Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Má Fòyà Tàbí Kí Ẹ Jáyà”

“Ẹ Má Fòyà Tàbí Kí Ẹ Jáyà”

“Ẹ Má Fòyà Tàbí Kí Ẹ Jáyà”

‘Ẹ má fòyà tàbí kí ẹ jáyà. Jèhófà yóò wà pẹ̀lú yín.’—2 KÍRÓNÍKÀ 20:17.

1. Ipa wo ni àwọn apániláyà ti ní lórí àwọn èèyàn, kí sì nìdí tí ìbẹ̀rù àwọn èèyàn fi lẹ́sẹ̀ nílẹ̀?

 ÀWỌN apániláyà! Pàrá làyà máa ń já téèyàn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí lásán, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn ronú pé ẹ̀mí òun ò dè àti pé kò sí nǹkan tí òun lè ṣe. Ó máa ń jẹ́ kí ìbẹ̀rùbojo múni, ó ń fa ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́. Ọ̀rọ̀ náà sì tún ń tọ́ka sí àwọn kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń bẹ̀rù pé wọ́n ṣì máa han ẹ̀dá èèyàn léèmọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún sí i. Ìbẹ̀rù táwọn èèyàn ní kúkú lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nítorí pé láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn làwọn orílẹ̀-èdè kan ti ń gbógun ti ìwà ìpániláyà lónírúurú ọ̀nà àmọ́ tí wọn ò tíì borí rẹ̀.

2. Ojú wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo ìṣòro ìwà ìpániláyà, àwọn ìbéèrè wo sì lèyí gbé dìde?

2 Síbẹ̀, kò yẹ kéèyàn sọ̀rètí nù. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n ń wàásù ní ilẹ̀ òjìlénígba ó dín mẹ́fà [234] àti àwọn ìpínlẹ̀ káàkiri ayé ní ìrètí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pé nǹkan á dára. Dípò èyí tí wọ́n á fi máa bẹ̀rù pé ìwà ìpániláyà ò ní kásẹ̀ nílẹ̀ láé, ńṣe ni ọkàn wọn balẹ̀ dẹ́dẹ́ pé àfẹ́kù máa tó bá a. Ǹjẹ́ ó yẹ kí gbogbo èèyàn ní irú ẹ̀mí pé nǹkan ṣì máa dára yìí? Ta ló lè gba aráyé kúrò lọ́wọ́ ìwà burúkú tó gbòde kan yìí, báwo ló sì ṣe máa ṣeé ṣe? Nígbà tó kúkú jẹ́ pé gbogbo wa pátá ló ti fojú winá ìwà ipá lọ́nà kan tàbí òmíràn, ó máa dára nígbà náà láti ṣàyẹ̀wò ìdí tó fi yẹ láti ní ẹ̀mí pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dára.

3. Àwọn ohun wo ló lè máa múni bẹ̀rù, àsọtẹ́lẹ̀ wo la sì sọ nípa àkókò wa?

3 Lóde òní, onírúurú nǹkan ló ń kó ìbẹ̀rù àti ìdágìrì bá àwọn èèyàn. Ronú nípa ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọn ò lè bójú tó ara wọn mọ́ nítorí ara tó ti ń dara àgbà, ro tàwọn tí àrùn tí ò gbóògùn ń gbẹ̀mí wọn àtàwọn ìdílé tó ń tiraka láti ní àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé. Àní sẹ́, ronú nípa bí ìgbésí ayé fúnra rẹ̀ ò ṣe dáni lójú! Jàǹbá tàbí àjálù lè mú kéèyàn kàgbákò ikú òjijì, èyí á sì fòpin sí gbogbo nǹkan tá a nífẹ̀ẹ́ sí. Irú ìbẹ̀rù àtàwọn àníyàn bí èyí, tó so mọ́ ọ̀pọ̀ wàhálà ara ẹni mìíràn àti ìjákulẹ̀, ló mú kí àkókò wa rí bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́, pé: “Mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere.”—2 Tímótì 3:1-3.

4. Ìrètí tó dára wo ló máa jẹ́ ojútùú sáwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú jáì tá a kọ sínú 2 Tímótì 3:1-3?

4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ̀rọ̀ nípa ipò nǹkan tí ò fara rọ, síbẹ̀ ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìrètí ń bẹ. Ohun tó sọ ni pé àwọn àkókò tó le koko á wà “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí tó jẹ́ ti Sátánì. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn ìṣòro náà máa tó kásẹ̀ nílẹ̀ àti pé ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run tí kò lábààwọ́n, èyí tí Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa gbàdúrà fún máa tó rọ́pò ayé búburú yìí. (Mátíù 6:9, 10) Ìṣàkóso Ọlọ́run lókè ọ̀run tí wòlíì Dáníẹ́lì sọ pé “a kì yóò run láé,” ni Ìjọba yìí, àmọ́ ó máa “fọ́ ìjọba wọ̀nyí [ti ẹ̀dá èèyàn] túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.

Àìdásí-Tọ̀túntòsì Kristẹni Kì Í Ṣe Ìwà Ìpániláyà

5. Kí làwọn orílẹ̀-èdè ti ṣe sọ́ràn ìwà ìpániláyà lẹ́nu àìpẹ́ yìí?

5 Ìwà ìpániláyà ti gbẹ̀mí àìmọye èèyàn láti ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. Àmọ́ lẹ́yìn táwọn apániláyà ṣọṣẹ́ nílùú New York àti ìlú Washington, D.C., ní September 11, 2001 ni gbogbo èèyàn kárí ayé tó wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ewu ńlá ni ọ̀ràn yìí. Bí ìwà ìpániláyà ṣe wá gbalẹ̀ gbòde yìí ti mú káwọn orílẹ̀-èdè kárí ayé pawọ́ pọ̀ láti rẹ́yìn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn sọ pé ní December 4, 2001, “àwọn mínísítà fún ọ̀ràn ilẹ̀ òkèèrè láti orílẹ̀-èdè márùnléláàádọ́ta, ti ilẹ̀ Yúróòpù, Àríwá Amẹ́ríkà àti Àárín Gbùngbùn Éṣíà panu pọ̀ gbé ètò kan kalẹ̀” láti ṣe kòkáárí àwọn ìsapá wọn. Ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ àgbà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé ìgbésẹ̀ yìí dára gan-an nítorí pé ó jẹ́ “àfikún agbára” láti gbógun ti ìwà ìpániláyà. Kò pẹ́ rárá tí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn fi bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ nínú ohun tí ìwé ìròyìn The New York Times Magazine pè ní “ìbẹ̀rẹ̀ ogun tá ò rírú rẹ̀ rí.” A ṣì ń fojú sọ́nà láti rí báwọn ìsapá wọ̀nyí ṣe máa gbéṣẹ́ tó. Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà nínú ìbẹ̀rùbojo tí wọ́n sì ń ṣàníyàn nípa ohun tó máa tẹ̀yìn irú ogun tó ń lọ lọ́wọ́ láti rẹ́yìn ìwà ìpániláyà yọ. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ò ba àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà o.

6. (a) Èé ṣe tó fi lè ṣòro fáwọn èèyàn kan nígbà míì láti fara mọ́ ipò àìdásí-tọ̀túntòsì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dì mú? (b) Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ti ọ̀ràn ìṣèlú?

6 Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sọ́ràn ìṣèlú. Lákòókò tí ìlú bá tòrò minimini, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa gbà pé ohun tó dáa ni wọ́n ṣe, àmọ́ ńṣe làwọn èèyàn máa ń fúngun mọ́ wọn nígbà tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìjayà àti àìsí ìbàlẹ̀ ọkàn tí ogun ń fa máa ń fa ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni. Èyí lè mú kó ṣòro fáwọn kan láti lóye ìdí tẹ́nì kan á fi kọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ tó kóra jọ láti jà fún orílẹ̀-èdè wọn. Àmọ́ ṣá, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé àwọn gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù tó sọ pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19; 17:14-16; 18:36; Jákọ́bù 4:4) Èyí ń béèrè pé kí wọ́n jẹ́ aláìdásí-tọ̀túntòsì nínú ọ̀ràn òṣèlú tàbí ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Jésù fúnra rẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó yẹ lélẹ̀. Pẹ̀lú ọgbọ́n pípé tó ní àti agbára rẹ̀ tí ò láfiwé, ì bá ti ṣe àwọn àtúnṣe tó gadabú sáwọn ìgbòkègbodò ẹ̀dá èèyàn nígbà ayé rẹ̀. Síbẹ̀, ńṣe ló ta kété sí ọ̀ràn ìṣèlú. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, gbogbo ara ló fi kọ ìṣàkóso gbogbo ìjọba ayé tí Sátánì sọ pé òun á fún un. Nígbà tó tún ṣe, ó kọ ipò òṣèlú táwọn èèyàn fẹ́ yàn án sí.—Mátíù 4:8-10; Jòhánù 6:14, 15.

7, 8. (a) Kí ni àìdásí-tọ̀túntòsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ti ọ̀ràn ìṣèlú kò túmọ̀ sí, kí sì nìdí? (b) Báwo ni Róòmù 13:1, 2 ṣe fi hàn pé híhùwà ipá sáwọn aláṣẹ kò bójú mu?

7 Kò yẹ káwọn èèyàn ronú pé àìdásí-tọ̀túntòsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túmọ̀ sí pé wọ́n ń ti ìwà ipá lẹ́yìn. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á tako jíjẹ́ tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ìránṣẹ́ “Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà.” (2 Kọ́ríńtì 13:11) Wọ́n ti mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwà ipá. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Bákan náà ni wọ́n tún mọ ohun tí Jésù sọ fún àpọ́sítélì Pétérù pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.”—Mátíù 26:52.

8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìtàn ti fi hàn kedere pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èké Kristẹni ti lo “idà,” àmọ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀. Wọn kì í lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó jọ bẹ́ẹ̀. Gbogbo ara làwọn Ẹlẹ́rìí fi ń ṣègbọràn sí àṣẹ tó wà ní Róòmù 13:1, 2, tó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga [àwọn aláṣẹ ìjọba], nítorí kò sí ọlá àṣẹ kankan bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; àwọn ọlá àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹni tí ó bá tako ọlá àṣẹ ti mú ìdúró kan lòdì sí ìṣètò Ọlọ́run; àwọn tí wọ́n ti mú ìdúró kan lòdì sí i yóò gba ìdájọ́ fún ara wọn.”

9. Ọ̀nà méjì wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń gbógun ti ìwà ìpániláyà?

9 Bó ṣe jẹ́ pé ìwà ibi gbáà ni ìwà ìpániláyà, ṣé kò wá yẹ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ohun kan láti gbógun tì í ni? Ó kúkú yẹ, wọ́n sì ń ṣe é. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn fúnra wọn kì í lọ́wọ́ nínú irú ìwà bẹ́ẹ̀. Lọ́nà kejì, wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn láwọn ìlànà Kristẹni, èyí tó ń mú gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìwà ipá kúrò téèyàn bá tẹ̀ lé e. a Lọ́dún tó kọjá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi wákàtí bílíọ̀nù kan, mílíọ̀nù igba ó lé méjì, ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó ó dín mọ́kàndínlógún àti ọ̀ọ́dúnrún ó lé méjì [1,202,381,302] ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà Kristẹni. Wọn ò fi àkókò yìí ṣòfò o, nítorí pé àbájáde ìgbòkègbodò yìí ni pé ọ̀kẹ́ mẹ́tàlá ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àti ọ̀rìnlénírínwó ó dín mọ́kànlá [265,469] èèyàn ló ṣèrìbọmi láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì tipa báyìí fi hàn ní gbangba pé gbogbo ara làwọn fi kọ ìwà ipá sílẹ̀.

10. Ta ló lè mú ìwà ipá kúrò pátápátá láyé òde òní?

10 Láfikún sí i, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé àwọn nìkan ò lè dá mú gbogbo ibi tó ń ṣẹlẹ̀ láyé kúrò. Ìdí rèé tí wọ́n fi gbọ́kàn lé ẹnì kan ṣoṣo tó lè ṣe é—ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Pẹ̀lú gbogbo ìsapá tí ẹ̀dá èèyàn ti ṣe tọkàntọkàn, kò tíì lè mú ìwà ipá kúrò. Òǹkọ̀wé Bíbélì kan tá a mí sí ti kìlọ̀ fún wa ṣáájú nípa àkókò wa, ìyẹn “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ó sì ti sọ pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.” (2 Tímótì 3:1, 13. ) Tá a bá tibi kókó yìí wò ọ̀ràn náà, àá rí i pé kò sọ́gbọ́n tí ẹ̀dá èèyàn fi lè ṣẹ́gun ibi. Àmọ́ o, a lè gbọ́kàn lé Jèhófà pé yóò rẹ́yìn ibi pátápátá àti títí láé.—Sáàmù 37:1, 2, 9-11; Òwe 24:19, 20; Aísáyà 60:18.

Níní Ìgboyà Lójú Inúnibíni Tó Ti Dé Tán

11. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni Jèhófà ti gbé láti fòpin sí ìwà ipá?

11 Kíkórìíra tí Ọlọ́run àlàáfíà kórìíra ìwà ipá ló mú ká mọ ìdí tó fi ṣètò láti pa Sátánì Èṣù tó dá ọ̀ràn náà sílẹ̀ run. Kódà, Ó tiẹ̀ ti mú kí Máíkẹ́lì tó jẹ́ olórí áńgẹ́lì, ìyẹn Jésù Kristi tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ fi jẹ Ọba, ṣẹ́gun Sátánì lọ́nà ẹ̀sín. Ọ̀nà tí Bíbélì gbà ṣàpèjúwe rẹ̀ rèé: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jagun ṣùgbọ́n kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”—Ìṣípayá 12:7-9.

12, 13. (a) Kí ló mú kí ọdún 1914 jẹ́ ọdún tó ṣàrà ọ̀tọ̀? (b) Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì sọ nípa àwọn tó ń ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn?

12 Ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé fi hàn pé ọdún 1914 ni ogun yẹn bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run. Àtìgbà náà wá ni ipò àwọn nǹkan ti ń burú bògìrì sí i lórí ilẹ̀ ayé. Ìṣípayá 12:12 ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ní tìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn! Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”

13 Abájọ tó fi jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró olùjọsìn Ọlọ́run àtàwọn “àgùntàn mìíràn” ẹlẹgbẹ́ wọn ni Èṣù dìídì dojú ìbínú rẹ̀ kọ. (Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 12:17) Ìbínú yìí máa dé òtéńté rẹ̀ nígbà tí Èṣù bá dojú inúnibíni rírorò kọ gbogbo àwọn tó bá fara mọ́ Ìjọba tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ tí wọ́n sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀. Ìwé Ìsíkíẹ́lì orí 38 pe inúnibíni gbígbóná janjan yìí ní ìkọlù látọwọ́ “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.”

14. Irú ààbò wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí sẹ́yìn, ṣé bẹ́ẹ̀ ni yóò sì ṣe máa rí títí lọ?

14 Lẹ́yìn tá a ti lé Sátánì kúrò lókè ọ̀run, a ń dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà mìíràn kúrò lọ́wọ́ inúnibíni tí Sátánì ń ṣe nípasẹ̀ àwọn olóṣèlú tá a fi èdè ìṣàpẹẹrẹ ṣàpèjúwe nínú Ìṣípayá 12:15, 16. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, Bíbélì fi hàn pé nígbà ìkọlù Sátánì tó máa kẹ́yìn, kò ní sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó máa gbèjà àwọn tó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà. Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí èyí kó ìbẹ̀rù tàbí ìpayà bá àwọn Kristẹni? Rárá o!

15, 16. (a) Ìdánilójú wo ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fi ki àwọn èèyàn rẹ̀ láyà lọ́jọ́ Jèhóṣáfátì fún àwọn Kristẹni lóde òní? (b) Àpẹẹrẹ wo ni Jèhóṣáfátì àtàwọn èèyàn rẹ̀ fi lélẹ̀ fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní?

15 Ọlọ́run á ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn gan-an gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣètìlẹ́yìn fún orílẹ̀-èdè rẹ̀ lásìkò tí Ọba Jèhóṣáfátì wà lórí oyè. A kà á pé: “Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo Júdà àti ẹ̀yin olùgbé Jerúsálẹ́mù àti Jèhóṣáfátì Ọba! Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún yín, ‘Ẹ má fòyà tàbí kí ẹ jáyà nítorí ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí; nítorí pé ìjà ogun náà kì í ṣe tiyín, bí kò ṣe ti Ọlọ́run. . . . Kì yóò sí ìdí kankan fún yín láti jà nínú ọ̀ràn yìí. Ẹ mú ìdúró yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà fún yín. Ìwọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù, ẹ má fòyà tàbí kí ẹ jáyà. Lọ́la, ẹ jáde sí wọn, Jèhófà yóò sì wà pẹ̀lú yín.’”—2 Kíróníkà 20:15-17.

16 A mú un dá àwọn èèyàn Júdà lójú pé kò sídìí fún wọn láti jà. Lọ́nà kan náà, nígbà tí Gọ́ọ̀gù ti Mágọ́gù bá kọlu àwọn èèyàn Ọlọ́run, wọn ò ní múra ogun láti gbèjà ara wọn. Dípò ìyẹn, ńṣe ni wọ́n á ‘dúró jẹ́ẹ́ láti rí ìgbàlà Jèhófà’ fún wọn. Lóòótọ́, dídúró jẹ́ẹ́ kò túmọ̀ sí pé kí wọ́n jókòó gẹlẹtẹ láìṣe ohunkóhun, ó ṣe tán àwọn èèyàn Ọlọ́run lákòókò Jèhóṣáfátì kò jókòó gẹlẹtẹ. A kà pé: “Ní kíá, Jèhóṣáfátì tẹrí ba mọ́lẹ̀ ní ìdojúbolẹ̀, gbogbo Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù sì wólẹ̀ níwájú Jèhófà láti wárí fún Jèhófà. . . . Síwájú sí i, [Jèhóṣáfátì] fọ̀ràn lọ àwọn ènìyàn náà, ó sì yan àwọn akọrin fún Jèhófà sípò àti àwọn tí ń mú ìyìn wá nínú ọ̀ṣọ́ mímọ́ bí wọ́n ti ń jáde lọ ṣíwájú àwọn ọkùnrin tí ó dìhámọ́ra, tí wọ́n sì ń wí pé: ‘Ẹ fi ìyìn fún Jèhófà, nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.’” (2 Kíróníkà 20:18-21) Àní sẹ́, lójú ìkọlù ọ̀tá pàápàá àwọn èèyàn náà kò yé fi ìyìn fún Jèhófà. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ tó yẹ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ lé nígbà tí Gọ́ọ̀gù bá gbógun tì wọ́n.

17, 18. (a) Irú ẹ̀mí ìgboyà wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ní nípa ìkọlù Gọ́ọ̀gù? (b) Ìránnilétí wo làwọn Kristẹni ọ̀dọ́ rí gbà lẹ́nu àìpẹ́ yìí?

17 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ní yé ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn títí Gọ́ọ̀gù á fi bẹ̀rẹ̀ ìkọlù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n á máa bá a lọ lẹ́yìn náà. Wọ́n á máa rí okun àti ààbò bí wọ́n ṣe ń kóra jọ nínú ìjọ tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún ó dín ẹgbàájọ [94,600] kárí ayé. (Aísáyà 26:20) Ẹ ò rí i pé àkókò tó rọgbọ láti fi ìgboyà yin Jèhófà gan-an la wà yìí! Ó dájú pé ríretí tí wọ́n ń retí ogun tí Gọ́ọ̀gù á gbé dé láìpẹ́ kò mú kí wọ́n fà sẹ́yìn nítorí ìbẹ̀rù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń mú kí wọ́n túbọ̀ fi kún ẹbọ ìyìn wọn dé ibi tí gbogbo agbára wọn bá mọ.—Sáàmù 146:2.

18 A rí àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìgboyà yìí nínú ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ kárí ayé tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Láti lè túbọ̀ mọ bí yíyan irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ ṣe dára gan-an la ṣe mú ìwé ìléwọ́ náà Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe? jáde láwọn àpéjọ àgbègbè ọdún 2002. Tọmọdé tàgbà àwọn Kristẹni ni inú wọn dùn gan-an fún irú àwọn ìránnilétí tó bágbà mu bẹ́ẹ̀.—Sáàmù 119:14, 24, 99, 119, 129, 146.

19, 20. (a) Èé ṣe tí ò fi sídìí fáwọn Kristẹni láti páyà tàbí láti bẹ̀rù? (b) Kí ni àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣe?

19 Pẹ̀lú bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ayé, kò sídìí kankan fún àwọn Kristẹni láti páyà tàbí láti bẹ̀rù. Wọ́n mọ̀ pé Ìjọba Jèhófà máa tó mú ìwà ipá lónírúurú kúrò títí láé. Wọ́n tún ń rí ìtùnú nínú mímọ̀ tí wọ́n mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti tipasẹ̀ ìwà ipá pàdánù ẹ̀mí wọn ló máa jíǹde. Bí èyí ṣe máa fún àwọn kan láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ló tún ṣe máa mú káwọn mìíràn máa tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà.—Ìṣe 24:15.

20 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, a mọ̀ pé ó ṣe kókó láti wà láìdásí-tọ̀túntòsì, a sì ti múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀. A fẹ́ máa bá a lọ ní fífojúsọ́nà fún àkókò náà tí àá lè ‘dúró jẹ́ẹ́ ká sì rí ìgbàlà Jèhófà.’ Àpilẹ̀kọ tó kàn máa fún ìgbàgbọ́ wa lókun nípa jíjẹ́ ká mọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé lóde òní tó ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tó jáwọ́ nínú ìgbésí ayé oníwà ipá láti di Ẹlẹ́rìí, wo Jí! September 22, 1990, ojú ìwé 21; January 8, 1992, ojú ìwé 18; àti Ilé Ìṣọ́ January 1, 1996, ojú ìwé 5; August 1, 1998, ojú ìwé 5.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ èèyàn òde òní ò fi gbà pé ọjọ́ iwájú á dára?

• Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbà pé ọjọ́ ọ̀la á dára?

• Kí ni Jèhófà ti ṣe sí ohun tó fa gbogbo ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀?

• Èé ṣe tí ò fi sídìí kankan fún wa láti bẹ̀rù ìkọlù látọwọ́ Gọ́ọ̀gù?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Jésù fi àpẹẹrẹ tó tọ́ lélẹ̀ nípa àìdásí-tọ̀túntòsì Kristẹni

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kárí ayé ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tayọ̀tayọ̀

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 12]

FỌ́TÒ UN 186226/M. Grafman