Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Àbájáde Aláyọ̀ Tí Sùúrù àti Ìfaradà Ń Mú Wá

Àwọn Àbájáde Aláyọ̀ Tí Sùúrù àti Ìfaradà Ń Mú Wá

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Àwọn Àbájáde Aláyọ̀ Tí Sùúrù àti Ìfaradà Ń Mú Wá

JÉSÙ KRISTI sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn “ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.” Ìdí nìyẹn táwọn èèyàn fi máa ń dágunlá sí ìhìn rere Ìjọba náà lápá ibi púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Ńṣe làwọn kan tiẹ̀ máa ń pẹ̀gàn ìsìn pàápàá.—Mátíù 24:12, 14.

Àmọ́ síbẹ̀, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti sùúrù, àwọn olùpòkìkí Ìjọba ṣì ń kẹ́sẹ járí nínú kíkojú ìṣòro náà, gẹ́gẹ́ bí ìrírí tó wá láti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech yìí ṣe fi hàn.

Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì bá obìnrin kan tó tilẹ̀kùn mọ́rí sọ̀rọ̀. Nígbà tó yá, obìnrin náà rọra ṣí ilẹ̀kùn náà ó sì nawọ́ gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! táwọn Ẹlẹ́rìí náà fi lọ̀ ọ́. Ó ní “ẹ ṣeun,” ó sì palẹ̀kùn rẹ̀ dé. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà wá ń ṣe kàyéfì pé, “Ṣé ká tún padà wá sílé obìnrin yìí ni?” Ọ̀kan nínú wọn tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, pinnu láti padà lọ, àmọ́ ohun kan náà ló tún ṣẹlẹ̀, èyí sì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ fún ọdún kan gbáko.

Aṣáájú ọ̀nà náà wá pinnu pé òun gbọ́dọ̀ yí ọ̀nà tí òun ń gbà bá obìnrin náà sọ̀rọ̀ padà, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Nígbà tó tún padà lọ fún obìnrin náà láwọn ìwé ìròyìn, ó béèrè àwọn ìbéèrè ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó ní: “Ṣé àlàáfíà lo wà? Báwo lo ṣe ń gbádùn àwọn ìwé ìròyìn náà sí?” Obìnrin náà ò kọ́kọ́ dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn ìbẹ̀wò bíi mélòó kan, obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bí ọ̀rẹ́. Ìgbà kan wà tó ṣílẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu, àmọ́ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà ò tó nǹkan.

Nítorí pé obìnrin náà ń lọ́ tìkọ̀ láti bá wọn fọ̀rọ̀ wérọ̀ lẹ́nu ilẹ̀kùn rẹ̀, aṣáájú ọ̀nà yìí wá pinnu pé òun á kọ lẹ́tà kan sí i láti ṣàlàyé ìdí tóun fi ń ṣèbẹ̀wò sílé rẹ̀ àti láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ̀ ọ́. Níkẹyìn, lẹ́yìn ọdún kan àtààbọ̀ tí aṣáájú ọ̀nà yìí ti fi sùúrù sapá, ó ṣeé ṣe fún un láti bẹ̀rẹ̀ sí í bá onílé náà ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó yà á lẹ́nu gan-an, àmọ́ inú rẹ̀ dùn nígbà tí onílé náà wá sọ fún un níkẹyìn pé: “Àtìgbà tó o ti wá ń fún mi láwọn ìwé ìròyìn ni mo ti gbà pé Ọlọ́run wà.”

Láìsí àní-àní, sùúrù àti ìfaradà lè mú àbájáde rere wá nínú iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Mátíù 28:19, 20.