Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Àṣà Lásán Ni àbí Rìbá?

Ṣé Àṣà Lásán Ni àbí Rìbá?

Ṣé Àṣà Lásán Ni àbí Rìbá?

OHUN táwọn akẹ́kọ̀ọ́ sábàá máa ń ṣe láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga kan nílẹ̀ Poland ni pé wọ́n á dáwó jọ, wọ́n á wá fi ra ẹ̀bùn lóríṣiríṣi fáwọn olùkọ́ wọn kí wọ́n bàa lè gba máàkì tó jọjú nígbà ìdánwò. Abájọ tí Kristẹni ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Katarzyna ò fi mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì pé: “Ṣé kí n bá wọn dáwó yìí àbí kí n máà dá a? Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kù sọ pé: “Àṣà tó gbòde ni. Kò lè pa ọ́ lára rárá, àti pé èrè ibẹ̀ kúrò ní kékeré, kí wá ló dé tó o fi ń ṣiyèméjì?”

Katarzyna sọ pé: “Lóòótọ́, èmi náà bá wọn dá owó yìí lọ́dún àkọ́kọ́ tí mo wọ ilé ìwé. Ìgbà tó yá ni mo wá rí i pé èmi náà ti lọ́wọ́ nínú rìbá èyí tí Bíbélì kà léèwọ̀.” Ó wá rántí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tó fi hàn pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ sí rìbá rárá. (Diutarónómì 10:17; 16:19; 2 Kíróníkà 19:7) Katarzyna sọ pé: “Mo mọ̀ pé ó rọrùn gan-an láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun táwọn ẹgbẹ́ ẹni ń ṣe. Mo tún ọ̀rọ̀ náà gbé yẹ̀ wò mi ò sì bá wọn lọ́wọ́ nínú àṣà náà mọ́.” Láti nǹkan bí ọdún mẹ́ta báyìí ló ti ń ṣàlàyé fún díẹ̀ lára àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé ìgbàgbọ́ òun tó dá lórí Bíbélì ni kò jẹ́ kóun bá wọn lọ́wọ́ nínú fífúnni ní “ẹ̀bùn” yìí mọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́ gan-an.

Àwọn kan sọ pé ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń bá Katarzyna jà àti pé ńṣe ló ń ya ara rẹ̀ láṣo. Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ èmi àti díẹ̀ lára wọn ò tíì wọ̀ títí dòní olónìí. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn ló fara mọ́ èrò mi lórí ọ̀ràn yìí, èyí sì ń múnú mi dùn.” Àwọn èèyàn wá mọ Katarzyna sí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń pa àwọn ìlànà Bíbélì mọ́ lójoojúmọ́.