Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kristi Bá Àwọn Ìjọ Sọ̀rọ̀

Kristi Bá Àwọn Ìjọ Sọ̀rọ̀

Kristi Bá Àwọn Ìjọ Sọ̀rọ̀

“Ìwọ̀nyí ni ohun tí ẹni tí ó di ìràwọ̀ méje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ wí.”—ÌṢÍPAYÁ 2:1.

1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí Kristi sọ fáwọn ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré?

 JÉSÙ KRISTI, ọmọ kan ṣoṣo tí Jèhófà bí ni Orí ìjọ Kristẹni. Kí ìjọ àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè wà ní àìlábààwọ́n ni Kristi ṣe lo ipò orí rẹ̀ láti gbóríyìn fún wọn àti láti bá wọn wí. (Éfésù 5:21-27) Àwọn àpẹẹrẹ èyí wà nínú Ìṣípayá orí kejì àti ìkẹta, níbi tá a ti rí àwọn iṣẹ́ lílágbára tó sì jẹ́ ti onífẹ̀ẹ́ tí Jésù rán sáwọn ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré.

2 A ti kọ́kọ́ fi ìran “ọjọ́ Olúwa” han àpọ́sítélì Jòhánù kó tó di pé ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn ìjọ méjèèje náà. (Ìṣípayá 1:10) Ìgbà tá a fìdí ìjọba Mèsáyà múlẹ̀ lókè ọ̀run ní 1914 ni “ọjọ́” náà bẹ̀rẹ̀. Ohun tí Kristi sọ fáwọn ìjọ náà sì ṣe pàtàkì gan-an láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí àti ìmọ̀ràn rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn àkókò líle koko wọ̀nyí.—2 Tímótì 3:1-5.

3. Kí ni ohun tí “ìràwọ̀,” “àwọn áńgẹ́lì,” àti “ọ̀pá fìtílà . . . oníwúrà” tí àpọ́sítélì Jòhánù rí túmọ̀ sí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ?

3 Jòhánù rí Jésù Kristi tá a ṣe lógo náà, ẹni “tí ó di ìràwọ̀ méje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀” tí ó sì “ń rìn ní àárín ọ̀pá fìtílà méje oníwúrà,” tàbí àwọn ìjọ. Àwọn “ìràwọ̀” yẹn ni “àwọn áńgẹ́lì ìjọ méje.” (Ìṣípayá 1:20; 2:1) Àwọn ìràwọ̀ máa ń dúró fún àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí nígbà mìíràn, àmọ́ Kristi ò jẹ́ lo ènìyàn láti ṣàkọsílẹ̀ iṣẹ́ tó wà fún àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Nítorí náà, àwọn “ìràwọ̀” náà túmọ̀ sí àwọn alábòójútó tá a fẹ̀mí yàn, tàbí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà. Ọ̀rọ̀ náà “àwọn áńgẹ́lì” ní í ṣe pẹ̀lú ẹrù iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́. Nítorí bí ètò àjọ Ọlọ́run ṣe ń gbòòrò sí i, àwọn “olùṣòtítọ́ ìríjú” ti yan àwọn ọkùnrin tó tóótun lára “àwọn àgùntàn mìíràn” Jésù láti jẹ́ alábòójútó.—Lúùkù 12:42-44; Jòhánù 10:16.

4. Báwo làwọn alàgbà ṣe ń jàǹfààní látinú kíkọbiara sí ohun tí Kristi sọ fáwọn ìjọ?

4 Àwọn “ìràwọ̀” náà wà ní ọwọ́ ọ̀tún Jésù—ìyẹn ni pé ó lágbára lórí wọn, ó ń darí wọn, wọ́n ń rí ojú rere rẹ̀, ó sì ń dáàbò bò wọ́n. Nítorí náà, wọ́n ní láti jíhìn fún un. Kíkọbiara sáwọn ọ̀rọ̀ tó sọ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìjọ méje náà yóò jẹ́ kí àwọn alàgbà òde òní mọ báwọn ṣe lè bójú tó àwọn ipò tó fara jọ tìgbà yẹn. Àmọ́, gbogbo Kristẹni ló yẹ kó fetí sílẹ̀ sí Ọmọ Ọlọ́run. (Máàkù 9:7) Nítorí náà, ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ nípa títẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ tí Kristi sọ fún àwọn ìjọ?

Sí Áńgẹ́lì Ìjọ ní Éfésù

5. Irú ìlú wo ni Éfésù?

5 Jésù gbóríyìn fún ìjọ tó wà ní Éfésù, ó sì tún bá wọn wí pẹ̀lú. (Ka Ìṣípayá 2:1-7) Ìlú tí okòwò ti búrẹ́kẹ tí ìsìn sì ti jẹ wọ́n lógún ní etíkun ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré yìí ni wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì gàgàrà kan sí fún Átẹ́mísì, abo-ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà pálapàla, ìsìn èké, àti iṣẹ́ òkùnkùn ló gbòde kan ní Éfésù, síbẹ̀ Ọlọ́run bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti ti àwọn ẹlòmíràn ní ìlú ńlá yẹn.—Ìṣe, orí 19.

6. Báwo làwọn Kristẹni adúróṣinṣin lóde òní ṣe dà bí àwọn tó wà ní Éfésù ìgbàanì?

6 Kristi gbóríyìn fún ìjọ tó wà ní Éfésù, nípa sísọ pé: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, àti òpò àti ìfaradà rẹ, àti pé ìwọ kò lè gba àwọn ènìyàn búburú mọ́ra, àti pé ìwọ ti dán àwọn tí wọ́n sọ pé àpọ́sítélì ni àwọn wò, ṣùgbọ́n tí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀, o sì rí wọn ní òpùrọ́.” Bákan náà làwọn ìjọ tó jẹ́ ti àwọn ọmọlẹ́yìn tòótọ́ fún Jésù ṣe ní àkọsílẹ̀ iṣẹ́ rere, iṣẹ́ àṣekára, àti ìfaradà lóde òní. Wọn ò gba àwọn èké arákùnrin tó fẹ́ káwọn èèyàn máa wò wọ́n bí àpọ́sítélì mọ́ra. (2 Kọ́ríńtì 11:13, 26) Bíi táwọn ará Éfésù, àwọn Kristẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin lóde òní “kò lè gba àwọn ènìyàn búburú mọ́ra.” Kí ìjọsìn Jèhófà lè wà ní àìlábùlà kí wọ́n sì lè dáàbò bo ìjọ ni wọn kì í ṣe é bá àwọn apẹ̀yìndà tí kò ronú pìwà dà kẹ́gbẹ́.—Gálátíà 2:4, 5; 2 Jòhánù 8-11.

7, 8. Ìṣòro ńlá wo ló wà nínú ìjọ Éfésù, báwo làwa náà sì ṣe lè borí irú ipò bẹ́ẹ̀?

7 Síbẹ̀, àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù ní ìṣòro ńlá kan. Jésù sọ pé: “Mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.” Àwọn tó wà nínú ìjọ ní láti bu epo síná ìfẹ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ní fún Jèhófà. (Máàkù 12:28-30; Éfésù 2:4; 5:1, 2) Àwa náà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa pàdánù ìfẹ́ tá a kọ́kọ́ ní fún Ọlọ́run. (3 Jòhánù 3) Àmọ́, bí àwọn nǹkan bí ìfẹ́ fún ọrọ̀ àlùmọ́nì tàbí lílépa ìgbádùn bá lọ di ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn jù nínú ìgbésí ayé wa ńkọ́? (1 Tímótì 4:8; 6:9, 10) Nígbà náà, a ní láti gbàdúrà àtọkànwá pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà àti ìmọrírì fún gbogbo ohun tí òun àti Ọmọ rẹ̀ ti ṣe fún wa rọ́pò irú èrò ọkàn bẹ́ẹ̀.—1 Jòhánù 4:10, 16.

8 Kristi rọ àwọn ará Éfésù pé: “Rántí inú ohun tí o ti ṣubú, kí o sì ronú pìwà dà, kí o sì ṣe àwọn iṣẹ́ ti ìṣáájú.” Bí wọn ò bá ṣe bẹ́ẹ̀ ńkọ́? Jésù sọ pé: “Bí ìwọ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, ṣe ni èmi yóò gbé ọ̀pá fìtílà rẹ kúrò ní àyè rẹ̀.” Bí gbogbo àwọn àgùntàn bá lọ pàdánù ìfẹ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ní, a jẹ́ pé “ọ̀pá fìtílà,” tàbí ìjọ náà, kò ní sí mọ́ nìyẹn. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni onítara, ǹjẹ́ kí a máa ṣiṣẹ́ àṣekára láti jẹ́ kí ìjọ lè máa tàn yòò nípa tẹ̀mí.—Mátíù 5:14-16.

9. Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ẹ̀ya ìsìn?

9 Ó jẹ́ ìwúrí pé àwọn ará Éfésù kórìíra “iṣẹ́ ẹ̀ya ìsìn Níkóláọ́sì.” Yàtọ̀ sí ohun ti ìwé Ìṣípayá sọ, a ò mọ ohun pàtó kankan nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀kọ́, àti àṣà ẹ̀ya ẹ̀sìn yìí. Àmọ́ nítorí pé Jésù ka títẹ̀lé èèyàn léèwọ̀, a ní láti máa bá a lọ láti kórìíra ẹ̀ya ìsìn, báwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù ti ṣe.—Mátíù 23:10.

10. Kí ni àwọn tó ń pa ohun tí ẹ̀mí ń sọ mọ́ yóò gbádùn?

10 Kristi sọ pé: “Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.” Abẹ́ ìdarí ẹ̀mí Ọlọ́run ni Jésù ti ń sọ̀rọ̀ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 61:1; Lúùkù 4:16-21) Ìdí nìyẹn tá a fi gbọ́dọ̀ kọbi ara sí ohun tí Ọlọ́run wá ń tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ gbẹnu rẹ̀ sọ nísinsìnyí. Abẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ ni Jésù ti ṣèlérí pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò yọ̀ǹda fún láti jẹ nínú igi ìyè, èyí tí ń bẹ nínú párádísè Ọlọ́run.” Àìleèkú nínú “párádísè Ọlọ́run” ní ọ̀run, tàbí níbi ti Jèhófà fúnra rẹ̀ wà ni èyí túmọ̀ sí fáwọn ẹni àmì òróró tó pa ohun tí ẹ̀mí ń sọ mọ́. Àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tó fetí sí ohun tí ẹ̀mí ń sọ pẹ̀lú yóò gbádùn Párádísè orí ilẹ̀ ayé níbi tí wọ́n á ti mu omi látinú “odò omi ìyè kan” tí wọn ó sì rí ìmúláradá látinú “ewé àwọn igi” tó wà ní àyíká rẹ̀.—Ìṣípayá 7:9; 22:1, 2; Lúùkù 23:43.

11. Báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe fún wa láti fi kún ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà?

11 Àwọn ará Éfésù ti pàdánù ìfẹ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ní, àmọ́ bí irú ipò bẹ́ẹ̀ bá dìde nínú ìjọ kan lónìí ńkọ́? Ẹ jẹ́ kí àwa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan fi kún ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà nípa sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ tó ń gbà ṣe nǹkan. A lè fi ìmọrírì hàn fún ìfẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn ní pípèsè ìràpadà nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. (Jòhánù 3:16; Róòmù 5:8) Nígbà tó bá yẹ, a lè mẹ́nu kan ìfẹ́ Ọlọ́run nínú àwọn ìdáhùn wa àti nínú àwọn iṣẹ́ tá a bá ní láwọn ìpàdé. A lè fi ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà hàn nípa yíyin orúkọ rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. (Sáàmù 145:10-13) Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa lè ṣe púpọ̀ láti bu epo sí iná ìfẹ́ tí ìjọ kan kọ́kọ́ ní tàbí kó fún un lókun.

Sí Áńgẹ́lì ní Símínà

12. Kí ni ìtàn fi hàn nípa Símínà àti irú ìsìn tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀?

12 Oríyìn ni ìjọ tó wà ní Símínà gbà látọ̀dọ̀ Kristi, “‘Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn,’ ẹni tí ó di òkú tẹ́lẹ̀, tí ó sì tún wá sí ìyè” nípasẹ̀ àjíǹde. (Ka Ìṣípayá 2:8-11) Etíkun ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré ni Símínà (tó ti di Izmir, Turkey báyìí) wà. Àwọn Gíríìkì ló tẹ̀dó sí ìlú ńlá náà, àmọ́ àwọn ará Lydia pa ibẹ̀ run ní nǹkan bí ọdún 580 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àwọn tó gorí àlééfà lẹ́yìn Alẹkisáńdà Ńlá wá tún Símínà kọ́ sí àgbègbè tuntun. Ó di ara ìpínlẹ̀ Róòmù ti Éṣíà ó sì jẹ́ ibùdó okòwò ńlá táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó nítorí ilé mèremère tí wọ́n máa ń kọ́ fún ìlò gbogbo ará ìlú. Tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ fún Tìbéríù Késárì níbẹ̀ ló sọ ọ́ di ọ̀gangan ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn olú ọba. Àwọn olùjọsìn ní láti sun tùràrí kíún kí wọ́n sì sọ pé, “Késárì ni Olúwa.” Àwọn Kristẹni ò lè bá wọn lọ́wọ́ sí èyí nítorí pé lójú tiwọn, “Jésù ni Olúwa.” Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi fojú winá ìpọ́njú.—Róòmù 10:9.

13. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tálákà làwọn Kristẹni tó wà ní Símínà, ọ̀nà wo ni wọ́n gbà jẹ́ ọlọ́rọ̀?

13 Yàtọ̀ sí ìpọ́njú, àwọn Kristẹni tó wà ní Símínà tún fara da ipò òṣì, ìyẹn ni pé ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn fi àwọn nǹkan kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ọrọ̀ ajé dù wọ́n nítorí pé wọn ò bá wọn lọ́wọ́ nínú jíjọ́sìn olú ọba. Irú àdánwò bẹ́ẹ̀ ò yẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní sílẹ̀. (Ìṣípayá 13:16, 17) Bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ tálákà, síbẹ̀ àwọn Kristẹni tó wà ní Símínà lọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí, ohun tó sì ṣe pàtàkì jù lọ nìyẹn!—Òwe 10:22; 3 Jòhánù 2.

14, 15. Ìtùnú wo làwọn ẹni àmì òróró lè rí látinú Ìṣípayá 2:10?

14 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù tó wà ní Símínà ló jẹ́ ti “sínágọ́gù Sátánì” nítorí pé àwọn àṣà tí ò bá Ìwé Mímọ́ mu ni wọ́n ń tẹ̀ lé, wọ́n kọ Ọmọ Ọlọ́run sílẹ̀, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ òdì sáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí a fi ẹ̀mí bí. (Róòmù 2:28, 29) Àmọ́ àwọn ẹni àmì òróró lè rí ìtùnú gbà látinú ọ̀rọ̀ tí Kristi sọ tẹ̀ lé e! Ó ní: “Má fòyà àwọn ohun tí ìwọ máa tó jìyà rẹ̀. Wò ó! Èṣù yóò máa bá a nìṣó ní sísọ àwọn kan nínú yín sí ẹ̀wọ̀n kí a lè dán yín wò ní kíkún, kí ẹ sì lè ní ìpọ́njú fún ọjọ́ mẹ́wàá. Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè.”—Ìṣípayá 2:10.

15 Jésù ò bẹ̀rù àtikú nítorí gbígbé ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lárugẹ. (Fílípì 2:5-8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì wá ń gbógun ti ìyókù àwọn ẹni àmì òróró báyìí, síbẹ̀ wọn ò bẹ̀rù ohun tí wọ́n ní láti jìyà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan—ìyẹn ni ìpọ́njú, ìfinisẹ́wọ̀n, tàbí ikú oró pàápàá. (Ìṣípayá 12:17) Wọn óò di aṣẹ́gun ayé. Àti pé dípò òbìrìkìtì ìtànná òdòdó tó ń gbẹ dà nù, èyí tí wọ́n máa ń fún àwọn tó bá ṣẹ́gun nínú àwọn eré àṣedárayá àwọn kèfèrí, ìlérí gbígba “adé ìyè” gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìleèkú ni ọ̀run ni Kristi ṣe fáwọn ẹni àmì òróró tá a jí dìde. Ẹ ò rí i pé ẹ̀bùn tí kò ṣeé díye lé lèyí!

16. Kókó wo ló yẹ kó máa gba àfiyèsí wa tó bá jẹ́ pé irú ìjọ tó wà ní Símínà yẹn là ń dara pọ̀ mọ́?

16 Yálà ìrètí wa jẹ́ ti ọ̀run tàbí ti ayé, tó bá jẹ́ pé irú ìjọ bíi ti Símínà ìgbàanì la wà ńkọ́? Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ran àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ ìdí pàtàkì tí Ọlọ́run fi fàyè gba inúnibíni—ìyẹn jẹ́ nítorí ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ ọ̀run òun ayé. Gbogbo àwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ló ń fẹ̀rí hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, wọ́n sì tún ń fi hàn pé kódà àwọn èèyàn tó ń fojú winá inúnibíni pàápàá lè jẹ́ alágbàwí tó dúró gbọn-in ti ẹ̀tọ́ Ọlọ́run láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Ọ̀run òun Ayé. (Òwe 27:11) Ẹ jẹ́ ká fún àwọn Kristẹni mìíràn níṣìírí láti fara da inúnibíni, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ máa bá a lọ láti ní “àǹfààní ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Jèhófà] láìbẹ̀rù pẹ̀lú ìdúróṣinṣin àti òdodo níwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ wa”—kódà títí láé.—Lúùkù 1:68, 69, 74, 75.

Sí Áńgẹ́lì ní Págámù

17, 18. Irú ìjọsìn wo ni Págámù jẹ́ ìkóríta fún, kí ló sì lè ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó bá kọ̀ láti kópa nínú irú ìbọ̀rìṣà yẹn?

17 Oríyìn àti ìbáwí ni ìjọ tó wà ní Págámù gbà ní tiẹ̀. (Ka Ìṣípayá 2:12-17) Ìlú Págámù wà ní nǹkan bí ọgọ́rin kìlómítà sí ìhà àríwá Símínà, ẹ̀sìn kèfèrí ló sì kúnnú rẹ̀ fọ́fọ́. Ó dà bíi pé láti Bábílónì ni àwọn awòràwọ̀ ará Kálídíà ti sá wá síbẹ̀. Ńṣe làwọn aláìsàn máa ń rọ́ lọ sí tẹ́ńpìlì lílókìkí ti Asclepius, ìyẹn ọlọ́run èké ti ìwòsàn àti ìṣègùn. Págámù, pẹ̀lú tẹ́ńpìlì rẹ̀ tí wọ́n yà sí mímọ́ fún Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì ni wọ́n pè ní “olórí ibùdó ẹgbẹ́ òkùnkùn tó jẹ́ ti olú ọba lábẹ́ ilẹ̀ ọba ìjímìjí.”—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica, 1959, Apá 17, ojú ìwé 507.

18 Pẹpẹ kan tí wọ́n yà sí mímọ́ fún Súúsì wà ní Págámù. Ìlú ńlá náà tún jẹ́ ibi tí Èṣù ti ń mú káwọn èèyàn máa jọ́sìn àwọn ẹ̀dá ènìyàn bíi tiwọn. Abájọ tí wọ́n fi sọ pé ìjọ tó wà níbẹ̀ ń gbé níbi tí “ìtẹ́ Sátánì” wà! Kíkọ̀ láti jọ́sìn olú ọba lè já sí ikú fún ẹnikẹ́ni tó bá fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Ayé ṣì wà lábẹ́ agbára Èṣù, àwọn èèyàn sì ti sọ àwọn àmì orílẹ̀-èdè dòrìṣà báyìí. (1 Jòhánù 5:19) Láti ọ̀rúndún kìíní títí di àkókò tá a wà yìí, ọ̀pọ̀ Kristẹni tòótọ́ ló ti kú ikú ajẹ́rìíkú, bíi ti “Áńtípà” tí Kristi pè ní “ẹlẹ́rìí mi, olùṣòtítọ́, ẹni tí a pa ní ẹ̀gbẹ́ yín.” Ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ò lè gbàgbé irú àwọn ìránṣẹ́ adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀.—1 Jòhánù 5:21.

19. Kí ni Báláámù ṣe, kí ló sì yẹ kí gbogbo Kristẹni ṣọ́ra fún?

19 Kristi tún sọ̀rọ̀ nípa “ẹ̀kọ́ Báláámù.” Tìtorí àtijèrè ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ni Báláámù, wòlíì èké nì, ṣe fẹ́ fi Ísírẹ́lì ré. Nígbà tí Ọlọ́run sọ èpè Báláámù di ìre, ló wá lọ bá Bálákì Ọba àwọn ọmọ Móábù lẹ̀dí àpò pọ̀ tó sì sún Ísírẹ́lì sínú ìbọ̀rìṣà àti ìwà pálapàla láàárín takọtabo. Àwọn Kristẹni alàgbà gbọ́dọ̀ dúró ṣinṣin ti òdodo bíi ti Fíníhásì tó gbé ìgbésẹ̀ tó lòdì sí iṣẹ́ ọwọ́ Báláámù. (Númérì 22:1–25:15; 2 Pétérù 2:15, 16; Júúdà 11) Láìsí àní-àní, gbogbo Kristẹni ló gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ìbọ̀rìṣà àti jíjẹ́ kí ìwà pálapàla láàárín takọtabo yọ́ wọnú ìjọ.—Júúdà 3, 4.

20. Bí Kristẹni kan bá bẹ̀rẹ̀ sí ní èrò apẹ̀yìndà lọ́kàn, kí ló yẹ kó ṣe?

20 Inú ewu ńlá ni ìjọ Págámù wà nítorí pé ó ti jẹ́ kí “àwọn tí ó di ẹ̀kọ́ ẹ̀ya ìsìn Níkóláọ́sì mú ṣinṣin” wà láàárín òun. Kristi sọ fún ìjọ náà pé: “Ronú pìwà dà. Bí ìwọ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, mo ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ ní kíákíá, ṣe ni èmi yóò fi idà gígùn ẹnu mi bá wọn jagun.” Àwọn oníyapa-ìsìn fẹ́ ṣe ìpalára tẹ̀mí fáwọn Kristẹni, àwọn tó sì máa ń fẹ́ dá ìyapa àti ẹ̀ya ìsìn sílẹ̀ kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run. (Róòmù 16:17, 18; 1 Kọ́ríńtì 1:10; Gálátíà 5:19-21) Bí Kristẹni kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò apẹ̀yìndà lọ́kàn tó sì fẹ́ tàn wọ́n kálẹ̀, ó gbọ́dọ̀ gba ìkìlọ̀ látọ̀dọ̀ Kristi! Tó bá fẹ́ yọ ara rẹ̀ nínú ewu, ó gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà, kó sì wá ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà nínú ìjọ. (Jákọ́bù 5:13-18) Ó ṣe pàtàkì láti gbé ìgbésẹ̀ ní kíá, nítorí pé Jésù ń bọ̀ kíákíá láti wá ṣèdájọ́.

21, 22. Àwọn wo ló ń jẹ lára “mánà tí a fi pa mọ́,” kí ló sì dúró fún?

21 Kó sídìí tó fi yẹ káwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn ẹlẹgbẹ́ wọn adúróṣinṣin máa bẹ̀rù ìdájọ́ tó ń bọ̀. Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tó bá kọbi ara sí ìmọ̀ràn tí Jésù fúnni nípasẹ̀ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹni àmì òróró tó ti ṣẹ́gun ayé la ó pè láti jẹ lára “mánà tí a fi pa mọ́” a ó sì fún wọn ní “òkúta róbótó funfun” tí a kọ “orúkọ tuntun” sí lára.

22 Ọlọ́run pèsè mánà láti gbé ẹ̀mí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ró fún odindi ogójì ọdún tí wọ́n fi rin nínú aginjù. Wọ́n fi díẹ̀ lára “oúnjẹ” yẹn sínú ìṣà wúrà tó wà nínú àpótí májẹ̀mú, wọ́n sì gbé e pa mọ́ sínú àgọ́ ìjọsìn tó wà ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ, níbi tí iná àgbàyanu kan wà, èyí tó dúró fún wíwà tí Jèhófà wà níbẹ̀. (Ẹ́kísódù 16:14, 15, 23, 26, 33; 26:34; Hébérù 9:3, 4) Kò sẹ́ni tá a fún láyè láti jẹ mánà tí a fi pa mọ́ yẹn. Àmọ́, nígbà àjíǹde àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù, wọ́n á gbé àìkú wọ̀, èyí tí jíjẹ “mánà tí a fi pa mọ́” dúró fún.—1 Kọ́ríńtì 15:53-57.

23. Kí ni ìjẹ́pàtàkì “òkúta róbótó funfun” àti “orúkọ tuntun” náà?

23 Òkúta róbótó dúdú máa ń dúró fún ìdálẹ́bi nínú ilé ẹjọ́ àwọn ará Róòmù, nígbà tó sì jẹ́ pé ìdásílẹ̀ ni òkúta róbótó funfun túmọ̀ sí. Fífún tí Jésù fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣẹ́gun ní “òkúta róbótó funfun” fi hàn pé ó ti kà wọ́n sí aláìlẹ́ṣẹ̀, aláìní àbààwọ́n, àti ẹni tó mọ́ tónítóní. Níwọ̀n bí àwọn ará Róòmù tún ti máa ń lo òkúta róbótó bíi tíkẹ́ẹ̀tì láti wọlé sí àwọn ibi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì, “òkúta róbótó” náà lè tọ́ka sí gbígbà tá a gba àwọn ẹni àmì òróró wọlé sí ibi kan ní ọ̀run níbi ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn. (Ìṣípayá 19:7-9) Ó hàn gbangba pé “orúkọ tuntun” náà dúró fún àǹfààní wíwà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Jésù gẹ́gẹ́ bí àjùmọ̀jogún nínú Ìjọba ọ̀run. Ẹ ò rí i pé ìṣírí ńlá lèyí jẹ́ fáwọn ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ìyẹn àwọn tó ní ìrètí gbígbé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé!

24. Irú ipò wo ló yẹ ká dì mú nígbà tó bá kan ọ̀rọ̀ ìpẹ̀yìndà?

24 Ó bọ́gbọ́n mu láti rántí pé àwọn apẹ̀yìndà ló wu ìjọ Págámù léwu. Bí irú ipò kan náà bá ń wu ipò tẹ̀mí ìjọ tá à ń dara pọ̀ mọ́ léwu, ẹ jẹ́ ká kọ ìpẹ̀yìndà sílẹ̀ pátápátá ká sì máa bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́. (Jòhánù 8:32, 44; 3 Jòhánù 4) Níwọ̀n bí àwọn olùkọ́ èké tàbí àwọn tó ń hùwà ìpẹ̀yìndà ti lè ba odindi ìjọ jẹ́, a gbọ́dọ̀ mú ìdúró wa gbọn-in lòdì sí ìpẹ̀yìndà, ká má ṣe jẹ́ kí ìyíniléròpadà burúkú dí wa lọ́wọ́ láé láti ṣègbọràn sí òtítọ́.—Gálátíà 5:7-12; 2 Jòhánù 8-11.

25. Àwọn iṣẹ́ tí Kristi rán sáwọn ìjọ wo la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

25 Ẹ ò rí àwọn ọ̀rọ̀ amúnironújinlẹ̀ tó jẹ́ ti oríyìn àti ìmọ̀ràn tí Jésù Kristi tá a ṣe lógo sọ fún àwọn ìjọ́ mẹ́ta tá a ti gbé yẹ̀ wò lára ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré! Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń darí rẹ̀, ó tún ní púpọ̀ láti sọ fáwọn ìjọ mẹ́rin tó kù. Àwọn iṣẹ́ tó rán sí Tíátírà, Sádísì, Filadẹ́fíà, àti Laodíkíà, la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká kọbi ara sí ohun tí Kristi sọ fún àwọn ìjọ?

• Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ láti bu epo síná ìfẹ́ tí ìjọ kan kọ́kọ́ ní?

• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn Kristẹni tí ò rí já jẹ ní Símínà ìgbàanì jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní ti gidi?

• Nígbà tá a bá ronú lórí ipò tó dìde nínú ìjọ Págámù, ojú wo ló yẹ ká fi wo èrò apẹ̀yìndà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 10]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

GÍRÍÌSÌ

ÉṢÍÀ KÉKERÉ

Símínà

Éfésù

Págámù

Tíátírà

Sádísì

Filadẹ́fíà

Laodíkíà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” yóò gbádùn Párádísè orí ilẹ̀ ayé

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwọn Kristẹni tá a ṣe inúnibíni sí jẹ́ aṣẹ́gun ayé