Fara Wé Jèhófà, Ọlọ́run Wa Tí Kì í Ṣojúsàájú
Fara Wé Jèhófà, Ọlọ́run Wa Tí Kì í Ṣojúsàájú
“Kò sí ojúsàájú lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”—RÓÒMÙ 2:11.
1, 2. (a) Kí ni ète tí Jèhófà ní fún àwọn ará Kénáánì lápapọ̀? (b) Kí ni Jèhófà ṣe, àwọn ìbéèrè wo lèyí sì gbé dìde?
ÍSÍRẸ́LÌ tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ Mósè nígbà tí wọ́n pàgọ́ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lọ́dún 1473 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ìṣòro ńlá kan ń dúró dè wọ́n lẹ́yìn Odò Jọ́dánì. Mósè polongo ète Jèhófà pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè ńlá méje tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Kénáánì ní Ilẹ̀ Ìlérí. Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ ṣe fini lọ́kàn balẹ̀ tó pé: “Dájúdájú, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì jọ̀wọ́ wọn fún ọ, ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn”! Ísírẹ́lì ò ní í bá wọn dá májẹ̀mú kankan wọn ò sì ní í rí ojú rere rẹ̀.—Diutarónómì 1:1; 7:1, 2.
2 Síbẹ̀, Jèhófà pa ìdílé kan mọ́ nínú ìlú tí Ísírẹ́lì kọ́kọ́ bá jagun. Àwọn èèyàn láti inú ìlú mẹ́rin mìíràn tún rí ààbò Ọlọ́run gbà. Kí nìdí? Kí ni ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó ní í ṣe pẹ̀lú pípa àwọn ará Kénáánì wọ̀nyí mọ́ láàyè kọ́ wa nípa Jèhófà? Báwo la sì ṣe lè fara wé e?
Ohun Tí Òkìkí Jèhófà Mú Káwọn Èèyàn Ṣe
3, 4. Ipa wo ni ìròyìn nípa báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń ṣẹ́gun ní lórí àwọn èèyàn ilẹ̀ Kénáánì?
3 Odindi ogójì ọdún tí Ísírẹ́lì fi wà nínú aginjù kí wọ́n tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí ni Jèhófà fi dáàbò bò wọ́n tó sì jà fún àwọn èèyàn rẹ̀. Ọba àwọn ọmọ Kénáánì ti ìlú Árádì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì dojú kọ ní ìhà gúúsù Ilẹ̀ Ìlérí. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ ní Hóómà. (Númérì 21:1-3) Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì rìn yí ilẹ̀ Édómù ká, wọ́n sì rìnrìn àjò lọ sí ìhà àríwá títí lọ dé àríwá ìlà oòrùn Òkun Òkú. Àwọn Móábù ló ń gbé àgbègbè yìí tẹ́lẹ̀, àmọ́ àwọn Ámórì ló wá ń gbébẹ̀ báyìí. Síhónì Ọba Ámórì kọ̀ délẹ̀, ó ní òun ò ní jẹ́ kí Ísírẹ́lì gba ìpínlẹ̀ òun kọjá. Bí wọ́n ṣe gbógun dìde síra wọn ní Jáhásì, tó wà ní apá àríwá Àfonífojì Olójú Ọ̀gbàrá ti Áánónì nìyẹn, ibẹ̀ ni wọ́n sì pa Síhónì sí. (Númérì 21:23, 24; Diutarónómì 2:30-33) Ógù ló ń ṣàkóso lórí àwọn Ámórì yòókù ní Báṣánì tó wà ní ìhà àríwá lọ́hùn-ún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òmìrán ni Ógù, síbẹ̀ kò lè bá Jèhófà figẹ̀ wọngẹ̀. Bí wọ́n ṣe pa Ógù sí Édíréì nìyẹn. (Númérì 21:33-35; Diutarónómì 3:1-3, 11) Ìròyìn àwọn ìṣẹ́gun wọ̀nyí pa pọ̀ mọ́ àwọn ìtàn bí Ísírẹ́lì ṣe jáde kúrò ní Íjíbítì nípa tó lágbára lórí àwọn kọ̀ọ̀kan tó ń gbé ní Kénáánì. a
4 Nígbà tí Ísírẹ́lì kọ́kọ́ wọ ilẹ̀ Kénáánì lẹ́yìn tí wọ́n sọdá Jọ́dánì, Gílígálì ni wọ́n pàgọ́ sí. (Jóṣúà 4:9-19) Jẹ́ríkò ìlú ńlá olódi nì ò sì jìnnà síbẹ̀ rárá. Ohun tí Ráhábù ará Kénáánì ti gbọ́ nípa Jèhófà ló mú kó fi ìgbàgbọ́ gbégbèésẹ̀. Nítorí ìdí èyí, nígbà tí Jèhófà pa Jẹ́ríkò run, ó pa obìnrin náà àtàwọn tó wà nínú ilé rẹ̀ mọ́ láàyè.—Jóṣúà 2:1-13; 6:17, 18; Jákọ́bù 2:25.
5. Kí ló mú káwọn ará Gíbíónì fọgbọ́n hùwà?
5 Lẹ́yìn ìyẹn, Ísírẹ́lì gòkè láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó wà nítòsí odò, wọ́n sì forí lé àwọn òkè tó wà ní àgbègbè náà. Nípa títẹ̀lé ìdarí Jèhófà, Jóṣúà lo ọgbọ́n bíba níbùba láti gbógun ti ìlú Áì. (Jóṣúà, orí kẹjọ) Ìròyìn nípa àwọn ìṣẹ́gun wọ̀nyí ló mú kí àwọn ọba Kénáánì kóra jọ fún ogun. (Jóṣúà 9:1, 2) Àmọ́ àwọn tó ń gbé ìlú Hífítè tó jẹ́ ti àwọn ará Gíbéónì tó wà nítòsí ṣe ohun tó yàtọ̀. Ìwé Jóṣúà 9:4 ròyìn pé: “Àwọn, àní láti inú ìdánúṣe wọn, gbé ìgbésẹ̀ ìfọgbọ́nhùwà.” Bíi ti Ráhábù, àwọn náà ti gbọ́ nípa bí Jèhófà ṣe dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè nígbà Ìjádelọ wọn àti nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun Síhónì àti Ógù. (Jóṣúà 9:6-10) Àwọn ará Gíbíónì rí i pé ìmúlẹ̀mófo ló máa jẹ́ táwọn bá sọ pé àwọ́n fẹ́ jagun. Nítorí náà, lórúkọ Gíbéónì àti ti ìlú ńlá mẹ́ta tó wà nítòsí wọn—ìyẹn Kéfírà, Béérótì, àti Kiriati-jéárímù—wọ́n rán àwọn ońṣẹ́ lọ bá Jóṣúà ní Gílígálì, àwọn yẹn sì díbọ́n bí ẹni pé ọ̀nà jíjìn làwọn ti wá. Ọgbọ́n tí wọ́n dá yẹn gbéṣẹ́ gan-an. Jóṣúà bá wọn dá májẹ̀mú tó mú un dá wọn lójú pé a ó pa wọ́n mọ́ láàyè. Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn ìyẹn ni Jóṣúà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ó mọ̀ pé títàn ni wọ́n tan àwọn jẹ. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ti fi orúkọ Jèhófà búra láti pa májẹ̀mú náà mọ́, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kí wọ́n yí ohùn padà. (Jóṣúà 9:16-19) Ǹjẹ́ Jèhófà fara mọ́ ohun tí wọ́n ṣe yìí?
6. Ojú wo ni Jèhófà fi wo ọ̀ràn májẹ̀mú tí Jóṣúà bá àwọn ará Gíbíónì dá?
6 Wọ́n fàyè gba àwọn ará Gíbíónì láti di aṣẹ́gi àti apọnmi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kódà “fún pẹpẹ Jèhófà” ní àgọ́ ìjọsìn. (Jóṣúà 9:21-27) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà táwọn ọba Ámórì márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àtàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn ń halẹ̀ mọ́ àwọn ará Gíbíónì, Jèhófà dá sí ọ̀ràn náà lọ́nà ìyanu. Àwọn tí òkúta yìnyín pa lára àwọn ọ̀tá náà pọ̀ ju àwọn tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jóṣúà pa lọ. Kódà Jèhófà dáhùn ẹ̀bẹ̀ Jóṣúà pé kí oòrùn àti òṣùpá dúró lójú kan kí wọ́n lè ráyè pa àwọn ọ̀tá náà run pátápátá. Jóṣúà sọ pé: “Kò sì sí ọjọ́ kankan tí ó tíì dà bí ìyẹn, yálà ṣáájú rẹ̀ tàbí lẹ́yìn rẹ̀, ní ti pé Jèhófà fetí sí ohùn ènìyàn, nítorí Jèhófà ni ó ń jà fún Ísírẹ́lì.”—Jóṣúà 10:1-14.
7. Òtítọ́ tí Pétérù mẹ́nu kàn wo la rí nínú ọ̀ràn àwọn ará Kénáánì kan?
7 Ráhábù ará Kénáánì àti ìdílé rẹ̀, títí kan àwọn ará Gíbíónì, bẹ̀rù Jèhófà wọ́n sì hùwà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn yẹn fi hàn pé òtítọ́ pọ́ńbélé ni ohun tí Kristẹni àpọ́sítélì Pétérù wá mẹ́nu kàn níkẹyìn pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
Bó Ṣe Bá Ábúráhámù àti Ísírẹ́lì Lò
8, 9. Báwo ni àìṣojúsàájú Jèhófà ṣe hàn kedere nínú ọ̀nà tó gbà bá Ábúráhámù àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lò?
8 Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù pe àfiyèsí sórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn nínú bó ṣe bá Ábúráhámù àtàwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ lò. Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù ló sọ ọ́ di “ọ̀rẹ́ Jèhófà,” kì í ṣe ẹ̀yà tó ti wá. (Jákọ́bù 2:23) Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù àti ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà mú ìbùkún wá fún àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. (2 Kíróníkà 20:7) Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé: “Èmi yóò bù kún ọ dájúdájú, èmi yóò sì sọ irú-ọmọ rẹ di púpọ̀ dájúdájú bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun.” Àmọ́ kíyè sí ìlérí tó wá ṣe ní ẹsẹ tó tẹ̀ lé e pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18; Róòmù 4:1-8.
9 Láìsí ọ̀ràn ṣíṣe ojúsàájú rárá, bí Jèhófà ṣe bá Ísírẹ́lì lò fi ohun tó lè ṣe fáwọn tó bá ṣègbọràn sí i hàn. Irú ìbálò bẹ́ẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi ìfẹ́ adúróṣinṣin hàn sí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “àkànṣe dúkìá” ni Ísírẹ́lì jẹ́ fún Jèhófà, síbẹ̀ èyí ò túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn mìíràn ò lè gbádùn inúure Ọlọ́run. (Ẹ́kísódù 19:5; Diutarónómì 7:6-8) Lóòótọ́, Jèhófà tún Ísírẹ́lì rà kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì, ó sì wá polongo pé: “Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀ nínú gbogbo ìdílé tí ń bẹ lórí ilẹ̀.” Àmọ́ Jèhófà tún tipasẹ̀ wòlíì Ámósì àtàwọn mìíràn ṣèlérí àgbàyanu kan fáwọn èèyàn tó wà ní “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”—Ámósì 3:2; 9:11, 12; Aísáyà 2:2-4.
Jésù, Olùkọ́ Tí Kì Í Ṣojúsàájú
10. Báwo ni Jésù ṣe fara wé Baba rẹ̀ nínú jíjẹ́ ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú?
10 Nígbà tí Jésù tó jẹ́ àwòrán Baba rẹ̀ gẹ́lẹ́ wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó fara wé àìṣojúsàájú Jèhófà. (Hébérù 1:3) Ohun tó ká a lára jù lọ lákòókò yẹn ni wíwá “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọnù” rí. Síbẹ̀, kò lọ́ tìkọ̀ láti wàásù fún obìnrin ara Samáríà kan tó bá létí kànga. (Mátíù 15:24; Jòhánù 4:7-30) Ó tún ṣe iṣẹ́ ìyanu kan tí ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan, tó hàn gbangba pé kì í ṣe Júù, bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣe. (Lúùkù 7:1-10) Ìyẹn jẹ́ àfikún sí bó ṣe ń fi ìfẹ́ tó ní fún àwọn èèyàn Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìṣe rẹ̀. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tún wàásù níbi gbogbo pẹ̀lú. Ó wá hàn gbangba pé rírí ìbùkún Jèhófà gbà kò sinmi lórí orílẹ̀-èdè ẹni bí kò ṣe lórí irú ẹ̀mí téèyàn ní. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ èèyàn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́kàntútù tí ebi òtítọ́ ń pa fetí sí ìhìn rere Ìjọba náà. Àmọ́, àwọn agbéraga àti onírera tẹ́ńbẹ́lú Jésù àti iṣẹ́ rẹ̀. Jésù polongo pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti rọra fi ohun wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó. Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ Baba, nítorí pé láti ṣe bẹ́ẹ̀ wá di ọ̀nà tí ìwọ tẹ́wọ́ gbà.” (Lúùkù 10:21) Nígbà tá a bá fi ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ bá àwọn ẹlòmíràn lò, à ń hùwà láìṣojúsàájú nìyẹn, níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé ọ̀nà tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà nìyí.
11. Báwo ni wọ́n ṣe fi àìṣojúsàájú hàn nínú ìjọ Kristẹni ìjímìjí?
11 Àwọn Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù bára dọ́gba nínú ìjọ Kristẹni ìjímìjí. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ògo àti ọlá àti àlàáfíà fún gbogbo ẹni tí ń ṣe ohun rere, fún Júù lákọ̀ọ́kọ́ àti fún Gíríìkì pẹ̀lú. Nítorí kò sí ojúsàájú lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” b (Róòmù 2:10, 11) Kì í ṣe ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́ ló máa pinnu bóyá wọ́n máa jàǹfààní látinú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà, bí kò ṣe ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa Jèhófà àti ohun tí ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀, Jésù mú kéèyàn máa fojú sọ́nà fún. (Jòhánù 3:16, 36) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Òun kì í ṣe Júù ẹni tí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní òde ara, bẹ́ẹ̀ ni ìdádọ̀dọ́ kì í ṣe èyí tí ó wà ní òde ara. Ṣùgbọ́n òun jẹ́ Júù ẹni tí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní inú, ìdádọ̀dọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ti ọkàn-àyà nípasẹ̀ ẹ̀mí, kì í sì í ṣe nípasẹ̀ àkójọ òfin tí a kọ sílẹ̀.” Yàtọ̀ sí ìyẹn, nípa lílo ọgbọ́n ìpèdè tó ní ọ̀rọ̀ náà “Júù” nínú (èyí tó túmọ̀ sí “ti ẹ̀yà Júdà,” tí wọ́n ń gbé gẹ̀gẹ̀ tí wọ́n sì ń yìn), Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Ìyìn ẹni yẹn kò wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Róòmù 2:28, 29) Jèhófà nawọ́ ìyìn yẹn láìṣe ojúsàájú. Ǹjẹ́ àwa náà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?
12. Ìfojúsọ́nà wo ni ìwé Ìṣípayá 7:9 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àwọn wò ló sì wà fún?
12 Nígbà tó yá, nínú ìran kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí àwọn Kristẹni olóòótọ́ ẹni àmì òróró tí a pè ní orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, “tí a fi èdìdì dì láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” Lẹ́yìn èyí, Jòhánù rí “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, wọ́n wọ aṣọ funfun; imọ̀ ọ̀pẹ sì ń bẹ ní ọwọ́ wọn.” (Ìṣípayá 7:4, 9) Nítorí ìdí èyí, kò sí ẹ̀yà kankan tàbí èdè tá a yọ kúrò nínú ìjọ Kristẹni òde òní. Àwọn èèyàn látinú onírúurú ipò ló ń fojú sọ́nà de líla “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀ já kí wọ́n sì mu omi látinú “àwọn ìsun omi ìyè” nínú ayé tuntun.— Ìṣípayá 7:14-17.
Àbájáde Rere Tó Ní
13-15. (a) Báwo la ṣe lè borí ọ̀ràn ẹ̀yà àti àṣà ìbílẹ̀ tó yàtọ̀ síra? (b) Fúnni láwọn àpẹẹrẹ àǹfààní tí fífi ẹ̀mí ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ hàn lè mú wá.
13 Jèhófà mọ̀ wá dáadáa, gẹ́gẹ́ bí bàbá rere kan ṣe mọ àwọn ọmọ rẹ̀. Bákan náà, nígbà tá a bá lóye àwọn ẹlòmíràn nípa fífi ìfẹ́ hàn sí àṣà ìbílẹ̀ wọn àti irú èèyàn tí wọ́n jẹ́, a ó rí i pé ìyàtọ̀ tó wà láàárín wa kò ní já mọ́ nǹkan kan mọ́. Ọ̀ràn ẹlẹ́yàmẹ̀yà á pòórá, àwọn ìdè ọ̀rẹ́ àti ìfẹ́ á sì lókun sí i. Ìṣọ̀kan á wà. (1 Kọ́ríńtì 9:19-23) Èyí hàn gbangba nínú ìgbòkègbodò àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tá a yàn fún wọn nílẹ̀ òkèèrè. Wọ́n máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn tó ń gbé níbẹ̀, nítorí èyí, kì í pẹ́ rárá táwọn míṣọ́nnárì náà fi máa ń mú ara wọn bá àwọn ìjọ àdúgbò tí wọ́n dára pọ̀ mọ́ mu.—Fílípì 2:4.
14 Ipa rere tí àìṣojúsàájú wọn ní ti hàn kedere ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Aklilu, tó wá láti Etiópíà, rí i pé ńṣe lòun ń dá nìkan jẹ̀ ní London tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Èrò pé òun ò ní alábàárò túbọ̀ lágbára sí i nígbà tó rí i pé àwọn èèyàn kì í sábà bá ẹni tó bá ti orílẹ̀-èdè mìíràn wá ṣọ̀rẹ́, èyí sì jẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ìlú ńlá Yúróòpù òde òní. Ohun tí Aklilu rí nígbà tó lọ sí ìpàdé Kristẹni ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sí èyí! Àwọn tó wà níbẹ̀ gbà á tọwọ́tẹsẹ̀, kò sì pẹ́ rárá tó fi di ọ̀rẹ́ wọn. Ó tẹ̀ síwájú gan-an nípa jíjẹ́ kí òye tó ní nípa Ẹlẹ́dàá túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Kíá ló wá bóun á ṣe máa kópa nínú sísọ ìhìn rere Ìjọba náà fáwọn ẹlòmíràn lágbègbè yẹn. Kódà, lọ́jọ́ kan tí ẹni tí Aklilu ń bá ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí béèrè ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ nísinsìnyí, ojú ẹsẹ̀ ni Aklilu dáhùn pé ohun tó ń wu òun ni pé kí òun wà nínú ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ìbílẹ̀ òun lọ́jọ́ kan, ìyẹn èdè Amharic. Nígbà táwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ Gẹ̀ẹ́sì ládùúgbò náà gbọ́ nípa èyí, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi ṣètò fún sísọ àsọyé kan ní èdè ìbílẹ̀ Aklilu. Pípè tí wọ́n pe àwọn èèyàn wá síbẹ̀ mú kí ọ̀pọ̀ àjèjì àtàwọn aládùúgbò náà kóra jọ pọ̀ láti ṣètìlẹ́yìn fún ìpàdé yìí tí wọ́n kọ́kọ́ fi èdè Amharic ṣe nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Lónìí, àwọn ará Etiópíà àtàwọn mìíràn ládùúgbò yẹn wà níṣọ̀kan nínú ìjọ elédè Amharic kan tó ń gbèrú. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló ti rí i pé kò sí ohun tó dá àwọn dúró láti mú ìdúró wọn síhà ọ̀dọ̀ Jèhófà kí wọ́n sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípasẹ̀ ṣíṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni.—Ìṣe 8:26-36.
15 Ànímọ́ àti irú èèyàn tẹ́nì kan jẹ́ látilẹ̀wá yàtọ̀ síra. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ohun la fi ń mọ ẹni tó lọ́lá jù tàbí ẹni tí kò lọ́lá, wọ́n wulẹ̀ jẹ́ ohun tá a fi yàtọ̀ síra ni. Nígbà táwọn ará ń wo ìrìbọmi àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ya ara wọn sí mímọ́ ní erékùṣù Malta, ẹ̀rín ayọ̀ tó fi ìdùnnú àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò náà hàn pa pọ̀ mọ́ omijé ayọ̀ tó ń ṣàn lójú àwọn àlejò tó wá láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì yìí, ìyẹn àwọn ará Malta àtàwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà ló fi bí ọ̀ràn ọ̀hún ṣe rí lára wọn hàn, àmọ́ wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó yàtọ̀ síra, ìfẹ́ lílágbára tí wọ́n sì ní fún Jèhófà ló fún ìdè ìpéjọpọ̀ Kristẹni náà lókun.—Sáàmù 133:1; Kólósè 3:14.
Bíborí Ẹ̀tanú
16-18. Sọ ìrírí kan tó fi bá a ṣe lè ṣẹ́pá ẹ̀tanú hàn nínú ìjọ Kristẹni.
16 Bí ìfẹ́ wa fún Jèhófà àti fún àwọn Kristẹni arákùnrin wa ṣe ń jinlẹ̀ sí i, a lè túbọ̀ fara wé Jèhófà nínú ọ̀nà tá a gbà ń wo àwọn ẹlòmíràn. Ẹ̀tanú èyíkéyìí tá a ti lè ní sí orílẹ̀-èdè kan, ẹ̀yà kan, tàbí àṣà ìbílẹ̀ kan tẹ́lẹ̀ lè di èyí tá a borí. Wo àpẹẹrẹ ti Albert, tó wà nínú Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, tí àwọn ará Japan sì kó nígbèkùn nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun ilẹ̀ Singapore lọ́dún 1942. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá fi nǹkan bí ọdún mẹ́ta ṣiṣẹ́ ní “ojú irin tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àṣekú” nítòsí ibi tá a wá mọ̀ sí afárá tó wà lórí odò Kwai. Nígbà tí wọ́n wá tú u sílẹ̀ lẹ́yìn tí ogun parí, kìlógíráàmù méjìlélọ́gbọ̀n péré ló wọ̀n, egungun àgbọ̀n àti ti imú rẹ̀ ti fọ́, ó ń ya ìgbẹ́ ọ̀rìn, làpálàpá tún bò ó, ibà sì ń ṣe é. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí wọ́n jọ wà níbẹ̀ ní ipò wọn burú ju tiẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ ló tiẹ̀ kú síbẹ̀ pàápàá. Nítorí gbogbo ìwà ìkà bíburú jáì tí Albert fojú ara rẹ̀ rí tí wọ́n sì hù sí òun alára yìí, ó padà wálé lọ́dún 1945 pẹ̀lú ìbínú, kó sì fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run tàbí ìsìn rárá.
17 Irene tó jẹ́ ìyàwó Albert di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí Albert lè múnú aya rẹ̀ dùn, ó wá sáwọn ìpàdé bíi mélòó kan ní ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ̀. Ọ̀dọ́kùnrin Kristẹni kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Paul, tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Albert láti bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ tí Albert fi wá rí i pé bí ọkàn olúkúlùkù ṣe rí ni Jèhófà ṣe ń wo àwọn èèyàn. Ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ṣe ìrìbọmi.
18 Nígbà tó yá, Paul ṣí lọ sí London, ó kọ́ èdè Japanese níbẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè Japanese. Nígbà tó wá sọ pé òun fẹ́ mú àwọn ọmọ ilẹ̀ Japan bíi mélòó kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí wá sí ìjọ tóun wà tẹ́lẹ̀, àwọn arákùnrin tó wà níbẹ̀ rántí ẹ̀tanú kíkorò tí Albert ní sí àwọn tó wá láti àgbègbè yẹn. Àtìgbà tí Albert ti dé láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni kò ti fẹ́ rí ẹnikẹ́ni láti ilẹ̀ Japan sójú, ìyẹn ló wá ń ṣe àwọn ará ní kàyéfì nítorí pé wọ́n ò mọ ohun tó máa ṣe nínú ọ̀ràn tó délẹ̀ yìí. Wọn ì bá má tiẹ̀ dààmú rárá—tọ̀yàyàtọ̀yàyà ni Albert fi kí àwọn àlejò náà káàbọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ ará tó jinlẹ̀.—1 Pétérù 3:8, 9.
“Ẹ Gbòòrò Síwájú”
19. Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni tó lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá rí i pé a fẹ́ máa ṣe ojúsàájú?
19 Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba nì kọ̀wé pé: “Fífi ojúsàájú hàn kò dára.” (Òwe 28:21) Ó rọrùn láti sún mọ́ àwọn tá a mọ̀ dáadáa. Àmọ́ àwọn ìgbà mìíràn wà tó máa ń dà bíi pé a kì í sábà fìfẹ́ hàn sáwọn tá ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀. Irú ojúsàájú bẹ́ẹ̀ kò yẹ ìránṣẹ́ Jèhófà. Láìsí àní-àní, ó yẹ kí gbogbo wa gbìyànjú láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ṣíṣe kedere tí Pọ́ọ̀lù fúnni pé kí a “gbòòrò síwájú”—bẹ́ẹ̀ ni o, a ní láti gbòòrò síwájú nínú ìfẹ́ wa fún àwọn Kristẹni bíi tiwa tí wọ́n wá láti àwọn ibi tó yàtọ̀ síra.— 2 Kọ́ríńtì 6:13.
20. Inú àwọn nǹkan wo ló ti yẹ ká fara wé Jèhófà, Ọlọ́run wa tí kì í ṣojúsàájú?
20 Yálà a ní àǹfààní ìpè ti ọ̀run ni o tàbí a ní ìrètí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé, àìṣojúsàájú wa á mú kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn ìṣọ̀kan agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan. (Éfésù 4:4, 5, 16) Sísakun láti fara wé Jèhófà, Ọlọ́run wa tí kì í ṣojúsàájú, lè ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa, nínú ìdílé wa, àti nínú ìjọ, kódà, nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wa. Lọ́nà wo? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóó jíròrò kókó yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Òkìkí Jèhófà wá di kókó ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń kọ àwọn orin mímọ́ níkẹyìn.—Sáàmù 135:8-11; 136:11-20.
b Níhìn-ín, ọ̀rọ̀ náà “àwọn Gíríìkì” ń tọ́ka sí àwọn Kèfèrí lápapọ̀.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni Jèhófà ṣe fi àìṣojúsàájú hàn sí Ráhábù àti àwọn ará Gíbíónì?
• Báwo ni Jésù ṣe fi àìṣojúsàájú hàn nínú bó ṣe ń kọ́ni?
• Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ẹ̀tanú àṣà àti ti ẹ̀yà èyíkéyìí?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun Kénáánì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jésù ò lọ́ tìkọ̀ láti jẹ́rìí fún obìnrin ará Samáríà kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìpàdé fún gbogbo ènìyàn tá a fi èdè Amharic ṣe nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìfẹ́ tí Albert ní fún Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá ẹ̀tanú