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Ẹ fún àwọn ọwọ́ tí kò lera lókun, ẹ sì mú àwọn eékún tí ń gbò yèpéyèpé le gírígírí.” (Aísáyà 35:3) Nítorí náà, o ò ṣe kúkú fi ṣe góńgó rẹ láti máa fún ẹnì kan tàbí méjì tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni lókun kó o sì fún wọn níṣìírí nígbàkigbà tó o bá wà pẹ̀lú wọn? (Hébérù 10:24, 25) Àwọn ọ̀rọ̀ ìmọrírì àtàwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí tá a fún wọn nítorí bíbá a tí wọ́n ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an láti dúró gbọn-in kí wọ́n sì lè gba ẹ̀bùn eré ìje ìyè.
Àwọn Kristẹni alàgbà lè ṣe bẹbẹ nípa fífún àwọn ẹni tuntun níṣìírí. Wọ́n lè ṣe èyí nípa fífún wọn láwọn àbá àtàwọn ìmọ̀ràn tá a gbé karí Ìwé Mímọ́ àti nípa bíbá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Gbogbo àǹfààní tó bá yọjú ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń lò láti fún àwọn ẹlòmíràn lókun. Aáyun àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù ń yun ún nítorí kó bàa lè fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. (Róòmù 1:11) Ó pe àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ̀ tó wà ní Fílípì ní “ìdùnnú àti adé” òun, ó sì gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n “dúró gbọn-in gbọn-in ní ọ̀nà yìí nínú Olúwa.” (Fílípì 4:1) Gbàrà tí Pọ́ọ̀lù gbọ́ pé òde ò dẹrùn fáwọn ará ní Tẹsalóníkà ló ti rán Tímótì lọ bá wọn láti ‘fìdí wọn múlẹ̀ gbọn-in àti láti tù wọ́n nínú nítorí ìgbàgbọ́ wọn, kí ìpọ́njú má bàa mú ẹnì kankan yẹsẹ̀.’—1 Tẹsalóníkà 3:1-3.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Pétérù mọrírì ìsapá táwọn olùjọsìn bíi tiwọn ń fi tinútinú ṣe, wọ́n sì kan sáárá sí wọn. (Kólósè 2:5; 1 Tẹsalóníkà 3:7, 8; 2 Pétérù 1:12) Ǹjẹ́ kí àwa náà ṣe bẹ́ẹ̀, ká má ṣe máa wo kùdìẹ̀ kudiẹ àwọn arákùnrin wa àmọ́ ká máa wo àwọn ànímọ́ dáadáa wọn àti àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe láti dúró ṣinṣin àti láti bọlá fún Jèhófà.
Tó bá jẹ́ kùdìẹ̀ kudiẹ wọn là ń wò tàbí tá à ń ni wọ́n lára, a lè má mọ̀ pé ńṣe là ń jẹ́ kó ṣòro fáwọn kan láti dúró láìyẹsẹ̀ nínú ìgbàgbọ́. Ohun tó yẹ ká máa rántí nípa àwọn arákùnrin wa ni pé “a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká” nínú ètò àwọn nǹkan yìí! (Mátíù 9:36) Ó yẹ ká lè tù wọ́n nínú ká sì tún tù wọ́n lára nínú ìjọ Kristẹni. Nítorí náà, ǹjẹ́ kí gbogbo wa sa gbogbo ipá wa láti gbé àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ró ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin.
Àwọn kan lè hu àwọn ìwà kan sí wa nígbà míì kó sì jẹ́ èyí tó lè pa ìdúróṣinṣin wa lára. Ǹjẹ́ àá wá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tàbí ìwà ìkà mú ká bẹ̀rẹ̀ sí dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà? Ká má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣèpalára fún ìdúróṣinṣin wa láé!—2 Pétérù 3:17.
Àwọn Ìlérí Ọlọ́run Ń Mú Ká Dúró Ṣinṣin
Ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la tó gbámúṣé lábẹ́ àkóso Ìjọba náà ń fún wa ní ìrètí tó ń mú ká dúró ṣinṣin. (Hébérù 6:19) Bákan náà ni dídá tó dá wa lójú pé awí-bẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run tó bá kan ọ̀ràn àwọn ìlérí rẹ̀ ń mú ká ‘wà lójúfò ká sì dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.’ (1 Kọ́ríńtì 16:13; Hébérù 3:6) Bó ṣe dà bí ẹni pé ìmúṣẹ díẹ̀ lára àwọn ìlérí Ọlọ́run ń falẹ̀ lè dán ìgbàgbọ́ wa wò. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká wà lójúfò kí wọ́n má bàa fi ẹ̀kọ́ èké tàn wá jẹ ká sì wá sọ ìrètí wa nù.—Kólósè 1:23; Hébérù 13:9.
Ó yẹ ká fi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ṣègbé nítorí pé wọn ò nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà ṣàríkọ́gbọ́n. (Sáàmù 78:37) Dípò ká sọra wa dà bíi tiwọn, ẹ jẹ́ ká dúró ṣinṣin, ká máa fi ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú jọ́sìn Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Alàgbà kan tó ti pẹ́ nínú ètò sọ pé: “Ńṣe ni mò ń gbé ìgbésí ayé mi ojoojúmọ́ bí ẹni pé ọjọ́ ńlá Jèhófà á dé lọ́lá òde yìí.”—Jóẹ́lì 1:15.
Dájúdájú, ọjọ́ ńlá Jèhófà ti dé tán. Àmọ́ ṣá ìbẹ̀rù kankan ò sí fún wa tá a bá ṣáà ti sún mọ́ Ọlọ́run. Ta a bá rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ tá a sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, a lè ṣe àṣeyọrí nínú eré ìje ìyè àìnípẹ̀kun náà!—Òwe 11:19; 1 Tímótì 6:12, 17-19.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ǹjẹ́ o ń sa gbogbo ipá rẹ láti ran àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]
The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck