Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣíṣèrànwọ́ fún Àwùjọ Kan Tí Èdè Wọn Yàtọ̀ ní Korea

Ṣíṣèrànwọ́ fún Àwùjọ Kan Tí Èdè Wọn Yàtọ̀ ní Korea

Ṣíṣèrànwọ́ fún Àwùjọ Kan Tí Èdè Wọn Yàtọ̀ ní Korea

ÀWÙJỌ kan tó jẹ́ onítara àmọ́ tó máa ń pa rọ́rọ́ kóra jọ fún àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1997. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí wọ́n ṣètò àpéjọ àgbègbè irú èyí fún àwọn adití ní Korea. Àwọn èèyàn ẹgbẹ̀fà ó dín mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [1,174] ló wá síbẹ̀ lọ́jọ́ térò pọ̀ jù lọ. Gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà—tó ní àsọyé, ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò àti àwòkẹ́kọ̀ọ́ nínú—ni wọ́n ṣe ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Ilẹ̀ Korea, wọ́n sì fi ẹ̀rọ gbé àwọn àwòrán jáde lára ògiri ńlá kan kí gbogbo èèyàn tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà lè rí i. Èyí jẹ́ àbájáde iṣẹ́ àṣekára tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣe.

Àkókò ń bọ̀ nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tí ‘etí àwọn adití yóò ṣí.’ (Aísáyà 35:5) Láti lè gbádùn ìgbésí ayé nínú Párádísè, gbogbo èèyàn pátá títí kan àwọn adití gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ bọ́ sínú Párádísè tẹ̀mí, ìyẹn ipò táwọn nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù nípa tẹ̀mí nínú èyí táwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ aláyọ̀ wà. Wọ́n ní láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣèyàsímímọ́ àti ìrìbọmi, tí Ọlọ́run sì ń fún nítọ̀ọ́ni.—Míkà 4:1-4.

Iye Wọn Ò Tó Nǹkan Níbẹ̀rẹ̀

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn wàásù fáwọn adití wọ̀nyí láwọn ọdún 1960, ìgbà tó di àwọn ọdún 1970 làwọn díẹ̀ nínú wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Seoul tí í ṣe olú ìlú Korea. Kristẹni arákùnrin kan tó máa ń yára kọ̀wé gan-an máa ń kọ àwọn kókó pàtàkì inú àwọn àsọyé sára pátákó kan títí kan àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n kà.

Lọ́dún 1971 nílùú Taejon, Ẹlẹ́rìí kan tí ọmọ rẹ̀ kan dití bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọmọ rẹ̀ yìí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ adití ní ìhìn Ìjọba náà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwùjọ yìí ló wá di òpómúléró báyìí láwọn ìpínlẹ̀ tá a ti ń sọ èdè àwọn adití.—Sekaráyà 4:10.

Àwọn Èwe Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú

Bí àwọn adití bá máa gba ìmọ̀ Jèhófà àti ti Jésù kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ sọ́nà ìyè, àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni gbọ́dọ̀ sapá gan-an. (Jòhánù 17:3) Ìdí rèé tí díẹ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi kọ́ èdè àwọn adití a sì ti fi àwọn ìrírí tó ń gbéni ró bù kún wọn.

Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Park In-sun, pinnu pé òun máa kọ́ èdè àwọn adití lọ́nàkọnà. Kí ó lè mú ìpinnu rẹ̀ yìí ṣẹ, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ṣẹ́ nílé iṣẹ́ kan, ogún èèyàn tó jẹ́ adití ló ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ náà. Odindi oṣù mẹ́jọ gbáko ló fi bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ kó bà a lè kọ́ èdè wọn kó sì lè lóye ọ̀nà táwọn adití gbà ń ronú. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ó di aṣáájú ọ̀nà déédéé, tàbí olùpòkìkí Ìjọba náà déédéé ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwùjọ àwọn adití tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ inú Bíbélì. Iye àwọn èèyàn náà yara ròkè gan-an, kò sì pẹ́ tí iye àwọn tó ń wá sípàdé ọjọ́ Sunday fi lé ní márùndínlógójì.—Sáàmù 110:3.

Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣètò gbogbo àwọn ìpàdé Kristẹni lédè àwọn adití, ìgbà àkọ́kọ́ irú rẹ̀ sì rèé nílùú Seoul. Arákùnrin Park In-sun ń ṣe aṣáájú ọ̀nà àkànṣe láàárín àwùjọ tí iye wọn ń pọ̀ sí i náà. Ó sì ti di ìjìmì nínú èdè àwọn adití báyìí. Láàárín àwọn oṣù kan, ó darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjìdínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú àwọn adití. Ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí ló tẹ̀ síwájú tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Gẹ́gẹ́ bí àbájáde gbogbo iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni yìí, wọ́n dá ìjọ àkọ́kọ́ ní èdè àwọn adití sílẹ̀ ní Seoul ní October 1976, ogójì akéde àti aṣáájú ọ̀nà déédéé méjì ló sì wà níbẹ̀. Èyí wá mú kí ìgbòkègbodò náà tẹ̀ síwájú láwọn ìlú mìíràn ní Korea. Ọ̀pọ̀ àwọn adití mìíràn lebi ìhìn rere náà ń pa tí wọ́n sì ń retí ìgbà tí wọ́n á wá jẹ́rìí fún wọn.

Ṣíṣiṣẹ́ Láàárín Àwọn Adití

O lè máa ṣe kàyéfì nípa ọgbọ́n tí wọ́n ń dá láti rí àwọn adití yìí. Wọ́n kàn sí ọ̀pọ̀ lára wọn nípa bíbéèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Wọ́n tún máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ni ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta ìrẹsì ládùúgbò náà, àwọn yẹn á sì fún wọn lórúkọ àwọn adití àti ibi tí wọ́n ń gbé. Àwọn iléeṣẹ́ ìjọba mìíràn ṣèrànwọ́ láti rí irú àwọn ìsọfúnni wọ̀nyí. Wíwàásù táapọn-táapọn láwọn ìpínlẹ̀ táwọn adití pọ̀ sí gbéṣẹ́ gan-an débi pé bí àkókò ti ń lọ, ìjọ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè àwọn adití la dá sílẹ̀ níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ la tún fún ọ̀pọ̀ Kristẹni ọ̀dọ́ nímọ̀ràn pé kí wọ́n kọ́ èdè àwọn adití.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yan àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe tí wọ́n ti kọ́ èdè àwọn adití láti lọ máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ìjọ náà. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn tá a yàn sáwọn ìjọ wọ̀nyí lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege láti Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti fún wọn lókun gan-an nípa tẹ̀mí.

Àwọn ìṣòro wà láti borí. Sísìn ní irú ìpínlẹ̀ yìí béèrè pé kéèyàn sapá gan-an láti lóye ọ̀nà táwọn adití gbà ń ronú àti bí wọ́n ṣe ń hùwà. Wọn kì í fi dúdú pe funfun nínú èrò àti ìṣe wọn. Èyí lè ya àwọn èèyàn lẹ́nu nígbà míì ó sì lè fa èdè àìyedè. Síwájú sí i, táwọn Ẹlẹ́rìí bá ń bá àwọn adití ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣe pàtàkì kéèyàn jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lóye èdè wọn sí i dáadáa kéèyàn sì tún fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ ìwé kíkà àti ẹ̀kọ́ kíkọ́.

Níbi ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́, àwọn adití máa ń kojú àwọn ìṣòro kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò mọ̀. Bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láwọn ilé iṣẹ́ ìjọba àti ilé ìwòsàn, àti ọ̀ràn káràkátà sábà máa ń fa ìṣòro ńláǹlà fún wọn. Nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí láti àwọn ìjọ tó wà nítòsí ti fi tìfẹ́tìfẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́, àwọn adití ń rí ojúlówó ìfẹ́ tó wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará nínú ìjọ Kristẹni.—Jòhánù 13:34, 35.

Ìjẹ́rìí Aláìjẹ́-bí-Àṣà Ń Méso Jáde

Nílùú Pusan tí í ṣe ìlú tí ọkọ̀ òkun máa ń gúnlẹ̀ sí níhà gúúsù Korea, Ẹlẹ́rìí kan pàdé àwọn adití méjì tó kọ ọ̀rọ̀ kan sínú bébà pé: “Párádísè wù wá. A fẹ́ mọ ìwé mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa ìyè àìnípẹ̀kun.” Arákùnrin náà kọ àdírẹ́sì wọn sílẹ̀ ó sì ṣètò láti lọ bẹ̀ wọ́n wò. Nígbà tó débẹ̀, kìkì àwọn adití ló bá tí wọ́n kúnnú ilé náà tí wọ́n ń retí àtigbọ́ ìhìn Ìjọba náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kí arákùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ èdè àwọn adití. Kò sì pẹ́ tí wọ́n fi dá ìjọ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè adití sílẹ̀ ní Pusan.

Arákùnrin kan nínú ìjọ yẹn rí i táwọn adití méjì ń fi èdè adití bára wọn sọ̀rọ̀ ló bá sún mọ́ wọn. Ó wá rí i pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ibi tí wọ́n ti lọ ṣe ìsìn ni, ló bá ní kí wọ́n wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba láago méjì ọ̀sán ọjọ́ yẹn náà. Wọ́n kúkú wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn méjèèjì lọ sí àpéjọ àgbègbè pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn tí wọ́n jẹ́ adití tí iye wọ́n jẹ́ ogún. Ọ̀pọ̀ ló ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà láàárín àwùjọ yẹn. Méjì lára wọn ti di alàgbà ìjọ ọ̀kan sì ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè adití.

Ìmúratán Ń Mú Èrè Wá

Nítorí pé ibi táwọn adití kan ń gbé jìnnà gan-an sí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè adití, ó sábà máa ń gba ìsapá ńláǹlà àti ìpinnu láti fún wọn ní oúnjẹ aṣaralóore nípa tẹ̀mí látinú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ibi erékùṣù ni ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n ti máa ń pẹja láti gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Ọ̀dọ̀ àbúrò rẹ̀ ọkùnrin táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wàásù fún un ló ti gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Bíbélì. Kí ọkùnrin adití tó jẹ́ apẹja yìí bàa rí oúnjẹ jẹ sí ebi tẹ̀mí tó ń pa á ló mú un fi ọkọ̀ òbèlè rìnrìn àjò kìlómítà mẹ́rìndínlógún lọ sí Ìlú Tongyoung, tó wà ní ìhà gúúsù etíkun Korea. Nítorí àtilọ pàdé aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan látinú ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè adití nílùú Masan ló ṣe ń ṣe èyí o. Lọ́jọọjọ́ Monday ni aṣáájú ọ̀nà àkànṣe yìí máa rìnrìn kìlómítà márùndínláàádọ́rin nítorí àtikọ́ ọ̀gbẹ́ni adití tó jẹ́ apẹja náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Tí ọ̀gbẹ́ni adití yìí bá fẹ́ lọ sípàdé ọjọ́ Sunday nílùú Masan, ó di pé kó fi ọkọ̀ òbèlè rìnrìn kìlómítà mẹ́rìndínlógún, lẹ́yìn náà lá wá wọ mọ́tò fún ìrìn kìlómítà márùndínláàádọ́rin. Ìpinnu rẹ̀ mú èso rere jáde o. Láàárín oṣù bí i mélòó kan, ó ti ń dọ̀gá nínú èdè adití, ó ti mọ àwọn ááfábẹ́ẹ̀tì èdè Korea, èyí tó tiẹ̀ wá ṣe pàtàkì jù lọ níbẹ̀ ni pé ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà kan ṣoṣo náà láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Nígbà tó wá rí i pé lílọ sípàdé àti jíjẹ́rìí déédéé ṣe pàtàkì gan-an, ó ṣí lọ sí ìpínlẹ̀ tí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè adití wà. Ǹjẹ́ ohun tó ṣe yìí rọrùn láti ṣe? Rárá o. Ó di pé kó fi iṣẹ́ ẹja pípa rẹ̀ sílẹ̀ èyí tó máa ń fún un ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó dín igba [3,800] dọ́là lóṣù tẹ́lẹ̀, àmọ́ a bù kún ìpinnu rẹ̀ yìí. Nígbà tó tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́, ó ṣèrìbọmi, tayọ̀tayọ̀ sì lòun àti ìdílé rẹ̀ fi ń sin Jèhófà pa pọ̀ báyìí.

Títúmọ̀ Ìwé Fáwọn Adití

Ọ̀rọ̀ ẹnu la sábà máa ń fi polongo ìhìn rere Ìjọba náà. Àmọ́ ṣá, láti lè sọ ìhìn inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn lọ́nà tó túbọ̀ pé pérépéré, ó ṣe pàtàkì pé káwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì wà lákọọ́lẹ̀. Ìdí rèé táwọn àgbààgbà onírìírí fi kọ àwọn ìwé àtàwọn lẹ́tà ní ọ̀rúndún kìíní. (Ìṣe 15:22-31; Éfésù 3:4; Kólósè 1:2; 4:16) Lákòókò tiwa, a ti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu nípasẹ̀ àwọn ìwé ńlá àtàwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni mìíràn. A ti tú àwọn ìwé yìí sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè, tó fi dórí èdè àwọn adití. Nítorí àtiṣe èyí ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Ilẹ̀ Korea ló mú kí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tó wà níbẹ̀ ní ẹ̀ka kan tí wọ́n ti ń túmọ̀ ìwé sí èdè àwọn adití. Ẹ̀ka tó ń rí sí fídíò ṣe àwọn fídíò jáde lédè àwọn adití. Èyí ń fún àwọn adití tí wọ́n ń polongo ìhìn rere náà àtàwọn olùfìfẹ́hàn nínú gbogbo ìjọ tó wà ní Korea ní ohun agbẹ́mìíró nípa tẹ̀mí.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló ti di ìjìmì nínú èdè àwọn adití tí wọ́n sì ti ṣèrànwọ́ láti ṣe àwọn fídíò jáde, àmọ́ àwọn ọmọ tí òbí wọn jẹ́ adití ló sábàá máa ń jẹ́ olùtumọ̀ tó dára jù lọ. Láti kékeré ni wọ́n ti kọ́ èdè adití. Kì í ṣe pé àwọn wọ̀nyí máa ń sọ èdè àwọn adití lọ́nà tó péye nìkan ni àmọ́ wọ́n tún máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yéni wọ́n sì tún máa ń tẹnu mọ́ ọn nípa fífara ṣàpèjúwe àti nípa ìrísí ojú wọn, èyí á sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà wọni lọ́kàn ṣinṣin.

Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀ lédè àwọn adití lóòrèkóòrè ní Korea. Èyí ń béèrè iṣẹ́ àṣekára, owó àti ọ̀pọ̀ ìsapá kó bà a lè yọrí sí rere. Àmọ́ ṣá o, àwọn tó wá gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà mọrírì ètò yìí púpọ̀ púpọ̀. Lẹ́yìn tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà parí, ọ̀pọ̀ ló ṣì dúró síbi àpéjọ náà fún ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin síwájú sí i kí wọ́n sì tún lè jíròrò àwọn oúnjẹ tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ tí wọ́n ti jẹ. Ó ṣe kedere pé àwọn ìpèníjà wà nínú ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn pẹ̀lú àwùjọ tí èdè wọn yàtọ̀ yìí, àmọ́ ṣá àwọn ìbùkún tẹ̀mí tó wà níbẹ̀ mú kí ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀ kó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn fídíò tá a mú jáde lédè àwọn adití ní Korea: “Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?,” “Mímọrírì Ogún Tẹ̀mí Tá A Ní,” “Àwọn Ohun Àríkọ́gbọ́n fún Wa Lónìí,” àti “Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọlá Àṣẹ Jèhófà”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Nísàlẹ̀ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún: Àwọn fídíò tá a mú jáde lédè àwọn adití ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ní Korea; wíwá àmì fáwọn ọ̀rọ̀ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lò; àwùjọ tó ń ṣe ìtumọ̀ sí èdè àwọn adití; sísọ àwọn àmì tó kàn láti lò fún ẹni tó ń sọ èdè àwọn adití nígbà tá a bá ń ṣe fídíò