“Wò ó! Ọlọ́run Wa Nìyí”
“Wò ó! Ọlọ́run Wa Nìyí”
A gbé àwọn ìsọfúnni tá a jíròrò nínú àwọn àpilẹ̀kọ méjèèjì yìí ka ìwé Sún Mọ́ Jèhófà, tá a mú jáde láwọn àpéjọ àgbègbè tá a ṣe kárí ayé lọ́dún 2002 àti 2003.—Wo àpilẹ̀kọ náà “Ó Dí Àlàfo Tó Wà Lọ́kàn Mi,” lójú ìwé 20.
“Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí. Àwa ti ní ìrètí nínú rẹ̀, òun yóò sì gbà wá là. Jèhófà nìyí.”—AÍSÁYÀ 25:9.
1, 2. (a) Kí ni Jèhófà pe baba ńlá náà Ábúráhámù, kí lèyí sì lè mú ká máa ṣe kàyéfì nípa rẹ̀? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe mú un dá wa lójú pé àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run kì í ṣe nǹkan tọ́wọ́ ò lè tẹ̀?
“Ọ̀RẸ́ mi.” Bí Jèhófà, Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé ṣe pe Ábúráhámù baba ńlá náà nìyí. (Aísáyà 41:8) Àbí ẹ ò rí nǹkan—kí ẹ̀dá èèyàn lásánlàsàn máa bá Olúwa Ọba Aláṣẹ ọ̀run òun ayé ṣọ̀rẹ́! O lè wá máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ èmi náà á lè sún mọ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ tó bẹ́ẹ̀?’
2 Bíbélì mú kó dá wa lójú pé níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run kì í ṣe nǹkan tọ́wọ́ ò lè tẹ̀. Ábúráhámù ní irú àjọṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.” (Jákọ́bù 2:23) Bákan náà ló ṣe rí lóde òní, “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ [Jèhófà] wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.” (Òwe 3:32) Bíbélì rọ̀ wá nínú ìwé Jákọ́bù 4:8, pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” Ó ṣe kedere pé tá a bá gbé ìgbésẹ̀ láti sún mọ́ Jèhófà, òun náà á ṣe bẹ́ẹ̀. Láìsí àní-àní, ó máa sún mọ́ wa. Àmọ́ ṣé àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí wọ̀nyí wá túmọ̀ sí pé àwa—ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé—ló máa kọ́kọ́ gbégbèésẹ̀? Rárá o. Ohun tó tiẹ̀ jẹ́ kó ṣeé ṣe láti sún mọ́ Jèhófà ni pé Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ ti kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ méjì tó ṣe pàtàkì.—Sáàmù 25:14.
3. Ìgbésẹ̀ méjì wo ni Jèhófà ti gbé kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti di ọ̀rẹ́ rẹ̀?
3 Lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà ṣètò pé kí Jésù “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Ìràpadà yẹn ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Ní tiwa, àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòhánù 4:19) Dájúdájú, nígbà tó ti jẹ́ pé Ọlọ́run “ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa,” òun ló fi ìpìlẹ̀ bí a ó ṣe di ọ̀rẹ́ rẹ̀ lélẹ̀. Ìgbésẹ̀ kejì ni pé Jèhófà ti ṣí ara rẹ̀ payá fún wa. Bí a bá ń bá ẹnì kan ṣọ̀rẹ́, ohun tí yóò mú wa fà mọ́ onítọ̀hún tímọ́tímọ́ ni pé kí á mọ̀ ọ́n dáadáa, kí àwọn ànímọ́ rẹ̀ sì wù wá gidigidi. Gbé ohun tí èyí túmọ̀ sí yẹ̀ wò. Ká sọ pé Ọlọ́run ìkọ̀kọ̀ kan tí ò ṣe é mọ̀ ni Jèhófà, a ò ní lè sún mọ́ ọn láé. Àmọ́ dípò fífi ara rẹ̀ pa mọ́, Jèhófà ń fẹ́ ká mọ òun. (Aísáyà 45:19) Àwọn ọ̀rọ̀ tó lè yé wa ni Jèhófà fi ṣí ara rẹ̀ payá fún wa nínú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀—tó fi ẹ̀rí hàn pé yàtọ̀ sí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó ń fẹ́ ká mọ òun ká sì nífẹ̀ẹ́ òun gẹ́gẹ́ bíi Bàbá wa ọ̀run.
4. Kí ni a óò máa mọ̀ lára nípa Jèhófà bí a ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ sí i?
4 Ǹjẹ́ o ti rí ibi tí ọmọ kékeré kan ti ń fi bàbá rẹ̀ han àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tó sì fi orí yíyá gágá sọ fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe ọmọdé, pé, “Bàbá mi nìyẹn”? Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló yẹ kí Jèhófà ṣe rí sí àwọn tó ń sìn ín. Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan yóò wà tí àwọn olóòótọ́ èèyàn yóò kéde pé: “Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí.” (Aísáyà 25:8, 9) Bí a bá ṣe túbọ̀ ń ní ìjìnlẹ̀ òye nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tó, ni àá ṣe máa mọ̀ ọ́n lára pé Baba tó tó baba í ṣe àti Ọ̀rẹ́ tó tó ọ̀rẹ́ gan-an la ní. Dájúdájú, tá a bá lóye àwọn ànímọ́ Jèhófà, a óò rí ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ ká sún mọ́ ọn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé àwọn nǹkan tá a lè pè ní àwọn lájorí ànímọ́ mẹ́rin pàtàkì tí Jèhófà ní, ìyẹn agbára, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n, àti ìfẹ́. A máa jíròrò mẹ́ta àkọ́kọ́ lára àwọn ànímọ́ wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
“Ó Ga ní Agbára”
5. Èé ṣe tó fi bá a mu wẹ́kú pé Jèhófà nìkan ṣoṣo là ń pè ní “Olódùmarè,” àwọn ọ̀nà wo ló sì máa ń gbà lo agbára ńlá rẹ̀?
5 Jèhófà “ga ní agbára.” (Jóòbù 37:23) Jeremáyà 10:6 sọ pé: “Lọ́nàkọnà, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dà bí ìwọ, Jèhófà. O tóbi, orúkọ rẹ sì pọ̀ ní agbára ńlá.” Jèhófà ní tiẹ̀ kò dà bí ẹ̀dá èèyàn kankan nítorí pé agbára rẹ̀ kò láàlà. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé òun nìkan ṣoṣo là ń pè ní “Olódùmarè.” (Ìṣípayá 15:3) Jèhófà máa ń lo agbára ńlá rẹ̀ láti fi ṣẹ̀dá, láti fi ṣèparun, láti fi dáàbò bò àti láti fi mú nǹkan bọ̀ sípò. Gbé àpẹẹrẹ méjì péré yẹ̀ wò—ìyẹn agbára ìṣẹ̀dá àti agbára ìdáàbòboni tó ní.
6, 7. Báwo ni oòrùn ṣe lágbára tó, òtítọ́ pàtàkì wo ló sì jẹ́rìí sí?
6 Tó o bá dúró síta nígbà tójú ọjọ́ mọ́ rekete lọ́sàn-án, kí ló máa ń rà ọ́ lára? Ìtànṣán oòrùn ni. Ara iṣẹ́ tí agbára ìṣẹ̀dá Jèhófà ń ṣe lo rí yẹn. Báwo ni oòrùn tiẹ̀ ṣe lágbára tó? Bí a bá fi ohun tí a fi ń díwọ̀n ìgbóná nǹkan wọn àárín gbùngbùn oòrùn lọ́hùn-ún, ìwọ̀n ìgbóná rẹ̀ á dé orí ipele mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lórí òṣùwọ̀n ọ̀hún. Ká sọ pé ó ṣeé ṣe fún ọ láti mú èyí tí kò ju orí abẹ́rẹ́ lọ lára ibi àárín gbùngbùn oòrùn yẹn wá sórí ilẹ̀ ayé, gbígbóná tí ìwọ̀nba bíńtín yẹn máa gbóná yóò pọ̀ débi pé o kò ní lè dúró ní nǹkan bí ogóje kìlómítà síbi tó bá wà! Agbára tó ń ti ara oòrùn jáde ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan dà bí ìgbà tí ọ̀kẹ́ àìmọye àgbá bọ́ǹbù átọ́míìkì bá bú gbàù pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Síbẹ̀, ìwọ̀n tó tọ́ gẹ́lẹ́, láìjìnnà jù láìsúnmọ́ ọn jù, ni ayé wà tó ń yípo oòrùn, tí í ṣe àgbáàràgbá iná ìléru tó ń kẹ̀ rìrì yẹn. Bí ayé bá sún mọ́ ọn jù bẹ́ẹ̀, ooru rẹ̀ á fa gbogbo omi ayé gbẹ; bó bá sì jìnnà jù bẹ́ẹ̀, omi inú ayé yóò di yìnyín gbagidi. Bí èyíkéyìí nínú méjèèjì bá ṣẹlẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ayé ò ní ṣeé gbé fún ohun alààyè rárá.
7 Síbẹ̀, àwọn èèyàn ò ka oòrùn sí rárá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ló gbé ẹ̀mí wọn ró. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n pàdánù ẹ̀kọ́ tó yẹ kí wọ́n rí kọ́ lára oòrùn. Sáàmù 74:16 sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ . . . ni ó pèsè orísun ìmọ́lẹ̀ sílẹ̀, àní oòrùn.” Dájúdájú, oòrùn ń ṣe Jèhófà “Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé” lógo. (Sáàmù 146:6) Síbẹ̀, èyí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan péré lára ọ̀kẹ́ àìmọye ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run tó ń kọ́ wa nípa agbára kíkàmàmà tí Jèhófà ní. Bá a bá ṣe mọ̀ sí i tó nípa agbára ìṣẹ̀dá Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe túbọ̀ hàn sí wa tó pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba gidigidi.
8, 9. (a) Àpèjúwe wo ló jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń fẹ́ láti fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn olùjọsìn rẹ̀ kó sì dáàbò bò wọ́n? (b) Irú ìtọ́jú wo làwọn olùṣọ́ àgùntàn àkókò tá à ń kọ Bíbélì máa ń fún àwọn àgùntàn wọn, kí lèyí sì kọ́ wa nípa Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá wa?
8 Jèhófà tún máa ń lo agbára ńláǹlà tó ní láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti láti tọ́jú wọn. Bíbélì lo àwọn àkàwé tó ṣe kedere, tó sì wọni lọ́kàn gan-an láti fi ṣàpèjúwe ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun á fìṣọ́ ṣọ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, wo Aísáyà 40:11. Níbẹ̀, Jèhófà fi ara rẹ̀ wé Olùṣọ́ Àgùntàn, ó sì fi àwọn èèyàn rẹ̀ wé àgùntàn. Ibẹ̀ kà pé: “Bí olùṣọ́ àgùntàn ni yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀; oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí. Àwọn tí ń fọ́mọ lọ́mú ni yóò máa rọra dà.” Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ohun tí ẹsẹ yìí ń sọ?
9 Nínú àwọn ẹranko tí kò mọ bí wọ́n ṣe ń dáàbò bo ara wọn rárá, ti àgùntàn ló yọyẹ́. Olùṣọ́ àgùntàn ayé ìgbà tá à ń kọ Bíbélì ní láti jẹ́ onígboyà láti lè dáàbò bo àgùntàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìkookò, béárì àti kìnnìún pàápàá. (1 Sámúẹ́lì 17:34-36; Jòhánù 10:10-13) Ṣùgbọ́n àwọn ìgbà mìíràn wà tí dídáàbò bo àgùntàn àti títọ́jú rẹ̀ máa ń gba ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Bí àpẹẹrẹ, bó bá ṣẹlẹ̀ pé àgùntàn kan bímọ síbi tó jìnnà sí ọgbà ẹran, báwo ni olùṣọ́ àgùntàn náà ṣe máa dáàbò bo ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò lágbára náà? “Oókan àyà” rẹ̀, ìyẹn ibi ìṣẹ́po aṣọ rẹ̀ lápá òkè, ni yóò máa gbé e sí, bóyá fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ pàápàá. Àmọ́, báwo ni ọ̀dọ́ àgùntàn yìí yóò ṣe dé oókan àyà olùṣọ́ àgùntàn náà? Ó ṣeé ṣe kí àgùntàn náà tọ olùṣọ́ àgùntàn wá, bóyá kó tiẹ̀ máa forí nù ún lẹ́sẹ̀. Àmọ́, olùṣọ́ àgùntàn náà ni yóò fúnra rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ gbé ọ̀dọ́ àgùntàn náà lé oókan àyà rẹ̀ láti dáàbò bò ó. Àpèjúwe bí Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá wa ṣe ń fẹ́ láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kó sì tọ́jú wọ́n yìí mà tuni lára o!
10. Irú ààbò wo ni Jèhófà ń pèsè lónìí, èé ṣe tí irú ààbò bẹ́ẹ̀ sì fi ṣe pàtàkì gan-an?
10 Jèhófà ò kàn fẹnu ṣèlérí ààbò lásán, ó ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Láyé ìgbà tá a kọ Bíbélì, onírúurú ọ̀nà ìyanu ló gbà fi hàn pé òun lè “dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.” (2 Pétérù 2:9) Òde òní wá ńkọ́? A mọ̀ pé kì í lo agbára rẹ̀ láti gbà wá lọ́wọ́ gbogbo ohun tó bá sáà ti ń jẹ́ ìjábá nísinsìnyí. Àmọ́, ó ń pèsè ohun kan tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ fún wa, ìyẹn ni ààbò nípa tẹ̀mí. Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ máa ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ewu tẹ̀mí nípa pípèsè ohun tá a nílò láti lè forí ti àdánwò ká má sì jẹ́ kí àjọṣe àárín wa pẹ̀lú rẹ̀ bà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Lúùkù 11:13 sọ pé: “Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” Ipá alágbára yẹn lè fún wa lókun láti kojú àdánwò tàbí ìṣòro èyíkéyìí tá a bá dojú kọ. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Nípa ṣíṣe èyí, ńṣe ni Jèhófà ń bá wa pa ìwàláàyè wa mọ́, kì í sì í ṣe ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ ló máa fi pa á mọ́ o, títí láé ni. Tá a ba fi èrò yìí sọ́kàn, a óò lè ka ìjìyà èyíkéyìí tó lè bá wa nínú ètò ìsinsìnyí sí èyí tó jẹ́ fún “ìgbà díẹ̀, tí ó sì fúyẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 4:17) Ǹjẹ́ ọkàn wa ò fà mọ́ Ọlọ́run tó ń fi ìfẹ́ lo agbára rẹ̀ fún wa lọ́nà bẹ́ẹ̀?
“Olùfẹ́ Ìdájọ́ Òdodo ni Jèhófà”
11, 12. (a) Kí nìdí tí ìdájọ́ òdodo Jèhófà fi ń mú ká sún mọ́ ọn? (b) Ibo ni Dáfídì parí ọ̀rọ̀ sí nípa ìdájọ́ òdodo Jèhófà, báwo sì làwọn ọ̀rọ̀ onímìísí wọ̀nyí ṣe lè fún wa ní ìtùnú?
11 Ohun tó tọ́ àtèyí tó yẹ kálukú ni Jèhófà máa ń ṣe nígbà gbogbo láìsí ojúsàájú. Ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, kì í ṣe ànímọ́ aláìláàánú tó ń léni sá, ó jẹ́ ànímọ́ rere tó ń mú wa fà mọ́ Jèhófà. Bíbélì ṣe àpèjúwe kedere nípa bí ànímọ́ yìí ṣe kún fún ìyọ́nú tó. Ẹ jẹ́ ká wá gbé ọ̀nà mẹ́ta tí Jèhófà gbà ń lo ìdájọ́ òdodo rẹ̀ yẹ̀ wò.
12 Àkọ́kọ́ ni pé, ìdájọ́ òdodo Jèhófà mú kó máa fi ìṣòtítọ́ dúró ṣinṣin ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Dáfídì onísáàmù nì mọyì apá yìí nínú ìdájọ́ òdodo Jèhófà. Èrò wo ni Dáfídì fi sọ́kàn látinú ìrírí tí òun fúnra rẹ̀ ní àti ẹ̀kọ́ tó kọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa ń ṣe nǹkan? Ó sọ pé: “Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀. Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni a óò máa ṣọ́ wọn dájúdájú.” (Sáàmù 37:28) Ọ̀rọ̀ yìí mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Ó fi hàn pé Ọlọ́run wa ò ní kọ àwọn tó dúró ṣinṣin tì í sílẹ̀ láéláé. Nípa bẹ́ẹ̀, kí ọkàn wa balẹ̀ pé a ní atóófaratì tó máa tọ́jú wa. Ìdájọ́ òdodo rẹ̀ mú èyí dá wa lójú!—Òwe 2:7, 8.
13. Báwo la ṣe rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ń ṣàníyàn nípa àwọn aláìní nínú Òfin tó fún Ísírẹ́lì?
13 Ìkejì ni pé, ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run máa ń gba tàwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ rò. A rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ń ṣàníyàn nípa àwọn aláìní nínú Òfin tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bí àpẹẹrẹ, Òfin náà ṣètò kan láti rí i dájú pé a bójú tó àìní àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti àwọn opó. (Diutarónómì 24:17-21) Jèhófà mọ̀ pé nǹkan kì í fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ fún ìdílé irú wọn, ìyẹn ló fi fúnra rẹ̀ di baba Onídàájọ́ àti Olùdáàbòbò wọn. (Diutarónómì 10:17, 18) Ó kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé bí wọ́n bá fìtínà àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tí wọn kò ní olùgbèjà, òun á gbọ́ igbe wọn. Lẹ́yìn náà, ó sọ ohun tó wà nínú Ẹ́kísódù 22:22 sí 24 pé: “Ìbínú mi yóò sì ru ní ti gidi.” Òótọ́ ni pé ìbínú kì í ṣe ara ànímọ́ tó gba iwájú nínú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n téèyàn bá dìídì ń hùwà ìrẹ́jẹ, pàápàá tó bá lọ jẹ́ pé àwọn aláìní àti aláìlólùrànlọ́wọ́ lonítọ̀hún ń fìyà jẹ, ìyẹn lè mú kí ìbínú òdodo rẹ̀ ru.—Sáàmù 103:6.
14. Ẹ̀rí wo ló wúni lórí gan-an tó fi hàn pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú rárá?
14 Ìkẹta ni pé, nínú Diutarónómì 10:17, Bíbélì mú un dá wa lójú pé Jèhófà “kì í fi ojúsàájú bá ẹnikẹ́ni lò tàbí kí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.” Ọrọ̀ tàbí ìrísí ẹni kò lè tan Jèhófà jẹ, nítorí kò dà bí àwọn alágbára tàbí ọlọ́lá nínú ọmọ aráyé. Ẹ̀tanú tàbí ojúsàájú kò sí nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ rárá. Ẹ̀rí kan tó wúni lórí gan-an tó fi hàn pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú rárá nìyí: Kò fi àǹfààní dídi olùjọsìn rẹ̀ àti níní ìrètí ìyè ayérayé mọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀tọ̀kùlú kéréje kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìṣe 10:34, 35 sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” Gbogbo èèyàn làǹfààní yìí ṣí sílẹ̀ fún, láìka ipòkípò tí wọ́n bá wà, àwọ̀ ara wọn, tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé sí. Ǹjẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà ṣèdájọ́ òdodo ní tòótọ́ kọ́ nìyẹn? Dájúdájú, bá a bá túbọ̀ lóye ìdájọ́ òdodo Jèhófà a ó fà mọ́ ọn tímọ́tímọ́!
‘Ìjìnlẹ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Pọ̀ O!”
15. Kí ni ọgbọ́n, báwo sì ni Jèhófà ṣe ń fi í hàn?
15 Ọkàn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sún un láti sọ ohun tó wà nínú Róòmù 11:33, pé: ‘Ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o!’ Òótọ́ sì ni, bá a bá ń ronú nípa onírúurú ẹ̀ka ọgbọ́n àìlópin tí Jèhófà ní, dandan ni kí ẹ̀rù Ọlọ́run bani. Àmọ́, báwo la ṣe lè ṣàlàyé ànímọ́ yìí? Ńṣe ni ọgbọ́n máa ń pa ìmọ̀, ìfòyemọ̀ àti òye pọ̀ láti fi ṣàṣeyọrí nǹkan kan. Bí Jèhófà bá ti gbé ọ̀ràn karí ìmọ̀ ńláǹlà tó ní àti òye rẹ̀ jíjinlẹ̀, ìpinnu tó dára jù lọ láyé lọ́run ló máa ń ṣe, á sì mú un ṣẹ lọ́nà tó dára jù lọ.
16, 17. Báwo làwọn ohun tí Jèhófà dá ṣe jẹ́rìí sí ọgbọ́n ńláǹlà tó ní? Sọ àpẹẹrẹ kan.
16 Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀rí tó fi ọgbọ́n ńláǹlà Jèhófà hàn? Sáàmù 104:24, sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe. Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ.” Bá a bá ṣe ń mọ̀ sí i nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n rẹ̀ yóò ṣe máa yà wá lẹ́nu tó. Kódà, ẹ̀kọ́ táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti rí kọ́ lára ìṣẹ̀dá Jèhófà kúrò ní kékeré! Àní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ ẹ̀rọ kan wà tó jẹ mọ́ ìgbékalẹ̀ ara ìṣẹ̀dá àti bó ṣe ń ṣiṣẹ́ (biomimetics). Inú ẹ̀ka ẹ̀kọ́ yìí ni wọ́n ti ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè wo ìgbékalẹ̀ ara ìṣẹ̀dá láti fi ṣe èyí tó jọ ọ́.
17 Bí àpẹẹrẹ, o lè ti wo àrà tí aláǹtakùn ń fi okùn rẹ̀ dá kó sì yà ọ́ lẹ́nu. Ní tòótọ́, ohun àrà gbáà ni ọ̀nà tó gbà ń ta okùn yẹn. Òmíràn tó dà bíi pé ó ṣe tín-ín-rín jù lára okùn aláǹtakùn yẹn lágbára ju irin líle lọ, ó sì yi ju àwọn fọ́nrán òwú ẹ̀wù ayẹta ti òyìnbó lọ. Kí lèyí túmọ̀ sí gan-an? Jẹ́ ká sọ pé wọ́n sọ àwọ̀n okùn aláǹtakùn di títóbi tó fi nípọn bí àwọ̀n ìpẹja tí wọ́n ń dè mọ́ ọkọ̀ ojú omi. Tí wọ́n bá ta á dínà ọkọ̀ òfuurufú akérò tó ń fi gbogbo agbára fò lọ, ṣìnkún ló máa mú ọkọ̀ yẹn! Dájúdájú, Jèhófà “fi ọgbọ́n ṣe” gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn lóòótọ́.
18. Báwo la ṣe rí ọgbọ́n Jèhófà nínú bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀dá èèyàn ló lò láti ṣàkọsílẹ̀ Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀?
18 Inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ti lè rí ẹ̀rí tó lágbára jù lọ nípa ọgbọ́n Jèhófà. Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú rẹ̀ fi ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà gbé ìgbésí ayé hàn wá. (Aísáyà 48:17) Ṣùgbọ́n ọ̀nà tá a gbà kọ Bíbélì tún fi ọgbọ́n aláìláfiwé tí Jèhófà ní hàn pẹ̀lú. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Jèhófà fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn nípa lílò tó lo àwọn èèyàn láti kọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Ká ní àwọn áńgẹ́lì ni Jèhófà lò láti kọ Bíbélì ni, kó má lo ènìyàn, ṣé Ọ̀rọ̀ onímìísí inú rẹ̀ tó mú kó fani mọ́ra á ṣì rí bákan náà? Lóòótọ́, àwọn áńgẹ́lì ì bá gbé Jèhófà yọ lọ́nà ọlọ́lá ńlá bí wọ́n ṣe mọ̀ ọ́n, wọ́n á sì ṣàlàyé báwọn ṣe ń fọkàn sìn ín. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ìmọ̀, ìrírí àti agbára àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí pípé ti ju tiwa lọ fíìfíì, ǹjẹ́ ojú tí wọ́n fi ń wo àwọn nǹkan lè bá tiwa mu?—Hébérù 2:6, 7.
19. Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé lílò tí Ọlọ́run lo ọmọ ènìyàn láti kọ Bíbélì jẹ́ kó wọni lọ́kàn kó sì fani mọ́ra?
19 Bí Ọlọ́run ṣe lo èèyàn láti kọ Bíbélì ló jẹ́ kó wọni lọ́kàn kó sì fani mọ́ra gidigidi. Ẹlẹ́ran ara bíi tiwa náà làwọn tó kọ ọ́. Bí wọ́n ṣe jẹ́ aláìpé, onírúurú àdánwò àti pákáǹleke làwọn pẹ̀lú dojú kọ bíi tiwa. Nígbà mìíràn, wọ́n ṣàkọsílẹ̀ bí ọ̀ràn ṣe rí lára àwọn fúnra wọn àti ìjàkadì tí wọ́n ń jà. (2 Kọ́ríńtì 12:7-10) Nítorí náà, àwọn ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì kankan ì bá má lè kọ sílẹ̀ rárá ni wọ́n kọ. Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀rọ̀ Dáfídì tó wà nínú Sáàmù 51. Àkọlé sáàmù náà fi hàn pé ẹ̀yìn tí Dáfídì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tó burú jáì ló kọ ọ́. Ó tú èrò ọkàn rẹ̀ síta, ó fi hàn pé ọkàn òun bà jẹ́ gidigidi ó sì tọrọ àforíjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ẹsẹ 2 àti 3 kà pé: “Wẹ̀ mí mọ́ tónítóní kúrò nínú ìṣìnà mi, kí o sì wẹ̀ mí mọ́ àní kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nítorí èmi fúnra mi mọ àwọn ìrélànàkọjá mi, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì ń bẹ ní iwájú mi nígbà gbogbo.” Kíyè sí ẹsẹ 5, ó ní: “Wò ó! Pẹ̀lú ìṣìnà ni a bí mi nínú ìrora ìbímọ, nínú ẹ̀ṣẹ̀ sì ni ìyá mi lóyún mi.” Ẹsẹ 17 fi kún un pé: “Àwọn ẹbọ sí Ọlọ́run ni ẹ̀mí tí ó ní ìròbìnújẹ́; ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀ ni ìwọ, Ọlọ́run, kì yóò tẹ́ńbẹ́lú.” Ǹjẹ́ o kò mọ ẹ̀dùn ọkàn òǹkọ̀wé yìí lára bí? Yàtọ̀ sí ẹ̀dá aláìpé, ta ni ì bá tún lè sọ irú ọ̀rọ̀ arò bẹ́ẹ̀ látọkànwá?
20, 21. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ọgbọ́n Jèhófà ló wà nínú Bíbélì bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ló lò láti kọ ọ́? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
20 Bí Jèhófà ṣe lo ẹ̀dá èèyàn aláìpé yìí, ohun tá a nílò gẹ́lẹ́ ló fi èyí pèsè, ìyẹn ni àkọsílẹ̀ kan tí “Ọlọ́run mí sí” síbẹ̀ táwọn ànímọ́ ọmọ ènìyàn ṣì hàn nínú rẹ̀. (2 Tímótì 3:16) Láìsí àní-àní, ẹ̀mí mímọ́ ló darí àwọn òǹkọ̀wé wọ̀nyẹn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ọgbọ́n Jèhófà ni wọ́n kọ sílẹ̀ kì í ṣe ọgbọ́n tiwọn. Ọgbọ́n Ọlọ́run yìí sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé dọ́ba. Ọgbọ́n yẹn ga ju tiwa lọ gan-an débi pé Ọlọ́run fi ìfẹ́ rọ̀ wá pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Bí a bá ń ṣe bí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yẹn ṣe wí, a óò máa túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run wa ọlọ́gbọ́n gbogbo.
21 Èyí tó fani mọ́ra tó sì wuni jù nínú gbogbo ànímọ́ Jèhófà ni ìfẹ́. Àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà fi ìfẹ́ hàn la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni Jèhófà ti gbé kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti di ọ̀rẹ́ rẹ̀?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ tó ń fi agbára ìṣẹ̀dá àti agbára ìdáàbòboni Jèhófà hàn?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń fi ìdájọ́ òdodo rẹ̀ hàn?
• Báwo la ṣe rí ọgbọ́n Jèhófà nínú àwọn ohun tó dá àti nínú Bíbélì?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jèhófà ń fi ìfẹ́ tọ́jú àgùntàn Rẹ̀ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa ń gbé ọ̀dọ́ àgùntàn sí oókan àyà rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
A rí ọgbọ́n Jèhófà nínú ọ̀nà tá a gbà kọ Bíbélì