Béèyàn Ṣe Lè ní Ojúlówó Ìfẹ́
Béèyàn Ṣe Lè ní Ojúlówó Ìfẹ́
“Ìfẹ́ ni gbogbo-ǹ-ṣe ìgbésí ayé; ìfẹ́ ni ìwàláàyè.”—Living to Purpose, láti ọwọ́ Joseph Johnson, 1871.
BÁWO lèèyàn ṣe ń kọ́ bá a ṣe ń nífẹ̀ẹ́? Ṣé nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrònú òun ìhùwà ni? Ṣé nípa kíka àwọn ìwé tí ń pèsè ìmọ̀ràn bí-a-ti-í-ṣe-é ni? Àbí nípa wíwo àwọn sinimá táwọn èèyàn ti ń tage? Rárá o. Ibi táwọn èèyàn ti kọ́kọ́ máa ń kọ́ bá a ṣe ń nífẹ̀ẹ́ ni ìgbà tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àti ẹ̀kọ́ àwọn òbí wọn. Àwọn ọmọ yóò kọ́ ohun tí ìfẹ́ túmọ̀ sí tó bá jẹ́ pé àyíká táwọn èèyàn ti nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú ni wọ́n wà, tí wọ́n ń rí i táwọn òbí wọn ń bọ́ wọn, tí wọ́n ń dáàbò bò wọ́n, tí wọ́n ń bá wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì fẹ́ràn wọn dénúdénú. Wọ́n tún máa ń kọ́ béèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́ nígbà táwọn òbí wọn bá kọ́ wọn láti pa àwọn ìlànà yíyè kooro lórí ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́ mọ́.
Ojúlówó ìfẹ́ ju ká kàn fẹ́ràn èèyàn lóréfèé lọ. Ó máa múni hùwà lọ́nà tó fi hàn pé a ní ire àwọn ẹlòmíràn lọ́kàn, bí wọn ò tiẹ̀ mọrírì rẹ̀ lákòókò yẹn, bó ṣe sábà máa ń rí nínú ọ̀ràn àwọn ọmọdé nígbà tá a bá ń fún wọn ní ìbáwí onífẹ̀ẹ́. Àpẹẹrẹ pípé kan tó jẹ́ tẹni tó fìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan hàn ni ti Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọmọ mi, má fi ojú kékeré wo ìbáwí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni kí o má rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá tọ́ ọ sọ́nà; nítorí ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí.”—Hébérù 12:5, 6.
Ẹ̀yin òbí, báwo lẹ ṣe lè fara wé Jèhófà nínú fífi ìfẹ́ hàn sí ìdílé yín? Báwo sì ni àpẹẹrẹ tẹ́ ẹ fi lélẹ̀ nínú àjọṣe àárín ẹ̀yin méjèèjì gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti aya ti ṣe pàtàkì tó?
Fi Àpẹẹrẹ Bí A Ṣe Ń Fi Ìfẹ́ Hàn Kọ́ni
Tó o bá jẹ́ ọkọ, ǹjẹ́ o máa ń buyì fún aya rẹ tàbí kó o gbé e gẹ̀gẹ̀, kó o sì bá a lò tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀? Tó o bá jẹ́ aya, ṣé aya tó nífẹ̀ẹ́ tó sì ń ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn ni ọ́? Bíbélì sọ pé ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn pẹ̀lú. (Éfésù 5:28; Títù 2:4) Nígbà tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ á fojú ara wọn rí ohun tó ń jẹ́ ìfẹ́ Kristẹni ní tààràtà. Ẹ ò rí irú ẹ̀kọ́ tó lágbára tó sì ṣeyebíye tíyẹn lè jẹ́!
Àwọn òbí tún máa ń jẹ́ kí ìfẹ́ wà nínú ilé nígbà tí wọn ò bá fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn ìlànà gíga tí wọ́n gbé kalẹ̀ fún ìdílé wọn lórí àwọn nǹkan bí eré ìdárayá, ìwà híhù, àti àwọn góńgó tí wọ́n gbé ka iwájú wọn àtàwọn ohun tí wọ́n fi ṣe ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wọn. Jákèjádò ayé làwọn èèyàn ti rí i pé Bíbélì ń ṣèrànwọ́ gan-an nínú gbígbé irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀ kalẹ̀ fún ìdílé, tó fi ẹ̀rí hàn pé ní ti tòótọ́ ní 2 Tímótì 3:16) Àní sẹ́, gbogbo èèyàn ló ti rí i pé àwọn ìlànà ìwà rere àti ọ̀nà téèyàn lè gbà gbé ìgbésí ayé bó ṣe wà nínú Ìwàásù Lórí Òkè kò láfiwé.—Mátíù, orí 5 sí 7.
Bíbélì jẹ́ ìwé tí “Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (Nígbà tí gbogbo ìdílé bá ń wojú Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, ọkàn olúkúlùkù yóò balẹ̀, ìyẹn sì lè jẹ́ káwọn ọmọ dàgbà dẹni tó nífẹ̀ẹ́ tó sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn. Ní ọ̀nà kejì, àwọn ọmọ lè dẹni tá a dá lágara, kí wọ́n máa bínú, kí wọ́n sì di ọlọ̀tẹ̀ nínú ilé táwọn òbí bá ti jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, tí ìlànà tí wọ́n gbé kalẹ̀ ò nítumọ̀, tí ò sì ṣe gúnmọ́.—Róòmù 2:21; Kólósè 3:21.
Àwọn òbí tó ń dá nìkan tọ́mọ ńkọ́? Ǹjẹ́ ipò tí wọ́n wà burú débi tí wọn ò fi ní lè kọ́ àwọn ọmọ wọn béèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́? Ó lè máà rí bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tó dà bíi kéèyàn ní ìyá tó dáa àti bàbá rere tí wọ́n jọ jẹ́ òṣùṣù ọwọ̀, síbẹ̀ ìrírí ti fi hàn pé bí àjọṣe tó ṣe gúnmọ́ bá wà nínú ìdílé, ìyẹn lè máà jẹ́ kí wọ́n mọ òbí tí ò sí nítòsí lára. Tó o bá jẹ́ òbí tó ń dá tọ́mọ, gbìyànjú láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ilé rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni o, òwe kan sọ fún wa pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́”—títí kan ipa ọ̀nà jíjẹ́ òbí.—Òwe 3:5, 6; Jákọ́bù 1:5.
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó ń ṣe déédéé la tọ́ dàgbà nínú ìdílé olóbìí kan tí wọ́n sì ń fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run báyìí nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìjọ Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé. Èyí jẹ́rìí sí i pé àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ pẹ̀lú lè ṣàṣeyọrí nínú kíkọ́ àwọn ọmọ wọn béèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́.
Bí Gbogbo Èèyàn Ṣe Lè Nífẹ̀ẹ́
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àìsí “ìfẹ́ni àdánidá” yóò jẹ́ àmì “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìyẹn ni àìsí ìfẹ́ àdánidá táwọn tó jọ jẹ́ ara ìdílé kan náà máa ń ní fún ara wọn. (2 Tímótì 3:1, 3) Síbẹ̀, àwọn tá a tọ́ dàgbà níbi tí kò ti sí ìfẹ́ pàápàá lè kẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìfẹ́. Lọ́nà wo? Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, tó jẹ́ Orísun ìfẹ́ gan-an, tó sì ń fi ìfẹ́ àti ọ̀yàyà hàn sí gbogbo àwọn tó bá yíjú sí i tọtàntọkàn. (1 Jòhánù 4:7, 8) Onísáàmù kan sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.”—Sáàmù 27:10.
Jèhófà ń fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí wa ní onírúurú ọ̀nà. Lára àwọn ọ̀nà náà ni ìtọ́sọ́nà bíi ti bàbá nípasẹ̀ Bíbélì, ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, àti ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ tí ẹgbẹ́ àwọn ará tó jẹ́ Kristẹni ń fúnni. (Sáàmù 119:97-105; Lúùkù 11:13; Hébérù 10:24, 25) Ronú lórí bí ọ̀nà mẹ́ta tá a sọ yìí ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò.
Ìtọ́sọ́nà Onímìísí Bíi Ti Bàbá
Kí àjọṣe tímọ́tímọ́ tó lè wà láàárín àwa àti ẹnì kan, a gbọ́dọ̀ mọ onítọ̀hún dáadáa. Jèhófà ń ké sí wa pé ká sún mọ́ òun nípa fífi ara rẹ̀ hàn wá nípasẹ̀ Bíbélì. Àmọ́ o, kíka Bíbélì nìkan kò tó. A gbọ́dọ̀ fi àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ sílò ká lè rí àwọn àǹfààní tó ń tibẹ̀ jáde. (Sáàmù 19:7-10) Ìwé Aísáyà 48:17 sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà, tó jẹ́ àpẹẹrẹ ìfẹ́ gan-an, ń tọ́ wa sọ́nà fún àǹfààní ara wa—kì í ṣe pé ó fẹ́ fi àwọn òfin àti àṣẹ kan tí kò ní láárí ká wa lọ́wọ́ kò.
Ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bíi tiwa. Ìdí èyí ni pé òtítọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwa Fílípì 1:9.
èèyàn, ó sì fi àwọn ìlànà tó yẹ kó darí bá a ṣe ń bá ara wa lò hàn wá. Pẹ̀lú irú ìsọfúnni yẹn, a nídìí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èyí sì ni ohun tí mo ń bá a lọ ní gbígbàdúrà, pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún.”—Láti ṣàpèjúwe ọ̀nà tí “ìmọ̀ pípéye” fi lè darí ìfẹ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, gbé òtítọ́ pàtàkì tó wà nínú ìwé Ìṣe 10:34, 35 yẹ̀ wò, èyí tó sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ òdodo táwọn èèyàn ṣe àti ìbẹ̀rù tí wọ́n ní fún Ọlọ́run ní ohun tí Ọlọ́run ń wò, tí kò ro ti orílẹ̀-èdè wọn tàbí ẹ̀yà wọn, ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà máa wo àwọn èèyàn bíi tiwa lọ́nà kan náà láìṣe ojúsàájú?—Ìṣe 17:26, 27; 1 Jòhánù 4:7-11, 20, 21.
Ìfẹ́—Ọ̀kan Lára Èso Ẹ̀mí Ọlọ́run
Gẹ́gẹ́ bí òjò tó rọ̀ sórí igi eléso kan lásìkò tó yẹ yóò ṣe jẹ́ kí igi náà mú èso tó pọ̀ jáde, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀mí Ọlọ́run yóò ṣe jẹ́ káwọn elétí ọmọ ní àwọn ànímọ́ tí Bíbélì ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “èso ti ẹ̀mí.” (Gálátíà 5:22, 23) Èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ pàá nínú àwọn ànímọ́ yìí ni ìfẹ́. (1 Kọ́ríńtì 13:13) Àmọ́ báwo la ṣe ń rí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà? Ọ̀nà pàtàkì kan ni nípasẹ̀ àdúrà. Bá a bá gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀, yóò fi í fún wa. (Lúùkù 11:9-13) Ǹjẹ́ ò ń “bá a nìṣó” ní gbígbàdúrà láti rí ẹ̀mí mímọ́ gbà? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àwọn ànímọ́ rẹ̀ ṣíseyebíye, tí ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára wọn yóò túbọ̀ máa fara hàn nínú ìgbésí ayé rẹ.
Àmọ́ ṣá o, ẹ̀mí mìíràn tún wà tó ń ṣiṣẹ́ lòdì sí ẹ̀mí Ọlọ́run. Bíbélì pe èyí ní “ẹ̀mí ayé.” (1 Kọ́ríńtì 2:12; Éfésù 2:2) Ipa búburú ni, kò sì ní orísun mìíràn yàtọ̀ sí Sátánì Èṣù, tó jẹ́ “olùṣàkóso ayé yìí,” ìyẹn ìran ènìyàn tó sọ ara wọn dàjèjì sí Ọlọ́run. (Jòhánù 12:31) Bí ẹ̀fúùfù tó ń fọ́n ekuru káàkiri tó sì ń da àwọn nǹkan rú, bẹ́ẹ̀ náà ni “ẹ̀mí ayé” ṣe máa ń ru ìfẹ́ ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ sókè, èyí tó ń ba ìfẹ́ jẹ́ tó sì ń gbé àwọn àìlera ẹran ara lárugẹ.—Gálátíà 5:19-21.
Àwọn èèyàn máa ń ní ẹ̀mí búburú yìí nígbà tí wọ́n bá sọ ara wọn di onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, tí wọ́n ń ní ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá, tí wọ́n ń hu ìwà ipá, tí wọ́n sì ń ní èrò tó lòdì nípa ìfẹ́, èyí tó wọ́pọ̀ nínú ayé. Tó o bá fẹ́ ní ojúlówó ìfẹ́, o gbọ́dọ̀ fi gbogbo ara dènà ẹ̀mí ayé. (Jákọ́bù 4:7) Àmọ́, má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé okun ti ara rẹ o; ké pe Jèhófà pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́. Ẹ̀mí rẹ̀—tó jẹ́ ipá tó lágbára jù lọ ní ọ̀run òun ayé—lè fún ọ lágbára kó sì jẹ́ kó o ṣàṣeyọrí.—Sáàmù 121:2.
Kọ́ Béèyàn Ṣe Ń Nífẹ̀ẹ́ Látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Ará Tó Jẹ́ Kristẹni
Gẹ́gẹ́ báwọn ọmọdé ṣe ń kọ́ béèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́ tá a bá fìfẹ́ hàn sí wọn nínú ilé, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo wa—lọ́mọdé lágbà—lè mú ìfẹ́ dàgbà nípa bíbá àwọn ẹlòmíran tó jẹ́ Kristẹni kẹ́gbẹ́. (Jòhánù 13:34, 35) Láìsí àní-àní, ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ pàtàkì tí ìjọ Kristẹni máa ń ṣe ni pé kó pèsè àyíká tá a ti lè “sún ara wa lẹ́nì kìíní kejì sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ rere.”—Hébérù 10:24, New International Version.
Àwọn tó máa ń mọrírì irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ jù lọ làwọn tó jẹ́ pé a ti “bó láwọ, a sì fọ́n wọn ká” nínú ayé aláìnífẹ̀ẹ́ tó yí wa ká yìí. (Mátíù 9:36) Ìrírí táwọn èèyàn ní ti fi hàn pé àjọṣe onífẹ̀ẹ́ téèyàn ní nígbà tó dàgbà lè borí ọ̀pọ̀ ipa búburú tí ìgbà èwe tí wọn ò ti fìfẹ́ hàn síni máa ń ní. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí gbogbo Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ máa fọ̀yàyà kí àwọn ẹni tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ wọn káàbọ̀!
“Ìfẹ́ Kì Í Kùnà Láé”
Bíbélì sọ pé “ìfẹ́ kì í kùnà láé.” (1 Kọ́ríńtì 13:8) Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Ó hàn gbangba pé ìfẹ́ yìí kì í ṣe èyí tá à ń fi hàn lóréfèé tàbí èyí tó jẹ́ ti ojú ayé. Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn—àwọn tó ń fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn mọ̀ pé èèyàn lè ní ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́, àmọ́ wọn ò jẹ́ kí ìwọ̀nyí ba ìfẹ́ tí wọ́n ní fún àwọn èèyàn bíi tiwọn jẹ́. Ní ti tòótọ́, irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:12-14.
Gbé àpẹẹrẹ Kristẹni ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ní Kòríà yẹ̀ wò. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà Ọlọ́run, ńṣe làwọn èèyàn rẹ̀ tutọ́ sókè fojú gbà á, tó sì di pé kí ó kó kúrò nílé. Àmọ́, dípò tí ì bá fi jẹ́ kí ọ̀ràn náà bí òun nínú, ńṣe ló gbàdúrà nípa rẹ̀, tó sì jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí rẹ̀ darí ìrònú òun. Lẹ́yìn ìyẹn, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ lẹ́tà sí ìdílé rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, ó sì máa ń kọ ọ́ sínú àwọn lẹ́tà náà pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn dénúdénú. Àbájáde rẹ̀ ni pé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin méjì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ti di Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ báyìí. Ìyá rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ ọkùnrin náà tún kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ inú Bíbélì. Níkẹyìn, bàbá rẹ̀, tó ti fìgbà kan ń ṣàtakò gan-an, yí èrò rẹ̀ padà. Ọmọbìnrin náà wá kọ̀wé pé: “Àwọn Kristẹni bíi tiwa ni gbogbo wa bá ṣègbéyàwó, ó ti di àwa mẹ́tàlélógún lápapọ̀ báyìí tá a jẹ́ olùjọsìn tó wà níṣọ̀kan nínú ìdílé wa. Ẹ ò rí i pé ìfẹ́ jagun mólú!
Ǹjẹ́ o fẹ́ ní ojúlówó ìfẹ́ kó o sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe bákan náà? A jẹ́ pé wàá yíjú sí Jèhófà, ẹni tó jẹ́ Orísun ànímọ́ tó níye lórí gan-an yẹn. Bẹ́ẹ̀ ni o, fi àwọn Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ́kàn, gbàdúrà pé kó fún ọ ní ẹ̀mí mímọ́, kó o sì máa dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn ará tó jẹ́ Kristẹni déédéé. (Aísáyà 11:9; Mátíù 5:5) Ẹ ò rí i bó ṣe mọ́kàn ẹni yọ̀ tó láti mọ̀ pé láìpẹ́ gbogbo ẹni ibi yóò pòórá, yóò sì ku kìkì àwọn tó ní ojúlówó ìfẹ́ Kristẹni! Ní ti tòótọ́, ìfẹ́ ló ń fúnni ní ayọ̀ àti ìyè.—Sáàmù 37:10, 11; 1 Jòhánù 3:14.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojúlówó ìfẹ́