Olúkúlùkù Yóò Jókòó Lábẹ́ Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Rẹ̀
Olúkúlùkù Yóò Jókòó Lábẹ́ Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Rẹ̀
ÌBÒÒJI jẹ́ ibi tó máa ń wu àwọn èèyàn tó sì máa ń ṣòro láti rí nígbà ẹ̀ẹ̀rùn tí oòrùn máa ń ràn gan-an láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Inú èèyàn máa ń dùn láti rí igi èyíkéyìí tó bá lè ṣíji boni kúrò lọ́wọ́ ìtànṣán oòrùn, àgàgà nígbà tí irú igi bẹ́ẹ̀ bá hù sítòsí ilé ẹni. Àwọn ewé ńláńlá tí igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àtàwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó tàn kálẹ̀ ló jẹ́ kó ní ìbòòji tó dára ju tàwọn igi mìíràn lọ lágbègbè yẹn.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé Plants of the Bible ṣe wí, “ìbòòji [abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́] jẹ́ èyí tó ń túni lára tó sì tún tutù ju ti abẹ́ àtíbàbà lọ.” Igi ọ̀pọ̀tọ́ tó bá hù sí eteetí ọgbà àjàrà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì máa ń jẹ́ káwọn òṣìṣẹ́ ríbi tí wọ́n á ti máa sinmi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Lẹ́yìn táwọn èèyàn bá ti ṣiṣẹ́ nínú oòrùn tó gbóná janjan látàárọ̀ ṣúlẹ̀, àwọn tó jẹ ara ìdílé kan náà lè wá jókòó sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn kí wọ́n sì jùmọ̀ gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, igi ọ̀pọ̀tọ́ tún máa ń pèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èso aṣaralóore fún ẹni tó ni ín. Nítorí náà, àtìgbà ayé Sólómọ́nì Ọba ni jíjókòó sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ ẹni ti túmọ̀ sí àlàáfíà, aásìkí, àti ọ̀pọ̀ nǹkan.—1 Àwọn Ọba 4:24, 25.
Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú àkókò yẹn ni wòlíì Mósè ṣàpèjúwe Ilẹ̀ Ìlérí gẹ́gẹ́ bí ‘ilẹ̀ ọ̀pọ̀tọ́.’ (Diutarónómì 8:8) Àwọn amí méjìlá ṣì fi ẹ̀rí bó ṣe jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá tó hàn nípa mímú àwọn ọ̀pọ̀tọ́ àtàwọn èso mìíràn látibẹ̀ padà wá sí àgọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Númérì 13:21-23) Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, arìnrìn-àjò kan tó lọ sáwọn ilẹ̀ tá a ti kọ Bíbélì ròyìn pé igi ọ̀pọ̀tọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn igi tó wọ́pọ̀ jù lọ níbẹ̀. Abájọ tí Ìwé Mímọ́ sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀pọ̀tọ́ àti igi ọ̀pọ̀tọ́!
Igi Tí Wọ́n Ń Kórè Rẹ̀ Lẹ́ẹ̀mejì Lọ́dún
Ṣàṣà ilẹ̀ ni igi ọ̀pọ̀tọ́ ò ti lè hù, gbòǹgbò rẹ̀ tó sì máa ń ta wọlẹ̀ gan-an ni kì í jẹ́ kó kú láwọn ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ilẹ̀ máa ń gbẹ táútáú ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Àrà ọ̀tọ̀ ni igi náà, nítorí pé ó máa ń mú ọ̀pọ̀tọ́ àkọ́pọ́n tí wọ́n máa ń kórè lóṣù June jáde, ẹ̀yìn ìyẹn lá tún bẹ̀rẹ̀ sí í mú èso jáde láti oṣù August lọ. (Aísáyà 28:4) Ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń jẹ èso àkọ́pọ́n yẹn ní tútù. Wọ́n á sì sá èyí tó bá so lẹ́yìn ìyẹn gbẹ kí wọ́n lè rí i lò títí ọdún á fi yí po. Wọ́n lè lọ ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ kí wọ́n sì fi ṣe kéèkì roboto, ìgbà mìíràn sì wà tí wọ́n máa ń fi álímọ́ńdì kún un. Àwọn kéèkì ọ̀pọ̀tọ́ wọ̀nyí máa ń dáa gan-an, wọ́n máa ń fára lókun, àjẹpọ́nnulá sì ni wọ́n.
Ábígẹ́lì, obìnrin ọlọgbọ́n nì, fún Dáfídì ní igba ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́, tó dájú pé ó kà sí oúnjẹ tó dára jù lọ fáwọn tó ń sá káàkiri. (1 Sámúẹ́lì 25:18, 27) Ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ náà tún ṣeé lò bí egbòogi. Òróró ataniyẹ́ẹ́ tí wọ́n mú jáde lára ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ ni wọ́n fi sórí oówo tó fẹ́ gbẹ̀mí Hesekáyà Ọba, bó tilẹ̀ jẹ́ pé dídá tí Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn náà ni olórí ohun tó wo Hesekáyà sàn. a—2 Àwọn Ọba 20:4-7.
Àwọn èèyàn mọyì ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ gan-an jákèjádò àgbègbè Mẹditaréníà láyé àtijọ́. Olóṣèlú nì, Cato gbọn ọ̀pọ̀tọ́ kan jìgìjìgì láti yí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Róòmù lérò padà láti bá Carthage ja ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí Róòmù bá Ilẹ̀ Ọba Carthage jà. Ìlú Caria, ní Éṣíà Kékeré ni wọ́n ti ń rí ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ tó dára jù lọ ní Róòmù. Abájọ tí carica fi di orúkọ tí wọ́n ń pe ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ lédè Látìn. Àgbègbè kan náà yẹn tó wà ní ilẹ̀ Turkey òde òní ṣì ń mú ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ tó jẹ́ ojúlówó gan-an jáde.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ àgbẹ̀ sábà máa ń gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ sáwọn ọgbà àjàrà wọn, àmọ́ gígé ni wọ́n máa ń gé àwọn igi tí ò bá méso jáde dà nù. Ilẹ̀ tó dáa ṣọ̀wọ́n ju pé kéèyàn máa fi igi tí kò so èso gbàyè. Nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa igi ọ̀pọ̀tọ́ tí kò méso jáde, àgbẹ̀ náà sọ fún olùrẹ́wọ́ àjàrà pé: “Ọdún mẹ́ta nìyí tí mo ti wá ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, ṣùgbọ́n n kò rí ìkankan. Ké e lulẹ̀! Èé ṣe ní ti gidi tí yóò fi sọ ilẹ̀ náà di aláìwúlò?” (Lúùkù 13:6, 7) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé wọ́n máa ń san owó orí lórí igi eléso nígbà tí Jésù wà láyé, igi èyíkéyìí tí kò bá méso jáde yóò wulẹ̀ jẹ́ òwò àṣedànù ni.
Ipò tí ọ̀pọ̀tọ́ wà nínú oúnjẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í ṣe kékeré. Nítorí ìdí èyí, ọ̀pọ̀tọ́ tí kò bá méso jáde—tó ṣeé ṣe ko so pọ̀ mọ́ ìdájọ́ búburú látọ̀dọ̀ Jèhófà—yóò jẹ́ àjálù ibi. (Hóséà 2:12; Ámósì 4:9) Wòlíì Hábákúkù sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igi ọ̀pọ̀tọ́ lè má yọ ìtànná, àjàrà sì lè má mú èso jáde; iṣẹ́ igi ólífì lè yọrí sí ìkùnà ní ti tòótọ́, àwọn ilẹ̀ onípele títẹ́jú sì lè máà mú oúnjẹ wá ní ti tòótọ́; . . . Síbẹ̀, ní tèmi, dájúdájú, èmi yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà; èmi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.”—Hábákúkù 3:17, 18.
Àmì Orílẹ̀-Èdè Tí Kò Nígbàgbọ́
Ìwé Mímọ́ máa ń lo ọ̀pọ̀tọ́ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bí àpẹẹrẹ, Jeremáyà fi àwọn olóòótọ́ ìgbèkùn Júdà wé ọ̀pọ̀tọ́ tó dára, ìyẹn àkọ́pọ́n ọ̀pọ̀tọ́ tí wọ́n sábà máa ń jẹ ní tútù. Àmọ́, ó fi àwọn ìgbèkùn tó jẹ́ aláìṣòótọ́ wé ọ̀pọ̀tọ́ búburú, tí ò ṣeé jẹ tí wọ́n sì ní láti dà nù.— Jeremáyà 24:2, 5, 8, 10.
Jésù fi sùúrù tí Ọlọ́run ní sí orílẹ̀-èdè Júù hàn nínú àpèjúwe tó ṣe nípa igi ọ̀pọ̀tọ́ tí kò méso jáde. Gẹ́gẹ́ bá a ti mẹ́nu kàn án ṣáájú, ó sọ nípa ọkùnrin kan tó ní igi ọ̀pọ̀tọ́ nínú ọgbà àjàrà rẹ̀. Igi náà ò Lúùkù 13:8, 9.
méso jáde fún odindi ọdún mẹ́ta, olówó rẹ̀ sì fẹ́ gé e dà nù. Àmọ́, olùrẹ́wọ́ àjàrà rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀gá, jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́ ní ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi yóò fi walẹ̀ yí i ká, kí n sì fi ajílẹ̀ sí i; nígbà náà bí ó bá sì mú èso jáde ní ẹ̀yìn ọ̀la, dáadáa náà ni; ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣe ni ìwọ yóò ké e lulẹ̀.”—Nígbà tí Jésù sọ àpèjúwe yìí, o ti wàásù fún ọdún mẹ́ta gbáko, tó ń gbìyànjú láti rí i pé ìgbàgbọ́ gbilẹ̀ láàárín àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Júù. Jésù wá tẹra mọ́ ìgbòkègbodò rẹ̀, ó “fi ajílẹ̀” sí igi ọ̀pọ̀tọ́ ìṣàpẹẹrẹ náà—ìyẹn orílẹ̀-èdè Júù—ó sì tún fún un láǹfààní àtimú èso jáde. Àmọ́, ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú ikú Jésù ló wá hàn kedere pé orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ ti kọ Mèsáyà sílẹ̀.—Mátíù 23:37, 38.
Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jésù tún lo igi ọ̀pọ̀tọ́ láti ṣàpèjúwe ipò búburú tí orílẹ̀-èdè náà wà nípa tẹ̀mí. Nígbà tó ń rìnrìn àjò láti Bẹ́tánì sí Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ mẹ́rin ṣáájú ikú rẹ̀, ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tó léwé lórí dáadáa àmọ́ tí kò ní èso kankan. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe làwọn àkọ́pọ́n ọ̀pọ̀tọ́ máa ń jáde pẹ̀lú àwọn ewé—tó tiẹ̀ máa ń jáde káwọn ewé tó dàgbà nígbà mìíràn pàápàá—bí igi náà ò ṣe léso lórí fi hàn pé kò wúlò fún ohunkóhun rárá nìyẹn.—Máàkù 11:13, 14. b
Bíi ti igi ọ̀pọ̀tọ́ tó dà bí èyí tí ara rẹ̀ le àmọ́ tí kò mú èso jáde náà ni orílẹ̀-èdè Júù ṣe ní ìrísí tó ń tanni jẹ. Àmọ́ kò mú èso tó ń múnú Ọlọ́run dùn jáde, ó sì wá kọ Ọmọ Jèhófà fúnra rẹ̀ sílẹ̀ níkẹyìn. Jésù gégùn-ún fún igi tí kò lè méso jáde náà, nígbà tó sì di ọjọ́ kejì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kíyè sí i pé igi náà ti rọ pátápátá. Rírọ tí igi yẹn rọ fi hàn lọ́nà tó ṣe wẹ́kú pé Ọlọ́run kò ní ka àwọn Júù sí àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́ lọ́jọ́ iwájú.—Máàkù 11:20, 21.
‘Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Igi Ọ̀pọ̀tọ́’
Jésù tún lo igi ọ̀pọ̀tọ́ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan nípa wíwà níhìn-ín rẹ̀. Ó ní: “Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ kókó yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́ gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe kan pé: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ tuntun bá yọ ọ̀jẹ̀lẹ́, tí ó sì mú ewé jáde, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn.” (Mátíù 24:32, 33) Àwọn ewé igi ọ̀pọ̀tọ́ tó máa ń tutù yọ̀yọ̀ jẹ́ àmì tí kò fara sin rárá táwọn èèyàn fi máa ń mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti dé. Bákan náà ni àsọtẹ́lẹ̀ ńlá tí Jésù sọ nínú àkọsílẹ̀ Mátíù orí 24, Máàkù orí 13, àti Lúùkù orí 21 fún wa ní ẹ̀rí tó ṣe kedere nípa wíwà níhìn-ín rẹ̀ nísinsìnyí nínú agbára Ìjọba ọ̀run.—Lúùkù 21:29-31.
Níwọ̀n bá a ti ń gbé ní irú àkókò líle koko bẹ́ẹ̀ nínú ìtàn, ó dájú pé àwa náà á fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Bá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, tá a sì wà lójúfò nípa tẹ̀mí, a ó ní ìrètí rírí ìmúṣẹ ìlérí àgbàyanu náà, tó sọ pé: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.”—Míkà 4:4.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a H.B. Tristram, oníṣègùn ìbílẹ̀ kan tó ṣèbẹ̀wò sáwọn ilẹ̀ tá a ti kọ Bíbélì láàárín ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ṣàkíyèsí pé àwọn ará ibẹ̀ ṣì ń lo òróró ataniyẹ́ẹ́ tí wọ́n mú jáde lára ọ̀pọ̀tọ́ fún ìtọ́jú eéwo.
b Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé nítòsí abúlé Bẹtifágè. Orúkọ ibẹ̀ túmọ̀ sí “Ilé Àwọn Àkọ́pọ́n Ọ̀pọ̀tọ́.” Èyí lè fi hàn pé àwọn èèyàn mọ àgbègbè yẹn mọ́ mímú àwọn àkọ́pọ́n ọ̀pọ̀tọ́ jáde lọ́pọ̀ yanturu.