Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtùnú fún Àwọn Tó Nílò Ìrànlọ́wọ́

Ìtùnú fún Àwọn Tó Nílò Ìrànlọ́wọ́

Ìtùnú fún Àwọn Tó Nílò Ìrànlọ́wọ́

BÍBÉLÌ kì í ṣe ìwé ìṣègùn o. Ṣùgbọ́n ó ń pèsè ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ lórí bá a ṣe lè gbádùn ìgbésí ayé láìfi àwọn ìṣòro tá à ń dojú kọ pè. Ní ti tòótọ́, Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Àìpé àwa fúnra wa ló máa ń fa díẹ̀ lára àwọn àdánwò wa. Ṣùgbọ́n ta ló wà nídìí ìṣòro ẹ̀dá ènìyàn gan-an?

Bíbélì pe ẹni náà ní ẹ̀mí búburú tí í ṣe Èṣù àti Sátánì. Ó ń “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé pátá lọ́nà” òun ló sì ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣòro tó ń dé bá ẹ̀dá èèyàn. Síbẹ̀, Bíbélì tún sọ fún wa pé àkókò rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin. (Ìṣípayá 12:9, 12) Láìpẹ́, gbogbo wàhálà tí Sátánì ti fà wá sórí àwọn olùgbé ayé ni yóò dópin nígbà tí Ọlọ́run bá dá sí ọ̀ràn náà. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, ayé tuntun òdodo tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò fi òpin sí àìnírètí àti ìpayà.—2 Pétérù 3:13.

Ẹ wo bó ṣe tuni nínú tó láti mọ̀ pé ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá ènìyàn kò ní máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí láé! Àìṣèdájọ́ òdodo àti ìjìyà yóò dópin nínú Ìjọba Ọlọ́run lọ́run, lábẹ́ ìṣàkóso Jésù Kristi. Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Ọba tí Ọlọ́run yàn sípò náà ni pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.”—Sáàmù 72:12-14.

Àkókò fún ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ti sún mọ́lé. A lè gbádùn ìyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lábẹ́ àwọn ipò tó gbádùn mọ́ni. (Lúùkù 23:43; Jòhánù 17:3) Ìmọ̀ nípa àwọn ìlérí tó ń tuni nínú látinú Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí ń pèsè ìtùnú àti ìrètí fún àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Ọmọbìnrin tí ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò: Fọ́tò ILO/J. Maillard