Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Irú Ìfẹ́ Tó Ga Jù Lọ

Irú Ìfẹ́ Tó Ga Jù Lọ

Irú Ìfẹ́ Tó Ga Jù Lọ

Ọ̀RỌ̀ Gíríìkì náà a·gaʹpe la túmọ̀ sí “ìfẹ́” ní ibi tó pọ̀ jù lọ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tàbí Májẹ̀mú Tuntun.

Nígbà tí ìwé Insight on the Scriptures a tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ń ṣàlàyé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn, ó sọ pé: “[A·gaʹpe] kì í ṣe ìfẹ́ tó ń ru boni lójú, tó dá lórí ìfàsí ọkàn lásánlàsàn, gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn èèyàn sábà máa ń rò. Àmọ́ ó jẹ́ ìfẹ́ tá a fi ìwà rere pilẹ̀ rẹ̀ tó dá lórí mímọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó wuni tó jẹ́ ọ̀ràn nípa ìlànà, ojúṣe ẹni, àti ohun tó bójú mu, tó máa ń fi gbogbo ọkàn wá ire àwọn ẹlòmíràn níbàámu pẹ̀lú ohun tó tọ́. A·gaʹpe (jẹ́ ìfẹ́) tó borí bíbániṣọ̀tá, kò ní jẹ́ kí ohun tí ẹlòmíràn ṣe múni pa ìlànà rere tì láé kò sì ní jẹ́ kéèyàn fi búburú san búburú.”

A·gaʹpe tún lè ní ìmọ̀lára tó jinlẹ̀ nínú. Àpọ́sítélì Pétérù gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan [a·gaʹpe] fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Pétérù 4:8) Látàrí èyí, a lè sọ pé a·gaʹpe ní í ṣe pẹ̀lú ọkàn kì í ṣe pẹ̀lú èrò inú nìkan. O ò ṣe gbé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi mélòó kan yẹ̀ wò, èyí tó fi bí irú ìfẹ́ tó ga lọ́lá yìí ṣe lágbára tó hàn tó sì tún jẹ́ ká mọ ibi tó nasẹ̀ dé? Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nísàlẹ̀ yìí lè ṣèrànwọ́: Mátíù 5:43-47; Jòhánù 15:12, 13; Róòmù 13:8-10; Éfésù 5:2, 25, 28; 1 Jòhánù 3:15-18; 4:16-21.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.