Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fídíò Tá A Ṣe Láti Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́

Fídíò Tá A Ṣe Láti Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́

Fídíò Tá A Ṣe Láti Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́

ÀWỌN ọ̀dọ́ rí ìṣírí ńláǹlà tó máa mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀ lórí ìwà wọn gbà nígbà tí wọ́n wo fídíò Young People Ask—How Can I Make Real Friends? a Fídíò náà ní àwọn ìmọ̀ràn tó gbámúṣé látinú Ìwé Mímọ́ nínú, àwọn ọ̀rọ̀ tó tẹnu àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni jáde wà níbẹ̀, ó sì tún ní àwòkẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń wọni lákínyẹmí ara nínú, èyí tá a gbé karí ìtàn inú Bíbélì nípa Dínà. (Jẹ́nẹ́sísì, orí 34) Ohun táwọn èèyàn sọ nípa fídíò náà láti Mẹ́síkò rèé.

Martha sọ pé: “Fídíò náà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni. Ńṣe ló dà bíi pé torí tèmi gan-an ni wọ́n ṣe ṣe é jáde. Mo máa ń rò pé táwọn olùkọ́ mi àtàwọn tá a jọ wà nílé ìwé kan náà bá ṣáà ti mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mi, ìyẹn ti tó. Mo ti kùnà láti fẹ̀rí èyí hàn nípa jíjẹ́rìí fún wọn. Mo mọrírì gbogbo ìsọfúnni tí Jèhófà ń fúnni gan-an, àgàgà nígbà tó bá wọ̀ wá lọ́kàn gan-an bíi ti fídíò yìí.”

Juan Carlos sọ pé: “Fídíò yìí múni ronú jinlẹ̀ gan-an ni. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́kùnrin, mo ti ṣe àwọn àṣìṣe bíi mélòó kan, mo sì lè fi ara mi sípò àwọn kan lára àwọn tá a rí nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ yẹn. Mo gbé ìgbésí ayé méjì ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, àmọ́ mo wá rí i pé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ lè ní àbájáde tó burú jáì. Lẹ́yìn tí mo wo fídíò náà, mo ti pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.”

Sulem jẹ́wọ́ pé: “Nígbà tí mo wo fídíò náà, ọkàn mi gbọgbẹ́. Ṣáájú ìgbà yẹn, mo ti ṣíwọ́ Bíbélì kíkà, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ gbàdúrà sí Jèhófà mọ́. Nígbà tí mo fetí sí ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú fídíò náà, ó mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́ẹ̀kan sí i kí n sì máa gbàdúrà sí Jèhófà.”

Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló ń dojú kọ àwọn ọ̀dọ́ lónìí, irú ọ̀rẹ́ tí wọ́n ń kó sì sábà máa ń nípa tó lágbára lórí bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn. (Sáàmù 26:4; Òwe 13:20) Fídíò náà, Young People Ask—How Can I Make Real Friends? ń ran ọ̀pọ̀ lára wọn lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dára nínú ọ̀ràn yìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é jáde.