Kíkọ́ Béèyàn Ṣe Ń Lẹ́mìí Ohun-Moní-Tómi
Kíkọ́ Béèyàn Ṣe Ń Lẹ́mìí Ohun-Moní-Tómi
Nínú lẹ́tà ìṣírí kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Fílípì, ó kọ ọ́ pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́, nínú àwọn ipò yòówù tí mo bá wà, láti máa ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi. . . . Nínú ohun gbogbo àti nínú ipò gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó àti bí a ti ń wà nínú ebi, bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu àti bí a ti ń jẹ́ aláìní.”—Fílípì 4:11, 12.
Kí ni àṣírí ẹ̀mí ohun-moní-tómi tí Pọ́ọ̀lù ní? Tá a bá ro ti iye owó ìgbọ́bùkátà tó ń ga sí i àti bí ètò ọrọ̀ ajé ò ṣe dúró sójú kan lákòókò tá a wà yìí, yóò ṣe àwọn Kristẹni tòótọ́ láǹfààní gan-an láti kọ́ béèyàn ṣe ń lẹ́mìí ohun-moní-tómi kí wọ́n lè gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run.
NÍ APÁ ìbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ, ó ṣàpèjúwe irú ẹni tí òun jẹ́ tẹ́lẹ̀. Ó ní: “Bí ènìyàn èyíkéyìí mìíràn bá rò pé òun ní àwọn ìdí fún ìgbọ́kànlé nínú ẹran ara, tèmi tún jù bẹ́ẹ̀: ẹni tí ó dádọ̀dọ́ ní ọjọ́ kẹjọ, láti inú ìlà ìran ìdílé Ísírẹ́lì, láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Hébérù tí a bí láti inú àwọn Hébérù; ní ti òfin, Farisí; ní ti ìtara, mo ń ṣe inúnibíni sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó jẹ́ nípasẹ̀ òfin, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi.” (Fílípì 3:4-6) Láfikún síyẹn, gẹ́gẹ́ bíi Júù tó nítara, Pọ́ọ̀lù tún ní iṣẹ́ kan tó gba àṣẹ rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà tó wà ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì wà lẹ́yìn rẹ̀ gbágbáágbá. Gbogbo èyí fi hàn pé agbára máa tó tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ nínú ètò àwọn Júù ó sì tún máa wà nípò iyì—nínú ọ̀ràn ìṣèlú, ní ti ìsìn, àti nínú ọ̀ran ìṣúnná owó.—Ìṣe 26:10, 12.
Àmọ́ àwọn nǹkan yí padà pátápátá nígbà tí Pọ́ọ̀lù di Kristẹni òjíṣẹ́ tó nítara. Nítorí ìhìn rere náà, ó fínúfíndọ̀ jáwọ́ nínú iṣẹ́ tó ń ṣe jẹun àti nínú gbogbo ohun tó kà sí pàtàkì tẹ́lẹ̀. (Fílípì 3:7, 8) Báwo ló ṣe máa wá gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ báyìí? Ṣé yóò máa gba owó oṣù nídìí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń ṣe ni? Báwo ni yóò ṣe máa rówó ra àwọn ohun tó nílò?
Pọ́ọ̀lù ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láìgba owó ọ̀yà kankan. Kí ó má bàa di ẹrù ìnira fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ fún, ó dara pọ̀ mọ́ Ákúílà àti Pírísílà nínú iṣẹ́ àgọ́ pípa nígbà tó wà ní Kọ́ríńtì, ó sì tún ṣe àwọn nǹkan mìíràn láti gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. (Ìṣe 18:1-3; 1 Tẹsalóníkà 2:9; 2 Tẹsalóníkà 3:8-10) Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò míṣọ́nnárì lọ sáwọn ọ̀nà jíjìn réré, ó sì tún lọ sáwọn ìjọ tó nílò àbẹ̀wò. Kò fi bẹ́ẹ̀ láwọn nǹkan ti ara nítorí pé iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ló gbájú mọ́. Àwọn ará ló sábà máa ń pèsè ohun tó bá nílò fún un. Àmọ́ àwọn ìgbà mìíràn wà tó máa ń wà nínú ipò àìní nítorí ipò nǹkan tí kò fara rọ. (2 Kọ́ríńtì 11:27; Fílípì 4:15-18) Síbẹ̀ náà, Pọ́ọ̀lù ò ṣàròyé nípa ipò tó wà rí, kò sì ṣojú kòkòrò ohun táwọn ẹlòmíràn ní. Tinútinú àti tayọ̀tayọ̀ ló fi ṣiṣẹ́ àṣekára fún àǹfààní àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀. Kódà, Pọ́ọ̀lù lẹni tó ṣàyọlò ọ̀rọ̀ Jésù tí gbogbo èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” Àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá lèyí mà jẹ́ fún gbogbo wa o!—Ìṣe 20:33-35.
Ohun Tí Níní Ẹ̀mí Ohun-Moní-Tómi Túmọ̀ Sí
Olórí ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn ni ẹ̀mí ohun-moní-tómi tó ní. Kí wá ni níní ẹ̀mí ohun-moni-tómi túmọ̀ sí? Láìfọ̀rọ̀gùn, ó tùmọ́ sí níní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémáàní. Tìtorí èyí ni Pọ́ọ̀lù ṣe sọ fún Tímótì tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pé: “Láìsí àní-àní, ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi. Nítorí a kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tímótì 6:6-8.
Ṣàkíyèsí pé Pọ́ọ̀lù so ẹ̀mí ohun-moní-tómi pọ̀ mọ́ ìfọkànsin Ọlọ́run. Ó rí i pé ayọ̀ tòótọ́ máa ń wá látinú ìfọkànsin Ọlọ́run, ìyẹn ni látinú fífi iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run sí ipò kìíní kì í ṣe látinú àwọn ohun ìní ti ara tàbí ọrọ̀. “Ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ” wulẹ̀ jẹ́ ohun tí yóò jẹ́ kí o máa bá a lọ ní lílépa ìfọkànsin Ọlọ́run ni. Nítorí náà, àṣírí ẹ̀mi ohun-moní-tómi tí Pọ́ọ̀lù ní ni pé kéèyàn gbára lé Jèhófà, láìka ipòkípò tó bá wà sí.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣàníyàn lóde òní tí wọn ò sì láyọ̀ nítorí pé wọ́n ò mọ àṣírí yẹn tàbí nítorí pé wọn kò kà á sí. Dípò kí wọ́n ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi, wọ́n yàn láti gbé ìgbẹ́kẹ̀lé wọn karí owó àti ohun téèyàn lè fowó rà. Àwọn ilé iṣẹ́ tó ń polówó ọjà àti ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde 1 Tímótì 6:9, 10.
máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ronú pé kò sí bí wọ́n ṣe lè láyọ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ní àwọn ohun àfiṣọ̀ṣọ́ àti àwọn ẹ̀rọ tó jáde kẹ́yìn—wọ́n sì gbọ́dọ̀ ní wọn lójú ẹsẹ̀. Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi di ẹni tó ń lépa owó àtàwọn nǹkan ìní ti ara ṣáá. Dípò kí wọ́n rí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn, ńṣe ni wọ́n “ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.”—Wọ́n Ti Kọ́ Àṣírí Náà
Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kéèyàn gbé pẹ̀lú ìfọkànsin Ọlọ́run àti ẹ̀mí ohun-moní-tómi, kó sì ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn láyé òde òní? Bẹ́ẹ̀ ni o. Kódà, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ lónìí. Wọ́n ti kọ́ àṣírí níní ayọ̀ pẹ̀lú àwọn nǹkan ti ara tí wọ́n ní. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń sọ, wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọ́n ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn ní ète rẹ̀ níbi gbogbo.
Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn tí wọ́n ti yọ̀ǹda ara wọn láti gba Mátíù 24:14) Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ipò nǹkan ò rọ̀ ṣọ̀mù láwọn ibi tá a rán wọn lọ bíi ti ibi tó ti mọ́ wọn lára. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn míṣọ́nnárì dé sí orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1947, ọṣẹ́ tí ogun ṣe ṣì nípa lórí orílẹ̀-èdè náà gan-an lákòókò yẹn, kìkì àwọn ilé díẹ̀ ló sì ní iná mànàmáná. Ọ̀pọ̀ ilẹ̀ làwọn míṣọ́nnárì ti rí i pé ọ̀kọ̀ọ̀kan làwọn èèyàn máa ń fọ aṣọ wọn lórí ọpọ́n tàbí lórí àwọn okúta tó wà létí odò dípò kí wọ́n lo ẹ̀rọ ìfọṣọ àbánáṣiṣẹ́. Àmọ́ níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òtítọ́ Bíbélì ni wọ́n wá fi kọ́ àwọn èèyàn, wọ́n ti jẹ́ kí ipò àdúgbò náà mọ́ wọn lára, wọ́n sì ń jẹ́ kí ọwọ́ àwọn dí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
ìdálẹ́kọ̀ọ́ ká sì rán wọn jáde gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láwọn ilẹ̀ tó ṣàjèjì sí wọn. (Àwọn mìíràn ti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tàbí kí wọ́n kó lọ sáwọn àgbègbè tí ìhìn rere náà ò tíì dé. Adulfo ti sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún fún ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún ní onírúurú àdúgbò ní Mẹ́síkò. Ó sọ pé: “Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, èmi àti ìyàwó mi ti kọ́ bá a ṣe ń mú kí ipò náà bá wa lára mu. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn ìjọ tá a bẹ̀ wò jìnnà gan-an sí ilú ńlá tàbí ọjà èyíkéyìí. Lásìkò oúnjẹ kọ̀ọ̀kan, ohun táwọn ará máa ń jẹ ni ìṣù búrẹ́dì kan ṣoṣo pẹ̀lú ọ̀rá ẹran díẹ̀ àti iyọ̀ àti ife kọfí kan. Kìkì oúnjẹ tí wọ́n rí jẹ nìyẹn—ìṣù búrẹ́dì mẹ́ta péré lóòjọ́. Àwa náà wá kọ́ láti máa ṣe bíi tàwọn ará náà. Ọ̀pọ̀ ìrírí bí èyí ni mo ti ní láàárín ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta tí mo ti ń sin Jèhófà lákòókò kíkún.”
Florentino rántí bí òun àti ìdílé rẹ̀ ṣe mu ara wọn bá ipò líle koko mu. Nígbà tó ń rántí ìgbà tó wà lọ́mọdé, ó ní: “Oníṣòwò tó rí towó ṣe gan-an ni bàbá mi. Ó ní ilẹ̀ tó pọ̀ gan-an. Mo ṣì rántí káńtà tó wà ní ilé ìtajà wa. Dúrọ́ọ̀ kan wà níbẹ̀ tó fẹ̀ tó àádọ́ta ṣẹ̀ǹtímítà tó sì jìn tó ogún sẹ̀ǹtímítà, ó tún ní ojú mẹ́rin. Ibẹ̀ la máa ń kówó tá a bá pa lójúmọ́ sí. Ńṣe lowó máa ń kúnnu rẹ̀ fọ́fọ́ lójoojúmọ́.
“Lójijì ni gbogbo rẹ̀ yí padà, tí nǹkan ò wá ṣẹnure fún wa mọ́, látorí ọ̀pọ̀ yanturu tá a ní láti wá dẹni tí kò ní ohunkóhun mọ́. Gbogbo nǹkan la pàdánù, àyàfi ilé wa nìkan. Yàtọ̀ síyẹn, ẹgbọ́n mi ọkùnrin tún ṣèṣe nínú jàǹbá ọkọ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì sì rọ. Kò sóhun tó tún rí bíi ti àtẹ̀yìnwá mọ́. Ìgbà kan wà tí mò bẹ̀rẹ̀ sí ta èso àti ẹran. Mò tún máa ń bá wọn kórè òwú, èso àjàrà, àti èso igi alfalfa, mo tún ń bá wọn bomi rin pápá. Àwọn kan tiẹ̀ ń pè mí ní ọ̀nà-kan-ò-wọjà. Màmá mi sábà máa ń tù wá nínú nípa sísọ pé a ní òtítọ́, ọrọ̀ tẹ̀mí sì nìyẹn tó jẹ́ pé àwọn èèyàn díẹ̀ ló ní in. Bí mo ṣe kọ́ béèyàn ṣe ń ní púpọ̀ tó sì tún ń ní díẹ̀ tàbí kó má tiẹ̀ ní ohunkóhun nìyẹn o. Nísinsìnyí tí mo ti fi àkókò kíkún sin Jèhófà fún nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, mo lè sọ pé ojoojúmọ́ ni mò ń rí ìbùkún tó wà nínú mímọ̀ pé mo ti yan ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù—ìyẹn ni ti fífi àkókò kíkún sin Jèhófà.”
Bíbélì là á mọ́lẹ̀ kedere fún wa pé “ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” Nítorí ìdí èyí, ó tún rọ̀ wá pé: “[Kí] àwọn tí ń yọ̀ [dà] bí àwọn tí kò yọ̀, àti àwọn tí ń rà bí àwọn tí kò ní, àti àwọn tí ń lo ayé bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—1 Kọ́ríńtì 7:29-31.
Nítorí náà, ìsinsìnyí gan-an ni àkókò tó yẹ kó o ṣàyẹ̀wò ọ̀nà tó o gbà ń lo ìgbésí ayé rẹ. Bó o bá wà nípò tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, ṣọ́ra kó o má bàa di ẹni tó ń bínú, tó kún fún ìbìnújẹ́ kíkorò àti ìlara. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, nǹkan ìní yòówù tó o lè ní, yóò bọ́gbọ́n mu láti má ṣe kà wọ́n sí bàbàrà ju ibi tí wọ́n mọ lọ kí wọ́n má bàa di ọ̀gá lé ọ lórí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani níyànjú pé kó o má ṣe gbé ìrètí rẹ “lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.” Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ náà á lè sọ pé ó ti kọ́ béèyàn ṣe ń lẹ́mìí ohun-moní-tómi.—1 Tímótì 6:17-19.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Pọ́ọ̀lù fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣiṣẹ́ kó má bàa di ẹrù ìnira sí àwọn ẹlòmíràn lọ́rùn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń rí ayọ̀ nínú ìgbésí ayé “fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi”