Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Sí Wọn?

Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Sí Wọn?

Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Sí Wọn?

NÓFÌ àti Nóò lorúkọ tí wọ́n fi ń pe Mémúfísì àti Tíbésì tí wọ́n ti fìgbà kan jẹ́ olú ìlú lílókìkí gan-an fún ilẹ̀ Íjíbítì. Nófì (Mémúfísì) wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́tàlélógún ní ìhà gúúsù ìlú Cairo, ní apá ìlà oòrùn Odò Náílì. Àmọ́ nígbà tó yá, Mémúfísì pàdánù ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú ìlú Íjíbítì. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún ṣáájú Sànmánì Tiwa, Íjíbítì ti ní olú ìlú tuntun, ìyẹn Nóò (Tíbésì), tó wà ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta kìlómítà ní ìhà gúúsù Mémúfísì. Tẹ́ńpìlì Karnak tí wọ́n sọ pé òun ni ilé títóbi jù lọ tí wọ́n tíì fi òpó kọ́ wà lára ọ̀pọ̀ tẹ́ńpìlì tí wọ́n wó lulẹ̀ ní Tíbésì. Wọ́n ya Tíbésì àti tẹ́ńpìlì Karnak rẹ̀ sí mímọ́ fún ìjọsìn Ámọ́nì tó jẹ́ olórí ọlọ́run àwọn ará Íjíbítì.

Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa Mémúfísì àti Tíbésì? A kéde ìdájọ́ búburú lórí Fáráò ilẹ̀ Íjíbítì àtàwọn ọlọ́run rẹ̀, àgàgà olú ọlọ́run, ìyẹn “Ámọ́nì láti Nóò.” (Jeremáyà 46:25, 26) A ó sì “ké” ogunlọ́gọ̀ àwọn olùjọsìn tó ń wọ́ lọ síbẹ̀ “kúrò.” (Ìsíkíẹ́lì 30:14, 15) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Gbogbo ohun tó ṣẹ́ kù fún ìjọsìn Ámọ́nì ni àwókù tẹ́ńpìlì. Ìlú Luxor òde oní wà ní apá kan lára ibi tí Tíbésì ìgbàanì wà, àwọn abúlé kéékèèké sì wà láàárín àwọn àwókù rẹ̀.

Ní ti Mémúfísì ní tirẹ̀, kò sí ohun tó ṣẹ́ kù síbẹ̀ ju àwọn ibojì rẹ̀. Louis Golding, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ sọ pé: “Fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni àwọn ará Arébíà tó ṣẹ́gun ilẹ̀ Íjíbítì fi ń lo àwọn àwókù Mémúfísì tó pọ̀ bí nǹkan míì gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ti ń kó àwọn òkúta tí wọ́n fi ń kọ́ [Cairo] tó jẹ́ olú ìlú wọn ní apá kejì odò náà. Àpapọ̀ òkúta odò Náílì àti iṣẹ́ táwọn kọ́lékọ́lé ará Arébíà ṣe dára gan-an débi pé kò sí òkúta kan tó yọ gọnbu ju ilẹ̀ dúdú náà lọ láwọn ilé tí wọ́n kọ́ sí ọ̀pọ̀ kìlómítà láàárín ìlú ìgbàanì náà.” Ní ti tòótọ́, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, Mémúfísì di ‘ohun ìyàlẹ́nu lásán . . . láìní olùgbé kankan.’—Jeremáyà 46:19.

Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ méjì péré lára ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó fi bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe pé pérépéré tó hàn. Ìparun Tíbésì àti Mémúfísì fún wa nídìí tó ṣe gúnmọ́ láti nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé kíkún nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí kò tíì nímùúṣẹ.—Sáàmù 37:10, 11, 29; Lúùkù 23:43; Ìṣípayá 21:3-5.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Fọ́tò tá a yà nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì