Yùsíbíọ̀sì—“Ṣé Ògbóǹkangí Òpìtàn Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Ni?”
Yùsíbíọ̀sì—“Ṣé Ògbóǹkangí Òpìtàn Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Ni?”
LỌ́DÚN 325 Sànmánì Tiwa, Kọnsitatáìnì, Olú Ọba Róòmù pe gbogbo àwọn bíṣọ́ọ̀bù jọ sílùú Niséà. Ìdí tó fi pè wọ́n jọ ni: láti yanjú ọ̀rọ̀ kan tó dá lórí bí Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ ṣe jẹ́ síra wọn, èyí tó ti fa arukutu ńláǹlà. Lára àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ ni Yùsíbíọ̀sì tó wá láti ìlú Kesaréà, òun làwọn èèyàn kà sí ẹni tó kàwé jù lọ lákòókò yẹn. Yùsíbíọ̀sì ti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ taápọntaápọn ó sì ti di agbèjà ìgbàgbọ́ fáwọn Kristẹni tí wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé níbi Àpérò tí wọ́n ṣe ní Niséà, “Kọnsitatáìnì fúnra rẹ̀ ló ṣalága tó sì ń tukọ̀ ìjíròrò náà, òun fúnra rẹ̀ ló ṣí aṣọ lójú . . . ọ̀ràn pàtàkì náà nípa ṣíṣàlàyé bí Ọlọ́run àti Kristi ṣe jẹ́ síra wọn gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé ìpolongo ìgbàgbọ́ tí wọ́n pín fún wọn níbi àpérò náà, èyí tó sọ pé ‘ọ̀kan lòun àti Baba jẹ́‘ . . . Ẹ̀rù olú ọba náà ba àwọn bíṣọ́ọ̀bù, gbogbo wọn pátá ló buwọ́ lu ìwé náà bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tẹ́ ọ̀pọ̀ lára wọn lọ́rùn. Àmọ́ àwọn méjì kan wà tí kò buwọ́ lù ú o.” Ṣé Yùsíbíọ̀sì wà lára àwọn wọ̀nyí? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣe yìí? Ẹ jẹ́ ká wo Yùsíbíọ̀sì délédélé—ká wo bó ṣe tóótun tó àtàwọn nǹkan tó gbé ṣe.
Ó Kọ Àwọn Ìwé Tó Gbàfiyèsí
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Palẹ́sìnì ni wọ́n ti bí Yùsíbíọ̀sì ní nǹkan bí ọdún 260 Sànmánì Tiwa. Àtìgbà tó ti wà ní kékeré ló ti bẹ̀rẹ̀ sí bá Pamphilus kẹ́gbẹ́, ìyẹn alábòójútó ìjọ tó wà ní Kesaréà. Yùsíbíọ̀sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí Pamphilus dá sílẹ̀, ó sì tibẹ̀ di akẹ́kọ̀ọ́ tó gbó ṣáṣá. Ó ka jẹ̀jẹ̀rẹ̀ ìwé níbi ìkówèésí ti Pamphilus. Yùsíbíọ̀sì gbájú mọ́ ìwé rẹ̀ gan-an ni, pàápàá jù lọ ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́. Bẹ́ẹ̀ ló tún di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn fún Pamphilus, nígbà tó tiẹ̀ yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí pe ara rẹ̀ ní “Yùsíbíọ̀sì ọmọ Pamphilus.”
Yùsíbíọ̀sì sọ ohun tó wà lórí ẹ̀mí rẹ̀, ó ní: “Ohun tó wà lórí ẹ̀mí mi ni pé kí n kọ àkọsílẹ̀ ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé nípa àwọn Àpọ́sítélì mímọ́ àti nípa àkókò tó wà láàárín ìgbà ayé Olùgbàlà wa títí di àkókò tiwa; kí n ṣàkọsílẹ̀ nípa ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì gbà ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ṣọ́ọ̀ṣì àwọn ẹlẹ́sìn; kí n sì dárúkọ àwọn tó ti ṣàkóso tí wọ́n sì ti ṣe alábòójútó nínú àwọn ìjọ tó gbajúmọ̀ jù lọ, àtàwọn tó ti fi ẹnu polongo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú ìran kọ̀ọ̀kan.”
Àwọn èèyàn ò lè gbàgbé ìwé pàtàkì kan tí Yùsíbíọ̀sì kọ tó pe orúkọ rẹ̀ ní History of the Christian Church. Nǹkan bí ọdún 324 Sànmánì Tiwa ló tẹ ìwé rẹ̀ alápá mẹ́wàá náà jáde, èyí táwọn èèyàn kà sí ìwé tó ṣe pàtàkì jù lọ nípa ìtàn ṣọ́ọ̀ṣì tá a kọ láyé àtijọ́. Àṣeyọrí tí Yùsíbíọ̀sì ṣe yìí ló sọ ọ́ di ògbóǹkangí òpìtàn àwọn ṣọ́ọ̀ṣì.
Yàtọ̀ sí ìwé Ìtàn Ṣọ́ọ̀ṣì tí Yùsíbíọ̀sì kọ, ó tún kọ ìwé Chronicle alápá méjì. Ìtàn nípa àgbáyé ló
wà nínú apá kìíní. Ní ọ̀rúndún kẹrin, ìwé yìí ló di ọba ìwé táwọn èèyàn ń ṣèwádìí nínú rẹ̀ tó bá di ọ̀ràn ìtàn àgbáyé. Apá kejì sọ àwọn déètì tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé ṣẹlẹ̀. Yùsíbíọ̀sì fa ìlà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó wá kọ orúkọ oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè, ó sì to orúkọ àwọn ọba wọn àti ìgbà tí wọ́n gorí ìtẹ́ lẹ́sẹẹsẹ.Yùsíbíọ̀sì tún kọ oríṣi ìwé ìtàn méjì mìíràn tó kàmàmà, ó pe orúkọ wọn ní Martyrs of Palestine àti Life of Constantine. Tàkọ́kọ́ jẹ́ ìtàn tó bẹ̀rẹ̀ látọdún 303 sí ọdún 310 Sànmánì Tiwa, ó sì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ajẹ́rìíkú àkókò náà. Ó ní láti jẹ́ pé Yùsíbíọ̀sì fojú ara rẹ̀ rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí. Ìwé kejì jẹ́ ìdìpọ̀ ìwé mẹ́rin èyí tó ṣe lẹ́yìn ikú Olú Ọba Kọnsitatáìnì lọ́dún 337 Sànmánì Tiwa, àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn pàtàkì ló kúnnú rẹ̀. Kò kàn ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìwé yìí lọ́nà olówuuru o, àmọ́ ńṣe ló fi gbóríyìn fáwọn ẹni ìtàn náà.
Lára àwọn ìwé tí Yùsíbíọ̀sì kọ láti fi gbèjà ẹ̀sìn ni ọ̀kan tó fi fèsì ìwé tí Hierocles kọ—ìyẹn gómìnà kan ní Róòmù tí wọ́n jọ jẹ́ alájọgbáyé. Nígbà tí Hierocles kọ̀wé ọ̀tẹ̀ tó fi kọjúùjà sáwọn Kristẹni, Yùsíbíọ̀sì fèsì ìwé náà láti gbèjà wọn. Kò tán síbẹ̀ o, odindi ìwé márùnlélọ́gbọ̀n ló tún kọ láti gbè é lẹ́yìn pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Ìwé Mímọ́ ti wá. Wọ́n sì sọ pé àwọn ìwé yìí ò lẹ́gbẹ́ wọn ò sì lọ́gbà. Mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àkọ́kọ́ lára àwọn ìwé yìí ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ohun tó tọ́ tó sì yẹ ni títẹ́wọ́ táwọn Kristẹni tẹ́wọ́ gba àwọn Ìwé Mímọ́ ti Hébérù. Ó fi ogún ìwé tó tẹ̀ lé e sọ àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé ohun tó tọ́ làwọn Kristẹni ṣe pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń fi àwọn ìlànà ẹ̀sìn àwọn Júù sílẹ̀ tí wọ́n sì ń tẹ́wọ́ gba àwọn ìlànà àti àṣà tuntun. Lápapọ̀, àwọn ìwé yìí gbèjà ẹ̀sìn Kristẹni lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe yé Yùsíbíọ̀sì.
Nǹkan bí ọgọ́rin ọdún ni Yùsíbíọ̀sì lò láyé (láti nǹkan bí 260 sí 340 Sànmánì Tiwa), ó sì di ọ̀kan lára àwọn òǹkọ̀wé tó ń kọ jẹ̀jẹ̀rẹ̀ ìwé láyé ìgbàanì. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé láwọn ọ̀rúndún mẹ́ta àkọ́kọ́ títí di àkókò Olú Ọba Kọnsitatáìnì wà lára àwọn ohun tó kọ. Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ̀, ó pa iṣẹ́ òǹkọ̀wé tó ń ṣe pọ̀ mọ́ àwọn ìgbòkègbodò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi bíṣọ́ọ̀bù Kesaréà. Òpìtàn làwọn èèyàn mọ Yùsíbíọ̀sì sí jù lọ àmọ́ ó tún jẹ́ agbèjà ìgbàgbọ́, ayàwòrán ilẹ̀, oníwàásù, aṣelámèyítọ́ àti akọ̀wé ẹ̀sìn.
Ìdí Méjì Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ To Fi Kọ Àwọn Ìwé Rẹ̀
Kí nìdí tí Yùsíbíọ̀sì fi dáwọ́ lé iṣẹ́ bàǹtàbanta bẹ́ẹ̀? Èrò tó wà lọ́kàn rẹ̀ pé àkókò tóun wà jẹ́ èyí tí aráyé á fi wọnú sànmánì tuntun jẹ́ ká rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. Ó mọ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì ti ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ìran tó ti kọjá pé ó sì yẹ kí wọ́n wà lákọọ́lẹ̀ fáwọn ìran tó ń bọ̀.
Ìdí mìíràn tún wà tí Yùsíbíọ̀sì fi ṣiṣẹ́ yìí—ìyẹn ni jíjẹ́ tó jẹ́ agbèjà ìgbàgbọ́. Ó gbà gbọ́ pé àtọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀sìn Kristẹni ti wá. Àmọ́ àwọn kan ò fara mọ́ èrò náà. Yùsíbíọ̀sì kọ̀wé pé: “Ó tún wà lórí ẹ̀mí mi láti kọ orúkọ àwọn tí wọ́n tìtorí híhùmọ̀ ohun tuntun ṣe àṣìṣe ńláǹlà, tí wọ́n sì ń pe ara wọn ni olùṣàwárí ìmọ̀, tí wọ́n ń fi àìṣòótọ́ ṣe bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì ti fìwà ìkà ṣe agbo Kristi báṣubàṣu bíi ti ìkookò, kí n kọ iye tí wọ́n jẹ́ àti ìye ìgbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.”
Ǹjẹ́ Yùsíbíọ̀sì ka ara rẹ̀ sí Kristẹni? Ó kúkú ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó pe Kristi ní “Olùgbàlà wa.” Ó sọ pé: “Mo ní in lọ́kàn . . . láti ṣàkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tó ṣẹlẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn Júù nítorí bí wọ́n ṣe dìtẹ̀ mọ́ Olùgbàlà wa, mo sì fẹ́ ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀nà tí àwọn Kèfèrí ti gbà ta ko ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtiye ìgbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, kí n sì ṣàkọsílẹ̀ ìwà àwọn tó ti gbèjà rẹ̀ lákòókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láìfi ìdálóró pè àti báwọn èèyàn ṣe fi ìdúróṣinṣin wọn hàn
ní gbangba lákòókò tiwa àti ìrànlọ́wọ́ aláàánú tí Olùgbàlà wa ti ṣe fún gbogbo wọn.”Ìwádìí Jíjinlẹ̀ Tó Ṣe
Iye ìwé tí Yùsíbíọ̀sì fúnra rẹ̀ kà àtèyí tó tọ́ka sí pọ̀ lọ jàra. Inú àwọn ìwé tí Yùsíbíọ̀sì kọ nìkan la ti gbọ́ nípa ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn ọ̀rúndún mẹ́ta àkọ́kọ́ Sànmánì Tiwa. Inú àwọn ìwé rẹ̀ nìkan la ti rí àwọn ìsọfúnni tó túbọ̀ tànmọ́lẹ̀ sórí àwọn ẹgbẹ́ kan tó jẹ́ ẹgbẹ́ pàtàkì. Orísun ìmọ̀ tí ò sí lárọ̀ọ́wọ́tó mọ́ ni wọ́n ti wá.
Àyẹ̀wò kínníkínní àti ìsapá aláápọn ni Yùsíbíọ̀sì fi máa ń ṣàkópọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó jọ pé ó mọ ọ̀nà tó fi máa ń dá àwọn ìròyìn tó ṣeé gbíyè lé àtèyí tí kò ṣe é gbíyè lé mọ̀. Iṣẹ́ rẹ̀ ò sì lábààwọ́n. Àwọn ìgbà mìíràn wà táwọn àlàyé tó ṣe nípa àwọn èèyàn kan àtohun tí wọ́n ṣe kò tọ̀nà tó tiẹ̀ ṣì wọ́n lóye pàápàá. Nígbà mìíràn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó ṣe nípa ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kù díẹ̀ káàtó. Yùsíbíọ̀sì ò tún mọ bá a ṣe ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó máa múnú àwọn èèyàn dùn. Àmọ́ o, pẹ̀lú gbogbo kùdìẹ̀kudiẹ tó fara hàn nínú àwọn ìwé rẹ̀, àwọn èèyàn ṣì ń ka wọ́n sí ọrọ̀ ṣíṣeyebíye.
Ṣé Olùfẹ́ Òtítọ́ Ni?
Ohun tó wà lórí ẹ̀mí Yùsíbíọ̀sì ni ọ̀ràn kan tó ń fa awuyewuye nípa bí Baba àti Ọmọ ṣe jẹ́ síra wọn. Ṣe Baba ló kọ́kọ́ wà ṣáájú Ọmọ, gẹ́gẹ́ bí Yùsíbíọ̀sì ṣe gbà gbọ́? Àbí ṣé Baba àti Ọmọ jùmọ̀ jẹ́ ọ̀kan ni? Ó béèrè pé: “Tó bá jẹ́ pé ọgbọọgba ni wọ́n, báwo ni Baba á ṣe jẹ́ Baba tí Ọmọ náà á sì jẹ́ Ọmọ?” Ó tiẹ̀ tún fi àwọn àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ ti ìgbágbọ́ rẹ̀ yìí lẹ́yìn, ó tọ́ka sí Jòhánù 14:28, tó sọ pé ‘Baba tóbi ju Jésù lọ,’ àti Jòhánù 17:3, níbi tá a ti sọ pé Jésù ni ẹni tí Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà “rán jáde.” Yùsíbíọ̀sì tọ́ka sí Kólósè 1:15 àti Jòhánù 1:1, ó sì sọ pé Ọmọ Ọlọ́run, tí í ṣe “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí” ni Logos tàbí Ọ̀rọ̀ náà.
Àmọ́ ó yani lẹ́nu pé níbi ìparí Àpérò tó wáyé ní Niséà, Yùsíbíọ̀sì kọ́wọ́ ti èrò tó yàtọ̀ sí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lẹ́yìn. Ó gbà pẹ̀lú ohun tí olú ọba sọ, èyí tó tako èrò rẹ̀ tó bá Ìwé Mímọ́ mu pé Ọlọ́run àti Kristi kì í ṣe ọgbọọgba.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́
Kí nìdí tí Yùsíbíọ̀sì fi juwọ́ sílẹ̀ níbi Àpérò tó wáyé ní Niséà tó sì wá kọ́wọ́ ti ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu lẹ́yìn? Ṣé ó fẹ́ lé ipò ìṣèlú ni? Kí ló lọ ṣe níbi ìpàdé náà? Lóòótọ́ ni wọ́n ké sí gbogbo àwọn bíṣọ́ọ̀bù wá síbi àpérò náà, àmọ́ ìwọ̀nba díẹ̀—ìyẹn ọ̀ọ́dúnrún—ló wá síbẹ̀. Ṣé ipò ńlá tí Yùsíbíọ̀sì wà láwùjọ ló jẹ ẹ́ lógún jù lọ ni? Kí sì nìdí tí Olú Ọba Kọnsitatáìnì fi ń kan sáárá sí i tó bẹ́ẹ̀? Ọwọ́ ọ̀tún olú ọba yìí ni Yùsíbíọ̀sì jókòó níbi àpérò náà.
Ó ṣe kedere pé Yùsíbíọ̀sì kò tẹ̀ lé ohun tí Jésù sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Òun “kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16; 18:36) Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù béèrè pé: “Ẹ̀yin panṣágà obìnrin, ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run?” (Jákọ́bù 4:4) Ìṣílétí Pọ́ọ̀lù náà sì bọ́ sí i gan-an pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́”! (2 Kọ́ríńtì 6:14) Ǹjẹ́ ká ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé bá a ṣe ń “jọ́sìn [Baba] ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”—Jòhánù 4:24.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwòrán ara amọ̀ tútù tó ṣàpèjúwe Àpérò tó wáyé ní Niséà
[Credit Line]
Scala/Art Resource, NY
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]
Pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Special Collections Library, Yunifásítì Michigan