Yan Ìyè Ayérayé
Yan Ìyè Ayérayé
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ni kò tíì fìgbà kan rí ṣe yíyan tó pọ̀ rẹpẹtẹ tó èyí tí wọ́n ń ṣe báyìí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ lọ̀ràn aṣọ tá à ń wọ̀, oúnjẹ tá à ń jẹ, ibi tá a ti ń ṣiṣẹ́ àti ibi tá à ń gbé. Fúnra èèyàn ló tún máa ń yan irú ẹni tó bá wù ú láti fẹ́ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ kárí ayé. Àmọ́ o, Bíbélì wá gbé yíyàn kan tó ju gbogbo yíyàn mìíràn lọ ka iwájú wa—gbogbo ẹ̀dá èèyàn pátá ló sì kàn.
Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó dúró gbọn-in gbọn-in fún òdodo wà ní ìlà fún ìyè, ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ohun búburú wà ní ìlà fún ikú ara rẹ̀.” (Òwe 11:19) Jésù Kristi sì tún sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
Dájúdájú, Ẹlẹ́dàá wa ti fún wa láǹfààní láti yan ipa ọ̀nà tó máa fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun! Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti jèrè ìyè ayérayé?
Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, “ìyè wà ní ipa ọ̀nà òdodo.” (Òwe 12:28) A lè wà lára àwọn olódodo tí wọ́n wà lójú ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun. Lọ́nà wo? Nípa rírí i dájú pé ìgbésí ayé wa wà níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run àtàwọn àṣẹ rẹ̀. (Mátíù 7:13, 14) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká yan ohun tó dára ká lè gba ẹ̀bùn ìyè ayérayé tí Ọlọ́run ń fúnni.—Róòmù 6:23.