Ìdí Tá Ò Fi Lè Dá Wà Láìfi Tàwọn Ẹlòmíràn Ṣe
Ìdí Tá Ò Fi Lè Dá Wà Láìfi Tàwọn Ẹlòmíràn Ṣe
“Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan . . . bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.”—Sólómọ́nì Ọba
SÓLÓMỌ́NÌ ỌBA Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan, nítorí pé wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára wọn. Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde. Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe rí fún ẹnì kan ṣoṣo tí ó ṣubú nígbà tí kò sí ẹlòmíràn láti gbé e dìde?” (Oníwàásù 4:9, 10) Nípa báyìí, ohun tí ọlọgbọ́n tó kíyè sí ìhùwà ẹ̀dá yìí ń sọ ni pé a nílò ìbákẹ́gbẹ́ àwọn ẹlòmíràn àti pé kò dára ká máa ya ara wa láṣo. Àmọ́ o, èrò yìí kì í wulẹ̀ ṣe ti ẹ̀dá èèyàn lásán o. Ọgbọ́n Ọlọ́run àti ìmísí látọ̀dọ̀ rẹ̀ ló mú kí Sólómọ́nì sọ ọ̀rọ̀ yìí.
Ohun burúkú gbáà ni pé ká máa ya ara wa láṣo. Igi kan ò lè dágbó ṣe. Gbogbo wa la nílò okun àti ìrànlọ́wọ́ tá a bá lè rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀dá èèyàn mìíràn. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” (Òwe 18:1) Nítorí náà, kì í ṣohun tó ṣàjèjì nígbà táwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá bá gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn pé kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan kí wọ́n sì máa bá àwọn ẹlòmíràn kẹ́gbẹ́.
Ọ̀kan lára àwọn àbá tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Robert Putnam dá nípa ọ̀nà tá a lè gbà ṣàtúnṣe báwọn èèyàn ṣe ń gbé ìgbésí ayé láwùjọ ni “jíjẹ́ kí ipa tí ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ń ní túbọ̀ lágbára sí i.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ta yọ lọ́nà yìí nítorí pé wọ́n ń gbádùn ààbò nínú àwọn ìjọ tó dà bí ìdílé kárí ayé. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù, wọ́n “ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará,” tí wọ́n ní “ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (1 Pétérù 2:17) Àwọn Ẹlẹ́rìí tún yẹra fún yíya ara wọn láṣo àti àbájáde búburú tó lè ní nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn ìgbòkègbodò dáradára tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn tòótọ́ ń mú kí ọwọ́ wọn dí nínú ríran àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—2 Tímótì 2:15.
Ìfẹ́ àti Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Yí Ìgbésí Ayé Wọn Padà
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ẹgbẹ́ kan tó ṣera wọn ní òṣùṣù ọwọ̀, olúkúlùkù wọn ló sì ní ipa pàtàkì tó ń kó. Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Miguel, Froylán àti Alma Ruth yẹ̀ wò, tí wọ́n wá látinú ìdílé kan náà ní orílẹ̀-èdè Látìn-Amẹ́ríkà. Nígbà tí wọ́n bí wọn, eegun wọn láwọn ìṣòro kan tó sì sọ wọ́n di aràrá. Àga onítáyà làwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ń lò. Báwo ni ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe nípa lórí ìgbésí ayé wọn?
Miguel sọ pé: “Ojú pọ́n mi gan-an ni, àmọ́ ìgbésí ayé mi yí padà nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà. Yíya ara ẹni láṣo léwu gan-an. Dídarapọ̀ mọ́ àwọn onígbàgbọ́ bíi tèmi láwọn ìpàdé Kristẹni àti wíwà pẹ̀lú wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ti jẹ́ kí n ní ìfọ̀kànbalẹ̀.”
Alma Ruth fi kún un pé: “Àwọn ìgbà kan wà tí ìbànújẹ́ máa ń dorí mi kodò; inú mi kì í dùn rárá. Àmọ́ nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, mo rí i pé mo lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Ìyẹn sì wá di ohun tó ṣeyebíye jù lọ nínú ìgbésí ayé mi. Ìdílé mi ti ṣètìlẹ́yìn fún wa púpọ̀ púpọ̀, ìyẹn sì ti túbọ̀ mú wa ṣọ̀kan.”
Tìfẹ́tìfẹ́ ni bàbá Miguel kọ́ ọ níwèé kíkà àti kíkọ. Miguel náà wá kọ́ Froylán àti Alma Ruth. Èyí ṣe pàtàkì fún ipò tẹ̀mí wọn. Alma Ruth sọ pé: “Kíkọ́ béèyàn ṣe ń mọ̀wé kà ràn wá lọ́wọ́ gan-an nítorí pé ìyẹn á jẹ́ ká lè jẹ oúnjẹ aṣaralóore tẹ̀mí nípa kíka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì.”
Ní báyìí, Miguel ń sìn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni alàgbà. Froylán ti ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin ní ìgbà mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Alma Ruth ti mú kí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Jèhófà gbòòrò sí i nípa ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà tàbí olùpòkìkí Ìjọba náà ní àkókò kíkún látọdún 1996. Ó sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà ti jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ góńgó yìí, àwọn arábìnrin mi ọ̀wọ́n náà sì wà lẹ́yìn mi gbágbáágbá. Wọ́n mú kó ṣeé ṣe fún mi láti máa wàásù kí n sì máa kọ́ni nípa bí wọ́n ṣe ràn mí lọ́wọ́ tí mo fi lè máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́kànlá tí mo ti bẹ̀rẹ̀.”
Emelia, tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí tó sì dẹni tó ń lo àga onítáyà nítorí ọṣẹ́ tí jàǹbá náà ṣe fún ẹsẹ̀ àti eegun ẹ̀yìn rẹ̀ náà tún fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Mẹ́síkò kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1996. Emelia sọ pé: “Kó tó di pé mo mọ òtítọ́, mo ti fẹ́ gbẹ̀mí ara mi; ìgbésí ayé ti sú mi. Ńṣe ni gbogbo nǹkan tojú sú mi, ẹkún ni ṣáá lọ́sàn-án àti lóru. Àmọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà, mo rí i pé àwọn ará nífẹ̀ẹ́ mi gan-an. Bí wọ́n ṣe fìfẹ́ hàn sí mi fún mi níṣìírí púpọ̀ púpọ̀. Ọ̀kan lára àwọn alàgbà náà tiẹ̀ ti dà bí ẹ̀gbọ́n mi tàbí bàbá mi. Òun àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan máa ń fi àga onítáyà mi tì mí lọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí.”
José nìkan ló ń dá gbé, ó sì ti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1992. Ẹni àádọ́rin ọdún ni, ọdún 1990 ló sì fẹ̀yìn tì. Ńṣe ni ìbànújẹ́ máa ń dorí José kodò ṣáá tẹ́lẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn táwọn Ẹlẹ́rìí wàásù fún un, kíá ló bẹ̀rẹ̀ sí wá sáwọn ìpàdé Kristẹni. Àwọn nǹkan tó gbọ́ àtèyí tó rí níbẹ̀ Fílípì 1:1; 1 Pétérù 5:2) “Àrànṣe afúnnilókun” làwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ fún un. (Kólósè 4:11) Wọ́n máa ń mú un lọ sọ́dọ̀ dókítà, wọ́n máa ń lọ bẹ̀ ẹ́ wò nílé rẹ̀, wọ́n sì ti dúró tì í gbágbáágbá nígbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ abẹ fún un. Ó sọ pé, “Wọ́n bìkítà nípa mi. Ìdílé mi gidi ni wọ́n. Mo gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn.”
wù ú gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ó kíyè sí báwọn ará ṣe ń ṣìkẹ́ rẹ̀ ó sì wá rí i pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun. Àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ inú ìjọ tó wà ló ń bójú tó o báyìí. (Ayọ̀ Tòótọ́ Wà Nínú Fífúnni
Nígbà tí Sólómọ́nì Ọba sọ pé “ẹni méjì sàn ju ẹnì kan,” ńṣe ló ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ọ̀rọ̀ nípa bó ṣe jẹ́ pé asán ni kéèyàn máa fi gbogbo okun rẹ̀ wá ọrọ̀ nípa tara. (Oníwàásù 4:7-9) Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń wá kiri lónìí gan-an nìyẹn, kódà bí èyí tiẹ̀ túmọ̀ sí pé kí wọ́n pàdánù àjọṣe wọn láàárín ẹbí àti láàárín ará.
Ẹ̀mí ìwọra àti ìmọtara-ẹni-nìkan yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn ya ara wọn láṣo. Èyí ò sì fún wọn láyọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò mú kí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ìgbésí ayé wọn nítorí pé ìjákulẹ̀ àti àìnírètí ló wọ́pọ̀ láàárín àwọn tó nírú ẹ̀mí yìí. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, ìrírí tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí fi ipa rere tí kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń sin Jèhófà máa ń ní hàn, ìyẹn àwọn tí ìfẹ́ fún Jèhófà àti fún àwọn aládùúgbò wọn máa ń sún ṣe nǹkan. Lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, ìtìlẹ́yìn àti ìtọ́jú látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni bíi tẹni àti ìgbòkègbodò onítara nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ àwọn kókó pàtàkì láti ran àwọn èèyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí èrò ti kò dáa tó ń bá yíya ara ẹni láṣo rìn.—Òwe 17:17; Hébérù 10:24, 25.
Nígbà tó sì jẹ́ pé a nílò ara wa lẹ́nì kìíní kejì, ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé ṣíṣe àwọn nǹkan fáwọn ẹlòmíràn máa ń fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn. Albert Einstein, tí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní, sọ pé: “Ohun tẹ́nì kan bá lè ṣe fáwọn ẹlòmíràn . . . la fi ń mọ bó ti jẹ́ ẹni pàtàkì tó kì í ṣe ohun tó lè rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn.” Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí bá àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa wa Jésù Kristi mu tó sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Nítorí náà, òótọ́ ló dára pé káwọn èèyàn fìfẹ́ hàn síni o, àmọ́ fífi ìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíràn ń ṣeni láǹfààní ńláǹlà nípa tara àti nípa tẹ̀mí.
Alábòójútó arìnrìn àjò kan tó ti fi ọ̀pọ̀ ọdún bẹ àwọn ìjọ wò láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí tó sì tún ti ṣèrànwọ́ láti kọ́ àwọn ibi ìpàdé fáwọn Kristẹni tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, sọ bọ́ràn náà ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Ayọ̀ tó wà nínú lílo ara mi fún àwọn arákùnrin mi àti rírí i tí ìmọrírì hàn lójú wọn ló ń mú kí n máa wá àǹfààní láti ṣèrànwọ́. Mo ti wá mọ̀ pé fífi ìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíràn ni olórí ohun tó ń fúnni láyọ̀. Mo sì mọ̀ pé gẹ́gẹ́ bí alàgbà, a gbọ́dọ̀ dà ‘bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù . . . , bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.’”—Aísáyà 32:2.
Ó Mà Dùn Gan-an O Láti Máa Gbé Pọ̀ ní Ìṣọ̀kan!
Dájúdájú, àǹfààní ńláǹlà àti ayọ̀ tòótọ́ wà nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti nínú bíbá àwọn tó ń sin Jèhófà kẹ́gbẹ́. Onísáàmù náà sọ pé: “Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará Sáàmù 133:1) Ìṣọ̀kan ìdílé ṣe kókó láti lè fún ara wa ní ìtìlẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn Miguel, Froylán àti Alma Ruth ti fi hàn. Ẹ ò sì rí i pé ìbùkún ńláǹlà ló jẹ́ láti wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kìíní kejì nínú ìjọsìn tòótọ́! Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù ti fún àwọn Kristẹni ọkọ̀ àti aya nímọ̀ràn tán, ó kọ̀wé pé: “Lákòótán, gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú.”—1 Pétérù 3:8.
máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” (Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tòótọ́ máa ń mú àǹfààní púpọ̀ wá, ní ti ìmọ̀lára àti nípa tẹ̀mí. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ sọ̀rọ̀, ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn. . . . Nígbà gbogbo ẹ máa lépa ohun rere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì àti sí gbogbo àwọn ẹlòmíràn.”—1 Tẹsalóníkà 5:14, 15.
Nítorí náà, wá àwọn ọ̀nà tó o lè gbà ṣoore fáwọn ẹlòmíràn. ‘Máa ṣe ohun rere fún gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì fún àwọn tí ó bá ọ tan nínú ìgbàgbọ́.’ (Gálátíà 6:9, 10) Ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Bí arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan bá wà ní ipò ìhòòhò, tí ó sì ṣaláìní oúnjẹ tí ó tó fún òòjọ́, síbẹ̀ tí ẹnì kan nínú yín sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa lọ ní àlàáfíà, kí ara yín yá gágá, kí ẹ sì jẹun yó dáadáa,’ ṣùgbọ́n tí ẹ kò fún wọn ní àwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí fún ara wọn, àǹfààní wo ni ó jẹ́?” (Jákọ́bù 2:15, 16) Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí kò mù rárá. A kò gbọ́dọ̀ ‘máa mójú tó ire ti ara wa nìkan, ṣùgbọ́n ire ti ẹlòmíràn pẹ̀lú.’—Fílípì 2:4.
Ní àfikún sí ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa tara nígbà tí àìní àkànṣe bá dìde tàbí nígbà tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀, ọwọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dí gan-an bá a ṣe ń ṣe àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa láǹfààní ní ọ̀nà kan tó ṣe pàtàkì gan-an—ìyẹn nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Bí àwọn Ẹlẹ́rìí tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà ṣe ń lọ́wọ́ nínú pípolongo ìhìn ìrètí àti ìtùnú yìí jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn dénúdénú. Àmọ́ ṣá o, ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ látinú Ìwé Mímọ́ tún ń ṣèrànwọ́ láti bójú tó àìní mìíràn tí ẹ̀dá èèyàn ní. Irú àìní wo lèyí?
Bíbójútó Àìní Pàtàkì Kan
Tá a bá fẹ́ gbádùn ayọ̀ tòótọ́, a gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó gbámúṣé pẹ̀lú Ọlọ́run. Wọ́n ti sọ ọ́ pé: “Bó ṣe jẹ́ pé látìgbà ìwáṣẹ̀ títí di àkókò yìí ni ẹ̀dá èèyàn níbi gbogbo àti nígbà gbogbo ti rí i pé ó yẹ kóun ké pe ẹnì kan tó gbà gbọ́ pé ó jẹ́ ẹni gíga tó sì lágbára ju òun alára lọ, fi hàn pé ìsìn jẹ́ ohun kan tá a dá mọ́ni tó sì yẹ ká gbà bẹ́ẹ̀. . . . Ó yẹ kí ẹ̀rù bà wá, kí ẹnú yà wá, ká sì ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀, nígbà tá a bá rí bí gbogbo èèyàn kárí ayé ṣe ń wá ẹnì kan tó ga ju ẹ̀dá èèyàn lọ tí wọ́n sì ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.”—Ìwé Man Does Not Stand Alone, látọwọ́ Cressy Morrison.
Jésù Kristi sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ìgbésí ayé àwọn tó ń ya ara wọn láṣo, tí wọn kì í fẹ́ bá àwọn ẹlòmíràn ṣe kì í rí bó ṣe yẹ kó rí. Àmọ́ ṣá, èyí tó wá burú jù lọ ni pé ká sọ pé a ò ní fi ti Ẹlẹ́dàá wa ṣe. (Ìṣípayá 4:11) Ó yẹ kí níní àti lílo “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an” jẹ́ ohun pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa. (Òwe 2:1-5) Àní sẹ́, ó yẹ ká pinnu láti jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àwọn ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí nítorí pé a ò lè dá wà láìfi ti Ọlọ́run ṣe. Ìgbésí ayé tó ládùn tó lóyin tó sì ń mérè wá sinmi lórí níní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà tó jẹ́ “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 83:18.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Miguel: “Ojú pọ́n mi gan-an ni, àmọ́ ìgbésí ayé mi yí padà nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Alma Ruth: “Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, mo rí i pé mo lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Emelia: “Kó tó di pé mo mọ òtítọ́, . . . ìgbésí ayé ti sú mi”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn olùjọsìn tòótọ́ ń jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àwọn ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí