Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Lóòótọ́ Ni Àwárí Àwọn Awalẹ̀pìtàn Jẹ́rìí Sí i Pé Jésù Wá Sáyé?

Ṣé Lóòótọ́ Ni Àwárí Àwọn Awalẹ̀pìtàn Jẹ́rìí Sí i Pé Jésù Wá Sáyé?

Ṣé Lóòótọ́ Ni Àwárí Àwọn Awalẹ̀pìtàn Jẹ́rìí Sí i Pé Jésù Wá Sáyé?

“Ẹ̀RÍ Pé Jésù Wá Sáyé Wà Lára Òkúta.” Ohun tí àpilẹ̀kọ inú ìwé Biblical Archaeology Review sọ nìyẹn (ti oṣù November àti December 2002). Wọ́n ya àpótí tí wọ́n fi òkúta ẹfun ṣe tí wọ́n fi ń kó egungun òkú sí, tí wọ́n rí ní Ísírẹ́lì sára èèpo ẹ̀yìn ìwé náà. Àpótí tí wọ́n ń kó egungun òkú sí wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn Júù láàárín ọ̀rúndún kìíní ṣáájú Sànmánì Tiwa àti ọdún 70 Sànmánì Tiwa. Ohun tó mú kí àpótí eléyìí ṣàrà ọ̀tọ̀ ni ohun tí wọ́n fi èdè Árámáíkì kọ sí ẹgbẹ́ kan lára rẹ̀. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ náà kà pé: “Jákọ́bù, ọmọ Jósẹ́fù, arákùnrin Jésù.”

Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, Jésù ti Násárétì ní arákùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jákọ́bù, òun ni wọ́n sì pè ní ọmọ Jósẹ́fù tó jẹ́ ọkọ Màríà. Nígbà tí Jésù Kristi ń kọ́ àwọn èèyàn nílùú òun fúnra rẹ̀, ẹnu ya àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ́n sì béèrè pé: “Èyí ha kọ́ ni ọmọkùnrin káfíńtà náà? Kì í ha ṣe ìyá rẹ̀ ni a ń pè ní Màríà, àti àwọn arákùnrin rẹ̀ Jákọ́bù àti Jósẹ́fù àti Símónì àti Júdásì? Àti àwọn arábìnrin rẹ̀, gbogbo wọn kò ha wà pẹ̀lú wa?”—Mátíù 13:54-56; Lúùkù 4:22; Jòhánù 6:42.

Dájúdájú, ohun tí wọ́n kọ sára àpótí tí wọ́n fi ń kó egungun òkú sí yìí bá bí wọ́n ṣe ṣàpèjúwe Jésù ará Násárétì mu gan-an. Ohun tí André Lemaire, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà nípa àwọn àkọsílẹ̀ àtayébáyé tó sì tún kọ àpilẹ̀kọ tá a dárúkọ lókè nínú ìwé Biblical Archaeology Review, sọ ni pé tó bá ṣẹlẹ̀ pé Jákọ́bù tó jẹ́ iyèkan Jésù Kristi ni èyí tí wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ sára àpótí yìí, a jẹ́ pé òun ló máa jẹ́ “ẹ̀rí tó yàtọ̀ sí tinú Bíbélì tó sì lọ́jọ́ lórí jù lọ tó fi hàn pé Jésù wá sáyé.” Hershel Shanks, tí í ṣe olóòtú ìwé ìròyìn náà sọ pé àpótí tí wọ́n fi ń kó egungun òkú sí yìí “jẹ́ ohun tó ṣe é fọwọ́ kàn tó sì ṣe é fojú rí tó ń tọ́ka sí ẹni pàtàkì kan ṣoṣo tó tíì gbé orí ilẹ̀ ayé rí.”

Àmọ́ ṣá o, gbogbo orúkọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n rí kà lára àpótí tí wọ́n fi ń kó egungun òkú sí náà ló wọ́pọ̀ ní ọ̀rúndún kìíní. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdílé mìíràn wà tó yàtọ̀ sí ti Jésù Kristi, táwọn èèyàn inú ìdílé náà ń jẹ́ Jákọ́bù, Jósẹ́fù àti Jésù. Lemaire fojú bù ú pé: “Ní Jerúsálẹ́mù lákòókò àwọn ìran méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà ṣáájú ọdún 70 Sànmánì Tiwa, kìkì . . . nǹkan bí ogún èèyàn péré ló lè máa jẹ́ ‘Jákọ́bù tàbí Jékọ́bù ọmọ Jósẹ́fù tó jẹ́ arákùnrin Jésù.’” Síbẹ̀, ó ṣì ronú pé àfàìmọ̀ ni Jákọ́bù tí wọ́n kọ sára àpótí náà ò fi ní jẹ́ iyèkan Jésù Kristi.

Ìdí mìíràn wà táwọn kan tún fi gbà gbọ́ pé iyèkan Jésù Kristi ni Jákọ́bù tí wọ́n kọ sára àpótí náà. Kíkọ orúkọ baba ẹnì kan tó ti dolóògbé sára irú àpótí bẹ́ẹ̀ jẹ́ àṣà tó wọ́pọ̀ gan-an, àmọ́ kò wọ́pọ̀ rárá láti dárúkọ arákùnrin olóògbé náà. Ìdí rèé táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan fi gbà gbọ́ pé Jésù tá a rí orúkọ rẹ̀ yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ èèyàn pàtàkì kan, èyí ni wọ́n fi sọ pé Jésù Kristi ló máa jẹ́, ìyẹn ẹni tó dá ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀.

Ṣé Ohun Tó Ṣe É Gbà Gbọ́ Ni Àpótí Náà?

Irú àpótí wo là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí? Àpótí tí wọ́n ń kó egungun òkú sí ni lẹ́yìn tí òkú náà bá ti jẹrà tán nínú kòtò tí wọ́n sin ín sí. Ọ̀pọ̀ irú àwọn àpótí bẹ́ẹ̀ làwọn ẹlẹ́gírí máa ń jí gbé láwọn ibi ìsìnkú tó wà lágbègbè Jerúsálẹ́mù. Ọjà kan báyìí tí wọ́n ti ń ta àwọn ohun àtayébáyé ni wọ́n ti rí àpótí tí orúkọ Jákọ́bù wà lára rẹ̀, kì í ṣe níbì kan tí wọ́n ti ń walẹ̀. Wọ́n sọ pé owó táṣẹ́rẹ́ kan ni ẹni tó ni àpótí náà rà á láwọn ọdún 1970. Ìdí rèé tí ẹnikẹ́ni ò fi tíì mọ orírun àpótí náà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Bruce Chilton tó wà ní Bard College, nílùú New York sọ pé: “Tó ò bá ti lè sọ ibì kan pàtó tí wọ́n ti walẹ̀ rí ohun àtayébáyé kan tó ò sì mọ ibi tó wà fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́yìn, a jẹ́ pé kò sí bó o ṣe lè mọ bí nǹkan náà ṣe tan mọ́ àwọn èèyàn tá a dárúkọ nínú rẹ̀ nìyẹn.

Kí wọ́n lè mọ ìpilẹ̀ṣẹ̀ àpótí náà ló mú kí André Lemaire gbé e lọ sí Ibi Tí Wọ́n Ti Ń Ṣèwádìí Àwárí Àwọn Awalẹ̀pìtàn ní Ísírẹ́lì. Àwọn olùwádìí níbẹ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òkúta ẹfun ni wọ́n fi ṣe àpótí náà ní ọ̀rúndún kìíní sí ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa. Wọ́n sọ pé “kò sí àmì pé àwọn ohun èèlò ìgbàlódé ni wọ́n fi ṣe é.” Síbẹ̀, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ tí ìwé ìròyìn The New York Times fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ èrò wọn jáde pé: “Àwọn ẹ̀rí tó kín ọ̀ràn àpótí náà lẹ́yìn pọ̀ gan-an, síbẹ̀ ẹ̀rí ohun tó ṣẹlẹ̀ lásán ni wọ́n jẹ́.”

Ìwé ìròyìn Time sọ pé “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ọ̀mọ̀wé kankan lóde òní tó máa jiyàn pé Jésù wá sáyé.” Síbẹ̀, àwọn kan ṣì ń sọ pé ó yẹ kí ẹ̀rí mìíràn wà yàtọ̀ sí tinú Bíbélì láti fi hàn pé Jésù wá sáyé. Ṣé àwọn awalẹ̀pìtàn ló yẹ kó jẹ́ olórí ẹ̀rí tá a fi gbà pé Jésù Kristi wá sáyé? Ẹ̀rí wo la ní nípa ìtàn “ẹni pàtàkì kan ṣoṣo tó tíì gbé orí ilẹ̀ ayé rí”?

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Apá òsì, Àpótí tí wọ́n ń kó egungun òkú sí ti James: AFP PHOTO/J.P. Moczulski; apá ọ̀tún, ohun tá a kọ sára rẹ̀: AFP PHOTO/HO