Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọrẹ Tí Inú Ọlọ́run Ń Dùn Sí

Ọrẹ Tí Inú Ọlọ́run Ń Dùn Sí

Ọrẹ Tí Inú Ọlọ́run Ń Dùn Sí

JÉSÙ àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń gbádùn oúnjẹ aládùn kan ní Bẹ́tánì pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́ bíi mélòó kan, títí kan Màríà, Màtá, àti Lásárù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jíǹde. Nígbà tí Màríà mú ìdá mẹ́ta kìlógíráàmù nínú mẹ́wàá ìwọ̀n òróró olówó iyebíye tó sì fi pa ẹsẹ̀ Jésù, inú bí Júdásì Ísíkáríótù, kíá ló bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Ó ní: “Èé ṣe tí a kò ta òróró onílọ́fínńdà yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó dínárì [iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó owó ọ̀yà odidi ọdún kan], kí a sì fi fún àwọn òtòṣì?” Kíá làwọn tó kù ṣe bákan náà ṣàròyé.—Jòhánù 12:1-6; Máàkù 14:3-5.

Àmọ́, Jésù fèsì pé: “Ẹ jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́. . . . Nítorí ẹ ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo, nígbàkigbà tí ẹ bá sì fẹ́, ẹ lè ṣe rere fún wọn nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.” (Máàkù 14:6-9) Àwọn aṣáájú ìsìn Júù rò pé ṣíṣe ìtọrẹ àánú kì í wulẹ̀ ṣe ìwà rere lásán àmọ́ pé ó tún lè ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ pàápàá. Àmọ́ Jésù ní tiẹ̀ mú un ṣe kedere pé ọrẹ tí inú Ọlọ́run dùn sí kò mọ sórí ṣíṣe ìtọrẹ àánú fáwọn òtòṣì nìkan.

Ṣíṣàyẹ̀wò ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣètọrẹ nínú ìjọ Kristẹni ìjímìjí yóò jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tá a lè gbà fi ojú àánú hàn ká sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ọrẹ wa múnú Ọlọ́run dùn. Yóò sì tún jẹ́ ká mọ irú ọrẹ kan tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, tó sì ń ṣeni láǹfààní jù lọ.

“Fúnni ní Àwọn Ẹ̀bùn Àánú”

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa “fúnni ní àwọn ẹ̀bùn àánú,” tàbí kí wọ́n “ṣètọrẹ àánú” tàbí “lò ó fún ìtọrẹ àánú,” tá a bá ní ká sọ ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìtumọ̀ mìíràn ṣe lò gbólóhùn náà. (Lúùkù 12:33, New English Bible; A Translation in the Language of the People, láti ọwọ́ Charles B. Williams) Àmọ́ o, Jésù tún kìlọ̀ fún wọn nípa fífúnni lọ́nà ṣekárími, èyí tí ẹnì kan ṣe kìkì láti gba ògo fún ara rẹ̀ dípò kó fi ògo fún Ọlọ́run. Ó ní: “Nígbà tí o bá ń lọ fi àwọn ẹ̀bùn àánú fúnni, má ṣe fun kàkàkí níwájú rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn alágàbàgebè ti ń ṣe nínú sínágọ́gù àti ní àwọn ojú pópó, kí àwọn ènìyàn lè yìn wọ́n lógo.” (Mátíù 6:1-4) Nípa fífi ìkìlọ̀ yìí sọ́kàn, àwọn Kristẹni ìjímìjí yẹra fún ṣekárími àwọn onítara aṣáájú ìsìn ayé ti àkókò wọn, wọ́n sì yàn láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó jẹ́ aláìní nípa bíbá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ kan tàbí nípa fífún wọn ní ẹ̀bùn.

Bí àpẹẹrẹ, a sọ fún wa nínú Lúùkù 8:1-3 pé Màríà Magidalénì, Jòánà, Súsánà, àtàwọn mìíràn lo “àwọn nǹkan ìní wọn” láti ṣèránṣẹ́ fún Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́nà tí kò la ṣekárími lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kì í ṣe aláìní, síbẹ̀ wọ́n ti fi gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ wọn sílẹ̀ kí wọ́n lé ṣètìlẹyìn fún kìkì iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. (Mátíù 4:18-22; Lúùkù 5:27, 28) Lẹ́nu kan, àwọn obìnrin wọ̀nyí ń yin Ọlọ́run lógo nípa bí wọ́n ṣe ń ran àwọn ọkùnrin náà lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ láṣeyanjú. Ọlọ́run sì fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba ohun tí wọ́n ṣe nípa kíkọ àkọsílẹ̀ ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí wọ́n ní yìí sínú Bíbélì kí gbogbo ìran tó ń bọ̀ lè kà á.—Òwe 19:17; Hébérù 6:10.

Obìnrin mìíràn tó tún jẹ́ onínúure tó sì “pọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú” ni Dọ́káàsì. Ó ṣe aṣọ fáwọn tálákà opó tó ń gbé Jópà ìlú rẹ̀ tó wà lẹ́bàá òkun. Yálà owó ara rẹ̀ ló fi ń ra àwọn aṣọ náà o tàbí bóyá ńṣe ló kàn ń bá wọn rán an lọ́fẹ̀ẹ́, a ò lè sọ. Èyí ó wù ó jẹ́, iṣẹ́ rere rẹ̀ sọ ọ́ di ẹni ọ̀wọ́n lójú gbogbo àwọn tó ràn lọ́wọ́ àti lójú Ọlọ́run pẹ̀lú, ẹni tó fi àánú bù kún iṣẹ́ rere rẹ̀.—Ìṣe 9:36-41.

Èrò Tí Ó Tọ́ Ṣe Pàtàkì

Kí ló mú kí àwọn èèyàn wọ̀nyí ṣètọrẹ? Kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀mí ìyọ́nú tó ṣàdédé ń wá síni lọ́kàn ní wéré tá a bá rí ẹnì kan tó nílò ìrànlọ́wọ́ ló mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn fúnra wọn ló rí i pé ohun tó tọ́ ni pé káwọn ṣe ohun táwọn ba lè ṣe lójoojúmọ́ láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó wà nípò òṣì, àwọn tó wà nínú ìpọ́njú, àwọn tó ń ṣàìsàn, tàbí àwọn tó láwọn ìṣòro mìíràn. (Òwe 3:27, 28; Jákọ́bù 2:15, 16) Irú ọrẹ yìí ló ń múnú Ọlọ́run dùn. Olórí ohun tó sún wọn ṣe é ni ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àti fífẹ́ tí wọ́n fẹ́ láti fara wé bó ṣe jẹ́ aláàánú àti ọ̀làwọ́.—Mátíù 5:44, 45; Jákọ́bù 1:17.

Àpọ́sítélì Jòhánù tẹnu mọ́ apá pàtàkì yìí nínú ọ̀ràn fífúnni nígbà tó béèrè pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ní àlùmọ́ọ́nì ayé yìí fún ìtìlẹyìn ìgbésí ayé, tí ó sì rí i tí arákùnrin rẹ̀ ṣe aláìní, síbẹ̀ tí ó sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ mọ́ ọn, lọ́nà wo ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run fi dúró nínú rẹ̀?” (1 Jòhánù 3:17) Gbogbo wa la mọ ìdáhùn rẹ̀. Ìfẹ́ Ọlọ́run ló ń mú káwọn èèyàn máa hùwà ọ̀làwọ́. Ọlọ́run mọyì àwọn tó ń ṣe bíi tirẹ̀ fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn, ó sì ń pín èrè fún wọn. (Òwe 22:9; 2 Kọ́ríńtì 9:6-11) Ǹjẹ́ a máa ń rí irú ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yìí lónìí? Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀kan lára ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu àìpẹ́ yìí yẹ̀ wò.

Ilé ìyá arúgbó kan tó jẹ́ Kristẹni nílò àtúnṣe gidi gan-an. Òun nìkan ló ń dá gbé, kò sì ní mọ̀lẹ́bí kankan tó lè ràn án lọ́wọ́. Ó ti pẹ́ táwọn ará ti máa ń ṣe ìpàdé Kristẹni nílé rẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń ṣoúnjẹ fún ẹnikẹ́ni tó bá tẹ́wọ́ gba ìkésíni rẹ̀. (Ìṣe 16:14, 15, 40) Nígbà tí wọ́n rí ìṣòro tó ní, gbogbo àwọn ará ìjọ náà ló kọ́wọ́ tì í lẹ́yìn. Àwọn kan fowó sílẹ̀, àwọn mìíràn sì ṣe iṣẹ́ àṣekára. Láàárín àwọn òpin ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn wọ̀nyí fi páànù tuntun kan ilé náà, wọ́n ṣe balùwẹ̀ tuntun, wọ́n rẹ́ ẹ, wọ́n sì kun gbogbo àjà kìíní, wọ́n tún ṣe àwọn àpótí ìkó-ǹkan-sí tuntun sí ilé ìdáná. Kì í ṣe pé àbájáde fífúnni wọn yìí wulẹ̀ yanjú ìṣòro obìnrin náà nìkan ni, àmọ́ ó tún jẹ́ káwọn ará ìjọ náà túbọ̀ mojú ara wọn sí i, ó sì tún jẹ́ káwọn aládùúgbò rí àpẹẹrẹ fífúnni tó jẹ́ ti Kristẹni tòótọ́.

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ǹjẹ́ a lè lo àkókò díẹ̀ lọ́dọ̀ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí kò ní bàbá? Ǹjẹ́ a lè lọ bá ìyá arúgbó kan tó jẹ́ opó tó sì jẹ́ ẹni mímọ̀ wa ra nǹkan tàbí ká bá a ránṣọ? Ǹjẹ́ a lè ṣoúnjẹ fún ẹnì kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ tàbí ká fún un lówó? Kò dìgbà tá a bá di olówó rẹpẹtẹ ká tó lè ṣèrànwọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ìmúratán bá kọ́kọ́ wà, ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn kò ní.” (2 Kọ́ríńtì 8:12) Àmọ́, ṣé kìkì irú títani lọ́rẹ tààràtà bẹ́ẹ̀ nìkan ni Ọlọ́run ń bù kún? Rárá o.

Ìrànlọ́wọ́ Tá A Ṣètò Wá Ńkọ́?

Àwọn ìgbà mìíràn wà tí dídánìkan tani lọ́rẹ kì í tó. Kódà, àpò kan náà ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń dáwó sí fún àwọn òtòṣì, wọ́n sì tún máa ń gba ọrẹ lọ́wọ́ àwọn aláàánú èèyàn tí wọ́n ń bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. (Jòhánù 12:6; 13:29) Bákan náà ni ìjọ ọ̀rúndún kìíní kówó jọ nígbà tí wọ́n nílò rẹ̀ tí wọ́n sì ṣètò ìpèsè ìrànwọ́ lọ́nà gbígbòòrò.—Ìṣe 2:44, 45; 6:1-3; 1 Tímótì 5:9, 10.

Irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ wáyé ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Tiwa. Àwọn ìjọ tó wà ní Jùdíà wà nínú ipò òṣì, bóyá nítorí ìyàn ńlá tó wáyé láìpẹ́ sí àkókò yẹn. (Ìṣe 11:27-30) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí ọ̀ràn àwọn òtòṣì máa ń ká lára, béèrè ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn ìjọ títí dé ìjọ Makedóníà tó wà lọ́nà jíjìn réré. Òun fúnra rẹ̀ ṣètò ìkówójọ náà ó sì lo àwọn ọkùnrin táwọn èèyàn náà tẹ́wọ́ gbà láti pín àwọn ẹ̀bùn náà. (1 Kọ́ríńtì 16:1-4; Gálátíà 2:10) Kò sí ẹnikẹ́ni tó gba owó ọ̀yà nínú òun àtàwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ yìí.—2 Kọ́ríńtì 8:20, 21.

Bákan náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní máa ń yára láti ṣèrànwọ́ nígbà tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2001, òjò àti ìjì ńlá kan fa omíyalé tí ò ṣeé fẹnu sọ nílùú Houston tó wà ní Texas, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lápapọ̀, ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta [723] ilé tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí ló bà jẹ̀ dé ààyè kan, ọ̀pọ̀ lára wọn sì bà jẹ́ gan-an. Kíá ni wọ́n ṣètò ìgbìmọ̀ olùpèsè ìrànwọ́ tó láwọn Kristẹni alàgbà tó tóótun nínú láti ṣàyẹ̀wò ohun tó jẹ́ àìní olúkúlùkù kí wọ́n sì pín ọrẹ náà láti ṣèrànwọ́ fáwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò náà kó lè rọrùn fún wọn láti kojú ipò tí wọ́n bára wọn, kí wọ́n sì tún àwọn ilé wọn ṣe. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tinútinú látinú àwọn ìjọ tó wà nítòsí ló ṣe gbogbo iṣẹ́ náà. Ẹlẹ́rìí kan mọrírì ìrànwọ́ tí wọ́n ṣe yìí gan-an débi pé nígbà tí ilé iṣẹ́ ìbánigbófò san owó tó máa fi tún ilé rẹ̀ ṣe fún un, ojú ẹsẹ̀ ló fi owó náà tọrẹ sínú àpò àkànlò owó ìrànwọ́ kí wọ́n lè lò ó fáwọn ẹlòmíràn tó nílò ìrànwọ́.

Àmọ́ ṣá o, nígbà tó bá kan ọ̀ràn ọrẹ àánú táwọn èèyàn ṣètò, a gbọ́dọ̀ lo ìṣọ́ra nígbà tá a bá ń ṣàyẹ̀wò ipò olúkúlùkù àwọn èèyàn tí wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ fún owó ìrànlọ́wọ́. Àwọn ẹgbẹ́ aláàánú kan wà tí wọ́n ti ní iye pàtó kan tí wọ́n ṣètò láti máa fi sanwó àwọn òṣìṣẹ́ tàbí láti máa fi polówó iṣẹ́ wọn, tó fi jẹ́ pé owó táṣẹ́rẹ́ ló máa ń ṣẹ́ kù fún wọn láti lò fún ètè táwọn èèyàn tìtorí ẹ̀ ń dáwó sọ́dọ̀ wọn. Òwe 14:15 sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Nítorí náà ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ láti ṣàyẹ̀wò ọ̀ràn náà dáadáa.

Fífúnni Tó Ṣeni Láǹfààní Jù Lọ

Oríṣi fífúnni kan wà tó ṣe pàtàkì gan-an ju ọrẹ àánú lọ. Jésù tọ́ka sí èyí nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ olùṣàkóso béèrè ohun tó yẹ kóun ṣe láti rí ìyè àìnípẹ̀kun lọ́wọ́ rẹ̀. Jésù sọ fún un pé: “Lọ ta àwọn nǹkan ìní rẹ, kí o sì fi fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.” (Mátíù 19:16-22) Ṣàkíyèsí pé Jésù ò wulẹ̀ sọ pé, ‘Ta àwọn òtòṣì lọ́rẹ, ìwọ yóò sì rí ìyè.’ Dípò ìyẹn, ó fi kún un pé, “Wá di ọmọlẹ́yìn mi.” Ohun tó ń sọ ni pé, pẹ̀lú bí títọrẹ àánú ṣe dára tó sì ṣàǹfààní tó, iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn táwọn Kristẹni ń ṣe ṣàǹfààní ju ìyẹn lọ.

Ohun tó ká Jésù lára jù lọ ni ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Nígbà tó kù díẹ̀ kó kú, ó sọ fún Pílátù pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò kẹ̀rẹ̀ nínú ríran àwọn òtòṣì lọ́wọ́, mímú àwọn aláìsàn lára dá, àti bíbọ́ àwọn tí ebi ń pa, síbẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ni olórí ohun tó fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Mátíù 10:7, 8) Àní sẹ́, lára ìtọ́ni tó fún wọn kẹ́yìn ni àṣẹ tó pa fún wọn pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mátíù 28:19, 20.

Lóòótọ́, iṣẹ́ ìwàásù ò lè yanjú gbogbo ìṣòro ayé. Síbẹ̀, sísọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún onírúurú èèyàn ń fi ògo fún Ọlọ́run nítorí pé iṣẹ́ ìwàásù ń mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ, ó sì ń ṣí ọ̀nà àtirí àǹfààní ayérayé sílẹ̀ fáwọn tó bá tẹ́wọ́ gba ìhìn àtọ̀runwá náà. (Jòhánù 17:3; 1 Tímótì 2:3, 4) O ò ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá fẹ́ sọ nígbà tí wọ́n bá tún wá sílé rẹ? Ẹ̀bùn tẹ̀mí ni wọ́n mú wá bá ọ. Wọ́n sì mọ̀ pé ọ̀nà dídára jù lọ táwọn lè gbà fún ọ ní nǹkan rèé.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà fi hàn pé a bìkítà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere náà ń múnú Ọlọ́run dùn, ó sì ń ṣí ọ̀nà àtirí àǹfààní ayérayé sílẹ̀