Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Ọgọ́ta Ọdún Rèé Tó Ti Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Níṣẹ́ Míṣọ́nnárì

Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Ọgọ́ta Ọdún Rèé Tó Ti Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Níṣẹ́ Míṣọ́nnárì

Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Ọgọ́ta Ọdún Rèé Tó Ti Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Níṣẹ́ Míṣọ́nnárì

“ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ Bíbélì tá à ń fi gbogbo ara ṣe ló mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tá a sì túbọ̀ kọ́ nípa ètò àjọ rẹ̀. Èyí mú wa gbára dì láti sìn nílẹ̀ òkèèrè.” Bí ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì àkọ́kọ́ ṣe ṣàpèjúwe ẹ̀kọ́ tó kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead rèé. Látìgbà tá a ti dá a sílẹ̀ ní ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti ń rán àwọn míṣọ́nnárì jáde. Ní March 8, 2003, ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kẹrìnléláàádọ́fà wáyé ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní Patterson, New York. Àwọn èèyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, irínwó ó lé mẹ́rin [6,404] tí wọ́n wà ní gbọ̀ngàn àpéjọ náà àti láwọn ibi àpéjọ kéékèèké mìíràn tá a ṣètò fara balẹ̀ tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, èyí tó ní àsọyé, ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ nínú.

Theodore Jaracz tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ló ṣe alága lọ́jọ́ náà. Nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú tó sọ, ó mẹ́nu kan báwọn tó pé jọ síbi ayẹyẹ náà ṣe wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè, láti Éṣíà, ilẹ̀ Caribbean, Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà, Gúúsù Amẹ́ríkà àti ilẹ̀ Yúróòpù. Ìwé 2 Tímótì 4:5 ni arákùnrin Jaracz gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kà, ó sì tẹnu mọ́ olórí iṣẹ́ táwọn míṣọ́nnárì tó gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní Gílíádì ń ṣe—ìyẹn ni láti “ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere.” Àwọn míṣọ́nnárì ń jẹ́rìí sí òtítọ́ nípa kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Gba Ìtọ́ni Tó Kẹ́yìn

John Larson, tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló bẹ̀rẹ̀ àwọn àsọyé ọjọ́ náà nígbà tó sọ̀rọ̀ lórí kókó afúngbàgbọ́-lókun náà tó sọ pé “Bí Ọlọ́run Bá Wà fún Wa, Ta Ni Yóò Wà Lòdì Sí Wa?” (Róòmù 8:31) Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé àwọn ìdí tó bá Bíbélì mu tó fi yẹ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú agbára tí Jèhófà ní láti jẹ́ kí wọ́n borí ìdènà èyíkéyìí tí wọ́n lè ní lẹ́nu iṣẹ́ tá a yàn fún wọn. Arákùnrin Larson fi ìwé Róòmù 8:38, 39 gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fara balẹ̀ ná kẹ́ ẹ sì ronú jinlẹ̀ nípa bí agbára Ọlọ́run ti ń ṣiṣẹ́ nítorí yín, ẹ má sì ṣe gbà gbé pé kò sóhun náà tó lè paná ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí i yín.”

Guy Pierce, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ló sọ̀rọ̀ tẹ̀ lé e. Àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Ẹ Jẹ́ Kí Ojú Yín Máa Yọ̀!” (Lúùkù 10:23) Ó ṣàlàyé pé ayọ̀ tòótọ́ kan mímọ Jèhófà àti lílóye ète rẹ̀ ayérayé àti rírí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ibi yòówù káwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ, wọ́n lè ní ayọ̀ tòótọ́ nípa jíjẹ́ kí ojú wọn máa yọ̀. Arákùnrin Pierce fún àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà níṣìírí pé kí wọ́n máa ṣàṣàrò lórí àwọn ohun rere tí Jèhófà ṣe kí wọ́n sì pa ọkàn wọn àti èrò wọn pọ̀ sórí ṣíṣe ìfẹ́ Rẹ̀. (Sáàmù 77:12) Táwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà bá ní ẹ̀mí pé nǹkan á dára, wọ́n á lè borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá bá wọn.

Lẹ́yìn èyí làwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìdágbére látẹnu méjì lára àwọn olùkọ́ wọn tó ti ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ lójoojúmọ́. Ìbéèrè náà “Ṣé Ògo Lẹ̀ Ń Wá?” ni Lawrence Bowen fi ṣe àkòrí àsọyé tirẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló ka ògo sí gbígba ìyìn, níní ọlá àti títayọ ju àwọn ẹlòmíràn lọ. Àmọ́ ṣá, Ásáfù onísáàmù náà mọ ohun tí í ṣe ògo tòótọ́—ìyẹn ni ìṣúra aláìlẹ́gbẹ́ ti níní àjọṣe ọlọ́lá pẹ̀lú Jèhófà. (Sáàmù 73:24, 25) Wọ́n gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà níyànjú láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà nípa bíbá a lọ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀. Àwọn áńgẹ́lì ‘ń fẹ́ láti wo’ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí àwọn ète Jèhófà ṣe ń nímùúṣẹ nípasẹ̀ Kristi “ní àwòfín.” (1 Pétérù 1:12) Wọ́n fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó nípa Baba wọn kí wọ́n bàa lè gbé ògo rẹ̀ yọ. Olùbánisọ̀rọ̀ náà wá rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí pé kí wọ́n fi ògo fún Jèhófà nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn nípa ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti rí ohun ìṣúra tó jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ náà.

Wallace Liverance, tó máa ń forúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ náà, ló sọ àsọkágbá ọ̀wọ́ àkọ́kọ́ àwọn àsọyé náà pẹ̀lú àsọyé tó pe àkọlé rẹ̀ ní “Ẹ Máa Sọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Nínú Àṣírí Ọlọ́wọ̀.” (1 Kọ́ríńtì 2:7) Kí ni ọgbọ́n Ọlọ́run yìí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì rẹ̀? Ọ̀nà ọlọ́gbọ́n àti alágbára tí Jèhófà fi máa mú àlàáfíà àti ìṣọ̀kan kárí ayé wá ni. Ọgbọ́n yìí sì dá lórí Jésù. Dípò tí Pọ́ọ̀lù ì bá fi máa wàásù nípa fífi ìlànà Kristẹni yanjú ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ńṣe ló jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí Ọlọ́run ṣe máa mú àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù kúrò. (Éfésù 3:8, 9) Olùbánisọ̀rọ̀ náà gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé: “Ẹ lo àǹfààní àkànṣe iṣẹ́ ìsìn tẹ́ ẹ ní yìí bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹni tó ka iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó ń ṣe sí àǹfààní láti mú káwọn èèyàn mọ bí Jèhófà ṣe máa mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ.”

Lẹ́yìn èyí ni Mark Noumair, tóun náà jẹ́ olùkọ́ ní Gílíádì, wá ṣe alága ìjíròrò alárinrin kan tó wáyé láàárín òun àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ bíi mélòó kan ní kíláàsì náà. Àkòrí náà “Kíkẹ́kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Pèsè Àwọn Òjíṣẹ́ Onítara” gbé àwọn kókó ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà ní Róòmù 10:10 yọ. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ oríṣiríṣi ìrírí tí wọ́n ní lóde ẹ̀rí lákòókò tí wọ́n wà nílé ẹ̀kọ́ náà. Àwọn ìrírí wọn fi hàn pé tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ṣàṣàrò lé wọn lórí, àwọn ohun àgbàyanu nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ ló máa kún ọkàn wa ohun la ó sì máa sọ fáwọn èèyàn mìíràn. Láàárín oṣù márùn-ún táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lò ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n ju ọgbọ̀n lọ láwọn ìpínlẹ̀ àwọn ìjọ tó wà nítòsí tí wọ́n ti ń wàásù lóòrèkóòrè.

Ìmọ̀ràn Látẹnu Àwọn Àgbààgbà

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jàǹfààní nínú ìbákẹ́gbẹ́ wọn pẹ̀lú ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní gbogbo àkókò tí wọ́n fi wà nílé ẹ̀kọ́ náà. Robert Ciranko àti Robert P. Johnson tí wọ́n wà ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ náà fọ̀rọ̀ wá àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti ń sìn tipẹ́ lẹ́nu wò, títí kan àwọn alábòójútó arìnrìn àjò tí wọ́n ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe ní lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower. Àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gílíádì tí wọ́n sì ti fìgbà kan jẹ́ míṣọ́nnárì ni gbogbo àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò náà pátá. Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n látẹnu àwọn ẹni tẹ̀mí tó nírìírí yìí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, ìdílé wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn níṣìírí púpọ̀.

Lára ìmọ̀ràn wọn ni pé: “Ẹ jẹ́ kí ọwọ́ yín dí dáadáa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti nínú ìjọ.” “Má ṣe ka ara rẹ sí bàbàrà ju bó ṣe yẹ lọ. Fi ìdí tó o fi jẹ́ míṣọ́nnárì sọ́kàn, kó o sì sọ ibi tí wọ́n bá yàn ọ́ sí di ilé rẹ.” Àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tún jẹ́ ká mọ bí ìdálẹ́kọ̀ọ́ Gílíádì ṣe ń mú òjíṣẹ́ kan gbára dì fún iṣẹ́ rere, láìfi ibi yòówù kí wọ́n yàn án sí pè. Díẹ̀ lára wọn rèé: “A kẹ́kọ̀ọ́ pé ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ká sì máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀.” “Ilé ẹ̀kọ́ náà jẹ́ ká lè fara da àwọn àṣà ìbílẹ́ tó yàtọ̀ sí tiwa.” “A kọ́ wa ní bá a ṣe lè lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó ṣàkọ̀tun.”

John E. Barr tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso látọjọ́ pípẹ́ ló sọ lájorí àsọyé ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Àkòrí àsọyé rẹ̀ tó dá lórí Ìwé Mímọ́ ni “Ìró Wọn Jáde Lọ́ sí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé.” (Róòmù 10:18) Ó béèrè pé, Ǹjẹ́ ó ti ṣeé ṣe fáwọn èèyàn Ọlọ́run láti ṣe iṣẹ́ tó ṣòro yìí lọ́jọ́ tòní bí? Bẹ́ẹ̀ ni o! Látọdún 1881 la ti ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ pé: “Ǹjẹ́ ò ń wàásù?” Nígbà náà ni olùbánisọ̀rọ̀ náà wá rán gbogbo àwùjọ létí ìpè mánigbàgbé tó dún ní àpéjọ tó wáyé ní Cedar Point, Ohio, ní orílẹ-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1922, pé: “Ẹ polongo Ọba náà àti Ìjọba rẹ̀!” Bí àkókò ṣe ń lọ, ìtara àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run mú kí wọ́n polongo òtítọ́ ṣíṣeyebíye ti Ìjọba náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Nípa àwọn ìwé tá a tẹ̀ jáde àti ọ̀rọ̀ ẹnu, ìhìn rere náà ti dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—sí ọlá àti ìyìn Jèhófà. Arákùnrin Barr parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó runi lọ́kàn sókè, ó rọ àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà pé kí wọ́n fojú inú wo àwọn ìbùkún tí wọ́n ti rí gbà, ó ní: “Tẹ́ ẹ bá ń gbàdúrà sí Jèhófà lójoojúmọ́ níbi tá a yàn yín sí, ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ látọkànwá fún ipa tẹ́ ẹ̀ ń kó láti mú àwọn ọ̀rọ̀ náà ṣẹ pé, ‘Ìró wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé.’”

Lẹ́yìn àsọyé yìí, wọ́n ka àwọn lẹ́tà ìkíni, alága sì fún akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ní ìwé ẹ̀rí dípúlómà rẹ̀. Lẹ́yìn náà, bínú wọn ṣe ń dùn tójú sì ń ro wọ́n pé àwọn á fi ilé ẹ̀kọ́ táwọn fẹ́ràn yìí sílẹ̀ ni ẹnì kan tó ṣojú gbogbo kíláàsì náà ka ìpinnu wọn, èyí tí wọ́n kọ sí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso àti ìdílé Bẹ́tẹ́lì, tó fi ìpinnu àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà hàn pé àwọn á máa yin Jèhófà “láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 115:18.

A gbàdúrà pé kára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí mọlé níbi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lọ yìí kí wọ́n sì ṣèrànwọ́ nínú mímú kí iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé náà tẹ̀ síwájú, gẹ́gẹ́ báwọn tó ti jáde ṣáájú wọn ti ṣe fún odidi ọgọ́ta ọdún báyìí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tá a ṣojú fún: 12

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí: 16

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 34.4

Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 17.6

Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 13.5

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Kíláàsì Kẹrìnléláàádọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead

Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to àwọn orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Rosa, D.; Garrigolas, J.; Lindström, R.; Pavanello, P.; Tait, N. (2) Van Hout, M.; Donabauer, C.; Martínez, L.; Millar, D.; Festré, Y.; Nutter, S. (3) Martínez, P.; Clarke, L.; Maughan, B.; Fischer, L.; Romo, G. (4) Romo, R.; Eadie, S.; Tuynman, C.; Campbell, P.; Millar, D.; Rosa, W. (5) Lindström, C.; Garrigolas, J.; Markevich, N.; Lindala, K.; van den Heuvel, J.; Tait, S.; Nutter, P. (6) Maughan, P.; Pavanello, V.; Eadie, N.; West, A.; Clarke, D.; Markevich, J. (7) Fischer, D.; Donabauer, R.; Curry, P.; Curry, Y.; Carfagno, W.; West, M.; Tuynman, A. (8) Van Hout, M.; Campbell, C.; Festré, Y.; Carfagno, C.; van den Heuvel, K.; Lindala, D.