Jésù Kristi—Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé ó Wá Sáyé
Jésù Kristi—Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé ó Wá Sáyé
Ọ̀PỌ̀ jù lọ èèyàn ni kò rí Albert Einstein, ọkùnrin onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, tó gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta nì rí. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò tiẹ̀ mọ irú èèyàn tó jẹ́ rárá láwọn orílẹ̀-èdè kan. Síbẹ̀, àwọn ìròyìn tó ṣe é gbẹ́kẹ̀ lé nípa àwọn ohun tó ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé lóòótọ́ ló gbé ayé rí. A lè rí àwọn ohun tá a fi mọ̀ pé ó gbé ayé rí nínú báwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe ń lo àwọn àwárí tó ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń jàǹfààní iná mànàmáná àmọ́ lára àwọn ètò iná mànàmáná tá à ń lò yìí wá látinú àwárí tí ọ̀gbẹ́ni yìí ṣe.
Bí ti Jésù Kristi náà ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, ẹni tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn pè ní ọkùnrin tó lókìkí jù lọ nínú ìtàn. Ohun tá a kọ sílẹ̀ nípa rẹ̀ àtàwọn ẹ̀rí tó ṣeé fojú rí nípa bó ṣe gbajúmọ̀ tó jẹ́ ẹ̀rí lílágbára tó
fi hàn pé lóòótọ́ ló wá sáyé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn awalẹ̀pìtàn hú jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí tí orúkọ Jákọ́bù wà lára rẹ̀, èyí tá a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ṣe pàtàkì gan-an, síbẹ̀ kì í ṣe orí èyí tàbí ohun mìíràn tó dà bí rẹ̀ la gbé ìtàn Jésù kà. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé a lè rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù wá sáyé nínú ìwé táwọn òpìtàn kọ nípa rẹ̀ àti nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.Ẹ̀rí Àwọn Òpìtàn
Bí àpẹẹrẹ, gbé ohun tí Flavius Josephus tí í ṣe Farisí tó sì tún jẹ́ asọ̀tàn Júù ní ọ̀rúndún kìíní sọ yẹ̀ wò. Ó sọ̀rọ̀ nípa Jésù Kristi nínú ìwé Jewish Antiquities. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń ṣiyèméjì nípa ibi àkọ́kọ́ tí Josephus ti pe Jésù ní Mèsáyà náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Louis H. Feldman ní Yunifásítì Yeshiva sọ pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló ṣiyèméjì nípa ibì kejì tá a ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Josephus sọ níbì kejì náà pé: “[Ananíà àlùfáà àgbà] pe àwọn onídàájọ́ Sànhẹ́dírìn jọ ó sì mú ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jákọ́bù, arákùnrin Jésù ẹni tí a ń pè ní Kristi wá síwájú wọn.” (Jewish Antiquities, XX, 200) Àbí ẹ ò rí nǹkan, ẹni tó jẹ́ Farisí, tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà nínú ẹ̀ya ẹ̀sìn rẹ̀ ló jẹ́ ọ̀tá Jésù, gbà pé “Jákọ́bù, arákùnrin Jésù” gbé ayé rí.
A tún rí ẹ̀rí pé Jésù ti wá sáyé rí nínú ìgbòkègbodò àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Nígbà tí wọ́n fi àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù ní nǹkan bí ọdún 59 Sànmánì Tiwa, àwọn tí wọ́n jẹ́ sàràkí-sàràkí lára àwọn Júù sọ fún un pé: “Ní ti ẹ̀ya ìsìn yìí, a mọ̀ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.” (Ìṣe 28:17-22) Wọ́n pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní “ẹ̀ya ìsìn yìí.” Tó bá jẹ́ pé ibi gbogbo làwọn èèyàn ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí wọn, ó ṣeé ṣe káwọn òpìtàn ti ṣàkọsílẹ̀ nípa rẹ̀, àbí wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀?
Tásítọ́sì, tí wọ́n bí ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Tiwa táwọn èèyàn sì tún kà sí ọ̀kan lára àwọn àgbà òpìtàn, sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Annals. Nínú àkọsílẹ̀ tó kọ nípa bí Nérò ṣe di ẹ̀bi iná fòfò tó jó ní Róòmù lọ́dún 64 Sànmánì Tiwa ru àwọn Kristẹni, ó kọ ọ́ pé: “Nérò dẹ́bi fún ẹgbẹ́ kan táwọn èèyàn kórìíra nítorí ìwà ìríra wọn, ìyẹn àwọn ẹni táwọn èèyàn ń pè ní Kristẹni, ó sì tún dá wọn lóró lọ́nà tó burú jáì pẹ̀lú. Pípa sì ni wọ́n pa Christus ẹni tá a tinú orúkọ rẹ̀ yọ orúkọ náà Kristẹni jáde, Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ajẹ́lẹ̀ wa ló pa á nígbà tí Tìbéríù wà lórí oyè.” Kúlẹ̀kúlẹ̀ inú àkọsílẹ̀ yìí bá àwọn ìsọfúnni tá a ní nípa Jésù inú Bíbélì mu.
Òǹkọ̀wé mìíràn tó tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni Pliny Kékeré, tó jẹ́ gómìnà Bítíníà. Ní nǹkan bí ọdún 111 Sànmánì Tiwa, Pliny kọ̀wé ṣọwọ́ sí Olú Ọba Tírájánì, tó fi ń béèrè nǹkan tóun á ṣe fáwọn Kristẹni. Pliny kọ̀wé pé àwọn èèyàn táwọn kan parọ́ mọ́ pé Kristẹni ni wọ́n gbọ́dọ̀ pe àwọn èdè kan níwájú àwọn òrìṣà wọ́n sì tún gbọ́dọ̀ jọ́sìn ère Tírájánì láti fi hàn pé wọn kì í ṣe Kristẹni. Pliny tún sọ síwájú pé: “Wọ́n sọ pé wọn kì í fipá mú àwọn tó bá jẹ́ Kristẹni tòótọ́ láti ṣe èyíkéyìí lára àwọn nǹkan wọ̀nyí.” Èyí jẹ́rìí sí i pé lóòótọ́ ni Kristi wá sáyé, ẹni táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ múra tán láti fi ẹ̀mí wọn rúbọ nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú rẹ̀.
Lẹ́yìn tí ìwé The Encyclopædia Britannica (ti ọdún 2002) ti ṣàkópọ̀ báwọn òpìtàn ọ̀rúndún kìíní àti ọ̀rúndún kejì ṣe tọ́ka sí Jésù Kristi àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó parí ọ̀rọ̀ pé: “Àwọn ìtàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ̀nyí fi hàn pé nígbà àtijọ́, kódà àwọn tí wọ́n jẹ́ alátakò ẹ̀sìn Kristẹni pàápàá kò ṣiyèméjì nípa ìtàn Jésù, èyí táwọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ń ṣe awuyewuye nípa rẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ ní òpin ọ̀rúndún kejìdínlógún, láàárín ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àti ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, láìsí ìdí kan tó ṣe gúnmọ́.”
Ẹ̀rí Látọ̀dọ̀ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ pé “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹ̀rí tó fi ìtàn ìgbésí ayé Jésù àti kádàrá rẹ̀ hàn àti báwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe túmọ̀ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ ló wà nínú Májẹ̀mú Tuntun.” Àwọn oníyèméjì sì lè máà gbà pé Bíbélì jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù gbé ayé rí. Àmọ́, èrò méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a gbé karí ìtàn inú Ìwé Mímọ́ ló jẹ́ ká lè dìídì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni Jésù wá sáyé.
Gẹ́gẹ́ bá a ti kíyè sí i, àwọn àbá èrò orí ńláǹlà tí Einstein gbé kalẹ̀ fẹ̀rí hàn pé lóòótọ́ ló gbé láyé rí. Lọ́nà kan náà, àwọn ẹ̀kọ́ Jésù fi hàn pé lóòótọ́ ló gbé ayé rí. Wo àpẹẹrẹ ti Ìwàásù tó ṣe lórí Òkè, ìyẹn àsọyé tí Jésù sọ tí gbogbo èèyàn sì mọ̀ bí ẹní mowó. (Mátíù, orí 5 sí 7) Àpọ́sítélì Mátíù ṣàkọsílẹ̀ ipa tí ìwàásù náà ní lórí àwọn èèyàn, ó ní: “Háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀; nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹnì kan tí ó ní ọlá àṣẹ. (Mátíù 7:28, 29) Ọ̀jọ̀gbọ́n Hans Dieter Betz sọ̀rọ̀ lórí ipa tí ìwàásù náà ti ní lórí àwọn èèyàn láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún yìí wá, ó ní: “Ipa tí Ìwàásù Lórí Òkè ní lórí àwọn èèyàn ju ti ìsìn àwọn Júù àti ìsìn Kristẹni lọ fíìfíì, kódà ó ju ti àṣà àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé pàápàá.” Ó fi kún un pé ìwàásù náà “fani mọ́ra lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.”
Gbé àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó ṣe ṣókí tó sì gbéṣẹ́ tá a rí nínú Ìwàásù Lórí Òkè yẹ̀ wò: “Ẹnì yòówù tí ó bá gbá ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí èkejì sí i pẹ̀lú.” “Ẹ ṣọ́ra gidigidi láti má ṣe fi òdodo yín ṣe ìwà hù níwájú àwọn ènìyàn.” “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀.” “Ẹ má ṣe sọ àwọn péálì yín síwájú àwọn ẹlẹ́dẹ̀.” “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín.” “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé.” “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀.” “Gbogbo igi rere a máa mú èso àtàtà jáde.”—Mátíù 5:39; 6:1, 34; 7:6, 7, 12, 13, 16, 17.
Kò sí àní-àní pé o ti gbọ́ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tàbí àwọn kókó inú wọn. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n ti di ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn fi ń pòwe lédè rẹ. Inú Ìwàásù lórí Òkè ni gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yìí ti jáde. Ipa tí ìwàásù yìí ti ní lórí ọ̀pọ̀ èèyàn àti àṣà jẹ́rìí gbè é lẹ́yìn pé ẹnì kan tó jẹ́ “olùkọ́ ńlá” ti gbé ayé rí.
Ẹ jẹ́ ká fojú inú wò ó ná, ká ní ńṣe lẹnì kan lọ hùmọ̀ èèyàn kan tó wá pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù Kristi. Kẹ́ni yẹn wá gbọ́n débi pé ó kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ tí Bíbélì sọ pé Jésù fi kọ́ni. Ǹjẹ́ ẹni tó hùmọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yẹn ò ní sọ àsọdùn káwọn èèyàn lápapọ̀ lè tẹ́wọ́ gba Jésù àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀? Àmọ́ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ni pé: “Àwọn Júù ń béèrè àmì, àwọn Gíríìkì sì ń wá ọgbọ́n; ṣùgbọ́n àwa ń wàásù Kristi tí a kàn mọ́gi, lójú àwọn Júù okùnfà fún ìkọ̀sẹ̀ ṣùgbọ́n lójú àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀rọ̀ òmùgọ̀.” (1 Kọ́ríńtì 1:22, 23) Ìhìn nípa Kristi tí wọ́n kàn mọ́gi kò fa àwọn Júù mọ́ra páàpáà bákan náà ni kò fa àwọn orílẹ̀-èdè mọ́ra. Kristi táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní polongo rẹ̀ nìyẹn o. Kí ló wá dé tá a fi ń sọ̀rọ̀ Kristi tí wọ́n kàn mọ́gi? Àlàyé kan ṣoṣo tó lè tẹ́ni lọ́rùn sí ìbéèrè yìí ni pé ńṣe làwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ṣàkọsílẹ̀ àwọn òkodoro ọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù àti ikú rẹ̀.
Ọ̀nà ìrònú mìíràn tó tún ti ìtàn Jésù lẹ́yìn ni báwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò ṣe dẹ́kun wíwàásù àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún péré lẹ́yìn tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé ìhìn rere náà ni a ti “wàásù nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ Kólósè 1:23) Lóòótọ́, ńṣe làwọn ẹ̀kọ́ Jésù tàn kálẹ̀ láyé ìgbà yẹn láìfi àtakò pè. Pọ́ọ̀lù tóun náà jìyà inúnibíni gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, kọ̀wé pé: “Bí a kò bá tíì gbé Kristi dìde, dájúdájú, asán ni ìwàásù wa, asán sì ni ìgbàgbọ́ wa.” (1 Kọ́ríńtì 15:12-17) Tó bá jẹ́ pé asán ni wíwàásù nípa Kristi tí a kò jí dìde já sí, nígbà náà a jẹ́ pé asán lórí asán ni wíwàásù nípa Kristi tí ò tiẹ̀ wà láàyè rí máa já sí. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe kà á nínú àkọsílẹ̀ tí Pliny Kékeré kọ, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní múra tán láti kú nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jésù Kristi. Wọ́n fi ẹ̀mí wọn wewu fún Kristi nítorí pé ẹni gidi kan ni; ó ti wá sáyé rí ó sì gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tí àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere gbà sọ ọ́.
ọ̀run.” (O Ti Rí Ẹ̀rí Náà
Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde Jésù Kristi kí wọ́n tó lè wàásù. Ìwọ náà lè fojú inú rí Jésù tá a jí dìde nípa kíkíyèsí ipa tó ń kó lóde òní.
Nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n kan Jésù mọ́gi, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ lílágbára kan nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó tún sọ pé òun á jíǹde òun á sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run títí dìgbà tóun á bẹ̀rẹ̀ sí fìyà tó tọ́ jẹ àwọn ọ̀tá òun. (Sáàmù 110:1; Jòhánù 6:62; Ìṣe 2:34, 35; Róòmù 8:34) Ẹ̀yìn ìyẹn ló máa wá lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lókè ọ̀run.—Ìṣípayá 12:7-9.
Ìgbà wo ni gbogbo ìyẹn máa ṣẹlẹ̀? Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ‘àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan.’ Lára àwọn àmì tí a ó fi mọ wíwàníhìn-ín rẹ̀ tá ò lè fojú rí ni ogun, àìtó oúnjẹ, ìsẹ̀lẹ̀, àwọn èké wòlíì, ìwà àìlófin tó ń gbalẹ̀ àti àjàkálẹ̀ àrùn tó lágbára. A gbọ́dọ̀ retí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú wọ̀nyí nítorí pé lílé tá a máa lé Sátánì Èṣù kúrò lókè ọ̀run máa túmọ̀ sí ‘ègbé fún ilẹ̀ ayé.’ Èṣù ti wá sáyé, “ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” Láfikún sí i, àmì náà tún kan wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”—Mátíù 24:3-14; Ìṣípayá 12:12; Lúùkù 21:7-19.
Àwọn nǹkan tí Jésù sàsọtẹ́lẹ̀ wọn yìí ti ṣẹlẹ̀ ní ení tere èjì tere. Látìgbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ti bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1914, a ti rí ẹ̀rí tí ò ṣe é já ní koro nípa wíwàníhìn-ín Jésù Kristi lọ́nà tí ò ṣe é fojú rí. Òun ló ń ṣàkóso báyìí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ó sì ń nípa lórí àwọn èèyàn lọ́nà tó kàmàmà. Níní tó o ní ìwé ìròyìn yìí lọ́wọ́ jẹ́ ẹ̀rí pé a ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà lóde òní.
Ó di dandan kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o bàa lè túbọ̀ mọ ipa tí wíwá tí Jésù wá sáyé ń kó. O ò ṣe kúkú béèrè àlàyé kíkún nípa wíwàníhìn-ín Jésù lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Josephus, Tásítọ́sì àti Pliny Kékeré tọ́ka sí Jésù Kristi àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀
[Credit Line]
Gbogbo àwòrán mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: © Bettmann/CORBIS
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ó dá àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ lójú pé ẹni gidi kan ni Jésù