Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́ Kí ẹ Sì Rí Ìgbàlà Jèhófà!
Ẹ Dúró Jẹ́ẹ́ Kí ẹ Sì Rí Ìgbàlà Jèhófà!
“Ẹ mú ìdúró yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà fún yín.”—2 Kíróníkà 20:17.
1, 2. Èé ṣe tí àbájáde ìkọlù tó sún mọ́lé látọwọ́ “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù” á fi gbóná janjan ju ti ìwà ìpániláyà tó kárí ayé lọ?
ÀWỌN kan ti sọ pé ìwà ìpániláyà jẹ́ gbígbógun ti gbogbo ayé àti ìwà ọ̀làjú pàápàá. Abájọ téèyàn ò fi gbọ́dọ̀ gbojú bọ̀rọ̀ fún irú ewu bẹ́ẹ̀. Àmọ́ yàtọ̀ sí èyí, oríṣi ìkọlù mìíràn tún wà tó burú ju èyí tá à ń wí yìí lọ táwọn èèyàn lágbàáyé ò sì kà sí. Irú ìkọlù wo lèyí?
2 Ìkọlù náà jẹ́ látọwọ́ “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù,” èyí tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní Ìsíkíẹ́lì orí 38. Àmọ́ ṣé àsọdùn ni kéèyàn sọ pé àbájáde ìkọlù yìí á burú ju ti ìwà ìpániláyà tó kárí ayé lọ? Rárá o, nítorí pé kì í ṣe ìjọba èèyàn nìkan ni Gọ́ọ̀gù ń gbógun tì ní tiẹ̀. Ó tún ń gbógun ti ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run! Àmọ́ o, ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àwọn ẹ̀dá èèyàn tó jẹ́ pé díẹ̀ ni wọ́n lè ṣe láti dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ ìkọlù, Ẹlẹ́dàá náà ní tiẹ̀ lágbára tó pọ̀ tó láti kojú ìkọlù gbígbóná janjan látọwọ́ Gọ́ọ̀gù.
Gbígbógun Ti Ìjọba Ọlọ́run
3. Kí la sọ pé káwọn alákòóso ayé ṣe látọdún 1914, kí sì lohun tí wọ́n ṣe?
3 Àtìgbà tá a ti gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀ lókè ọ̀run lọ́dún 1914 ni Ọba tí Ọlọ́run gbé gorí ìtẹ́ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ àti ètò búburú Sátánì ti bẹ̀rẹ̀ sí forí gbárí. Lákòókò yẹn, a ké sáwọn alákòóso ẹ̀dá èèyàn pé kí wọ́n wá forí balẹ̀ fún Alákòóso tí Ọlọ́run yàn. Àmọ́ ńṣe ni wọ́n fárígá, gẹ́gẹ́ bá a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pé: “Àwọn ọba ilẹ̀ ayé mú ìdúró wọn, àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga sì ti wọ́ jọpọ̀ ṣe ọ̀kan lòdì sí Jèhófà àti lòdì sí ẹni àmì òróró rẹ̀, wọ́n wí pé: ‘Ẹ jẹ́ kí a fa ọ̀já wọn já kí a sì ju okùn wọn nù kúrò lọ́dọ̀ wa!’” (Sáàmù 2:1-3) Àtakò tí wọ́n ń ṣe sí ìṣàkóso Ìjọba náà máa légbá kan sí i nígbà tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá bẹ̀rẹ̀ ìkọlù rẹ̀.
4, 5. Ọ̀nà wo ni ẹ̀dá èèyàn lè gbà máa bá ìṣàkóso Ọlọ́run, tá ò lè fojú rí lókè ọ̀run jà?
4 A lè máa ṣe kàyéfì pé báwo ni ẹ̀dá èèyàn ṣe lè bá ìjọba òkè ọ̀run tí ò ṣe é fojú rí jà. Bíbélì fi yé wa pé àwọn “ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà, tí a ti rà láti ilẹ̀ ayé wá,” àti Jésù Kristi “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” ló para pọ̀ di ìjọba náà. (Ìṣípayá 14:1, 3; Jòhánù 1:29) Nítorí pé ọ̀run ni ìjọba tuntun náà wà la ṣe pè é ní “ọ̀run tuntun,” ó sì bọ́gbọ́n mu pé a pe àwọn èèyàn tó máa ṣàkóso lé lórí ní “ilẹ̀ ayé tuntun.” (Aísáyà 65:17; 2 Pétérù 3:13) Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà tó máa bá Kristi ṣàkóso ti fi ìṣòtítọ́ parí ìgbésí ayé wọn lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n tipa báyìí fi hàn pé àwọn tóótun láti gba ẹrù iṣẹ́ wọn tuntun ní òkè ọ̀run.
5 Àmọ́ o, ìwọ̀nba díẹ̀ tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. Nínú àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó wá síbi ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́dún 2002, kìkì ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ, ọgọ́rùn-ún méje le ọgọ́ta [8,760] péré ló fi ẹ̀rí hàn pé a ti yan àwọn síṣẹ́ lókè ọ̀run. Bí ẹnikẹ́ni bá lóun gbójú gbóyà tó lọ kọlu àwọn yòókù tó máa di ara Ìjọba náà, ńṣe lonítọ̀hún ń fẹsẹ̀ wọnsẹ̀ pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run.—Ìṣípayá 12:17.
Ọba Náà Parí Ìṣẹ́gun Rẹ̀
6. Báwo ni Jèhófà àti Kristi ṣe ń wo inúnibíni tá a bá ṣe sáwọn èèyàn Ọlọ́run?
6 A ti sàsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Jèhófà á ṣe sí àtakò tó bá dìde sí Ìjọba tó gbé kalẹ̀, pé: “Ẹni náà tí ó jókòó ní ọ̀run yóò rẹ́rìn-ín; Jèhófà yóò fi wọ́n ṣẹ̀sín. Ní àkókò yẹn, òun yóò sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ìbínú rẹ̀, yóò sì kó ìyọnu bá wọn nínú ìkannú gbígbóná rẹ̀, yóò wí pé: ‘Èmi, àní èmi, ti fi ọba mi jẹ lórí Síónì, òkè ńlá mímọ́ mi.’” (Sáàmù 2:4-6) Àkókò ti tó báyìí tí Kristi á “parí ìṣẹ́gun rẹ̀” lábẹ́ ìtọ́sọ́nà Jèhófà. (Ìṣípayá 6:2) Báwo ni inúnibíni tí wọ́n bá ṣe sáwọn èèyàn Jèhófà lákòókò àṣekágbá ìṣẹ́gun náà á ṣe rí lára rẹ̀? Ńṣe ló máa kà á sí pé òun fúnra rẹ̀ gan-an àti Ọba rẹ̀ tó ń ṣàkóso ni wọ́n ń ṣe é sí. Jèhófà sọ pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sekaráyà 2:8) Jésù fúnra rẹ̀ là á mọ́lẹ̀ kedere pé gbogbo nǹkan téèyàn bá ṣe sáwọn arákùnrin òun ẹni àmì òróró àti gbogbo ohun téèyàn bá kọ̀ tí ò ṣe fún wọn lòun ń kíyè sí.—Mátíù 25:40, 45.
7. Kí nìdí tí àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà tá a dárúkọ ní Ìṣípayá 7:9 á fi rí ìbínú Gọ́ọ̀gù?
7 Lóòótọ́, àwọn tó bá fi gbogbo ara ṣètìlẹ́yìn fún àṣẹ́kù ẹni àmì òróró náà á rí ìbínú Gọ́ọ̀gù pẹ̀lú. Àwọn tó máa di ara “ilẹ̀ ayé tuntun” Ọlọ́run yìí làwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tá a mú jáde “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” (Ìṣípayá 7:9) A sọ pé wọ́n “dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, wọ́n [sì] wọ aṣọ funfun.” Wọ́n tipa èyí ní ìdúró rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti Kristi Jésù. ‘Imọ̀ ọ̀pẹ ń bẹ lọ́wọ́ wọn,’ wọ́n ń yin Jèhófà pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àti lọ́run, pé ó sì ń ṣàkóso nípasẹ̀ Jésù Kristi tí í ṣe Ọba tó gbé gorí ìtẹ́ ìyẹn “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run.”—Jòhánù 1:29, 36.
8. Kí ni ìkọlù látọwọ́ Gọ́ọ̀gù á mú Kristi ṣe, kí ló sì máa tìdí èyí yọ?
8 Ìkọlù látọwọ́ Gọ́ọ̀gù yìí ló máa mú kí Ọba tí Ọlọ́run gbé gorí ìtẹ́ gbára dì kó sì ja ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14, 16) Gbogbo àwọn tí wọn ò gbà pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ láyé àti lọ́run ló máa ṣègbé. Àwọn tó sì ti fara da inúnibíni nítorí ìtìlẹyìn tí wọ́n ṣe fún Ìjọba Ọlọ́run máa rí ìtura wíwàpẹ́títí gbà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn wọ̀nyí pé: “Èyí jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, tí ń ṣamọ̀nà sí kíkà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, èyí tí ẹ ń jìyà fún ní tòótọ́. Èyí jẹ́ nítorí pé ó jẹ́ òdodo níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti san ìpọ́njú padà fún àwọn tí ń pọ́n yín lójú, ṣùgbọ́n, fún ẹ̀yin tí ń ní ìpọ́njú, ìtura pa pọ̀ pẹ̀lú wa nígbà ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò, bí ó tí ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.”—2 Tẹsalóníkà 1:5-8.
9, 10. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí Júdà ṣẹ́gun ọ̀tá búburú kan? (b) Kí làwọn Kristẹni òde òní gbọ́dọ̀ máa ṣe lọ?
9 Nígbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ lọ́nà yìí tó máa parí ní Amágẹ́dọ́nì, Kristi máa gbógun ti gbogbo ìwà ibi. Àmọ́ kò ní sídìí kankan fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti jà gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú ọ̀ràn àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba ẹ̀yà méjì Júdà ní àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Ogun Jèhófà ni ogun náà, ó sì fún wọn ní ogun náà jà tí wọ́n fi ṣẹ́gun. Àkọsílẹ̀ náà kà pé: “Jèhófà fi àwọn ènìyàn sí ibùba de àwọn ọmọ Ámónì, Móábù àti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì tí ń bọ̀ ní Júdà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì. Àwọn ọmọ Ámónì àti Móábù sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde sí àwọn olùgbé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Séírì láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun àti láti pa wọ́n rẹ́ ráúráú; gbàrà tí wọ́n sì ti yanjú àwọn olùgbé Séírì tán, wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́ ẹnì kìíní láti run ẹnì kejì rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ti Júdà, ó dé ilé ìṣọ́ tí ó wà ní aginjù. Nígbà tí wọ́n yíjú sí ogunlọ́gọ̀ náà, họ́wù, àwọn nìyẹn, tí òkú wọ́n ṣubú sí ilẹ̀ láìsí ẹnikẹ́ni tí ó sá àsálà.”—2 Kíróníkà 20:22-24.
10 Bí Jèhófà ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́ ló rí, pé: “Kì yóò sí ìdí kankan fún yín láti jà.” (2 Kíróníkà 20:17) Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn Kristẹni láti tẹ̀ lé nígbà tí Jésù Kristi bá gbéra “láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” Àmọ́ ní báyìí ná, wọn ò yé kọjú ìjà sáwọn ìwà ibi. Kì í ṣe àwọn ohun ìjà tara ni wọ́n ń lò o, àmọ́ ohun ìjà tẹ̀mí. Lọ́nà yìí ni wọ́n gbà ń “fi ire ṣẹ́gun ibi.”—Róòmù 6:13; 12:17-21; 13:12; 2 Kọ́ríńtì 10:3-5.
Àwọn Wo Ni Gọ́ọ̀gù Á Lò Láti Ṣe Ìkọlù Náà?
11. (a) Àwọn aṣojú wo ni Gọ́ọ̀gù á lò láti ṣe ìkọlù rẹ̀? (b) Kí ni wíwà lójúfò nípa tẹ̀mí ní nínú?
11 Sátánì Èṣù tó wà níbi tá a rẹ̀ ẹ́ nípò wálẹ̀ sí látọdún 1914 la mọ̀ sí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù. Jíjẹ́ tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí kò jẹ́ kó lè ṣe ìkọlù rẹ̀ ní tààràtà, àmọ́ ó máa lo àwọn aṣojú rẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn láti pa itú ọwọ́ rẹ̀. Ta làwọn aṣojú rẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn yìí? Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa wọn fún wa, àmọ́ ó sọ àwọn ohun kan fún wa tá a fi lè mọ́ irú ẹni táwọn wọ̀nyí á jẹ́. Báwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé láti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ṣẹ, bẹ́ẹ̀ náà la ó ṣe máa túbọ̀ mọ irú ẹni táwọn wọ̀nyí jẹ́ sí i. Àwọn èèyàn Jèhófà kì í méfò àmọ́ wọ́n wà lójúfò nípa tẹ̀mí, wọ́n sì mọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nínú ọ̀ràn ìṣèlú àti ti ìsìn tó ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ.
12, 13. Báwo ni wòlíì Dáníẹ́lì ṣe sàsọtẹ́lẹ̀ ogun tí wọ́n máa gbé dìde sáwọn èèyàn Ọlọ́run kẹ́yìn?
12 Wòlíì Dáníẹ́lì túbọ̀ ṣàlàyé nípa ogun tó máa gbé ti àwọn èèyàn Ọlọ́run kẹ́yìn, ó kọ̀wé pé: “Dájúdájú yóò [ìyẹn ọba àríwá] jáde lọ nínú ìhónú ńláǹlà láti pani rẹ́ ráúráú àti láti ya ọ̀pọ̀ sọ́tọ̀ fún ìparun. Yóò sì pa àgọ́ rẹ̀ tí ó dà bí ààfin sáàárín òkun títóbi lọ́lá náà àti òkè ńlá mímọ́ Ìṣelóge.”—Dáníẹ́lì 11:44, 45.
13 Ní àkókò tá a kọ Bíbélì, Òkun Ńlá tàbí Mẹditaréníà ni “òkun títóbi lọ́lá,” Síónì sì ni “òkè ńlá mímọ́,” èyí tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé: “Èmi, àní èmi, ti fi ọba mi jẹ lórí Síónì, òkè ńlá mímọ́ mi.” (Sáàmù 2:6; Jóṣúà 1:4) Nítorí náà, lọ́nà tẹ̀mí, ilẹ̀ tó wà láàárín “òkun títóbi lọ́lá náà àti òkè ńlá mímọ́” dúró fún ìgbòkègbodò tẹ̀mí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ń gbèrú. Wọn ò sí lára omilẹgbẹ ẹ̀dá èèyàn tá a ti sọ dàjèjì sí Ọlọ́run mọ́, wọ́n sì ń fojú sọ́nà láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi Jésù nínú Ìjọba ọ̀run. Ó ṣe kedere pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn adúróṣinṣin, ìyẹn ogunlọ́gọ̀ ńlá, ni ọba àríwá máa dájú sọ nígbà tó bá gbógun rírorò rẹ̀ dé ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì.—Aísáyà 57:20; Hébérù 12:22; Ìṣípayá 14:1.
Kí Làwọn Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Máa Ṣe?
14. Ohun mẹ́ta wo làwọn èèyàn Ọlọ́run á ṣe nígbà tí wọ́n bá gbógun tì wọ́n?
14 Kí làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run á ṣe nígbà tí wọ́n bá gbógun tì wọ́n? Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n tún rí àpẹẹrẹ ohun tí orílẹ̀-èdè Ọlọ́run ṣe nígbà ayé Jèhóṣáfátì. Wàá rí i pé ohun mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la pàṣẹ fáwọn èèyàn náà láti ṣe: (1) kí wọ́n mú ìdúró wọn, (2) kí wọ́n dúró jẹ́ẹ́ àti (3) kí wọ́n sì rí ìgbàlà Jèhófà. Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí á ṣe hùwà níbàámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí?—2 Kíróníkà 20:17.
15. Kí ló túmọ̀ sí fáwọn èèyàn Jèhófà láti mú ìdúró wọn?
15 Wọ́n á mú ìdúró wọn: Àwọn èèyàn Ọlọ́run ò ní ṣojo rárá, wọn ò ní yé dúró ti Ìjọba Ọlọ́run gbágbáágbá. Wọn ò ní jáwọ́ nínú àìdásí-tọ̀túntòsì wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Wọ́n á ‘fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, wọ́n á di aláìṣeéṣínípò’ nínú iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe sí Jèhófà tọkàntọkàn wọn ò sì ní jáwọ́ nínú yíyin Jèhófà ní gbangba nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́. (1 Kọ́ríńtì 15:58; Sáàmù 118:28, 29) Kò sí irú ìgbóguntì bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí tàbí lọ́jọ́ iwájú tó lè mú wọn jáwọ́ nínú ìpinnu wọn tí Ọlọ́run fọwọ́ sí yìí.
16. Lọ́nà wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà á fi dúró jẹ́ẹ́?
16 Wọ́n á dúró jẹ́ẹ́: Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ò ní sọ pé àwọn fẹ́ gba ara àwọn sílẹ̀ àmọ́ wọ́n á ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Jèhófà. Òun nìkan ló tóótun láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú rògbòdìyàn inú ayé, ó sì ti ṣèlérí pé òun á ṣe bẹ́ẹ̀. (Aísáyà 43:10, 11; 54:15; Ìdárò 3:26) Gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà yóò kan gbígbẹ́kẹ̀lé ọ̀nà tó ṣeé fojú rí lóde òní tó hàn kedere pé ó ti ń lò láti mú ète rẹ̀ ṣẹ fún ohun tó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Àkókò yìí gan-an làwọn Kristẹni tòótọ́ ní láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé tó ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nínú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn tí Jèhófà àti Ọba rẹ̀ tó ń ṣàkóso ti fún láṣẹ láti máa mú ipò iwájú. Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ wọ̀nyí ló máa darí àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ṣíṣàìgbọràn sí ìtọ́sọ́nà wọn lè yọrí sí àjálù ńlá.—Mátíù 24:45-47; Hébérù 13:7, 17.
17. Kí nìdí táwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run á fi rí ìgbàlà Jèhófà?
17 Wọ́n á rí ìgbàlà Jèhófà: Ìgbàlà ni èrè gbogbo àwọn tó di ipò ìdúróṣinṣin Kristẹni wọn mú tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á gba àwọn. Wọ́n á polongo dídé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà títí di wákàtí tó kẹ́yìn àti dé ibi tí agbára wọn bá gbé e dé. Gbogbo ìṣẹ̀dá gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ àti pé ó ní àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Kò tún ní sí ìdí kankan mọ́ fún àríyànjiyàn àṣeèṣetán lórí bóyá Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àti lọ́run.—Ìsíkíẹ́lì 33:33; 36:23.
18, 19. (a) Báwo ni orin ìṣẹ́gun tó wà nínú Ẹ́kísódù orí 15 ṣe fi ìmọ̀lára àwọn tó máa la ìkọlù látọwọ́ Gọ́ọ̀gù já hàn? (b) Kí lohun tó yẹ káwọn èèyàn Ọlọ́run máa ṣe báyìí?
18 Pẹ̀lú ìtara tó légbá kan sí i làwọn èèyàn Ọlọ́run á fi wọnú ayé tuntun náà, ara wọn á ti wà lọ́nà láti kọ orin ìṣẹ́gun irú èyí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ lẹ́yìn tí wọ́n la Òkun Pupa já. Títí láé ni wọ́n á fi máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ààbò rẹ̀, bákan náà ni ẹnì kọ̀ọ̀kan àti gbogbo wọn lápapọ̀ á tún àwọn ọ̀rọ̀ ìgbà láéláé nì sọ pé: “Jẹ́ kí n kọrin sí Jèhófà, nítorí ó ti di gbígbéga fíofío. . . . Jèhófà jẹ́ akin lójú ogun. Jèhófà ni orúkọ rẹ̀. . . . Jèhófà, ọwọ́ ọ̀tún rẹ lè fọ́ ọ̀tá túútúú. Àti nínú ọ̀pọ̀ yanturu ìlọ́lájù rẹ ni ìwọ lè wó àwọn tí ó dìde sí ọ palẹ̀; ìwọ rán ìbínú rẹ jíjófòfò jáde, ó jẹ wọ́n tán bí àgékù pòròpórò. . . . Nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, ìwọ ti ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn tí ìwọ gbà sílẹ̀; ìwọ nínú okun rẹ yóò darí wọn lọ sí ibi gbígbé rẹ mímọ́ dájúdájú. . . . Ìwọ yóò mú wọn wá, ìwọ yóò sì gbìn wọ́n sí òkè ńlá ogún rẹ, ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀ fún ara rẹ láti máa gbé, Jèhófà, ibùjọsìn kan tí ọwọ́ rẹ gbé kalẹ̀, Jèhófà. Jèhófà yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—Ẹ́kísódù 15:1-19.
19 Ní báyìí tí ìrètí ìyè ayérayé ti túbọ̀ ṣe kedere ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ẹ ò wá rí i pé àkókò tó rọgbọ rèé fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti fi hàn pé Jèhófà nìkan làwọn dúró tì kí wọ́n sì sọ ìpinnu wọn láti má ṣe jáwọ́ nínú sísìn ín gẹ́gẹ́ bí Ọba ayérayé!—1 Kíróníkà 29:11-13.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn ni Gọ́ọ̀gù á dojú ìkọlù rẹ̀ kọ?
• Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run á ṣe mú ìdúró wọn?
• Kí ló túmọ̀ sí láti dúró jẹ́ẹ́?
• Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run á ṣe rí ìgbàlà Jèhófà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jèhófà mú kí Jèhóṣáfátì àtàwọn èèyàn rẹ̀ ṣẹ́gun, láìjẹ́ pé wọ́n jà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn náà gbà pé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ láyé lọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn èèyàn Ọlọ́run máa tó kọ orin ìṣẹ́gun