Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Owó Táwọn Èèyàn Fi Ń Ṣètọrẹ Àánú?

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Owó Táwọn Èèyàn Fi Ń Ṣètọrẹ Àánú?

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Owó Táwọn Èèyàn Fi Ń Ṣètọrẹ Àánú?

LẸ́YÌN ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó wáyé ní September 11, 2001, nílùú New York City àti ìlú Washington, D.C., àwọn èèyàn dáwó tó pọ̀ gan-an láti fi ṣèrànwọ́ fáwọn tí ọ̀ràn ìbànújẹ́ náà kàn. Owó tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù mẹ́ta dọ́là làwọn èèyàn dá fún àwọn ẹgbẹ́ aláàánú pé kí wọ́n fi ṣèrànwọ́ fáwọn mọ̀lẹ́bí àwọn tó ko àgbákò náà. Nítorí bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe bani nínú jẹ́ tó, àwọn èèyàn láti ibi gbogbo ló múra tán láti ṣèrànwọ́.

Àmọ́, ó dun àwọn kan gan-an nígbà tí wọ́n wá gbọ́ pé àwọn ẹgbẹ́ aláàánú kan táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó kò ná owó náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Inú bí àwọn èèyàn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn pé ẹgbẹ́ aláàánú kan tó gbajúmọ̀ gan-an pinnu àtikó ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà [546] mílíọ̀nù dọ́là táwọn èèyàn dá pa mọ́, kó lè lò ó fún ète mìíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ náà wá tún ìpinnu rẹ̀ ṣe, ó sì tọrọ àforíjì, síbẹ̀ obìnrin oníròyìn kan sọ pé: “Ojú táwọn tó máa ń ṣe lámèyítọ́ fi wo ìpinnu tí wọ́n tún ṣe yìí ni pé ẹ̀pa ò bóró mọ́, àwọn èèyàn ò tún lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹgbẹ́ náà” bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ìwọ náà ńkọ́? Ṣé ìgbẹ́kẹ̀lé tó o ní nínú ẹgbẹ́ aláàánú ti dín kù sí ti tẹ́lẹ̀?

Ṣé Ìrànlọ́wọ́ Ni àbí Òfò?

Ìwà ọmọlúàbí làwọn èèyàn ka fífún ẹgbẹ́ aláàánú ní nǹkan sí. Àmọ́ gbogbo èèyàn kọ́ ló ń fi irú ojú yẹn wò ó. Ohun tí Samuel Johnson, aláròkọ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, kọ ní ohun tó lé ní igba ọdún sẹ́yìn ni pé: “Ọkàn rẹ á balẹ̀ dáadáa pé ohun rere lò ń ṣe nígbà tó o bá sanwó fáwọn òṣìṣẹ́ nítorí iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ṣe, ju ìgbà tó o bá kàn fowó ṣètọrẹ àánú lásán.” Àwọn kan ní irú èrò kan náà yẹn lóde òní, àwọn ìròyìn tí wọ́n sì ń gbọ́ nípa báwọn ẹgbẹ́ aláàánú ṣe ń lo ọrẹ táwọn èèyàn ń fún wọn síbi tí kò yẹ ò wá jẹ́ káwọn èèyàn nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú wọn mọ́ rárá. Gbé àwọn àpẹẹrẹ méjì tó wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí yẹ̀ wò.

Wọ́n lé olùdarí ẹgbẹ́ aláàánú kan tó jẹ́ táwọn onísìn ní San Francisco kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lẹ́yìn ẹ̀sùn pé ó ní kí ẹgbẹ́ aláàánú tó ń bá ṣiṣẹ́ wá sanwó iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fi ṣàtúnṣe ibi tó dápàá lára rẹ̀ kí wọ́n sì tún san ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] dọ́là tó fi ń jẹun lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún odidi ọdún méjì. Ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìtìjú bá àwọn olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ aláàánú kan tó máa ń polongo ètò rẹ̀ ní ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n lílókìkí kan nígbà tí àṣírí wọ́n tú pé nínú nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là tí wọ́n ní kí wọ́n fi kọ́ àwọn ilé tuntun fún ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí ní Romania, kìkì àwọn ilé hẹ́gẹhẹ̀gẹ méjìlá péré ni wọ́n kọ́ látìgbà náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún dọ́là ni wọ́n ò sì lè ṣàlàyé ibi tí wọ́n ná an sí. Irú àwọn ìròyìn kòbákùngbé bí ìwọ̀nyí tí mú káwọn tó ń ṣètọrẹ àánú túbọ̀ wà lójúfò nípa iye tí wọ́n fi ń tọrẹ àti ẹni tí wọ́n ń kó ọrẹ náà fún.

Ká Máa Ṣètọrẹ àbí Ká Máà Ṣe É

Àmọ́ ṣá o, ohun burúkú gbáà ló máa jẹ́ tá a bá jẹ́ kí ohun táwọn èèyàn kan tàbí àwọn ẹgbẹ́ kan ṣe sọ wá dẹni tí ò bìkítà tí ò sì láàánú àwọn ẹlòmíràn mọ́. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn.” (Jákọ́bù 1:27) Dájúdájú, ṣíṣe aájò àwọn aláìní àtàwọn tí nǹkan ò rọgbọ fún jẹ́ apá pàtàkì kan nínú ìsìn Kristẹni.

Síbẹ̀, o lè máa kọminú pé, ‘Ṣé kí n ṣì máa kó ọrẹ fún ẹgbẹ́ aláàánú ni, àbí kí n wulẹ̀ máa ṣèrànwọ́ nípa fífún àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ ní ọrẹ láyè ara mi?’ Irú ọrẹ wo ni Ọlọ́run retí pé ká máa ṣe? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.