Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Wá Ànímọ́ Rere Lára Gbogbo Ènìyàn

Ẹ Máa Wá Ànímọ́ Rere Lára Gbogbo Ènìyàn

Ẹ Máa Wá Ànímọ́ Rere Lára Gbogbo Ènìyàn

“Jọ̀wọ́ Ọlọ́run mi, rántí mi fún rere.”—NEHEMÁYÀ 13:31.

1. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣoore fún gbogbo èèyàn?

 ÌYÍPADÀ amóríyá ló máa ń jẹ́ nígbà tí ìtànṣán oòrùn bá yọ lẹ́yìn tí ojú ọjọ́ ti dágùdẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Ara àwọn èèyàn á yá gágá, inú wọn á sì máa dùn. Bákan náà, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti ràn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, tí gbogbo ilẹ̀ sì gbẹ táútáú, bí òjò bá wá rọ̀—bó tiẹ̀ jẹ́ òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá pàápàá—ńṣe ló máa tuni lára tí ara èèyàn á sì silé. Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ ti ṣètò ẹ̀bùn àgbàyanu bí ojú ọjọ́ ṣe ń rí yìí sínú afẹ́fẹ́ àyíká ilẹ̀ ayé. Jésù pe àfiyèsí sórí ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí Ọlọ́run ní nígbà tó kọ́ni pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, níwọ̀n bí ó ti ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mátíù 5:43-45) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo èèyàn. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ náà gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti fara wé e nípa wíwá ànímọ́ rere lára àwọn ẹlòmíràn.

2. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi ń ṣoore? (b) Kí ni Jèhófà ń kíyè sí nípa irú ojú tá a fi ń wo oore rẹ̀?

2 Kí nìdí tí Jèhófà fi ń ṣoore? Àtìgbà tí Ádámù ti ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ ni Jèhófà ti ń wo ànímọ́ tó dára lára àwọn èèyàn. (Sáàmù 130:3, 4) Ète rẹ̀ ni pé kí ìran ènìyàn onígbọràn padà wà láàyè nínú Párádísè. (Éfésù 1:9, 10) Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ ti fún wa ní ìrètí àtirí ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé nípasẹ̀ Irú Ọmọ tá a ṣèlérí náà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Róòmù 5:12, 15) Títẹ́wọ́gba ìṣètò ìràpadà náà ni yóò mú kó ṣeé ṣe láti padà sí ìjẹ́pípé nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Jèhófà wá ń kíyè sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wá báyìí láti mọ irú ọwọ́ tá a fi mú ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tó fi hàn sí wa. (1 Jòhánù 3:16) Ó ń kíyè sí ohunkóhun tá a bá ṣe láti fi hàn pé a mọrírì oore rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—Hébérù 6:10.

3. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?

3 Báwo la ṣe wá lè fara wé Jèhófà nínú wíwá ànímọ́ rere lára àwọn ẹlòmíràn? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìdáhùn sí ìbéèrè yìí yẹ̀ wò láwọn àgbègbè mẹ́rin nínú ìgbésí ayé: (1) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, (2) ìdílé, (3) ìjọ, àti (4) àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.

Nínú Wíwàásù àti Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn

4. Báwo ni kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ṣe fi hàn pé à ń wá ànímọ́ rere táwọn ẹlòmíràn ní?

4 “Pápá náà ni ayé,” ni Jésù sọ nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbé dìde nípa ìtumọ̀ àpèjúwe àlìkámà àti èpò. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn fún Kristi lóde òní, a máa ń rí i pé òtítọ́ lọ̀rọ̀ yìí nígbà tá a bá ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (Mátíù 13:36-38; 28:19, 20) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kan pípolongo ìgbàgbọ́ wa ní gbangba. Mímọ̀ táwọn èèyàn mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá à ń ṣe láti ilé de ilé àti lójú pópó fi hàn pé a jẹ́ aláápọn nínú wíwá gbogbo àwọn tó jẹ́ ẹni yíyẹ láti gbọ́ ìhìn Ìjọba náà kàn. Àní, Jésù pa á láṣẹ pé: “Ìlú ńlá tàbí abúlé èyíkéyìí tí ẹ bá wọ̀, ẹ wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn.”—Mátíù 10:11; Ìṣe 17:17; 20:20.

5, 6. Kí nìdí tá a fi máa ń ṣèbẹ̀wò léraléra sọ́dọ̀ àwọn èèyàn nínú ilé wọn?

5 Nígbà tá a bá ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tí ò retí wa, a máa ń kíyè sí irú ẹ̀mí tí wọ́n fi gba iṣẹ́ wa. Ìgbà mìíràn wà tá a máa ń rí i pé ẹnì kan nínú agbo ilé kan á tẹ́tí sí wa, nígbà tí ẹlòmíràn nínú agbo ilé kan náà á lọgun pé, “a ò fẹ́ gbọ́,” tí ìbẹ̀wò náà á sì parí síbẹ̀. Ó máa ń dùn wá gan-an pé àtakò tẹ́nì kan gbé dìde tàbí ohun tẹ́nì kan tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa sọ máa ń nípa lórí àwọn ẹlòmíràn tó fẹ́ gbọ́! Kí la wá lè ṣe nígbà náà, tá ò fí ní jáwọ́ nínú kíkíyèsí ànímọ́ rere lára gbogbo èèyàn?

6 Ìbẹ̀wò tá a bá tún padà ṣe sí irú ilé bẹ́ẹ̀ nígbà tá a bá tún ń wàásù lágbègbè yẹn lè fún wa láǹfààní àtibá ẹni tó bẹ́gi dínà ọ̀rọ̀ wa lákọ̀ọ́kọ́ yẹn sọ̀rọ̀. Rírántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ yẹn lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀. Ẹni tó ṣàtakò yẹn lè ní èrò tó dáa lọ́kàn, kó rò pé ó dáa bóun ò ṣe jẹ́ kẹ́ni tó fẹ́ gbọ́ yẹn fetí sí ìhìn Ìjọba náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó ti gbọ́ nípa wa ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ìyẹn ò ní ká má tẹra mọ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà nínú ilé ọ̀hún, ká fi ọgbọ́n mú èrò òdì táwọn èèyàn ní kúrò. Ó wù wá láti ran gbogbo èèyàn lọ́wọ́ láti di ẹni tó ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run. Ó lè wá jẹ́ pé Jèhófà ló máa fa irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀.—Jòhánù 6:44; 1 Tímótì 2:4.

7. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó dáa nígbà tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?

7 Àtakò ìdílé wà lára ìtọ́ni tí Jésù fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Àbí kò sọ pé: “Mo wá láti fa ìpínyà, láti pín ọkùnrin níyà sí baba rẹ̀, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, àti ọ̀dọ́ aya sí ìyá ọkọ rẹ̀”? Jésù tún fi kún un pé: “Àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀.” (Mátíù 10:35, 36) Síbẹ̀ ipò nǹkan tàbí ìṣarasíhùwà èèyàn máa ń yí padà. Àìsàn òjijì, ikú mọ̀lẹ́bí ẹni, ìjábá, másùnmáwo, àti àìmọye àwọn nǹkan mìíràn lè nípa lórí ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn sí iṣẹ́ ìwàásù wa. Tá a bá ní èrò òdì—pé àwọn tá à ń wàásù fún ò ní fetí sílẹ̀—ṣé lóòótọ́ là ń wo ànímọ́ rere tí wọ́n ní? O ò ṣe fi ìdùnnú padà ṣèbẹ̀wò sílé wọn nígbà mìíràn? Ìṣarasíhùwà wọ́n ti lè yí padà. Ìgbà mìíràn wà tó jẹ́ pé kì í ṣe kìkì ohun tá a sọ ló máa mú kí ìṣarasíhùwà wọn yí padà, bí kò ṣe ọ̀nà tá a gbà sọ ọ́. Ó dájú pé gbígbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí tó dáa ká sì wàásù ìhìn Ìjọba náà lọ́nà tó fa gbogbo èèyàn mọ́ra.—Kólósè 4:6; 1 Tẹsalóníkà 5:17.

8. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn Kristẹni bá wo ànímọ́ rere táwọn mọ̀lẹ́bí wọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ ní?

8 Àwọn ìjọ kan wà tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ara ìdílé kan náà ló ń sin Jèhófà níbẹ̀. Ìfaradà àgbàlagbà kan tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí wọn, tí àjọṣe rere tó ní nínú ìdílé àti èyí tó ní nínú ìdè ìgbéyàwó rẹ̀ ti jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ yí èrò inú wọn padà ló sábà máa ń fa àwọn tó jẹ́ ọ̀dọ́ nínú ẹbí mọ́ra. Kíkọbiara sí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pétérù ti ran ọ̀pọ̀ Kristẹni aya lọ́wọ́ láti jèrè ọkọ wọn “láìsọ ọ̀rọ̀ kan.”—1 Pétérù 3:1, 2.

Nínú Ìdílé

9, 10. Ọ̀nà wo ni Jékọ́bù àti Jósẹ́fù gbà wo ànímọ́ rere lára àwọn tó wà nínú ìdílé wọn?

9 Ìdè tímọ́tímọ́ tó so àwọn tó wà nínú ìdílé pa pọ̀ tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn tá a lè gbà wá ànímọ́ rere lára àwọn ẹlòmíràn. Gbé ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ látinú bí Jékọ́bù ṣe bá àwọn ọmọ rẹ̀ lò yẹ̀ wò. Bíbélì fi hàn nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kẹtàdínlógójì, ẹsẹ kẹta àti ìkẹrin pé Jékọ́bù dìídì nífẹ̀ẹ́ Jósẹ́fù. Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù jowú rẹ̀, débi pé wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa àbúrò wọn. Àmọ́, kíyè sí ìṣarasíhùwà Jékọ́bù àti ti Jósẹ́fù ní òpin ìgbésí ayé wọn. Àwọn méjèèjì ló wá ànímọ́ rere rí lára àwọn tó wà nínú ìdílé wọn.

10 Nígbà tí Jósẹ́fù di alábòójútó oúnjẹ ní ilẹ̀ Íjíbítì tébi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lu àwọn èèyàn ibẹ̀ pa, ó gba àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tọwọ́tẹsẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi ara rẹ̀ hàn lójú ẹsẹ̀, síbẹ̀ ó ṣètò láti rí i pé wọ́n jẹun dáadáa wọ́n sì rí oúnjẹ gbé lọ fún baba wọn tó ti di arúgbó. Àbẹ́ ẹ̀ rí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù lẹni tí wọ́n hùwà ìkà sí, síbẹ̀ ó ṣaájò wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 41:53–42:8; 45:23) Bákan náà ni Jékọ́bù bù kún gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tó kù díẹ̀ kó kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà búburú wọn yọrí sí pípàdánù àwọn àǹfààní kan, síbẹ̀ kò sí èyíkéyìí nínú wọn tí kò pín ogún fún ní ilẹ̀ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 49:3-28) Ẹ ò rí i pé àgbàyanu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni Jékọ́bù fi hàn yẹn!

11, 12. (a) Àpẹẹrẹ alásọtẹ́lẹ̀ wo ló tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì wíwo ànímọ́ rere tó wà lára àwọn tó wà nínú ìdílé ẹni? (b) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ bàbá tí Jésù mẹ́nu kàn nínú àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá?

11 Ẹ̀mí ìpamọ́ra tí Jèhófà fi bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì aláìgbàgbọ́ lò tún jẹ́ ká rí bó ṣe ń wo àwọn ànímọ́ rere táwọn èèyàn rẹ̀ ní. Jèhófà lo bí ipò nǹkan ṣe rí nínú ìdílé Hóséà láti ṣàpèjúwe ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ. Gómérì, aya Hóséà ṣe panṣágà léraléra. Pẹ̀lú ìyẹn náà, Jèhófà pàṣẹ fún Hóséà pé: “Lọ lẹ́ẹ̀kan sí i, nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan tí alábàákẹ́gbẹ́ kan nífẹ̀ẹ́, tí ó sì ń ṣe panṣágà, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ti ìfẹ́ Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n yí padà sí àwọn ọlọ́run mìíràn, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ìṣù èso àjàrà gbígbẹ.” (Hóséà 3:1) Kí ló fa irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀? Jèhófà mọ̀ pé a ṣì máa rí àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan tó máa kọ ìhà tó dáa sí sùúrù òun lára àwọn ará orílẹ̀-èdè tó ti yà bàrá kúrò ní ọ̀nà òun. Hóséà polongo pé: “Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò padà wá, wọn yóò sì wá Jèhófà Ọlọ́run wọn dájúdájú, wọ́n yóò sì wá Dáfídì ọba wọn; dájúdájú, wọn yóò sì fi ìgbọ̀npẹ̀pẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jèhófà àti sínú oore rẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.” (Hóséà 3:5) Dájúdájú, èyí jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà tó yẹ ká máa ronú lé lórí nígbà tá a bá ń kojú àwọn ìṣòro ìdílé. Bó o ṣe ń bá a lọ láti máa wá ànímọ́ rere lára àwọn yòókù nínú ìdílé, ó kéré tán wàá lè fi àpẹẹrẹ àtàtà ti sùúrù níní lélẹ̀.

12 Àpèjúwe tí Jésù fúnni nípa ọmọ onínàákúnàá túbọ̀ fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye nípa bá a ṣe lè máa wá ànímọ́ rere lára àwọn tó wà nínú ìdílé tiwa. Èyí àbúrò padà sílé lẹ́yìn tó ti jáwọ́ nínú ìgbésí ayé onínàákúnàá tó lọ gbé. Bàbá rẹ̀ ṣàánú rẹ̀. Kí ni bàbá náà ṣe nípa àròyé ọmọ rẹ̀ àgbà tí kò fi ìdílé rẹ̀ sílẹ̀ rí? Nígbà tí bàbá náà ń bá ọmọ rẹ̀ àgbà sọ̀rọ̀, ó ní: “Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ wà pẹ̀lú mi, gbogbo ohun tí ó jẹ́ tèmi jẹ́ tìrẹ.” Èyí kì í ṣe ìbáwí kíkorò, àmọ́ ó wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà láti mú un dá a lójú pé bàbá náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bàbá náà tún sọ pé: “Àwa sáà ní láti gbádùn ara wa, kí a sì yọ̀, nítorí pé arákùnrin rẹ yìí kú, ó sì wá sí ìyè, ó sọnù a sì rí i.” Bákan náà, àwa náà lè máa wo ànímọ́ rere tó wà lára àwọn ẹlòmíràn.—Lúùkù 15:11-32.

Nínú Ìjọ Kristẹni

13, 14. Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà tẹ̀ lé ọba òfin nì tí í ṣe ìfẹ́ nínú ìjọ Kristẹni?

13 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ó wù wá láti máa tẹ̀ lé ọba òfin nì tí í ṣe ìfẹ́. (Jákọ́bù 2:1-9) Lóòótọ́, a lè máa bá àwọn ará ìjọ wa tí wọ́n kò ní nǹkan ìní nípa tara tó tiwa ṣe nǹkan pọ̀. Àmọ́ ṣé a ṣì ní “ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́” lórí ọ̀ràn ẹ̀yà, àṣà, tàbí irú èèyàn tẹ́nì kan jẹ́ látilẹ̀wá? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe máa wá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jákọ́bù?

14 Fífi ọ̀yàyà kí gbogbo àwọn tó bá wá sípàdé Kristẹni ń fi ẹ̀rí hàn pé a ní ẹ̀mí ọ̀làwọ́. Nígbà tá a bá lo ìdánúṣe láti bá àwọn ẹni tuntun tó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba nígbà àkọ́kọ́ sọ̀rọ̀, gbogbo ẹ̀rù tó lè máa bà wọ́n tàbí ìtìjú tí wọ́n lè ní á pòórá. Kódà, àwọn kan tó wá sípàdé Kristẹni nígbà àkọ́kọ́ pàá sábà máa ń sọ pé: “Gbogbo àwọn tí mo rí ló lọ́yàyà. Ńṣe ló dà bíi pé gbogbo wọn ló mọ̀ mí tẹ́lẹ̀. Ọkàn mi balẹ̀.”

15. Báwo la ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn àgbàlagbà?

15 Nínú àwọn ìjọ kan, àwọn ọ̀dọ́ bíi mélòó kan lè kóra wọn jọ sí inú tàbí ìta Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yìn ìpàdé, kí wọ́n máà fẹ́ dara pọ̀ mọ́ àwọn àgbàlagbà. Kí la lè ṣe láti yanjú ìṣòro yìí? Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ pàá ni pé káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn láti ilé, kí wọ́n múra wọn sílẹ̀ fún ìpàdé. (Òwe 22:6) Wọ́n lè yanṣẹ́ wíwá oríṣiríṣi ìtẹ̀jáde tí wọ́n máa lò nípàdé fún wọn kí gbogbo ìdílé lè ní àwọn ìwé tí wọ́n máa lò nípàdé lọ́wọ́. Àwọn òbí tún láǹfààní láti máa gba àwọn ọmọ wọn níyànjú pé kí wọ́n máa bá àwọn àgbàlagbà àtàwọn aláìlera fèrò wérò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí àwọn ọmọdé bá ti ní ohun pàtó lọ́kàn láti bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sọ, ọkàn wọn á balẹ̀.

16, 17. Báwo làwọn àgbà ṣe lè kíyè sí àwọn ànímọ́ rere táwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ ní?

16 Kí àwọn ará, lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó jẹ́ àgbà, fi ìfẹ́ hàn sáwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ. (Fílípì 2:4) Wọ́n lè lo ìdánúṣe láti bá àwọn ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀ lọ́nà ìwúrí. A sábà máa ń jíròrò àwọn kókó tó gba àfiyèsí nínú ìpàdé. A lè bi àwọn ọ̀dọ́ bóyá wọ́n gbádùn ìpàdé náà àti bóyá a rí àwọn kókó tó wú wọn lórí tí wọ́n á fẹ́ mú lò níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí apá pàtàkì nínú ìjọ, a gbọ́dọ̀ mọrírì báwọn ọ̀dọ́ ṣe ń fetí sílẹ̀, ká sì máa gbóríyìn fún wọn nígbà tí wọ́n bá dáhùn láwọn ìpàdé tàbí nígbà tí wọ́n bá kópa nínú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan. Ọ̀nà táwọn ọ̀dọ́ gbà bá àwọn àgbà ṣe pọ̀ àti bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tá a ní kí wọ́n ṣe nínú ilé yóò fi hàn pé wọ́n á lè bójú tó ẹrù iṣẹ́ tó tóbi ju ìyẹn lọ nígbà tí wọ́n bá dàgbà.—Lúùkù 16:10.

17 Nípa títẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́, àwọn ọ̀dọ́ kan ti tẹ̀ síwájú débi pé àwọn ànímọ́ tí wọ́n ní nípa tẹ̀mí ti jẹ́ kí wọ́n lè tẹ́wọ́ gba àwọn iṣẹ́ tó túbọ̀ ṣe pàtàkì. Jíjẹ́ kí ọwọ́ ẹni dí tún lè ṣèrànwọ́ láti sá fún ìwà òmùgọ̀. (2 Tímótì 2:22) Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ èyí tá a fi ń ṣe ‘ìdánwò ní ti bí ẹnì kan ṣe yẹ sí’ fún àwọn arákùnrin tó ń nàgà láti sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. (1 Tímótì 3:10) Bí wọ́n ṣe máa ń múra tán láti kópa láwọn ìpàdé àti ìtara tí wọ́n ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, títí kan ìfẹ́ tí wọ́n ń fi hàn sí gbogbo èèyàn nínú ìjọ, ń ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti fòye mọ bí wọ́n ṣe tóótun tó nígbà tí wọ́n bá ń ronú àtigbé àfikún ẹrù iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́.

Wíwá Ànímọ́ Rere Lára Gbogbo Èèyàn

18. Àwọn ọ̀fìn wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún nínú ọ̀ràn ìdájọ́, kí sì nìdí?

18 Ìwé Òwe 24:23 là á mọ́lẹ̀ pé: “Fífi ojúsàájú hàn nínú ìdájọ́ kò dára.” Ọgbọ́n àtọ̀runwá béèrè pé kí àwọn alàgbà yẹra fún ṣíṣe ojúsàájú nígbà tí wọ́n bá ń ṣèdájọ́ nínú ìjọ. Jákọ́bù sọ pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere, kì í ṣe àwọn ìyàtọ̀ olójúsàájú, kì í ṣe àgàbàgebè.” (Jákọ́bù 3:17) Láìsí àní-àní, nígbà táwọn alàgbà bá ń kíyè sí ànímọ́ rere táwọn ẹlòmíràn ní, wọ́n ní láti rí i dájú pé àjọṣe àárín àwọn àti ẹni náà tàbí bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wọn kò nípa lórí ìdájọ́ tí wọ́n ń ṣe. Ásáfù onísáàmù nì kọ̀wé pé: “Ọlọ́run dúró nínú àpéjọ Olú Ọ̀run. Ó ń ṣe ìdájọ́ ní àárín àwọn ọlọ́run [tàbí lọ́rọ̀ mìíràn “àwọn ẹni bí ọlọ́run,” tó ń tọ́ka sí àwọn onídàájọ́ ènìyàn] pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ óò máa fi àìṣèdájọ́ òdodo dáni lẹ́jọ́, tí ẹ ó sì máa ṣe ojúsàájú àwọn ẹni burúkú?’” (Sáàmù 82:1, 2) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ làwọn Kristẹni alàgbà kì í ṣojúsàájú nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó àwọn ọ̀ràn tó kan ọ̀rẹ́ kan tàbí mọ̀lẹ́bí wọn. Ní ọ̀nà yìí, wọ́n á jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ, ìyẹn á sì jẹ́ kí ẹ̀mí Jèhófà máa ṣiṣẹ́ fàlàlà níbẹ̀.—1 Tẹsalóníkà 5:23.

19. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà wá ànímọ́ rere lára àwọn ẹlòmíràn?

19 Nígbà tá a bá ń wá ànímọ́ rere lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, irú ẹ̀mí tí Pọ́ọ̀lù ní nígbà tó bá àwọn ará Tẹsalóníkà sọ̀rọ̀ là ń gbé yọ yẹn. Ó ní: “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwa ní ìgbọ́kànlé nínú Olúwa nípa yín, pé ẹ ń ṣe àwọn ohun tí a pa láṣẹ, ẹ ó sì máa bá a lọ ní ṣíṣe wọ́n.” (2 Tẹsalóníkà 3:4) Yóò túbọ̀ ṣeé ṣe fún wa láti gbójú fo àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn dá, nígbà tá a bá ń wo ànímọ́ rere tí wọ́n ní. A ó ṣàwárí àwọn àgbègbè tá a ti lè gbóríyìn fáwọn arákùnrin wa, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ yàgò fún ẹ̀mí ṣíṣe lámèyítọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ohun tí a ń retí nínú àwọn ìríjú ni pé kí a rí ènìyàn ní olùṣòtítọ́.” (1 Kọ́ríńtì 4:2) Ìṣòtítọ́ gbogbo àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa ló sọ wọn di ẹni ọ̀wọ́n lójú wa, kì í ṣe ìṣòtítọ́ tàwọn tó jẹ́ ìríjú nínú ìjọ nìkan. Ìyẹn ló jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ wọn, tá a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fún ìdè ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Kristẹni lókun. Irú èrò tí Pọ́ọ̀lù ní nípa àwọn arákùnrin tó wà nígbà ayé rẹ̀ làwa náà ní. Àwọn ni ‘alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa fún ìjọba Ọlọ́run’ wọ́n sì tún jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fún wa. (Kólósè 4:11) A ó sì tipa bẹ́ẹ̀ gbé ẹ̀mí Jèhófà yọ.

20. Ìbùkún wo ni yóò jẹ́ ti àwọn tó ń wá ànímọ́ rere lára àwọn èèyàn?

20 Dájúdájú, a fara mọ́ àdúrà tí Nehemáyà gbà pé: “Jọ̀wọ́, Ọlọ́run mi, rántí mi fún rere.” (Nehemáyà 13:31) Inú wa mà dùn o, pe Jèhófà ń wo ànímọ́ rere táwa èèyàn ní! (1 Àwọn Ọba 14:13) Ǹjẹ́ kí àwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ ká máa fojú sọ́nà de ìtúnràpadà àti ìyè ayérayé nínú ayé tuntun tó sún mọ́lé.— Sáàmù 130:3-8.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

Kí nìdí tí Jèhófà fi ń ṣoore fún gbogbo èèyàn?

Báwo la ṣe lè máa wá ànímọ́ rere lára àwọn ẹlòmíràn

nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

nínú ìdílé wa?

nínú ìjọ wa?

nínú gbogbo àjọṣe wa?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Pẹ̀lú bí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù ṣe kórìíra rẹ̀ tó, ó tún wá ire wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àtakò kò dí wa lọ́wọ́ láti ṣèrànwọ́ fún gbogbo èèyàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Láìfi gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn pè, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ Jékọ́bù tí kò rí ìbùkún gbà lọ́dọ̀ rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ẹ kí gbogbo èèyàn tọ̀yàyàtọ̀yàyà láwọn ìpàdé Kristẹni