Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nígbà kan Rí àti Nísinsìnyí—Ẹhànnà Ẹ̀dá Nígbà Kan Rí Ti Di Oníwàtútù ní Báyìí

Nígbà kan Rí àti Nísinsìnyí—Ẹhànnà Ẹ̀dá Nígbà Kan Rí Ti Di Oníwàtútù ní Báyìí

“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò Sì Sún Mọ́ Yín”

Nígbà kan Rí àti Nísinsìnyí—Ẹhànnà Ẹ̀dá Nígbà Kan Rí Ti Di Oníwàtútù ní Báyìí

“Ọ̀RỌ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, . . . ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:12) Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ rèé nípa bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lágbára láti wọni lọ́kàn tó. Agbára láti wọni lọ́kàn tó ní yìí fara hàn gan-an ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Pẹ̀lú bí ìwàkiwà ṣe gbòde kan lákòókò náà, àwọn tó di Kristẹni gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.—Róòmù 1:28, 29; Kólósè 3:8-10.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì, à ń rí ẹ̀rí tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára láti yí èèyàn padà lóde òní pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn ọ̀gbẹ́ni kan báyìí, tó síngbọnlẹ̀ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Richard yẹ̀ wò. Richard kì í pẹ́ bínú rárá, bí ẹnì kan bá sì ti ṣe nǹkan kékeré fún un báyìí ìjà dé nìyẹn. Ìwà ipá ti bà á láyé jẹ́. Richard tiẹ̀ tún lọ wọnú ẹgbẹ́ àwọn tó ń ja ẹ̀ṣẹ́. Taratara ló fi kọ́ ẹ̀ṣẹ́ jíjà ó sì di ọ̀gá nínú ẹ̀ṣẹ́ kíkàn ní Westphalia, tó wà nílẹ̀ Jámánì. Richard tún máa ń mu ọtí àmuyíràá, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń báwọn èèyàn fìjà pẹẹ́ta. Lákòókò kan tí irú ìjà bẹ́ẹ̀ wáyé, ẹ̀mí ọ̀gbẹ́ni kan lọ sí i díẹ̀ ló sì kù kí Richard dèrò ẹ̀wọ̀n.

Ìgbéyàwó Richard wá ńkọ́? Ó sọ pé: “Kó tó di pé èmi àti Heike kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kóńkó jabele lọ̀rọ̀ wa, olúkúlùkù ló ń ṣèjọba rẹ̀ bó bá ṣe wù ú. Ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ Heike ló máa ń wà ṣáá tí èmi náà sì máa ń fàkókò mi ṣe ohun tí mo yàn láàyò—ìyẹn ẹ̀ṣẹ́ kíkàn, fífi pátákó sáré lórí omi àti lílúwẹ̀ẹ́.”

Nígbà tí Richard àti Heike bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Richard wá rí i pé òun ní láti ṣe àwọn ìyípadà kan láti mú kí ìgbésí ayé òun bá àwọn ìlànà gíga tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu, èyí dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe lójú rẹ̀ ó sì mú kí gbogbo nǹkan tojú sú u. Àmọ́ nígbà tí Richard wá túbọ̀ mọ Jèhófà Ọlọ́run sí i, ó wá ní ìfẹ́ tó lágbára láti múnú rẹ̀ dùn. Richard wá rí i pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ sáwọn èèyàn tó fẹ́ràn ìwà ipá tàbí àwọn tó ń fi í ṣe eré ìnàjú. Richard kẹ́kọ̀ọ́ pé: “Dájúdájú, ọkàn [Jèhófà] kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 11:5.

Ìyẹn nìkan kọ́ o, ìrètí wíwàláàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé wu Richard àti Heike gan-an. Àwọn méjèèjì fẹ́ jùmọ̀ wà níbẹ̀! (Aísáyà 65:21-23) Ìkésíni tó sọ pé “ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín,” wú Richard lórí gan-an. (Jákọ́bù 4:8) Ó wá rí i pé ó ṣe pàtàkì láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fúnni pé: “Má ṣe ìlara ọkùnrin oníwà ipá, bẹ́ẹ̀ ni kí o má yan èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀. Nítorí oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.”—Òwe 3:31, 32.

Ó wu Richard gan-an láti yí bó ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ padà, àmọ́ ó wá rí i pé agbára òun nìkan kò tó láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó wá rí i pé ó ṣe pàtàkì kóun gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́. Èyí ló mú kó ṣe ohun tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì Rẹ̀ pé: “Ẹ . . . máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò. Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.”—Mátíù 26:41.

Nígbà tí Richard wá mọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwà ipá àti ìbínú fùfù, ó wá yé e dáadáa pé ẹ̀ṣẹ́ kíkàn kò dára. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà àti ìṣírí látọ̀dọ̀ àwọn tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Richard jáwọ́ nínú ìwà ipá. Ó fi ẹ̀ṣẹ́ kíkàn sílẹ̀ kì í sì í jà mọ́, ó wá pinnu láti mú ìgbésí ayé ìdílé rẹ̀ sunwọ̀n sí i. Richard tó ti di alábòójútó tí ara rẹ̀ balẹ̀ gan-an báyìí nínú ọ̀kan lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí mo kọ́ látinú Bíbélì ti ràn mí lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ kí n tó ṣe nǹkan.” Ó tún sọ pé: “Ìlànà tó dá lórí ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ ló ń darí àjọṣe àárín èmi àti ìyàwó mi àtàwọn ọmọ mi báyìí. Èyí sì tún mú kí ìdílé wa dà bí òṣùṣù ọwọ̀.”

Àwọn èèyàn kan tí wọn ò mọ̀dí ọ̀rọ̀ máa ń sọ nígbà míì pé túlétúlé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ àpẹẹrẹ àwọn èèyàn bíi Richard ti fi hàn pé irọ́ funfun báláú ni irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀. Láìsí àní-àní, òtítọ́ inú Bíbélì lè mú kí ilé tùbà kó tùṣẹ kó sì sọ àwọn tí wọ́n ya ẹhànnà ẹ̀dá tẹ́lẹ̀ di oníwàtútù èèyàn.—Jeremáyà 29:11.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

“Ìrètí Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ló mú kí n yí padà”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Ṣe É Mú Lò

Bíbélì lè ní ipá tó lágbára nínú ìgbésí ayé àwọn èèyàn. Díẹ̀ lára àwọn ìlànà Bíbélì tó ti mú káwọn èèyàn tó jẹ́ oníwà ìpá yí padà rèé:

“Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá, ẹni tí ó sì ń ṣàkóso ẹ̀mí rẹ̀ sàn ju ẹni tí ó kó ìlú ńlá.” (Òwe 16:32) Àìlera ni kéèyàn má lè ṣàkóso ìbínú rẹ̀, kì í ṣe àmì tó fi hàn pé èèyàn jẹ́ alágbára.

“Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.” (Òwe 19:11) Téèyàn bá lóye ọ̀ràn kan jinlẹ̀jinlẹ̀, èyí á jẹ́ kí onítọ̀hún mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn náà kò sì ní jẹ́ sọ ọ̀ràn náà dìjà tàbí kó ṣàdédé fa ìbínú yọ.

‘Má ṣe bá ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ oníbìínú kẹ́gbẹ́ kí o má bàa mọ àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀ dunjú.’ (Òwe 22:24, 25) Àwọn Kristẹni máa ń yẹra fáwọn tó tètè máa ń fa ìbínú yọ.