Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayọ̀ Tí Ò Lẹ́gbẹ́!

Ayọ̀ Tí Ò Lẹ́gbẹ́!

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ayọ̀ Tí Ò Lẹ́gbẹ́!

GẸ́GẸ́ BÍ REGINALD WALLWORK ṢE SỌ Ọ́

“Kò sóhun náà láyé yìí tá a lè fi wé ayọ̀ tá a ní nínú iṣẹ́ alákòókò kíkún sí Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì!” Inú àwọn ìwé ìyàwó mi ni mo ti rí àkọsílẹ̀ yìí lẹ́yìn tó kú ní May 1994.

BÍ MO bá ronú lọ sàà lórí àwọn ọ̀rọ̀ Irene, mo máa ń rántí odidi ọdún mẹ́tàdínlógójì tó fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an, èyí tá a jọ fi ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè Peru. A gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ Kristẹni tó ṣeyebíye gan-an látìgbà tá a ti ṣègbéyàwó ní December 1942—ibí yìí láá dára kí n ti bẹ̀rẹ̀ ìtàn tí mo fẹ́ sọ yìí.

Inú ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n gbé tọ́ Irene dàgbà nílùú Liverpool, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ó jẹ́ ọ̀kan lára ọmọbìnrin mẹ́ta táwọn òbí rẹ̀ bí, bàbá rẹ̀ sì ti kú nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Nígbà tó yá, ìyá rẹ̀ fẹ́ Winton Fraser, ó sì bímọ ọkùnrin kan fún un tó ń jẹ́ Sidney. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, ìdílé wọn ṣí lọ sílùú Bangor, ní North Wales, ibẹ̀ sì ni Irene ti ṣèrìbọmi lọ́dún 1939. Sidney ní tiẹ̀ ti ṣèrìbọmi lọ́dún tó ṣáájú èyí, òun àti Irene sì jọ ń ṣe aṣáájú ọ̀nà—ìyẹn ajíhìnrere alákòókò kíkún—ní etíkun ìhà àríwá Wales, láti Bangor lọ dé Caernarvon, títí kan erékùṣù Anglesey.

Ìjọ Runcorn ni mo wà lákòókò náà, nǹkan bí ogún kìlómítà sí Liverpool ni ibẹ̀, èmi sì ni alábòójútó olùṣalága níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bá a ṣe ń pè é lóde òní. Irene wá bá mi ní àpéjọ àyíká kan ó sì sọ pé kí n fún òun láwọn ìpínlẹ̀ bíi mélòó kan tóun á ti máa wàásù nítorí pé òun á lo ọjọ́ bíi mélòó kan lọ́dọ̀ Vera, ìyẹn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó ti lọ́kọ tó ń gbé nílùú Runcorn. Ọ̀rẹ́ èmi àti Irene wọ̀ gan-an láàárín ọ̀sẹ̀ méjì tó fi wà pẹ̀lú wa yẹn, èmi náà sì máa ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ dáadáa ní Bangor nígbà tó yá. Ṣé ẹ rí i, béèyàn gẹṣin nínú mi kò lè kọsẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀ kan báyìí tí Irene gbà pé òun á fẹ́ mi!

Ní wéré tí mo délé lọ́jọ́ Sunday báyìí ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò fún ìgbéyàwó wa, àmọ́ mo gba wáyà kan látọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́jọ́ Tuesday. Ọ̀rọ̀ inú wáyà náà kà pé: “Mo mọ̀ pé wáyà yìí máa dùn ẹ́ gan-an, àmọ́ dákun máà bínú. Mo ti fagi lé ìgbéyàwó wa o. Wàá rí àlàyé kíkún nínú lẹ́tà ti mo kọ ránṣẹ́ sí ọ.” Ńṣe ni orí mi kọ́kọ́ laago. Kí ló lè fa irú èyí?

Lẹ́tà Irene tẹ̀ mí lọ́wọ́ lọ́jọ́ kejì. Ó sọ fún mi pé òun ń lọ sílùú Horsforth ní Yorkshire láti lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú Hilda Padgett. a Ó ṣàlàyé pé ní ọdún kan sẹ́yìn òun ti gbà láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ tí wọ́n bá ké sí òun láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Ńṣe lèyí dà bí ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún Jèhófà lójú mi, nígbà tó sì jẹ́ pé mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ náà fún un kí n tó mọ̀ ẹ́, ó ti di dandan kí n san ẹ̀jẹ́ mi.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú mi bà jẹ́, àmọ́ ìdúróṣinṣin rẹ̀ wú mi lórí gan-an. Lèmi náà bá gbá a ní wáyà padà pé: “Máa lọ. Màá dúró dè ẹ́.”

Nígbà tí Irene wà ní Yorkshire, wọ́n ní kó lọ fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta gbára nítorí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò jẹ́ kó ṣètìlẹ́yìn fún ogun. Àmọ́ ọdún kan àbọ̀ lẹ́yìn náà la ṣègbéyàwó, ìyẹn ní December 1942.

Ìgbà Èwe Mi

Lọ́dún 1919, màmá mi ra ìdìpọ̀ ìwé Studies in the Scriptures. b Bó tiẹ̀ jẹ́ pe bí bàbá ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ nígbà náà ló rí, pé Màmá ò tíì ka ìwé kankan rí, àmọ́ ó pinnu láti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé náà pẹ̀lú Bíbélì rẹ̀. Ó kúkú ṣe bẹ́ẹ̀ ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1920.

Bàbá mi ní tiẹ̀ kì í ṣèèyàn tó le koko, ó sì gba màmá mi láyè láti ṣe ohunkóhun tó bá wù ú, títí kan títọ́ ọmọ wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin—àǹtí mi méjì, ìyẹn Gwen àti Ivy; ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin Alec; àtèmi—ní ọ̀nà òtítọ́. Stanley Rogers àtàwọn Ẹlẹ́rìí adúróṣinṣin mìíràn ní Liverpool rìnrìn àjò lọ sí Runcorn láti lọ sọ àsọyé Bíbélì níbẹ̀, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi dá ìjọ tuntun sílẹ̀ níbẹ̀. Ìdílé wa ń ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí nínú ìjọ náà.

Gwen ń kẹ́kọ̀ọ́ tó fi máa gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ ní Ìjọ Áńgílíkà, àmọ́ ní wéré tóun àti Màmá bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló pa ìyẹn tì. Nígbà tí àlùfáà wá sílé wa láti mọ ohun tó fà á tí ò fi wá kẹ́kọ̀ọ́ náà mọ́, ńṣe la da ìbéèrè bò ó lọ́tùn-ún lósì, kò sì lè dáhùn wọn. Gwen béèrè ìtumọ̀ Àdúrà Olúwa lọ́wọ́ rẹ̀ àmọ́ ọ̀rọ̀ pèsì jẹ, ló bá kúkú ṣàlàyé rẹ̀ fún àlùfáà yìí! Ìwé 1 Kọ́ríńtì 10:21 ló fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fi yé àlùfáà náà pé ó tó gẹ́ẹ́ pé òun ò lè máa ‘jẹun lórí tábìlì méjì’ mọ́. Nígbà tí àlùfáà yìí kúrò nílé wa, ó sọ pé òun á lọ gbàdúrà fún Gwen pé òun á sì padà wá dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀, àmọ́ ọlọ́gbẹ̀ẹ́ni yìí ò padà wá mọ́. Kété tí Gwen ṣèrìbọmi ló di ajíhìnrere alákòókò kíkún.

Ọ̀nà tí wọ́n gbà ń bójú tó àwọn ọ̀dọ́ nínú ìjọ wa ṣàrà ọ̀tọ̀. Mo ṣì rántí àsọyé kan tí alàgbà kan láti ìjọ mìíràn wá sọ níjọ wa nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje. Lẹ́yìn àsọyé náà, ó wá bá mi sọ̀rọ̀. Mo sọ fún un pé mo ti ń kà nípa ìtàn Ábúráhámù àti bó ṣe fẹ́ fi ọmọ rẹ̀ Ísáákì rúbọ. Ló bá sọ fún mi pé: “Lọ́ sórí pèpéle kó o sì sọ ìtàn náà fún mi.” Inú mi dùn gan-an bí mo ṣe wà lórí pèpéle tí mo sì sọ “àsọyé fún gbogbo ènìyàn” fúngbà àkọ́kọ́!

Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni mí nígbà tí mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1931, ọdún yẹn sì ni màmá mi kú. Bí mi ò ṣe lè lọ sílé ìwé mọ́ nìyẹn tí mo wá bẹ̀rẹ̀ sí lọ kọ́ṣẹ́ àwọn tó ń ṣe iná mànàmáná. Ẹ̀rọ giramafóònù ni wọ́n fi máa ń lu àwọn àwo àsọyé Bíbélì fáwọn èèyàn láti gbọ́ lọ́dún 1936, arábìnrin àgbàlagbà kan sì gba èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin níyànjú pé ká lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò yìí. Lèmi àti Alec bá forí lé Liverpool láti lọ ra kẹ̀kẹ́ ká sì kan ilé sí ẹ̀yìn rẹ̀ ká lè ríbi gbé ẹ̀rọ giramafóònù wa sí. A gbé ẹ̀rọ gbohùngbohùn kan kọ́ sára ilé ẹ̀yìn kẹ̀kẹ́ náà tó ga tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà. Ọ̀gbẹ́ni tó kan ilé sẹ́yìn kẹ̀kẹ́ náà sọ pé òun ò tíì ṣe irú iṣẹ́ náà rí, àmọ́ ó ṣe é dáadáa! Pẹ̀lú ìtara la fi wàásù kárí ìpínlẹ̀ wa, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ arábìnrin tó gbà wá níyànjú láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí bẹ́ẹ̀ la mọrírì àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n fún wa.

Ogun Àgbáyé Kejì—Àkókò Ìdánwò

Bá a ṣe ń gbọ́ hùnrùn-hùnrùn lọ́tùn-ún lósì pé ogun fẹ́ bẹ̀rẹ̀ lèmi àti Stanley Rogers bẹ̀rẹ̀ sí polongo àsọyé ní gbangba tá a fẹ́ sọ ní Gbọ̀ngàn Royal Albert tìlú London ní September 11, 1938. Àkọlé àsọyé náà ni “Ẹ Gbọ́ Òótọ́ Ọ̀rọ̀.” Nígbà tó yá, èmi náà bá wọn pín ìwé pẹlẹbẹ tá a kọ àsọyé yìí sínú rẹ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ mìíràn tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Fascism or Freedom tá a tẹ̀ jáde lọ́dún tó tẹ̀ lé e fáwọn èèyàn. Ìwé pẹlẹbẹ méjèèjì tú àṣírí ìjọba oníkùmọ̀ ti Hitler ní Jámánì. Ní gbogbo àkókò yìí, iṣẹ́ ìwàásù tí mò ń ṣe ti jẹ́ kí tọmọdé tàgbà mọ̀ mí bí ẹni mowó nílùú Runcorn, wọ́n sì máa ń fi ọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí. Àní sẹ́, mímú tí mo máa ń mú ipò iwájú nínú ìgbòkègbodò ìjọba Ọlọ́run mú kí n wúlò fáwọn èèyàn nígbà tó yá.

Ilé iṣẹ́ tí mo ti ń ṣiṣẹ́ gba iṣẹ́ kan láti so àwọn èèlò iná mànàmáná sí ilé iṣẹ́ tuntun kan tí wọ́n kọ́ sí ìkángun ìlú náà. Nígbà tí mo wádìí tí mo sì rí i pé ohun èèlò ogun ni wọ́n fẹ́ máa ṣe ní ilé iṣẹ́ yìí, mo sọ fún wọn pé mi ò lè ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ní tèmi o. Èyí kò dùn mọ́ àwọn ọ̀gá pátápátá nínú àmọ́ ọ̀gá tó ń kó wa ṣiṣẹ́ bá mi bá wọn sọ̀rọ̀ wọ́n sì fún mi níṣẹ́ mìíràn. Ìgbà tó ṣe ni mó wá mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ̀kan lára mọ̀lẹ́bí ọ̀gá tó ń kó wa ṣiṣẹ́ náà.

Ọ̀rọ̀ tí ọ̀kan lára àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ sọ fún mi níṣìírí gan-an, ó sọ pé: “Ohun tá a retí pé kó o ṣe gan-an lo ṣe yẹn Reg, nítorí ọjọ́ ti pẹ́ tó o ti wà lẹ́nu iṣẹ́ Bíbélì yìí.” Síbẹ̀, ńṣe ni mò ń ṣọ́ ara mi dáadáa nítorí pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ló fẹ́ kó mi sí yọ́ọ́yọ́ọ́.

Kóòtù tó wà ní Liverpool fọwọ́ sí bí mo ṣe forúkọ sílẹ̀ ní June 1940 pé ẹ̀rí ọkàn mi ò gbà kí n ṣiṣẹ́ ológun, àmọ́ wọ́n sọ pé mi ò gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ tí mò ń ṣe sílẹ̀. Èyí sì fún mi láǹfààní láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni mi lọ ní rabidun.

Mo Bọ́ Sẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún

Nígbà tí ogun náà ń lọ sópin, mo fi iṣẹ́ mi sílẹ̀ mo sì lọ dara pọ̀ mọ́ Irene lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Lọ́dún 1946, mo kan ọkọ̀ kan tó ga tó ẹsẹ̀ bàtà méjìdínlógún inú rẹ̀ la sì ń gbé, lọ́dún tó tẹ̀ lé e wọ́n sọ pé ká ṣí lọ sí abúlé Alveston tó wà ní Gloucestershire. Lẹ́yìn náà la ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ìlú Cirencester àti ìlú Bath. Nígbà tó di ọdún 1951, wọ́n sọ mí di alábòójútó arìnrìn àjò pé kí n máa bẹ àwọn ìjọ wò níhà gúúsù Wales, àmọ́ kò tó ọdún méjì sígbà náà tá a fi lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead láti lọ gba ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ míṣọ́nnárì.

South Lansing tó wà níhà àríwá New York ni wọ́n ti ṣe kíláàsì kọkànlélógún ilé ẹ̀kọ́ náà, a sì ṣayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ní Àpéjọ New World Society [Ẹgbẹ́ Ayé Tuntun] tá a ṣe ní Ìlú New York lọ́dún 1953. Ọjọ́ tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege lèmi àti Irene tó mọ ibi tí wọ́n á yàn wá sí. Inú wa dùn gan-an nígbà tí wọ́n sọ fún wa pé orílẹ̀-èdè Peru là ń lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó ti lé lọ́dún kan tí Sidney Fraser tó jẹ́ ọbàkan Irene, àti ìyàwó rẹ̀ Margaret, ti ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà ní Lima lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kọkàndínlógún Gílíádì!

Bá a ṣe ń dúró dìgbà tá a máa rí ìwé àṣẹ ìwọ̀lú gbà, a fi àkókò díẹ̀ ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn, kò sì pẹ́ tá a fi gbọ̀nà Lima. Ìlú Callao ni ibi àkọ́kọ́ nínú ibi mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a ti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì, ibẹ̀ ni ibùdókọ̀ ojú omi ní orílẹ̀-èdè Peru, apá ìwọ̀ oòrùn Lima ló sì wà. Òótọ́ lèmi àti Irene gbọ́ tá-tà-tá nínú èdè Spanish, àmọ́ kò tíì yọ̀ mọ́ wa lẹ́nu lákòókò náà. Báwo la ṣe máa wá ṣiṣẹ́ wa báyìí?

Àwọn Ìṣòro Àtàwọn Àǹfààní Inú Iṣẹ́ Ìwàásù

Wọ́n kọ́ wa ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì pé ìyá kì í kọ́ ọmọ rẹ̀ lédè. Àmọ́ fúnra ọmọ ló máa kọ́ èdè náà nígbà tí ìyá rẹ̀ bá ń sọ ọ́ sí i. Ìmọ̀ràn tí wọ́n wá gbà wá ni pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ jáfara rárá láti máa lọ wàásù, ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tẹ́ ẹ máa bá pàdé lẹ ti máa kọ́ èdè náà. Wọ́n á ràn yín lọ́wọ́.” Ibi tí mo gbé ń sapá láti borí ìṣòro èdè tuntun yìí ni wọ́n ti tún yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága Ìjọ Callao láàárín ọ̀sẹ̀ méjì péré tá a débẹ̀, fojú inú wo bí èyí á ṣe rí lára mi! Mo lọ sọ́dọ̀ Sidney Fraser, àmọ́ ìmọ̀ràn kan náà tí wọ́n fún wa ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì lòun náà tún fún mi, ìyẹn ni pé kí n sún mọ́ àwọn ará nínú ìjọ àtàwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ náà. Mo pinnu pé màá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí.

Láàárọ̀ ọjọ́ Sátidé kan, mo bá káfíńtà kan ní ṣọ́ọ̀bù rẹ̀. Ó sọ pé: “Mi ò lè dá iṣẹ́ tí mò ń ṣe dúró o, àmọ́ jọ̀ọ́ wábi fìdí lé kó o máa sọ̀rọ̀ rẹ ǹṣó.” Mo sọ fún un pé màá ṣe bẹ́ẹ̀ kìkì tó bá gbà láti ṣe ohun kan fún mi: “Bí mo bá ti ṣi ọ̀rọ̀ kan sọ, jọ̀wọ́ sọ fún mi bó ṣe yẹ kí n sọ ọ́. Mi ò ní bínú rárá.” Ńṣe ló bú sẹ́rìn-ín tó sì sọ pé kò sí wàhálà nínú ìyẹn. Mo máa ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ mo sì rí i pé ọ̀nà tó gbéṣẹ́ gan-an rèé láti mọ èdè tuntun náà dáadáa gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ fún mi tẹ́lẹ̀.

Nígbà tá a dé ìlú Ica, ìyẹn ibì kejì tá a ti ṣe míṣọ́nnárì, mo tún bá káfíńtà mìíràn pàdé, mo yáa ṣàlàyé ètò tí mo ṣe nígbà tí mo wà ní Callao fún un. Òun náà gbà láti máa kọ́ mi lédè náà, èdè Spanish sì tipa báyìí bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ mọ́ mi lẹ́nu àmọ́ ó gba odidi ọdún mẹ́ta gbáko kí n tó di ìjìmì nínú èdè náà. Ọwọ́ ọkùnrin yìí máa ń dí gan-an, àmọ́ mo máa ń dọ́gbọ́n kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa kíka Ìwé Mímọ́ fún un tí màá sì wá ṣàlàyé ìtumọ̀ rẹ̀. Lọ́jọ́ kan tí mo wá a lọ, ọ̀gá rẹ̀ sọ fún mi pé ó ti kúrò níbẹ̀ pé ó ti ríṣẹ́ tuntun ní Lima. Nígbà tó ṣe tí èmi àti Irene lọ sí àpéjọ àgbègbè ní Lima, mo tún rí ọ̀gbẹ́ni yìí. Inú mi dùn gan-an pé ọ̀gbẹ́ni yìí ti kàn sáwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú náà láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ, òun àti ìdílé rẹ̀ sì ti di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣèyàsímímọ́!

Nínú ìjọ kan, a rí ọkùnrin kan tó ń gbé pẹ̀lú obìnrin kan láìjẹ́ pé wọ́n ti ṣègbéyàwó, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn méjèèjì ti ṣèrìbọmi. A ṣàlàyé àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́ nípa ọ̀ràn náà fún wọn, wọ́n sì pinnu láti lọ fìdí ìgbéyàwó wọn múlẹ̀ lábẹ́ òfin, èyí ló sì máa jẹ́ kí wọ́n di Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi lóòótọ́. Ni mo bá ṣètò láti bá wọn lọ sí gbọ̀ngàn ìlú náà láti lọ fìdí ìgbéyàwó wọn múlẹ̀. Àmọ́ ìṣòro tó wá jẹ yọ ni pé wọ́n ti bímọ mẹ́rin, wọn ò sì tíì forúkọ àwọn ọmọ náà sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba, bẹ́ẹ̀ sì rèé òfin béèrè pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀rú bẹ̀rẹ̀ sí bà wá nítorí pé a ò mọ ohun tí olórí ìlú náà máa ṣe. Àmọ́ ohun tó sọ ni pé: “Nítorí pé àwọn ẹni bí ẹni èèyàn bí èèyàn yìí, ìyẹn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ yìí ṣètò pé o gbọ́dọ̀ wá fìdí ìgbéyàwó rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin, mi ò ní jáwèé tó yẹ kí n já fún ẹ nítorí pé o kọ̀ láti forúkọ ọmọ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ tẹ́lẹ̀, màá forúkọ gbogbo wọn sílẹ̀ láìgba kọ́bọ̀ lọ́wọ́ ẹ.” Èyí múnú wa dùn gan-an nítorí ìdílé yìí ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ wàhálà ńlá sì ni ì bá jẹ́ ká ní wọ́n bu owó fún wọn láti san!

Nígbà tó ṣe, Albert D. Schroeder wá bẹ̀ wá wò láti orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, ó sì dábàá pé ká dá ilé míṣọ́nnárì mìíràn sílẹ̀ ní apá ibòmíràn ní Lima. Ní èmi àti Irene, àtàwọn arábìnrin méjì mìíràn ìyẹn Frances àti Elizabeth Good láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àti tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ Kánádà bá ṣí lọ sí àgbègbè San Borja. Láàárín ọdún méjì sí mẹ́ta, a ti dá ìjọ mìíràn tó ń ṣe dáadáa sílẹ̀ níbẹ̀.

A tún sìn nílùú Huancayo, tó lé ní nǹkan bí ẹgbàárùn-ún [10,000] ẹsẹ̀ bàtà láàárín gbùngbùn àwọn àgbègbè olókè, a sì dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó wà níbẹ̀ tó ní ọgọ́rin Ẹlẹ́rìí nínú. Ibẹ̀ ni mo ti lọ́wọ́ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kejì tá a kọ́ ní orílẹ̀-èdè náà. Wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí aṣojú nípa ọ̀ràn òfin fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nítorí pé ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la lọ sí kóòtù láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin pé àwa la nilẹ̀ tá a rà. Irú àwọn ìgbésẹ̀ báwọ̀nyí, àti iṣẹ́ fífi taratara sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn tí ọ̀pọ̀ àwọn míṣọ́nnárì olóòótọ́ ṣe láwọn àkókò wọ̀nyẹn, ló fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ fún ìbísí ńláǹlà tá à ń rí báyìí ní orílẹ̀-èdè Peru—látorí ọ̀rìnlénígba ó lé mẹ́ta [283] Ẹlẹ́rìí lọ́dún 1953 sórí iye tó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́rin ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dógún [83,000] lónìí.

Ó Dùn Wá Pé Ìlọ Yá

A gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ aládùn tá a ní pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì bíi tiwa ní gbogbo ilé míṣọ́nnárì tá a gbé, mo sì sábà máa ń láǹfààní láti jẹ́ alábòójútó àwọn ilé náà. A máa ń kóra jọ pọ̀ ní gbogbo àárọ̀ ọjọ́ Monday láti jíròrò nípa ìgbòkègbodò wa fún ọ̀sẹ̀ náà, àá sì yanṣẹ́ bíbójútó ilé náà fúnra wa. Gbogbo wa ló mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù ni olórí iṣẹ́ tá a yàn fún wa, a sì fi ìṣọ̀kan ṣiṣẹ́ pọ̀ láti bá góńgó yìí. Inú mi ń dùn bí mo ṣe ń rántí pé a ò fìgbà kan ní awuyewuye lílágbára láàárín ara wa.

Ìlú Breña la ti sìn gbẹ̀yìn, ìgbèríko Lima lòun náà wà. Kíá ni ìjọ ibẹ̀ tó ní àádọ́rin Ẹlẹ́rìí nínú gbèrú tí iye wọ́n fi lé ní ọgọ́rùn-ún, tó sì di pé ká dá ìjọ mìíràn sílẹ̀ ní Palominia. Àsìkò yìí ni Irene bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìsàn. Mo kọ́kọ́ kíyè sí i pé ìgbà kọ̀ọ̀kan wà tó máa ń gbàgbé ohun tó sọ, ó sì máa ń ṣòro fún un láti mọ̀nà tó máa gbà padà wálé nígbà míì. Ó rí ìtọ́jú tó jíire gbà o, àmọ́ ńṣe ni àìsàn rẹ̀ ń le sí i.

Ó dùn mi gan-an pé ní 1990, ó di dandan pé kí n ṣètò bá a ṣe máa padà sílé ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, arábìnrin mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ivy sì gbà wá sílé rẹ̀. Ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà ni Irene dolóògbè lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin. Mo ṣì ń bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ, mò ń sìn bí alàgbà nínú ọ̀kan lára ìjọ mẹ́ta tó wà nílùú mi. Mo tún máa ń lọ sílùú Manchester lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti lọ fún àwùjọ tó ń sọ èdè Spanish níbẹ̀ níṣìírí.

Mo ní ìrírí amọ́kànyọ̀ kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àmọ́ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ló ti bẹ̀rẹ̀ ìyẹn nígbà tí mo lu àwo tí àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún wà nínú rẹ̀ sétìgbọ̀ọ́ onílé kan. Mo ṣì rántí dáadáa pé ọmọbìnrin kékeré kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìyá rẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà, tó ń gbọ́ àsọyé náà.

Nígbà tó yá, ọmọbìnrin náà ṣí lọ sí Kánádà, àmọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó ń gbé nílùú Runcorn tó sì ti di Ẹlẹ́rìí báyìí ṣì máa ń kọ lẹ́tà sí i. Ọmọbìnrin náà kọ̀wé lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé àwọn Ẹlẹ́rìí méjì wá wàásù fóun wọ́n sì lo àwọn gbólóhùn kan tó mú kóun rántí nǹkan tóun gbọ́ nínú àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún ìgbà yẹn. Ó wá rí i pé òtítọ́ náà rèé, ó sì ti di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣèyàsímímọ́ báyìí, ó ní kí wọ́n bá òun dúpẹ́ lọ́wọ́ ọkùnrin tó wá wàásù fún màmá òun lóhun tó lé ní ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn! Lóòótọ́, a ò mọ ibi tí irúgbìn òtítọ́ náà ti lè fìdí múlẹ̀ kó sì hù dáadáa.—Oníwàásù 11:6.

Ṣẹ́ ẹ rí i, ńṣe ni inú mi máa ń dùn tí mo bá bojú wẹ̀yìn wo bí mo ṣe lo ìgbésí ayé mi nínu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tó ṣeyebíye. Látìgbà tí mo ti ṣèyàsímímọ́ lọ́dún 1931, mi ò tíì pa àpéjọ kankan tó jẹ́ ti àwa èèyàn Jèhófà jẹ rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi àti Irene ò ní ọmọ tá a fúnra wa bí, síbẹ̀ inú mi dùn pé ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin tá a ní nípa tẹ̀mí lé ní àádọ́jọ, gbogbo wọn ló sì ń sin Jèhófà tí í ṣe Bàbá wa ọ̀run. Bí aya mi ọ̀wọ́n ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí pé ìdùnnú tí ò lẹ́gbẹ́ ni àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ti ní.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìtàn ìgbésí ayé Hilda Padgett tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Títẹ̀ Lé Ipasẹ̀ Àwọn Òbí Mi,” wà nínú Ilé Ìṣọ́nà October 1, 1995, ojú ìwé 19 sí 24.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Màmá rèé níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1900

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Apá òsì: Hilda Padgett, èmi, Irene, àti Joyce Rowley nílùú Leeds, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1940

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Òkè pátápátá: Èmi àti Irene níwájú ilé alágbèérìn wa lọ́dún 1943

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

A ń polongo àsọyé fún gbogbo èèyàn nílùú Cardiff, ní Wales lọ́dún 1952