Lílo Ara Ẹni Fáwọn Ẹlòmíràn Ń Dín Ìṣòro Kù
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Lílo Ara Ẹni Fáwọn Ẹlòmíràn Ń Dín Ìṣòro Kù
GẸ́GẸ́ BÍ JULIÁN ARIAS ṢE SỌ Ọ́
Iṣẹ́ tí mò ń ṣe lọ́dún 1988, tí mo jẹ́ ẹni ogójì ọdún, dà bí èyí tí mìmì kan ò lè mì. Èmi ni olùdarí ẹ̀ka fún ilé iṣẹ́ ńlá kan tó ní ẹ̀ka káàkiri ayé. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe nígbà yẹn jẹ́ kí wọ́n fún mi ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rèǹtèrente kan, owó oṣù tí mò ń gbá pọ̀ gan-an, mo sì tún ní ọ́fíìsì ńlá kan tó lẹ́wà bí òṣùmàrè ní àárín gbùngbùn ìlú Madrid, ní Sípéènì. Ilé iṣẹ́ náà tiẹ̀ ń dámọ̀ràn pé èmi ni wọ́n máa fi ṣe olùdarí àgbà pátápátá lọ́jọ́ iwájú. Mi ò mọ̀ rárá nígbà yẹn pé ìgbésí ayé mi ò ní pẹ́ yí padà lójijì.
ỌJỌ́ kan nínú ọdún yẹn ni dókítà mi sọ fún mi pé mo ní àrùn kan tí wọ́n ń pè ní sclerosis, ìyẹn àrùn tó máa ń mú kí iṣan ara le gbagidi, kò sì gbóògùn. Ọkàn mi dà rú. Nígbà tí mo wá kàwé nípa ohun tí àrùn yìí lè sọ èèyàn dà, jìnnìjìnnì bò mí. a Ńṣe ni ká kúkú sọ pé inú ewu ni mo máa wà ní gbogbo ìyókù ọjọ́ ayé mi. Báwo ni mo ṣe fẹ́ gbọ́ bùkátà Milagros aya mi, àti ti Ismael ọmọ mi tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta? Báwo la ṣe máa borí ìṣòro yìí? Ibi táwọn ìbéèrè wọ̀nyí ti ń jà gùdù lọ́kàn mi ni ìṣòro mìíràn tó burú jáì tún ti yọjú.
Ní nǹkan bí oṣù kan lẹ́yìn tí dókítà mi sọ fún mi nípa irú àìsàn tó ń ṣe mi ni ọ̀gá mi pè mí sínú ọ́fíìsì rẹ̀ tó sì sọ fún mi pé àwọn èèyàn “tí ara wọ́n dá pé” ni ilé iṣẹ́ náà ń fẹ́. Ẹni tó bá sì ní àrùn abanilárajẹ́ bí èyí—kódà nígbà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú pàápàá—ò lè báwọn ṣiṣẹ́. Ojú ẹsẹ̀ yẹn ni ọ̀gá mi gbaṣẹ́ lọ́wọ́ mi. Bí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mi ṣe forí ṣánpọ́n lójijì nìyẹn!
Bí mo bá ti wà lọ́dọ̀ ìdílé mi, màá ṣe bíi pé nǹkankan ò ṣe mí, àmọ́ ó máa ń wù mí kí n wà lémi nìkan, kí n lè ronú lórí bípò nǹkan ṣe wá rí fún mi, kí n sì tún ṣàṣàrò lórí bí ọjọ́ iwájú ṣe máa rí. Mo gbìyànjú láti wá ọgbọ́n dá sí ìbànújẹ́ tó ń dorí mi kodò. Ohun tó dùn mí jù lọ ni pé lọ́sàn-án-kan-òru-kan ni mo dẹni ẹ̀kọ̀ tí kò wúlò mọ́ fún ilé iṣẹ́ mi.
Rírí Okun Látinú Àìlera
Mo dúpẹ́ pé àwọn ọ̀nà bíi mélòó kan wà tí mo ti lè rí okun gbà lákòókò tí nǹkan le koko fún mi yìí. Mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní nǹkan bí ogún ọdún ṣáájú àkókò yẹn. Mo wá gbàdúrà sí Jèhófà nípa ìbànújẹ́ tó ń bá mi àti nípa bí mi ò ṣe mọ bí ọjọ́ iwájú ṣe máa rí fún mi. Orísun okun gidi ni ìyàwó mi tá a jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà jẹ́ fún mi, mo tún rí ìṣírí àti ìrànwọ́ gbà látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bíi mélòó kan tí inú rere àti ìyọ́nú tí wọ́n fi hàn sí mi kúrò ní kékeré.—Òwe 17:17.
Mímọ̀ tí mo mọ̀ pé mo láwọn tí mo ní láti gbọ́ bùkátà wọn tún ṣèrànwọ́ fún mi. Mo fẹ́ tọ́ ọmọ mi dáadáa, kí n kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́, kí n bá a ṣeré, kí n sì kọ́ ọ níṣẹ́ ìwàásù. Nítorí náà, mi ò gbọ́dọ̀ bọ́hùn. Àti pé, mo tún jẹ́ alàgbà nínú ọ̀kan lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin mi sì nílò ìrànlọ́wọ́ mi gan-an. Bí mo bá jẹ́ kí ìṣòro tí mo ní jin ìgbàgbọ́ mi lẹ́sẹ̀, irú àpẹẹrẹ wo ni mo fẹ́ jẹ́ fáwọn ẹlòmíràn?
Kò sọ́gbọ́n tí mo lè dá sí i, ìgbésí ayé mi ti yí padà ní ti ara àti ní ti ìṣúnná owó—láwọn ọ̀nà kan ó mú kí nǹkan túbọ̀ burú sí i, àmọ́ láwọn ọ̀nà mìíràn, ńṣe ló jẹ́ kí nǹkan sunwọ̀n sí i. Mo ti fìgbà kan gbọ́ tí dókítà kan sọ pé: “Àìsàn kì í ba tèèyàn jẹ́; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń yí ìgbésí ayé èèyàn padà.” Mo sì ti wá rí i pé kì í ṣe gbogbo ìyípadà yẹn ló máa ń jẹ́ ìyípadà sí búburú.
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ‘ẹ̀gún tó wà nínú ẹran ara mi’ jẹ́ kí n lè túbọ̀ lóye àìlera àwọn ẹlòmíràn kí n sì bá wọn kẹ́dùn. (2 Kọ́ríńtì 12:7) Mo wá lóye ọ̀rọ̀ inú ìwé Òwe 3:5 yẹn ju ti ìgbàkígbà rí lọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.” Lékè gbogbo rẹ̀, ipò tí mo wá wà yìí jẹ́ kí n mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé àti ohun tó ń fini lọ́kàn balẹ̀, mo sì tún mọ béèyàn ṣe ń níyì lọ́wọ́ ara ẹ̀. Ohun púpọ̀ ṣì wà tí mo lè ṣe nínú ètò àjọ Jèhófà. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn wá túbọ̀ nítumọ̀ sí mi gan-an pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tuntun
Láìpẹ́ sí àkókò tí mo mọ àìsàn tó ń ṣe mi ni wọ́n pè mí sí ibi ìpàdé kan ní Madrid, níbi tí wọ́n ti dá àwọn Kristẹni tó yọ̀ǹda ara wọn lẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n á ṣe jẹ́ kí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wà láàárín àwọn oníṣègùn àtàwọn aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni wọ́n wá sọ àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn yẹn di Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn. Ìgbà tí mo nílò rẹ̀ gan-an jù lọ ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn wáyé. Mo wá rí iṣẹ́ tó dára jù, èyí tó máa fi mí lọ́kàn balẹ̀ ju iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ èyíkéyìí lọ.
Ibi ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn ni wọ́n ti sọ fún wa pé àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ yẹn yóò máa lọ sáwọn ilé ìwòsàn, wọ́n á máa fọ̀rọ̀ wá àwọn dókítà lẹ́nu wò, wọ́n á sì máa bá àwọn tó ń tọ́jú aláìsàn sọ̀rọ̀, ète tí wọ́n á sì fi máa ṣe gbogbo èyí ni kí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ lè wà, kó má sì sí àríyànjiyàn kankan. Àwọn ìgbìmọ̀ yìí ń ran àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn lọ́wọ́ láti wá àwọn dókítà tó máa múra tán láti ṣètọ́jú aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀gbẹ̀rì ni mi nínú ọ̀ràn ìṣègùn, mo ní láti kọ́ ohun púpọ̀ nípa èdè ìṣègùn, ìlànà ìṣègùn, àtàwọn ìṣètò ilé ìwòsàn. Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí mo fi máa padà sílé lẹ́yìn ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn, mo ti di ọkùnrin tuntun tó gbára dì dáadáa láti bójú tó iṣẹ́ tuntun tó múnú mi dùn yìí.
Ṣíṣèbẹ̀wò Sáwọn Ilé Ìwòsàn —Orísun Ìfọ̀kànbalẹ̀
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn tó ń ṣe mi túbọ̀ ń le sí i láìdábọ̀, síbẹ̀ ńṣe ni ẹrù iṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Wọ́n ti ń fún mi ní owó ìfẹ̀yìntì tí wọ́n máa ń fún àwọn aláìlera tí kò ṣiṣẹ́ mọ́, ìyẹn sì jẹ́ kí n ní àkókò láti ṣèbẹ̀wò sáwọn ilé ìwòsàn. Láìfi àwọn ìjákulẹ̀ tó máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pè, àwọn ìbẹ̀wò wọ̀nyí rọrùn fún mi, wọ́n sì tún mérè wá ju bí mo ṣe retí lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ àga onítáyà ni mò ń lò báyìí, síbẹ̀ èyí ò fi bẹ́ẹ̀ ká mi lọ́wọ́ kò. Ẹlòmíràn tá a jọ wà nínú ìgbìmọ̀ náà sábà máa ń tẹ̀ lé mi. Àti pé, bíbá àwọn tó wà lórí àga onítáyà fọ̀rọ̀ wérọ̀ kì í ṣe nǹkan àjèjì fáwọn dókítà mọ́, àwọn ìgbà mìíràn wà tó tiẹ̀ máa ń dà bíi pé wọ́n ń fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ju tàwọn mìíràn lọ nígbà tí wọ́n bá kíyè sí ìsapá tí mo ṣe láti dé ọ̀dọ̀ wọn.
Láti ọdún bíi mẹ́wàá sẹ́yìn, mo ti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn dókítà. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé ọjọ́ tá a ti kọ́kọ́ bá wọn sọ̀rọ̀ pàá ni wọ́n ti múra tán láti ṣèrànwọ́. Ojú ẹsẹ̀ ni Dókítà Juan Duarte—tó jẹ́ oníṣẹ́-abẹ ọkàn ní Madrid, tí kì í sì í fẹ́ ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn aláìsàn—múra tán láti ràn wá lọ́wọ́. Látìgbà yẹn, ó ti ṣe ohun tó lé ní igba iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ fáwọn aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí láti àwọn apá ibi púpọ̀ ní ilẹ̀ Sípéènì. Bí ọdún ti ń gorí ọdún làwọn dókítà tó ń ṣe iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àwọn ìbẹ̀wò tá à ń ṣe sọ́dọ̀ wọn déédéé wà lára ohun tíyẹn fi ṣeé ṣe, àmọ́ ìdí mìíràn tó tún fi rí bẹ́ẹ̀ ni ìtẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìṣègùn àti àwọn àbájáde rere tí wọ́n ń rí nínú ṣíṣe iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. Ó sì dá wa lójú pé Jèhófà ti bù kún ìsapá wa.
Èsì tá a rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn kan tó jẹ oníṣẹ́ abẹ ọkàn tó jẹ́ pé àwọn ọmọdé ni wọ́n máa ń tọ́jú ní tiwọn ti fún mi níṣìírí gan-an. Odindi ọdún méjì gbáko la fi lọ ságbo àwọn oníṣègùn kan tó ní àwọn oníṣẹ́ abẹ méjì àtàwọn oníṣègùn apàmọ̀lára nínú. A kó àwọn ìwé ìṣègùn tó ṣàlàyé ohun táwọn dókítà mìíràn ń ṣe lórí ọ̀ràn yìí fún wọn. Ìsapá wa mérè wa lọ́dún 1999, nígbà Ìpàdé Àpérò Ìṣègùn Iṣẹ́ Abẹ Ọkàn Àwọn Ọmọdé. Lábẹ́ ìdarí oníṣẹ́ abẹ kan tó fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn oníṣẹ́ abẹ méjì tá a ti bá sọ̀rọ̀ yẹn ṣe iṣẹ́ abẹ tó ṣòro gan-an fún ọmọ ọwọ́ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, tí òpójẹ̀ agbẹ́jẹ̀jáde rẹ̀ nílò àtúnṣe. b Mo bá àwọn òbí náà yọ̀ gan-an nígbà tí ọ̀kan lára àwọn oníṣẹ́ abẹ náà jáde látinú ibi tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ abẹ ọ̀hún, tó sì sọ pé iṣẹ́ abẹ náà ti yọrí sí rere, àwọn ò sì ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn ìdílé náà. Ní báyìí, gbogbo ìgbà làwọn dókítà méjì náà máa ń tẹ́wọ́ gba àwọn aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí láti ibi gbogbo nílẹ̀ Sípéènì.
Ohun tí mo rí i pé ó dìídì ń fún mi ní ìtẹ́lọ́rùn nípa irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ni mímọ̀ tí mo mọ̀ pé mo lè ran àwọn Kristẹni arákùnrin mi lọ́wọ́. Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé ọ̀kan lára àkókò tí nǹkan bá le fún wọn ju lọ ni wọ́n máa ń pe Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn. Ìyẹn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ, tí dókítà tó wà ní ilé ìwòsàn àgbègbè wọn ò sì fẹ́ ṣe é láìlo ẹ̀jẹ̀ tàbí tí ò tiẹ̀ mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe é láìlo ẹ̀jẹ̀. Àmọ́, inú àwọn ará dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ pé a ti ní àwọn oníṣẹ́ abẹ tí wọ́n ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa ní gbogbo ẹ̀ka ìṣègùn níhìn-ín ní Madrid. Mo ti rí i tí ojú arákùnrin kan yí padà
látorí tẹni tó ń ṣàníyàn sí tẹni tọ́kàn rẹ̀ balẹ̀, kìkì nítorí pé ó rí wa lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ nílé ìwòsàn.Agbo Àwọn Adájọ́ àti Àwọn Ìlànà Ìṣègùn
Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tún ti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn adájọ́. Láwọn àkókò ìbẹ̀wò wọ̀nyẹn, a fún wọn ní ìtẹ̀jáde kan tá a pè ní Family Care and Medical Management for Jehovah’s Witnesses, èyí tá a dìídì ṣètò láti jẹ́ kí irú àwọn aláṣẹ bẹ́ẹ̀ mọ ipò tá a dì mú lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀, kí wọ́n sì mọ̀ pé àwọn nǹkan mìíràn tá a lè lò dípò ẹ̀jẹ̀ ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Ìbẹ̀wò wọ̀nyí ṣe pàtàkì gan-an ni, nítorí pé ohun tó wọ́pọ̀ nílẹ̀ Sípéènì látijọ́ ni pé àwọn adájọ́ á pàṣẹ fáwọn dókítà pe kí wọ́n fàjẹ̀ sáwọn èèyàn lára bí aláìsàn náà tiẹ̀ sọ pé òun ò gbẹ̀jẹ̀.
Ibi iṣẹ́ àwọn adájọ́ jẹ́ ibi tó jojú ní gbèsè gan-an, débi pé nígbà àkọ́kọ́ tí mo lọ síbẹ̀, ńṣe ni mò ń wo ara mi bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkankan bí wọ́n ṣe ń yí mi gba àwọn ọ̀nà àbáwọlé wọn kọjá lórí àga onítáyà mi. Ohun tó tún wá mú kí ọ̀ràn náà burú jù ni pé a ṣèèṣì já sí ibi kan láìmọ̀, bí mo ṣe ṣubú látinú àga onítáyà mi nìyẹn tí mo si fi eékún mi lélẹ̀. Kíá làwọn adájọ́ àtàwọn agbẹjọ́rò bíi mélòó kan tí wọ́n rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi sá jáde tí wọ́n sì wá ràn mí lọ́wọ́, àmọ́ mo wo ara mi bíi dìndìnrìn níwájú wọn.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn adájọ́ náà ò mọ ìdí tá a fi wá sọ́dọ̀ àwọn, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Adájọ́ tí mo kọ́kọ́ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ ti máa ń ronú lórí ipò tá a dì mú, ó sì sọ pé òun á fẹ́ ká jọ sọ̀rọ̀ dáadáa. Nígbà tá a padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ ló bá mi ti àga onítáyà tí mo jókòó sí wọnú ọ́fíìsì rẹ̀, tó sì tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. Bí ìbẹ̀wò wa àkọ́kọ́ yìí ṣe yọrí sí rere fún èmi àti ẹnì kejì mi níṣìírí láti borí ẹ̀rù tó ń bà wá tẹ́lẹ̀, kò sì pẹ́ tá a tún fi rí àwọn àbájáde rere mìíràn.
Láàárín ọdún yẹn kan náà la fún adájọ́ mìíràn tó gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀ ní ẹ̀dà kan ìwé Family Care, ó sì ṣèlérí pé òun á ka ìsọfúnni tó wà nínú rẹ̀. Mo fún un ní nọ́ńbà tẹlifóònù mi bóyá ó lè fẹ́ bá wa sọ̀rọ̀ lórí ohun tó jẹ́ pàjáwìrì. Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà ló tẹ̀ mí láago tó sọ pé oníṣẹ́ abẹ kan sọ pé kí òun pàṣẹ pé kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sára Ẹlẹ́rìí kan tó nílò iṣẹ́ abẹ. Adájọ́ náà sọ pé òun fẹ́ ká ran òun lọ́wọ́ láti rí ojútùú tí kò ní jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tó lòdì sí yíyẹra tí Ẹlẹ́rìí náà fẹ́ yẹra fún ẹ̀jẹ̀. Kò ṣòro fún wa rárá láti rí ilé ìwòsàn mìíràn, níbi táwọn oníṣẹ́ abẹ tó wà níbẹ̀ tí ṣe iṣẹ́ abẹ náà láṣeyọrí láìlo ẹ̀jẹ̀. Inú adájọ́ náà dùn gan-an nígbà tó gbọ́ àbájáde rẹ̀, ó sì mú un dá wa lójú pé òun á wá irú ojútùú yẹn sírú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Láwọn ìgbà tí mò ń ṣèbẹ̀wò sílé ìwòsàn wọ̀nyẹn, ìbéèrè lórí àwọn ìlànà ìmọ̀ ìṣègùn sábà máa ń yọjú, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe la fẹ́ káwọn dókítà gbà ti ẹ̀tọ́ àti ẹ̀rí ọkàn àwọn aláìsàn rò. Ọ̀kan lára àwọn ọsibítù tó máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa ní Madrid pè mí láti wá kópa nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọn fẹ́ ṣe lórí ìlànà ìmọ̀ ìṣègùn. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí fún mi láǹfààní láti ṣàlàyé ojú ìwòye wa tá a gbé ka Bíbélì fún ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ògbóǹtagí ní ẹ̀ka iṣẹ́ yìí. Ó sì tún jẹ́ kí n lè mọ ọ̀pọ̀ ìpinnu líle koko táwọn dókítà ní láti ṣe.
Ọ̀kan lára àwọn tó jẹ́ olùkọ́ níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà, ìyẹn Ọ̀jọ̀gbọ́n Diego Gracia, sábà máa ń ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlànà ìmọ̀ ìṣègùn fáwọn dókítà ilẹ̀ Sípéènì tó ti gboyè àkọ́kọ́ jáde ní yunifásítì. Ọkùnrin yìí sì jẹ́ alátìlẹyìn gidi fún ẹ̀tọ́ tá a ní láti ṣèpinnu lórí ọ̀ràn ìfàjẹ̀sínilára. c Bá a ṣe máa ń kàn sí i ní gbogbo ìgbà ti jẹ́ kó ké sí àwọn aṣojú bíi mélòó kan láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Sípéènì pé kí wọ́n wá ṣàlàyé ipò tá a dì mú fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ti gboyè àkọ́kọ́ jáde, ìyẹn àwọn tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Gracia ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn kan lára wọn sì wà lára àwọn dókítà tá a gbà pé wọ́n mọṣẹ́ jù lọ lórílẹ̀-èdè náà.
Ohun Tí Mò Ń Fara Dà
Ká sòótọ́, iṣẹ́ tó fini lọ́kàn balẹ̀ tí mò ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ mi yìí kò tíì yanjú gbogbo ìṣòro tí mo ní. Àìsàn tó ń ṣe mi túbọ̀ ń burú sí i ni. Àmọ́, a dúpẹ́ pé, ọkàn mi ò rẹ̀wẹ̀sì. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ aya mi àti ọmọ mi, tí wọn ò ráhùn rí, ìyẹn ló jẹ́ kí n lè máa ṣe àwọn ojúṣe mi lọ. Tí kì í bá ṣe ti ìrànlọ́wọ́ àti ìtìlẹ́yìn wọn ni, èyí ì bá má ṣeé ṣe. Mi ò tiẹ̀ lè fúnra mi ta bọ́tìnnì ṣòkòtò mi tàbí kí n dá nìkan wọṣọ sọ́rùn ara mi. Mo máa ń gbádùn wíwàásù ní gbogbo ọjọ́ Sátidé, èmi àti Ismael, ọmọ mi la jọ máa ń jáde, òun ló máa ń tì mí káàkiri lórí àga mi tí mo fi ń ráyè bá àwọn onílé sọ̀rọ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Mo ṣì ń bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí alàgbà.
Mo ti nírìírí àwọn àkókò tọ́kàn mi dà rú gan-an láàárín ọdún méjìlá tó kọjá. Ìgbà mìíràn wà tó jẹ́ pé ipa tí àìsàn mi ń ní lórí ìdílé mi máa ń kó ìbànújẹ́ bá mi gan-an ju àìsàn náà fúnra rẹ̀ lọ. Mo mọ̀ pé kò rọrùn fún wọn, wọn ò kàn fẹ́ sọ̀rọ̀ ni. Kò tíì pẹ́ púpọ̀ báyìí, tí màmá ìyàwó mi àti bàbá mi kú láàárín ọdún kan ṣoṣo. Àárín ọdún yẹn náà ni mo dẹni tó ń fi àga onítáyà ṣe ẹsẹ̀ rìn. Àrùn mìíràn tó máa ń bani lára jẹ́ ló pa bàbá mi tó ń gbé lọ́dọ̀ wa. Ńṣe ló dà bíi pé Milagros, tó ń tọ́jú rẹ̀, ń wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí èmi náà lọ́jọ́ iwájú.
Àmọ́, apá tó dára níbẹ̀ ni pé ìdílé wá wà níṣọ̀kan bá a ṣe jọ ń kojú ìṣòro náà pa pọ̀. Èmi tí mo jẹ́ ọ̀gá ilé iṣẹ́ tẹ́lẹ̀ wá dẹni tó wà lórí àga onítáyà, àmọ́ ìgbésí ayé mi tí túbọ̀ dára sí i nítorí pé mò ń lo ara mi fún àwọn ẹlòmíràn. Lílo ara ẹni fáwọn ẹlòmíràn lè dín ìṣòro kù, Jèhófà sì ń mú ìlérí tó ṣe ṣẹ pé òun á fún wa lókun nígbà tá a bá nílò rẹ̀. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, èmi náà lè sọ ní ti tòótọ́ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:13.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àrùn sclerosis tó máa ń mú kí iṣan ara le gbagidi jẹ́ ìṣiṣẹ́ gbòdì ògóóró ẹ̀yìn. Ohun tó sì sábà máa ń fà ni pé kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, onítọ̀hún ò ní í lè nàró fúnra rẹ̀ mọ́, kò ní lè rìn mọ́, ìgbà mìíràn sì wà táwọn tó ń ṣe ò ní ríran dáadáa, tí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ò ní já geere, tàbí kí wọ́n máà tiẹ̀ lóye ohun téèyàn ń sọ fún wọn.
b Iṣẹ́ abẹ ní ìlànà Rose ni wọ́n máa ń pe irú iṣẹ́ abẹ yìí.
c Wo Ilé Ìṣọ́, February 15, 1997, ojú ìwé 19 sí 20.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Ohun Tí Aya Rẹ̀ Sọ
Gẹ́gẹ́ bí aya, gbígbé pẹ̀lú ọkọ tó ní àrùn sclerosis, tó máa ń mú kí iṣan ara le gbagidi ò rọrùn rárá—ní ti ìrònú, ní ti ìmí ẹ̀dùn àti ní ti ara pàápàá. Mo ní láti rí i pé mi ò dáwọ́ lé ohun tó ju agbára mi lọ, mi ò sì kó àwọn àníyàn tí kò ní láárí nípa ọjọ́ ọlá lé ara mi lọ́kàn. (Mátíù 6:34) Síbẹ̀síbẹ̀, yíyí ìyà mọ́ra lè jẹ́ kí ànímọ́ rere téèyàn ní fara hàn. Ìdè ìgbéyàwó wa ti lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, àjọṣe àárín èmi àti Jèhófà sì ti ṣe tímọ́tímọ́ sí i. Ìtàn ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn tó wà nínú irú ipò atánnilókun bíi tiwa ti fún mi lókun gan-an. Èmi náà ń ní ìtẹ́lọ́rùn tí Julián ń ní bó ṣe ń lo ara rẹ̀ lọ́nà tó ṣeyebíye fáwọn arákùnrin, mo sì ti rí i pé Jèhófà ò jẹ́ fi wá sílẹ̀ láé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ń yọjú lójoojúmọ́.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Ohun Tí Ọmọ Rẹ̀ Sọ
Mo ti rí àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá nínú ìfaradà bàbá mi àti ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára tó ní, mo sì máa ń wo ara mi bí ẹni tó wúlò nígbà tí mo bá ń tì í káàkiri. Mo mọ̀ pé mi ò lè máa fi gbogbo ìgbà ṣe ohun tó bá wù mi láti ṣe. Ọ̀dọ́langba ni mí báyìí, àmọ́ á wù mi kí n di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn nígbà tí mo bá dàgbà. Àwọn ìlérí inú Bíbélì ti jẹ́ kí n mọ̀ pé ìjìyà ò ní máa bá a lọ bẹ́ẹ̀, mo sì mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ni ìyà ń jẹ jù wá lọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ìyàwó mi jẹ́ orísun okun fún mi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Mò ń bá Dókítà Juan Duarte tó jẹ́ oníṣẹ́ abẹ ọkàn sọ̀rọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi àti ọmọ mi máa ń gbádùn jíjọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí