Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ó lòdì láti gbẹ̀mí ẹran ọ̀sìn kan tó ń ṣàìsàn líle tàbí to ti di arúgbó kùjọ́kùjọ́?

Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló ka onírúurú ẹranko sí ohun tó máa ń dáni lára yá téèyàn sì máa ń rí yọ̀. Àwọn ẹran ọ̀sìn kan wà tí wọ́n máa ń bá èèyàn ṣeré gan-an bí ọ̀rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo èèyàn ló mọ ajá sí ẹran ọ̀sìn tó máa ń ṣègbọràn tó sì máa ń fìfẹ́ hàn sí olówó rẹ̀. Èyí ló jẹ́ ká mọ bí ìfẹ́ táwọn èèyàn máa ń ní sírú ẹran ọ̀sìn bẹ́ẹ̀ ṣe pọ̀ tó, àgàgà tó bá jẹ ẹran ọ̀sìn tí wọ́n ti ní fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ẹran ọ̀sìn ni kì í pẹ́ láyé. Àwọn ajá lè lo nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láyé, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ológbò, àmọ́ ìyẹn sinmi lórí irú èyí tí wọ́n jẹ́. Nígbà táwọn ẹran ọ̀sìn bá darúgbó, wọ́n lè di olókùnrùn tàbí aláàbọ̀ ara, èyí sì lè kó ìbànújẹ́ bá olówó wọn bó ṣe ń rántí ìgbà táwọn ẹran ọ̀sìn wọ̀nyí ò tíì darúgbó tí wọ́n ń ta kébékébé. Ṣé ohun tó lòdì ló máa jẹ́ láti gbẹ̀mí irú àwọn ẹran bẹ́ẹ̀?

Kristẹni kan yóò fẹ́ ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu nígbà tó bá ń bójú tó àwọn ẹranko. Ó dájú pé híhùwà òǹrorò sí wọn lòdì pátápátá sí ìfẹ́ Ọlọ́run, nítorí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Olódodo ń bójú tó ọkàn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ̀.” (Òwe 12:10) Àmọ́, èyí ò wá túmọ̀ sí pé bí àwa èèyàn ṣe rí lójú Ọlọ́run làwọn ẹranko náà ṣe rí lójú rẹ̀ o. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ó fi hàn kedere pé wọ́n yàtọ̀ pátápátá sáwọn ẹranko. Bí àpẹẹrẹ, ó fún ènìyàn ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, àmọ́ kò fáwọn ẹranko nírú ìrètí bẹ́ẹ̀ rí. (Róòmù 6:23; 2 Pétérù 2:12) Nítorí pé òun ni Ẹlẹ́dàá, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti fi àjọṣe tí ó tọ́ sáàárín ènìyàn àti ẹranko.

Jẹ́nẹ́sísì 1:28 sọ bí àjọṣe náà ṣe rí fún wa. Ọlọ́run sọ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn tó kọ́kọ́ dá pé: “Kí ẹ . . . máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” Bákan náà ni Sáàmù 8:6-8 sọ pé: “[Ọlọ́run] ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀: àwọn ẹran ọ̀sìn kéékèèké àti màlúù, gbogbo wọn, àti àwọn ẹranko pápá gbalasa pẹ̀lú, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú òkun.”

Ọlọ́run mú un ṣe kedere pé àwọn èèyàn lè lo àwọn ẹranko lọ́nà tó tọ́ tó sì yẹ, wọ́n tiẹ̀ lè pa wọ́n pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè fi awọ wọn ṣe ẹ̀wù. Lẹ́yìn Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, Ọlọ́run tún fún ẹ̀dá ènìyàn láyè láti máa jẹ ẹran ara àwọn ẹranko, èyí sì jẹ́ àfikún sí kìkì ewébẹ̀ tó ní kí wọ́n máa jẹ níbẹ̀rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 3:21; 4:4; 9:3.

Èyí ò wá fàyè gba kéèyàn kàn máa pa àwọn ẹranko fún eré ìdárayá lásán o. Nínú Jẹ́nẹ́sísì 10:9, Bíbélì ṣàpèjúwe Nímírọ́dù gẹ́gẹ́ bí “ọdẹ alágbára ńlá.” Àmọ́ ẹsẹ kan náà yẹn sọ pé èyí jẹ́ kó wà “ní ìlòdì sí Jèhófà.”

Nítorí náà, bí ènìyàn tilẹ̀ jọba lórí àwọn ẹranko, síbẹ̀ kò gbọ́dọ̀ ṣi ọlá àṣẹ yẹn lò bí kò ṣe pé kó lò ó ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí lè kan ṣíṣàì jẹ́ kí ọjọ́ ogbó, egbò ńlá, tàbí àìsàn líle koko máa fìyà jẹ ẹran ọ̀sìn kan láìnídìí. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, ọwọ́ Kristẹni náà ló wà láti pinnu ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Tó bá rí i pé ìwà àìláàánú ló máa jẹ́ tóun bá kàn ń wo ẹran náà níran tó ń jìyà láìsí ìrètí pé ó máa kọ́fẹ padà, a jẹ́ pé ó lè yàn láti gbẹ̀mí rẹ̀ nígbà náà.