Nígbà kan Rí àti Nísinsìnyí—Ó Rí Okun Gbà Láti Yí Padà
“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò Sì Sún Mọ́ Yín”
Nígbà kan Rí àti Nísinsìnyí—Ó Rí Okun Gbà Láti Yí Padà
OBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Sandra nílùú Mẹ́síkò sọ pé ẹni ìtanù lòun jẹ́ nínú ìdílé òun. Kíkọ̀ ni wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ tí wọn ò sì bójú tó o ní gbogbo ìgbà tó wà ní ọ̀dọ́langba. Ó sọ pé: “Kò sí èrò méjì lọ́kàn mi ní gbogbo ìgbà tí mo fi wà léwe ju pé mi ò já mọ́ ohunkóhun lọ tí mo sì máa ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí mo fi wà láàyè àti nípa ìgbésí ayé lápapọ̀.”
Nígbà tí Sandra wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, ó bẹ̀rẹ̀ sí yọ́ ọtí tí bàbá rẹ̀ bá rà sílé mu. Nígbà tó yá, òun fúnra rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ra ọtí mu ó sì tibẹ̀ di òkú ọ̀mùtí. Ó sọ pé: “Kò sóhun tó mú kí wíwàláàyè wù mí.” Nígbà tí gbogbo nǹkan sì wá tojú sú Sandra, ó bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn olóró. Ó sọ pé: “Kìkì ohun tó ń jẹ́ kí n gbàgbé àwọn ìṣòro mi làwọn nǹkan tí mo máa ń kó sínú àpamọ́wọ́ mi: ìgò ọtí kan, oògùn olóró díẹ̀ tàbí igbó díẹ̀.”
Lẹ́yìn tí Sandra jáde ní ilé ẹ̀kọ́ nípa ìṣègùn, ńṣe ló túbọ̀ wá dọ̀gá sí i nínú ọtí àmuyíràá. Ó gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara rẹ̀. Àmọ́ ó yè é.
Sandra wá ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí àti nípa tara lọ sínú oríṣiríṣi ẹ̀sìn, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. Ó ti ro ara rẹ̀ pin pé tòun ti tán, ó sì ké pe Ọlọ́run lọ́pọ̀ ìgbà pé: “Ibo gan-an lo tiẹ̀ wà? Kí ló dé tó ò ràn mí lọ́wọ́?” Àkókò tí èrò pé òun ò já mọ́ ohunkóhun yìí wá dorí rẹ̀ kodò gan-an ni ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá a sọ̀rọ̀. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn. Sandra kẹ́kọ̀ọ́ pé “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà,” èyí sì wú u lórí gan-an.—Sáàmù 34:18.
Ẹni tó ń kọ́ Sandra ní Bíbélì jẹ́ kó mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù ló máa ń mú ká sọ̀rètí nù. Sandra wá rí i pé Ọlọ́run mọ̀ dáadáa pé a ò lè kúnjú ìwọ̀n àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. (Sáàmù 51:5; Róòmù 3:23; 5:12, 18) Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ pé kì í ṣe ibi tá a kù díẹ̀ káàtó sí ni Jèhófà máa ń wò, àti pé kì í béèrè ohun tó ju agbára wa lọ lọ́wọ́ wa. Onísáàmù náà béèrè pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?”—Sáàmù 130:3.
Òtítọ́ pàtàkì kan nínú Bíbélì tó mórí Sandra wú gan-an ni ti ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Nípa ẹbọ yìí, Jèhófà lo àánú láti mú kí ẹ̀dá èèyàn onígbọràn lè ní ìdúró rere lọ́dọ̀ òun láìka àìpé wọn sí. (1 Jòhánù 2:2; 4:9, 10) Dájúdájú, a lè rí “ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa” gbà ká sì tipa bẹ́ẹ̀ borí èrò náà pé a ò já mọ́ ohunkóhun.—Éfésù 1:7.
Sandra kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye látinú àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ẹni tó mọrírì inú rere Ọlọ́run gan-an pẹ̀lú bó ṣe dárí àwọn àṣìṣe rẹ̀ àtẹ̀yìnwá jì í tó sì tì í lẹ́yìn láti borí àìlera tó ní. (Róòmù 7:15-25; 1 Kọ́ríńtì 15:9, 10) Pọ́ọ̀lù ṣàtúnṣe ìgbésí ayé rẹ̀, ‘o lu ara rẹ̀ kíkankíkan ó sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú’ kó bà a lè dúró sójú ọ̀nà tí Ọlọ́run fọwọ́ sí. (1 Kọ́ríńtì 9:27) Kò jẹ́ káwọn nǹkan bí ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ̀ tó ń wá sọ́kàn rẹ̀ sọ ọ́ dẹrú.
Àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ Sandra Sáàmù 55:22; Jákọ́bù 4:8) Nígbà tí Sandra wá rí i pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ òun, ó yí ọ̀nà tó gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ padà. Ó sọ pé: “Mo láyọ̀ pé mò ń fi gbogbo àkókò mi kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Sandra ní àǹfààní láti ran ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin àti àbúrò rẹ̀ obìnrin lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà. Bó ṣe ń bá a lọ ní ‘ṣíṣe ohun rere,’ bẹ́ẹ̀ náà ló tún ń yọ̀ǹda láti fi ìmọ̀ ìṣègùn tó ní ṣèrànwọ́ láwọn àpéjọ àgbègbè àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Gálátíà 6:10.
fojú rẹ̀ rí màbo, àmọ́ òun náà kò gbojú bọ̀rọ̀ fún wọn. Ó gbàdúrà tọkàntọkàn pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ láti borí wọn ó sì wá àánú rẹ̀. (Àwọn nǹkan tí Sandra ti jingíri sínú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ wá ńkọ́? Ó fi ìgboyà sọ pé: “Ọkàn mi ti mọ́ báyìí. N kì í mutí mọ́, n kì í mu sìgá tàbí lo oògùn olóró mọ́. Kò sóhun tí mo fẹ́ fi wọ́n ṣe. Ọwọ́ mi ti ba ohun tí mò ń wá.”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
“Ọwọ́ mi ti ba ohun tí mò ń wá”
[Box on p̣age 9]
Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Ṣe É Mú Lò
Díẹ̀ lára àwọn ìlànà Bíbélì tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ohun tó ń sọni di ẹlẹ́gbin tó ti mọ́ wọn lára rèé:
“Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Àwọn tó ti wẹ ara wọn mọ́ kúrò nínú àwọn ohun tó ń sọni di ẹlẹ́gbin, tí wọ́n ń yẹra fún àwọn ìwà tí kò mọ́ ni Ọlọ́run ń bù kún.
“Ìbẹ̀rù Jèhófà túmọ̀ sí kíkórìíra ohun búburú.” (Òwe 8:13) Ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fun Ọlọ́run ń ranni lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí kò dára, títí kan lílo oògùn olóró. Yàtọ̀ sí pé èyí á múnú Jèhófà dùn, ẹni náà tó yí padà kò ní lè kó àwọn àrùn burúkú tó máa ń dáyà foni.
‘Ẹ wà ní ìtẹríba kí ẹ sì jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso.’ (Títù 3:1) Ọ̀pọ̀ ibi ló ti lòdì sófin láti lo àwọn oògùn kan tàbí kéèyàn ní wọn lọ́wọ́. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ní àwọn oògùn tí òfin kà léèwọ̀ lọ́wọ́ wọn kì í sì í lò wọ́n.