Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ẹni Rírẹlẹ̀ Láwùjọ Túmọ̀ Bíbélì

Àwọn Ẹni Rírẹlẹ̀ Láwùjọ Túmọ̀ Bíbélì

Àwọn Ẹni Rírẹlẹ̀ Láwùjọ Túmọ̀ Bíbélì

LỌ́DÚN 1835, Henry Nott, bíríkìlà kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àti John Davies, ará Wales tó ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń ta àwọn ọjà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, parí iṣẹ́ bàǹtàbanta kan tí wọ́n dáwọ́ lé. Lẹ́yìn iṣẹ́ àṣelàágùn tí wọ́n ti fi ohun tó lé ní ọgbọ̀n ọdún ṣe, wọ́n parí títúmọ̀ odindi Bíbélì sí èdè Tahiti. Kí lojú àwọn ọkùnrin méjì yìí tí wọ́n jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ láwùjọ rí nídìí iṣẹ́ náà, kí sì ni àbájáde iṣẹ́ tí wọn ò tìtorí owó ṣe náà?

“Ẹgbẹ́ Amúnisọjí”

Láàárín ọdún 1751 sí ọdún 1800, àwọn èèyàn kan tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n ń pè ní ẹgbẹ́ Amúnisọjí, bẹ̀rẹ̀ sí wàásù káàkiri àwọn abúlé, àwọn àgbègbè ibi ìwakùsà àtàwọn ilé iṣẹ́ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ohun tó wà lórí ẹ̀mí wọn ni láti wàásù fáwọn tó jẹ́ òṣìṣẹ́. Pẹ̀lú ìtara ni ẹgbẹ́ Amúnisọjí yìí fi ń pín Bíbélì fáwọn èèyàn.

Ẹlẹ́sìn Onítẹ̀bọmi kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ William Carey, ló dá ẹgbẹ́ náà sílẹ̀, ó sì wà lára àwọn tó dá Ẹgbẹ́ Àwọn Míṣọ́nnárì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sílẹ̀ lọ́dún 1795. Ẹgbẹ́ yìí ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn tó múra tán láti kọ́ èdè tí wọ́n ń sọ ní agbègbè Gúúsù Pàsífíìkì kí wọ́n sì máa lọ ṣe míṣọ́nnárì níbẹ̀. Ohun tó wà lórí ẹ̀mí àwọn míṣọ́nnárì yìí ni pé káwọn fi èdè táwọn èèyàn àgbègbè náà ń sọ wàásù Ìhìn Rere náà fún wọn.

Erékùṣù Tahiti, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni ibi àkọ́kọ́ táwọn míṣọ́nnárì tí Ẹgbẹ́ Àwọn Míṣọ́nnárì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì rán jáde ti kọ́kọ́ wàásù. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Amúnisọjí ní tiwọn ka àwọn erékùṣù wọ̀nyí sí ‘agbègbè ojú dúdú’ tó jẹ́ tàwọn kèfèrí, ibi tó yẹ káwọn ti ṣe iṣẹ́ ìkórè náà.

Àwọn Ẹni Rírẹlẹ̀ Láwùjọ Ṣe Iṣẹ́ Bàǹtàbanta Kan Láṣeyọrí

Láti ṣe iṣẹ́ ìkórè náà níbẹ̀, kíákíá ni wọ́n yan àwọn míṣọ́nnárì bí ọgbọ̀n tí wọn ò gbára dì tó bó ti yẹ, táwọn náà sì kó sínú ọkọ̀ Duff, ìyẹn ọkọ̀ òkun tí Ẹgbẹ́ Àwọn Míṣọ́nnárì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì rà láti rìnrìn àjò ọ̀hún. Àkọsílẹ̀ kan to orúkọ àwọn èèyàn tó lọ lẹ́sẹẹsẹ: “àlùfáà mẹ́rin [tí wọ́n ò tíì gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́], káfíńtà mẹ́fà, aránbàtà méjì, bíríkìlà méjì, ahunṣọ méjì, aránṣọ méjì, olùtajà kan, ẹnì kan tó ń rán awọ tí wọ́n fi ń jókòó lórí ẹṣin, ọmọ ọ̀dọ̀ kan, àgbẹ̀ kan, oníṣègùn kan, àlágbẹ̀dẹ kan, ẹnì kan tó máa ń fi pákó kọ́ ilé ohun ọ̀sìn, ẹnì kan tó ń ṣe òwú, ẹnì kan tó ń ṣe fìlà, ẹnì kan tó ń ṣe aṣọ, ẹnì kan tó máa ń kan kọ́ńbọ́ọ̀dù, ìyàwó ilé márùn-ún àtàwọn ọmọdé mẹ́ta.”

Gbogbo ohun èèlò táwọn míṣọ́nnárì yìí ní tí wọ́n fi lè lóye àwọn èdè tá a fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ kò ju ìwé atúmọ̀ èdè Gíríìkì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Bíbélì kan pẹ̀lú ìwé atúmọ̀ èdè Hébérù kan. Láàárín oṣù méje tí wọ́n fi wà lójú òkun, àwọn míṣọ́nnárì náà há àwọn ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan lédè Tahiti sórí, ìyẹn èyí tí wọ́n gbọ́ látọ̀dọ̀ àwọn tó ti lọ síbẹ̀ rí tí èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn jẹ́ àwọn tó ja ìjà àjàkú-akátá nínú ọkọ̀ òkun tí wọ́n ń pè ní Bounty. Nígbà tó yá, ọkọ̀ òkun Duff gúnlẹ̀ sí Tahiti, àwọn míṣọ́nnárì náà sì jáde nínú rẹ̀ ní March 7, 1797. Àmọ́ ní ọdún kan lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ lára wọn ni ipò nǹkan ti tojú sú tí wọ́n sì ti kúrò níbẹ̀. Kìkì míṣọ́nnárì méje péré ló ṣẹ́ kù.

Henry Nott tó jẹ́ bíríkìlà tẹ́lẹ̀, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn méje náà. Ẹni ọdún mẹ́tàlélógún péré sì ní nígbà náà. Tá a bá fojú àwọn lẹ́tà tó kọ́kọ́ kọ wò ó, àá rí i pé ìwé díẹ̀ ló kà. Àmọ́ ṣá, látìbẹ̀rẹ̀ ló ti fi hàn pé òun lẹ́bùn kíkọ́ èdè Tahiti. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé ó jẹ́ ẹnì kan tí kì í figbá kan bọ̀kan nínú, tí kò walé ayé máyà tó sì jẹ́ ẹni àríkẹ́ àríyọ̀.

Lọ́dún 1801, wọ́n yan Nott pé kó máa kọ́ àwọn míṣọ́nnárì mẹ́sàn-án mìíràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lédè Tahiti. Lára àwọn wọ̀nyí ni Welshman John Davies, ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n tó jẹ́ àkẹ́kọ̀ọ́ tó já fáfá àti òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́. Kì í bínú, ọ̀làwọ́ ẹ̀dá sì ni. Kò pẹ́ rárá táwọn ọkùnrin méjì wọ̀nyí fi pinnu pé àwọn á túmọ̀ Bíbélì sí èdè Tahiti.

Iṣẹ́ Bàǹtàbanta Kan

Ṣé ẹ rí i, iṣẹ́ ńlá ni títúmọ̀ Bíbélì sí èdè Tahiti jẹ́, nítorí pé wọn ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí kọ èdè náà sílẹ̀ nígbà yẹn. Àwọn míṣọ́nnárì náà ní láti kọ́ èdè ọ̀hún nípa fífetí lásán gbọ́ ọ. Kò síwèé atúmọ̀ èdè tàbí ìwé gírámà kankan lédè náà. Bí èdè yìí ṣe máa ń dún téèyàn bá ń sọ ọ́, bó ṣe jẹ́ pé ńṣe làwọn fáwẹ̀lì tẹ̀ lé ara wọn (odidi fáwẹ̀lì márùn-ún lè wà nínú ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo), àti bó ṣe jẹ́ pé ìwọ̀nba kọ́ńsónáǹtì díẹ̀ ló ní mú kó fẹ́ sú àwọn míṣọ́nnárì náà. Wọ́n sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ló jẹ́ pé kìkì fáwẹ̀lì ni, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì ní bó ṣe ń dún.” Wọn sọ pé àwọn ò lè “gbọ́ ìro àwọn ọ̀rọ̀ náà ní kíkún, kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.” Àní sẹ́, wọ́n tiẹ̀ ronú pé àwọn gbọ́ àwọn ìró kan tí ò sírú rẹ̀ láyé!

Ohun tó tún mú kí ọ̀rọ̀ náà tún burú ni pé látìgbàdégbà ni wọ́n máa ń fòfin de àwọn ọ̀rọ̀ kan ní èdè Tahiti, pé wọn ò gbọ́dọ̀ sọ wọ́n mọ́, ó sì di pé kí wọ́n wá ọ̀rọ̀ mìíràn rọ́pò wọn. Ìṣòro mìíràn tún ni ti àwọn ọ̀rọ̀ tó pọ̀ lọ jàra àmọ́ tó jẹ́ pé ohun kan náà ni wọ́n túmọ̀ sí. Oríṣi ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí “àdúrà” ní èdè Tahiti lé ní àádọ́rin. Ìṣòro mìíràn tún ni pé ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣètò àwọn ọ̀rọ̀ lédè Tahiti yàtọ̀ gan-an sí ti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo ìṣòro yìí, àwọn míṣọ́nnárì náà ṣe é wẹ́rẹ́ wẹ́rẹ́ títí wọ́n fi kó àwọn ọ̀rọ̀ jọ èyí tí Davies wá fi ṣe ìwé atúmọ̀ èdè ní àádọ́ta ọdún lẹ́yìn náà. Ẹgbàárùn-ún [10,000] ọ̀rọ̀ ló wà nínú ìwé atúmọ̀ èdè náà.

Ìṣòro mìíràn tó wá jẹ yọ ni bí wọ́n á ṣe máa kọ èdè Tahiti sílẹ̀. Làwọn míṣọ́nnárì yìí bá ní káwọn dá a bí ọgbọ́n pé káwọn lo àkọtọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́ ṣá, ááfábẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ń lò lédè Gẹ̀ẹ́sì ò bá ìró èdè Tahiti mu páàpáà. Èyí sì fa ìjíròrò àṣeèṣetán nípa ìró ohùn àti ọ̀nà ìkọ̀wé. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn míṣọ́nnárì yìí fúnra wọn ṣẹ̀dá sípẹ́lì tuntun nítorí pé àwọn lẹni àkọ́kọ́ tó máa ṣètò kíkọ èdè tí wọ́n ń fẹnu sọ sílẹ̀ lágbègbè àwọn Òkun Gúúsù. Àwọn aráabí wọ̀nyí ò sì mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ló máa di àwòkọ́ṣe fún ọ̀pọ̀ èdè lágbègbè Gúúsù Pàsífíìkì nígbà tó bá yá.

Irinṣẹ́ Wọn Ò Tó Nǹkan, àmọ́ Orí Wọ́n Pé

Kìkì ìwé díẹ̀ làwọn olùtúmọ̀ yìí ní tí wọ́n lè ṣèwádìí nínú rẹ̀. Ẹgbẹ́ Àwọn Míṣọ́nnárì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé kí wọ́n gbé ìtumọ̀ wọn ka Textus Receptus àti ìtumọ̀ King James Version. Nott sọ pé kí ẹgbẹ́ yìí fi àwọn ìwé atúmọ̀ èdè lédè Hébérù àti Gíríìkì ránṣẹ́ sóun, kí wọ́n sì tún fi Bíbélì ránṣẹ́ ní èdè méjèèjì. Bóyá ó rí àwọn ìwé náà gbà o tàbí kò rí wọn gbà, kò sẹ́ni tó yé. Davies ní tiẹ̀ rí àwọn ìwé táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kọ gbà látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ará Wales. Àkọsílẹ̀ fi hàn pé ó ní ó kéré tán, ìwé atúmọ̀ èdè Gíríìkì kan, Bíbélì èdè Hébérù kan, Májẹ̀mú Tuntun lédè Gíríìkì àti Septuagint.

Ní gbogbo àkókò yìí, iṣẹ́ ìwàásù àwọn míṣọ́nnárì náà ò méso jáde. Odidi ọdún méjìlá gbáko làwọn míṣọ́nnárì náà ti wà ní Tahiti, àmọ́ kò sí ẹnì kan ṣoṣo látibẹ̀ tó ṣèrìbọmi. Nígbà tó yá, ogun abẹ́lé tí ò dáwọ́ dúró mú kí gbogbo àwọn míṣọ́nnárì náà sá lọ sí Ọsirélíà, àmọ́ Nott ní tiẹ̀ ò lọ. Fún àkókò díẹ̀, òun nìkan ni míṣọ́nnárì tó ṣẹ́ kù ní gbogbo Erékùṣù Windward tó jẹ́ ara Erékùṣù Society. Àmọ́ ó tẹ̀ lé Ọba Pomare Kejì nígbà tíyẹn sá lọ sí erékùṣù Moorea tí ò jìnnà síbẹ̀.

Àmọ́ o, pé Nott kúrò níbi tó wà tẹ́lẹ̀ ò ní kí iṣẹ́ ìtumọ̀ náà dáwọ́ dúró o, Davies sì padà wá bá a lẹ́yìn tóun ti lo ọdún méjì ní Ọsirélíà. Ní gbogbo àkókò yìí, Nott ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ èdè Gíríìkì àti èdè Hébérù ó sì ti di ìjìmì nínú èdè méjèèjì. Èyí ló fi bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ díẹ̀ lára Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù sí èdè Tahiti. Ó ṣàṣàyàn àwọn ìwé Bíbélì tó láwọn àkọsílẹ̀ táwọn ará àgbègbè náà á tètè lóye.

Nípa bíbá Davies ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, Nott wá bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ Ìhìn Rere Lúùkù, èyí tó parí títúmọ̀ rẹ̀ ní September 1814. Ó ṣàkópọ̀ ìtumọ̀ náà lọ́nà tí wọ́n gbà ń sọ ọ́ gẹ́lẹ́ lédè Tahiti, Davies sì ṣàyẹ̀wò ìtúmọ̀ náà láti rí i pé ó péye. Lọ́dún 1817, Ọba Pomare Kejì sọ pé kí wọ́n jẹ́ kóun fúnra òun tẹ ojú ìwé àkọ́kọ́ ìwé Ìhin Rere Lúùkù. Ó tẹ̀ ẹ́ jáde lórí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ọlọ́wọ́ táwọn míṣọ́nnárì kan gbé wá sí Moorea. Tá a bá ń sọ ìtàn bá a ṣe túmọ̀ Bíbélì sí èdè Tahiti, a ò gbọ́dọ̀ máà dárúkọ ọ̀gbẹ́ni ará Tahiti kan tó ń jẹ́ Tuahine. Ọ̀gbẹ́ni yìí ò fìgbà kan kúrò lọ́dọ̀ àwọn míṣọ́nnárì yìí ní gbogbo ọdún tí wọ́n fi ṣe ìtúmọ̀ náà, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ èdè náà.

Wọ́n Parí Ìtúmọ̀ Náà

Ní 1819, lẹ́yìn ọdún mẹ́fà gbáko tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ àṣekára, wọ́n parí títúmọ̀ àwọn ìwé Ìhìn Rere, Ìṣe àwọn Àpọ́sítélì àtàwọn ìwé Sáàmù. Wọn wá fi àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé táwọn míṣọ́nnárì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé gbé wá tẹ̀ ẹ́ jáde wọ́n sì pín in káàkiri fáwọn èèyàn.

Lẹ́yìn èyí ni wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ títúmọ̀, kíkàwéṣàtúnṣe àti ṣíṣe àtúntẹ̀. Lẹ́yìn tí Nott ti gbé ní Tahiti fún odindi ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣòjòjò lọ́dún 1825, Ẹgbẹ́ Àwọn Míṣọ́nnárì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì sọ pé kó padà sí ilẹ̀ England. Ó dùn mọ́ni pé wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí títúmọ̀ Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì nígbà náà. Ó ń bá ìtumọ̀ Bíbélì náà nìṣó bó ṣe ń rìnrìn àjò rẹ̀ padà sí ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì àti láàárín àkókò tó fi wà níbẹ̀. Nott padà sí Tahiti lọ́dún 1827. Ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, ìyẹn ní December 1835, ó ṣíwọ́ iṣẹ́ títúmọ̀. Lẹ́yìn ohun tó lé ní ọgbọ̀n ọdún tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ àṣekára nídìí títúmọ̀, wọ́n parí títúmọ̀ òdindi Bíbélì látibẹ̀rẹ̀ dópin.

Nígbà tó di ọdún 1836, Nott padà wá sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti wá tẹ odindi Bíbélì lédè Tahiti jáde nílùú London. Ní June 8, 1838, tìdùnnú-tìdùnnú ni Nott fi fi ẹ̀dà àkọ́kọ́ Bíbélì ní èdè Tahiti lé Ọbabìnrin Victoria lọ́wọ́. Èyí kò yani lẹ́nu o nítorí pé ó ti pé ogójì ọdún sẹ́yìn báyìí tí bíríkìlà tẹ́lẹ̀ rí yìí rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ òkun tí wọ́n ń pè ní Duff tó sì fi gbogbo ara kọ́ àṣà àwọn ará Tahiti kó bàa lè parí iṣẹ́ bàǹtàbanta náà èyí tó máa wà títí ayé.

Ní oṣù méjì lẹ́yìn èyí, Nott padà sí Gúúsù Pàsífíìkì pẹ̀lú páálí mẹ́tàdínlógún tó fi kó ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ẹ̀dá odindi Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde lédè Tahiti. Lẹ́yìn tó dúró díẹ̀ ní Sydney, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣòjòjò, àmọ́ kò fẹ́ fi àwọn páálí ṣíṣeyebíye náà sílẹ̀ rárá. Lẹ́yìn tára rẹ̀ yá, ó dé Tahiti ní 1840, àwọn èèyàn ibẹ̀ sì ya bo ọkọ̀ ẹrù ìwé náà tí wọ́n ń du Bíbélì èdè Tahiti mọ́ra wọn lọ́wọ́ wìtìwìtì. Nott kú ní Tahiti ní May 1844 lẹ́ni àádọ́rin ọdún.

Ipa Tó Ní Délé Dóko

Àmọ́ o, iṣẹ́ ọwọ́ Nott ń gbélé ayé fọhùn o. Ìtumọ̀ tó ṣe nípa lórí èdè àwọn ará Polynesia gan-an ni. Sísọ táwọn míṣọ́nnárì yìí sọ èdè Tahiti di èyí tó ṣe é kọ sílẹ̀ ni kò jẹ́ kí èdè náà run. Òǹṣèwé kan sọ pé: “Nott ló jẹ́ kí gírámà èdè Tahiti tó jẹ́ àfiṣàpẹẹrẹ wà lákọọ́lẹ̀. Dandan ni kéèyàn gbé Bíbélì tó bá fẹ́ kọ́ ojúlówó èdè Tahiti.” Iṣẹ́ àṣekára táwọn olùtúmọ̀ yìí ṣe ni ò jẹ́ kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀rọ̀ re oko ìgbàgbé. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, òǹṣèwé kan sọ pé: “Bíbélì èdè Tahiti tí Nott ṣe tí ò láfiwé jẹ́ àgbàyanu iṣẹ́ lédè Tahiti—kò sẹ́nì kankan tó sì sọ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀.”

Àwọn ará Tahiti nìkan kọ́ ni iṣẹ́ pàtàkì yìí ṣe láǹfààní o, àmọ́ ó tún jẹ́ ìpìlẹ̀ fáwọn ìtumọ̀ mìíràn láwọn èdè Gúúsù Pàsífíìkì. Bí àpẹẹrẹ, òun làwọn atúmọ̀ èdè láwọn Erékùṣù Cook àti Samoa fi ń ṣe àwòkọ́ṣe. Atumọ̀ èdè kan sọ pé: “Ọ̀gbẹ́ni Nott lèmi ń tẹ̀ lé ní tèmi o nítorí pé mo ti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìtúmọ̀ tó ṣe.” A gbọ́ pé atúmọ̀ èdè mìíràn ‘kó àwọn ìwé Sáàmù lédè Hébérù àti èdè Gẹ̀ẹ́sì àti ti èdè Tahiti tira’ nígbà tó ń ‘túmọ̀ ọ̀kan lára àwọn sáàmù Dáfídì sí èdè Samoa.’

Àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní Tahiti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó wà nínú Ẹgbẹ́ Amúnisọjí ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n fi ìgbónára gbárùkù ti ètò táá mú káwọn èèyàn kúrò ní púrúǹtù. Kódà, ó lé ní odindi ọ̀rúndún kan tí Bíbélì fi jẹ́ ìwé kan ṣoṣo táwọn ará Tahiti lè rí kà. Èyí ló mú kó di ìwé tá ò lè kóyán rẹ̀ kéré nínú àṣà àwọn ará Tahiti.

Ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì tó wà nínú Ìtumọ̀ Nott ni bó ṣe lo orúkọ Ọlọ́run láwọn ibi púpọ̀ nínú Ìwé Mímọ́ lédé Hébérù àti lédè Gíríìkì. Èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé nílé lóko làwọn èèyàn ti mọ orúkọ Jèhófà ní Tahiti àti láwọn erékùṣù rẹ̀ lóde òní. Ó tiẹ̀ tún wà lára àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì kọ̀ọ̀kan pàápàá. Àmọ́ ṣá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn èèyàn mọ̀ mọ́ orúkọ Ọlọ́run gan-an lónìí bákan náà ni wọ́n mọ̀ wọ́n mọ́ ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń fi ìtara ṣe. Nínú èyí tó jẹ́ pé lójú méjèèjì ni wọ́n ń lo Bíbélì lédè Tahiti tí Nott àtàwọn yòókù rẹ̀ túmọ̀. Bákan náà, iṣẹ́ àṣekára táwọn atúmọ̀ èdè bíi Henry Nott ṣe ránni létí bó ṣe yẹ́ kí inú wa dùn tó pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà lárọ̀ọ́wọ́tó ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn lóde òní.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì lédè Tahiti tá a kọ́kọ́ ṣe lọ́dún 1815. Orúkọ Jèhófà wà nínú rẹ̀

Henry Nott (1774 sí 1844), atúmọ̀ èdè tó ṣe bẹbẹ nínú títú Bíbélì sí èdè Tahiti

[Àwọn Credit Line]

Bíbélì èdè Tahiti: Copyright the British Library (3070.a.32); Henry Nott àti lẹ́tà: Collection du Musée de Tahiti et de ses Îles, Punauia, Tahiti; katikísìmù: Pẹ̀lú ìyọ̀ǹda the London Missionary Society Papers, Alexander Turnbull Library, Wellington, New Zealand

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Katikísìmù tó wà lédè àwọn ará Tahiti àti tàwọn ará Wales lọ́dún 1801, níbi tí orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn

[Credit Line]

Pẹ̀lú ìyọ̀ǹda the London Missionary Society Papers, Alexander Turnbull Library, Wellington, New Zealand

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n kọ orúkọ Jèhófà síwájú rẹ̀ ní erékùṣù Huahine, ní ilẹ̀ French Polynesia

[Credit Line]

Avec la permission du Pasteur Teoroi Firipa