Ǹjẹ́ o Ní “Ẹ̀mí Ìdúródeni”?
Ǹjẹ́ o Ní “Ẹ̀mí Ìdúródeni”?
“Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí!” —2 PÉTÉRÙ 3:11, 12.
1, 2. Báwo la ṣe lè ṣàpèjúwe níní “ẹ̀mí ìdúródeni” nípa ọjọ́ Jèhófà?
FOJÚ inú wo ìdílé kan tó ń retí àwọn àlejò tí wọ́n pè láti wá jẹ oúnjẹ alẹ́ lọ́dọ̀ wọn. Àkókò tí wọ́n sọ pé kí wọ́n dé ti fẹ́ tó. Ìyàwó ń lọ ó ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ló ń ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó kù kí oúnjẹ náà lè wà ní sẹpẹ́. Ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn ń ràn án lọ́wọ́ kí gbogbo nǹkan lè wà létòlétò. Ara gbogbo wọn ti wà lọ́nà. Ó dájú pé gbogbo ìdílé náà ló ń fi ìháragàgà dúró de àwọn àlejò náà tí wọ́n sì ń wọ̀nà fún oúnjẹ aládùn àti ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin tí wọ́n máa jọ gbádùn.
2 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, à ń dúró de ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an ju ìyẹn lọ. Kí ni nǹkan náà? Àní, gbogbo wa là ń dúró de “ọjọ́ Jèhófà”! Kó tóó dé, a ní láti dà bíi wòlíì Míkà, tó sọ pé: “Jèhófà ni èmi yóò máa wá. Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Míkà 7:7) Ǹjẹ́ ìyẹn túmọ̀ sí pé kéèyàn jókòó tẹtẹrẹ? Rárá o. Iṣẹ́ pọ̀ fún wa láti ṣe.
3. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé 2 Pétérù 3:11, 12, irú ẹ̀mí wo ló yẹ káwọn Kristẹni ní?
3 Àpọ́sítélì Pétérù ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí tó dáa lákòókò tá a fi ń dúró. Ó ní: “Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí!” (2 Pétérù 3:11, 12) Ṣàkíyèsí pé gbólóhùn alámì ìyanu nìyí. Kì í ṣe pé Pétérù ń béèrè ìbéèrè. Nínú àwọn ìwé onímìísí méjèèjì tó kọ, ó ṣàpèjúwe irú èèyàn tó yẹ káwọn Kristẹni jẹ́. Ó tún rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa bá a lọ ní ṣíṣe “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí Jésù Kristi fúnni ní àmì “ìparí ètò àwọn nǹkan,” síbẹ̀ àwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ dẹra nù. (Mátíù 24:3) Wọ́n ní láti máa “dúró de” wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà kí wọ́n sì máa “fi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.”
4. Kí ni ‘fífi wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí’ ní nínú?
4 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a pè ní “fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí” níhìn-ín túmọ̀ sí “yíyára kánkán.” Ká sọ tòótọ́, kò sí bá a ṣe lè fúnra wa mú kí ọjọ́ Jèhófà ‘yára kánkán.’ Ó ṣe tán a ò mọ “ọjọ́ àti wákàtí” tí Jésù Kristi yóò wá mú ìdájọ́ ṣẹ lórí àwọn ọ̀tá Bàbá rẹ̀. (Mátíù 24:36; 25:13) Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ṣàlàyé pé orísun ọ̀rọ̀ ìṣe gbólóhùn náà “yíyára kánkán” níhìn-ín túmọ̀ sí “‘láti kánjú’ ìyẹn sì wá fara jọ ‘láti jẹ́ onítara, aláápọn, tó ń ṣàníyàn nípa ohun kan.’” Nítorí náà, Pétérù ń rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti jẹ́ ẹni tó dìídì ń fọkàn fẹ́ kí ọjọ́ Jèhófà dé. Wọ́n lè ṣe èyí nípa fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí nígbà gbogbo. (2 Pétérù 3:12) Pẹ̀lú bí “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà” ṣe sún mọ́lé gan-an nísinsìnyí, àwa náà gbọ́dọ̀ ní irú ẹ̀mí ìrònú kan náà.—Jóẹ́lì 2:31.
Dúró Pẹ̀lú “Ìṣe Ìwà Mímọ́”
5. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a dìídì ń fọkàn fẹ́ láti rí “ọjọ́ Jèhófà”?
5 Tá a bá dìídì ń fọkàn fẹ́ láti la ọjọ́ Jèhófà já, a ó fi ìyẹn hàn nípa “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” wa. Gbólóhùn náà, “ìṣe ìfọkànsìn mímọ́” lè rán wa létí ìmọ̀ràn Pétérù tó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí onígbọràn ọmọ, ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ẹ ti ní tẹ́lẹ̀ rí nínú àìmọ̀kan yín, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ tí ó pè yín, kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín, nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.’”—1 Pétérù 1:14-16.
6. Tá a bá fẹ́ jẹ́ mímọ́, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
6 Láti jẹ́ mímọ́, a gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní nípa tara, ní ti èrò orí, ní ti ìwà híhù, àti nípa tẹ̀mí. Ǹjẹ́ à ń múra de “ọjọ́ Jèhófà” nípa sísọ ara wa di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tó ń bá Jèhófà jẹ́ orúkọ? Kò rọrùn láti wà ní mímọ́ tónítóní lóde òní nítorí pé ńṣe ni ìlànà ìwà rere inú ayé túbọ̀ ń jó àjórẹ̀yìn. (1 Kọ́ríńtì 7:31; 2 Tímótì 3:13) Ǹjẹ́ à ń rí i dájú pé ìlànà ìwà rere tiwa túbọ̀ ń yàtọ̀ sí ti ayé? Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká kíyè sára. Àbí ó lè jẹ́ pé ńṣe ni àwọn ìlànà tiwa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ga ju ti ayé, ń jó àjórẹ̀yìn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a ní láti gbé ìgbésẹ̀ tó dáa láti ṣàtúnṣe àwọn nǹkan ká lè mú inú Ọlọ́run dùn.
7, 8. (a) Báwo la ṣe lè fojú yẹpẹrẹ wo ìjẹ́pàtàkì kíkópa nínú “àwọn ìṣe ìwà mímọ́”? (b) Àwọn àtúnṣe wo ló lè di dandan láti ṣe?
7 Dókítà kan sọ pé, wíwọlé táwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè wọlé dé wẹ́rẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, téèyàn si lè máa wò wọ́n nínú kọ̀rọ̀ yàrá ẹ̀, ti mú káwọn tí kì í rí irú àwọn ohun tó jọ mọ́ ìṣekúṣe bẹ́ẹ̀ wò tẹ́lẹ̀ dẹni tó wá “láǹfààní àtimáa rí àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ wò bí wọ́n ṣe fẹ́” nísinsìnyí. Bá a bá ń wá irú àwọn ibi tó láwọn ohun àìmọ́ yìí kiri lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó dájú pé ńṣe là ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àṣẹ inú Bíbélì tó sọ pé “má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan.” (Aísáyà 52:11) Ǹjẹ́ a lè wá sọ tinútinú pé à ‘ń fi wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí’ nígbà náà? Àbí a lè máa sún ọjọ́ náà síwájú nínú ọkàn wa, ká máa rò pé a ṣì ní àkókò láti wẹ ara wa mọ́, bá a tiẹ̀ ń fi àwọn ohun búburú wọ̀nyí sọ èrò inú wa dìbàjẹ́ nísinsìnyí? Tá a bá rí i pé a ti ń ní ìṣòro tó ní í ṣe pẹ̀lú ohun tá à ń wí yìí, á dáa ká tètè bẹ Jèhófà o, pé kó ‘mú kí ojú wa kọjá lọ lára ohun tí kò ní láárí, kó sì pa wá mọ́ láàyè ní ọ̀nà tirẹ̀’!—Sáàmù 119:37.
8 Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lọ́mọdé lágbà ló ń tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere ti Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń yẹra fún àwọn nǹkan tó ń fani mọ́ra nínú ayé yìí. Mímọ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa ìjẹ́kánjúkánjú àkókò tá a wà yìí tí wọ́n sì tún kọbi ara sí ìkìlọ̀ Pétérù pé “ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè” ti jẹ́ kí wọ́n máa bá a lọ ní ṣíṣe “ìṣe ìwà mímọ́.” (2 Pétérù 3:10) Ìṣe wọn fi hàn pé wọ́n ń ‘dúró, wọ́n sì ń fi wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.’ a
Máa Dúró Pẹ̀lú “Àwọn Iṣẹ́ Ìfọkànsin Ọlọ́run”
9. Kí ló yẹ kí ìfọkànsin Ọlọ́run sún wa láti ṣe?
9 “Àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” tún ṣe pàtàkì tá a bá ní láti fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn. “Ìfọkànsin Ọlọ́run” ní ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run nínú, èyí tó ń sún wa láti ṣe ohun tó tọ́ ní ojú rẹ̀. Fífi ìdúróṣinṣin sún mọ́ Jèhófà ni ohun tó ń súnni ṣe àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run. Ìfẹ́ rẹ̀ ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Ọlọ́run “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Nítorí náà, ǹjẹ́ kò yẹ kí ìfọkànsin Ọlọ́run tá a ní sún wa láti fi kún bá a ṣe ń sapá láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà kí wọ́n sì fara wé e?—Éfésù 5:1.
10. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún “agbára ìtannijẹ ọrọ̀”?
10 Ìgbésí ayé wa yóò kún fún àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run bá a bá ń wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́. (Mátíù 6:33) Èyí sì kan ṣíṣàì ka àwọn ohun ìní ti ara sí bàbàrà. Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò, nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣòro láti fojú inú wo ara wa pé a lè di ẹni tí ìfẹ́ owó fọ́ lójú, síbẹ̀ á dáa ká ṣàkíyèsí pé “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀” lè “fún ọ̀rọ̀” Ọlọ́run “pa.” (Mátíù 13:22) Ó lè máà rọrùn láti gbọ́ bùkátà ara ẹni. Ohun táwọn kan wá ń rò láwọn apá ibì kan lórí ilẹ̀ ayé ni pé, táwọn bá fẹ́ gbé ìgbésí ayé tó dáa, àwọn ní láti ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti túbọ̀ rọ̀ ṣọ̀mù, bóyá káwọn tiẹ̀ fi ìdílé àwọn sílẹ̀ fún ọdún bíi mélòó kan pàápàá. Kódà àwọn kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run ti ronú lọ́nà yìí. Lílọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn lè mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti pèsè àwọn ohun ìgbàlódé fún ìdílé wọn. Àmọ́, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí ipò tẹ̀mí àwọn èèyàn wọn tí wọ́n fi sílẹ̀ nílé? Láìsí ẹni tó máa mú ipò orí lọ́nà tó yẹ nílé, ǹjẹ́ wọ́n á lè ní okun tẹ̀mí tí wọ́n nílò láti la ọjọ́ Jèhófà já?
11. Báwo ni ẹnì kan tó lọ ṣíṣẹ́ lórílẹ̀-èdè mìíràn ṣe fi hàn pé àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju ọrọ̀ lọ?
11 Ẹnì kan tó ti orílẹ̀-èdè Philippines wáṣẹ́ lọ sórílẹ̀-èdè mìíràn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Japan. Nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé ó jẹ́ ojúṣe ẹni tó wà ní ipò orí, ó wá rí i pé òun ní láti ran ìdílé òun lọ́wọ́ láti di olùjọsìn Jèhófà. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Ìyàwó rẹ̀ tó fi sílẹ̀ sílé ò fara mọ́ ẹ̀sìn tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí yìí, ó sì fẹ́ kó máa fi kìkì owó ránṣẹ́ sílé dípò tí yóò fi padà wálé láti wá kọ́ ìdílé náà ní ìgbàgbọ́ rẹ̀ tá a gbé karí Bíbélì. Àmọ́ ìjẹ́kánjúkánjú àkókò tá a wà àti ìfẹ́ tó ní fún àwọn èèyàn rẹ̀ sún un láti padà sílé. Sùúrù tó fi bá àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ̀ lò mú èrè wa. Nígbà tó yá, ìdílé rẹ̀ di èyí tó wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́, ìyàwó rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.
12. Kí nìdí tá a fi ní láti fi ire tẹ̀mí sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé?
12 A lè fi ipò tá a wà báyìí wé tàwọn tó ń gbé ilé kan tó ń jóná lọ́wọ́. Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn dúró sínú ilé náà tí iná ti ń sọ kẹ̀ù tí ò sì ní pẹ́ dà wó, kó sì máa sá sókè sódò níbẹ̀ nítorí àtikó ohun ìní rẹ̀ jáde? Dípò ìyẹn, ǹjẹ́ kò ní ṣe pàtàkì jù lọ láti gba ẹ̀mí là—ìyẹn ẹ̀mí tiwa fúnra wa, tàwọn ìdílé wa, àti tàwọn ẹlòmíràn tó ń gbé nínú ilé ọ̀hún? Tóò, ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí ti ń sún mọ́ àtidàwó báyìí, ẹ̀mí àwọn èèyàn sì wà nínú ewu. Níwọ̀n bí a ti mọ èyí, ó dájú pé a ní láti fi àwọn ohun tó jẹ́ ti ẹ̀mí sí ipò kìíní ká sì máa fi ìtara gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tó ń gba ẹ̀mí là.—1 Tímótì 4:16.
A Gbọ́dọ̀ Wà Ní “Àìléèérí”
13. Irú ipò wo la máa fẹ́ wà nígbà tí ọjọ́ Jèhófà bá dé?
13 Nígbà tí Pétérù ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì níní ẹ̀mí ìdúródeni, ó sọ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, níwọ̀n bí ẹ ti ń dúró de nǹkan wọ̀nyí, ẹ sa gbogbo ipá yín kí [Ọlọ́run] lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.” (2 Pétérù 3:14) Láfikún sí ìmọ̀ràn tí Pétérù fúnni pé ká máa kópa nínú àwọn ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ó tún tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì dídi ẹni tí Jèhófà yóò rí nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín pé a ti wẹ̀ mọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù tó níye lórí gan-an. (Ìṣípayá 7:9, 14) Èyí béèrè pé kí ẹnì kan lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù kó sì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ kó tún ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà.
14. Kí ni wíwà ní “àìléèérí” ní nínú?
14 Pétérù rọ̀ wá pé kí a sa gbogbo ipá wa kí a lè bá wa ní “àìléèérí.” Ǹjẹ́ à ń pa àwọn ẹ̀wù wa tó dúró fún ìwà àti ìṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni mọ́ ní àìléèérí, kí ayé má bàa kó àbààwọ́n bá wọn? Nígbà tá a bá rí èérí lára aṣọ wa, ojú ẹsẹ̀ la máa ń gbìyànjú láti mú un kúrò. Tó bá lọ jẹ́ aṣọ tá a fẹ́ràn gan-an ni, tìṣọ́ratìṣọ́ra la ó fi fọ èérí náà kúrò lójú ẹsẹ̀. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe wá bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀wù wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni bá ní èérí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, nítorí àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó kan nínú ìwà wa?
15. (a) Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ní láti ṣe ìṣẹ́tí fún ara wọn sétí apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ wọn? (b) Kí nìdí táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní fi yàtọ̀ sí ayé?
15 A ní kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe “ìṣẹ́tí fún ara wọn sétí apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ wọn” kí wọ́n sì “fi okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù sókè ìṣẹ́tí apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ náà.” Nítorí kí ni? Kí wọ́n lè rántí àwọn àṣẹ Jèhófà, kí wọ́n ṣègbọràn sí wọn, kí wọ́n sì “jẹ́ mímọ́” lójú Ọlọ́run wọn. (Númérì 15:38-40) Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní, a yàtọ̀ pátápátá sí ayé, nítorí pé à ń pa àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run mọ́. Bí àpẹẹrẹ, a jẹ́ mímọ́ nínú ìwà híhù, a bọ̀wọ̀ fún ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀, a sì ń yẹra fún ìbọ̀rìṣà lọ́nà èyíkéyìí. (Ìṣe 15:28, 29) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bọ̀wọ̀ fún wa nítorí ìpinnu tá a ṣe láti pa ara wa mọ́ láìní èérí.—Jákọ́bù 1:27.
A Ní Láti Wà Ní “Àìlábààwọ́n”
16. Kí ni wíwà “láìní àbààwọ́n” wé mọ́?
16 Pétérù tún sọ pé a ní láti bá wa ní “àìlábààwọ́n.” Báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Èérí ṣeé nù kúrò tàbí ká fọ̀ ọ́ kúrò, àmọ́ àbààwọ́n ò ṣeé mú kúrò. Àbààwọ́n fi hàn pé àbùkù kan ń bẹ nínú lọ́hùn-ún, pé nǹkan ò rí bó ṣe yẹ kó rí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó wà nílùú Fílípì pé: “Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn, kí ẹ lè wá jẹ́ aláìlẹ́bi àti ọlọ́wọ́-mímọ́, àwọn ọmọ Ọlọ́run láìní àbààwọ́n láàárín ìran oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó, láàárín àwọn tí ẹ̀yin ń tàn bí atànmọ́lẹ̀ nínú ayé.” (Fílípì 2:14, 15) Tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn, a óò yẹra fún ìkùnsínú àti ìjiyàn, a ó sì sin Ọlọ́run pẹ̀lú ète rere. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa yóò máa sún wa láti wàásù “ìhìn rere Ìjọba yìí.” (Mátíù 22:35-40; 24:14) Kò tán síbẹ̀ o, a óò tún máa kéde ìhìn rere náà báwọn èèyàn lápapọ̀ ò tiẹ̀ mọ ìdí tá a fi ń yọ̀ǹda àkókò wa tá a sì ń sa gbogbo ipá wa láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
17. Kí ló gbọ́dọ̀ wà lọ́kàn wa nígbà tá a bá ń fẹ́ láti ní àwọn àǹfààní nínú ìjọ Kristẹni?
17 Níwọ̀n bí a ti fẹ́ jẹ́ “aláìlábààwọ́n,” ì bá dára ká ṣàyẹ̀wò ìdí tá a fi ń ṣe gbogbo nǹkan tá à ń ṣe. A ti pa ọ̀nà tí ayé gbà ń ṣe nǹkan nítorí ìmọtara ẹni tì, irú bíi sísapá láti ní ọrọ̀ àti agbára. Bá a bá ń nàgà láti ní àǹfààní ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni, á dáa ká ní ète rere lọ́kàn, kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti fún àwọn ẹlòmíràn sì máa sún wa ṣe bẹ́ẹ̀. Ó máa ń tuni lára láti rí àwọn ọkùnrin tẹ̀mí, tí wọ́n “ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó” pẹ̀lú ayọ̀ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ láti sìnrú fún Jèhófà àtàwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tiwọn. (1 Tímótì 3:1; 2 Kọ́ríńtì 1:24) Ní ti tòótọ́, àwọn tó tóótun láti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ń ‘ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run . . . tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹní ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n wọ́n di àpẹẹrẹ fún agbo.’—1 Pétérù 5:1-4.
A Ní Láti Wà “ní Àlàáfíà”
18. Irú ànímọ́ wo la mọ̀ mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
18 Lópin gbogbo rẹ̀, Pétérù sọ fún wa pé kí a lè bá wa “ní àlàáfíà.” Kí a lè dé ojú ìwọ̀n ohun tá a béèrè yìí, a ní láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa. Pétérù tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì níní ‘ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì’ kí a sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa. (1 Pétérù 2:17; 3:10, 11; 4:8; 2 Pétérù 1:5-7) Ká tó lè wà ní àlàáfíà, a ní láti ní ìfẹ́ láàárín ara wa. (Jòhánù 13:34, 35; Éfésù 4:1, 2) Ìfẹ́ àti àlàáfíà tó wà láàárín wa sábà máa ń fara hàn gbangba nígbà tá a bá ń ṣe àwọn àpéjọ àgbáyé. Níbi àpéjọ kan ní Costa Rica lọ́dún 1999, ẹnì kan tó ń ta ìwé ìròyìn bẹ̀rẹ̀ sí bínú nítorí pé bí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò náà ṣe ń yọ̀ mọ́ àwọn tó wá ṣèpàdé tí wọ́n sì ń kí wọn káàbọ̀ kò jẹ́ káwọn èèyàn ráyè rí àtẹ tó pa. Àmọ́, nígbà tó di ọjọ́ kejì, ó kíyè sí ìfẹ́ àti àlàáfíà tó hàn gbangba nínú bí wọ́n ṣe ń kí àwọn tó wá ṣèpàdé náà tọ̀yàyàtọ̀yàyà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò náà ò mọ̀ wọ́n rí. Nígbà tó di ọjọ́ tó kẹ́yìn àpéjọ náà, ẹni tó ń ta ìwé ìròyìn náà dara pọ̀ mọ́ wọ́n láti máa kí àwọn ará káàbọ̀, ó sì sọ pé kí wọ́n wá máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
19. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa?
19 Bá a ṣe ń fi gbogbo ọkàn lépa àlàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí lè nípa lórí bá a ṣe ń fi gbogbo ọkàn dúró de ọjọ́ Jèhófà àti ayé tuntun tó ṣèlérí. (Sáàmù 37:11; 2 Pétérù 3:13) Tó bá jẹ́ pé ó ṣòro fún wa láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Ǹjẹ́ a lè fojú inú wo ara wa pé à ń gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú onítọ̀hún ní Párádísè? Bí arákùnrin kan bá ní ohun kan lòdì sí wa, a gbọ́dọ̀ ‘wá àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀’ ní kíá mọ́sá. (Mátíù 5:23, 24) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an tá a bá fẹ́ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Jèhófà.—Sáàmù 35:27; 1 Jòhánù 4:20.
20. Àwọn ọ̀nà wo ló yẹ ká máa gbà fi “ẹ̀mí ìdúródeni” hàn?
20 Ǹjẹ́ àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ‘ń dúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà, tá a sì ń fí i sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí’? Wíwà ní mímọ́ nínú ayé oníwà wíwọ́ yìí ló máa fi hàn pé ó ń wù wá láti rí òpin ìwà ibi. Iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run tá a sì ń ṣe jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé à ń yán hànhàn fún dídé ọjọ́ Jèhófà àti fún wíwàláàyè lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà. Bá a sì ṣe ń retí àtigbé nínú ayé tuntun àlàáfíà là ń rí kedere nínú bá a ṣe ń lépa àlàáfíà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nísinsìnyí. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé a ní “ẹ̀mí ìdúródeni” a sì ń ‘fi wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.’
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti rí àwọn àpẹẹrẹ, wo Ilé Ìṣọ́ ti January 1, 2000, ojú ìwé 16 àti ìwé 1997 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 51.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni ‘fífi wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí’ túmọ̀ sí?
• Báwo la ṣe ń fi “ẹ̀mí ìdúródeni” hàn nípa ọ̀nà tá a gbà ń hùwà?
• Kí nìdí táwọn “iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” fi ṣe pàtàkì?
• Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Jèhófà tó lè bá wa ní “àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà”?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
“Ẹ̀mí ìdúródeni” máa ń hàn gbangba nínú ìṣe ìwà mímọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ń gba ẹ̀mí là
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ Jèhófà, ẹ jẹ́ ká máa wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn